Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 131-133

Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.

131 Olúwa àyà mi kò gbéga,
    bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè:
bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi ọwọ́ mi lé ọ̀ràn ńlá,
    tàbí lé ohun tí ó ga jù mí lọ
Nítòótọ́ èmi mú ọkàn mi sinmi,
    mo sì mú un dákẹ́ jẹ́ẹ́,
bí ọmọ tí a ti ọwọ́ ìyá rẹ̀ gbà ní ẹnu ọmú:
    ọkàn mi rí gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí a já ní ẹnu ọmú.

Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa
    láti ìsinsin yìí lọ àti láéláé.

Orin fún ìgòkè.

132 Olúwa, rántí Dafidi
    nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.

Ẹni tí ó ti búra fún Olúwa,
    tí ó sì ṣe ìlérí fún Alágbára Jakọbu pé.
Nítòótọ́, èmi kì yóò wọ inú àgọ́ ilé mi lọ,
    bẹ́ẹ̀ èmi kì yóò gun orí àkéte mi:
Èmi kì yóò fi oorun fún ojú mi,
    tàbí òògbé fún ìpéǹpéjú mi,
Títí èmi ó fi rí ibi fún Olúwa,
    ibùjókòó fún Alágbára Jakọbu.

Kíyèsi i, àwa gbúròó rẹ̀ ni Efrata:
    àwa rí i nínú oko ẹgàn náà.
Àwa ó lọ sínú àgọ́ rẹ̀:
    àwa ó máa sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀
Olúwa, dìde sí ibi ìsinmi rẹ:
    ìwọ, àti àpótí agbára rẹ.
Kí a fi òdodo wọ àwọn àlùfáà rẹ:
    kí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ kí ó máa hó fún ayọ̀.

10 Nítorí tí Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀
    Má ṣe yí ojú ẹni òróró rẹ padà.

11 (A)Olúwa ti búra nítòótọ́ fún Dafidi:
    Òun kì yóò yípadà kúrò nínú rẹ̀,
    nínú irú-ọmọ inú rẹ ni èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ rẹ.
12 Bí àwọn ọmọ rẹ̀ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́
    àti ẹ̀rí mi tí èmi yóò kọ́ wọn,
    àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ láéláé.

13 Nítorí tí Olúwa ti yan Sioni:
    ó ti fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀.
14 Èyí ni ibi ìsinmi mi láéláé:
    níhìn-ín ni èmi yóò máa gbé:
    nítorí tí mo fẹ́ ẹ.
15 Èmi yóò bùkún oúnjẹ rẹ̀ púpọ̀púpọ̀:
    èmi yóò fi oúnjẹ tẹ́ àwọn tálákà rẹ̀ lọ́rùn.
16 Èmi yóò sì fi ìgbàlà wọ àwọn àlùfáà rẹ̀:
    àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ yóò máa hó fún ayọ̀.

17 Níbẹ̀ ni èmi yóò gbé mú ìwo Dafidi yọ̀,
    èmi ti ṣe ìlànà fìtílà kan fún ẹni òróró mi.
18 Àwọn ọ̀tá rẹ̀ ni èmi yóò fi ìtìjú wọ̀:
    ṣùgbọ́n lára òun tìkára rẹ̀ ni adé yóò máa gbilẹ̀.

Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi

133 Kíyèsi, ó ti dára ó sì ti dùn tó fún
    àwọn ará láti máa jùmọ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀.

Ó dàbí òróró ìkunra iyebíye ní orí,
    tí ó sàn dé irùngbọ̀n, àní irùngbọ̀n Aaroni:
    tí ó sì sàn sí etí aṣọ sórí rẹ̀;
Bí ìrì Hermoni
    tí o sàn sórí òkè Sioni.
Nítorí níbẹ̀ ní Olúwa gbé pàṣẹ ìbùkún,
    àní ìyè láéláé.

Saamu 140

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

140 Olúwa, gbà mi lọ́wọ́ ọkùnrin búburú u nì,
    yọ mí lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì;
Ẹni tí ń ro ìwà búburú ní inú wọn;
    nígbà gbogbo ni wọ́n ń rú ìjà sókè sí mi.
Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò,
    oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ ní abẹ́ ètè wọn.

Olúwa, pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú;
    yọ mí kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì
    ẹni tí ó ti pinnu rẹ̀ láti bi ìrìn mi ṣubú
Àwọn agbéraga ti dẹkùn sílẹ̀ fún mi àti okùn:
    wọ́n ti na àwọ̀n lẹ́bàá ọ̀nà;
    wọ́n ti kẹ́kùn sílẹ̀ fún mi.

Èmi wí fún Olúwa pé ìwọ ni Ọlọ́run mi;
    Olúwa, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
Olúwa Olódùmarè, agbára ìgbàlà mi,
    ìwọ ni ó bo orí mi mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ ìjà.
Olúwa, máa ṣe fi ìfẹ́ ènìyàn búburú fún un;
    Má ṣe kún ọgbọ́n búburú rẹ̀ lọ́wọ́;
    kí wọn kí ó máa ba à gbé ara wọn ga. Sela.

Bí ó ṣe ti orí àwọn tí ó yí mi káàkiri ni,
    jẹ́ kí ète ìka ara wọn kí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀.
10 A ó da ẹ̀yin iná sí wọn lára:
    Òun yóò wọ́ wọn lọ sínú iná,
sínú ọ̀gbun omi jíjìn,
    kí wọn kí ó má ba à le dìde mọ́.
11 Má ṣe jẹ́ kí aláhọ́n búburú fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ní ayé;
    ibi ni yóò máa dọdẹ ọkùnrin ìkà nì láti bì í ṣubú.

12 Èmi mọ̀ pé, Olúwa yóò mú ọ̀nà olùpọ́njú dúró,
    yóò sì ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tálákà
13 Nítòótọ́ àwọn olódodo yóò
    máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ;
    àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yóò máa gbé iwájú rẹ.

Saamu 142

Maskili ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú ihò òkúta. Àdúrà.

142 Èmi kígbe sókè sí Olúwa;
    Èmi gbé ohùn mi sókè sí Olúwa fún àánú.
Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú rẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú rẹ̀.

Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi,
    ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi.
Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìn
    ènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀
Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì rì i
    kò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn mi
èmi kò ní ààbò;
    kò sí ẹni tí ó náání ọkàn mi.

Èmi kígbe sí ọ, Olúwa:
    èmi wí pé, “ìwọ ni ààbò mi,
    ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè.”

Fi etí sí igbe mi,
    nítorí tí èmi wà nínú àìnírètí
gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi,
    nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ
Mú ọkàn mi jáde kúrò nínú túbú,
    kí èmi lè máa yin orúkọ rẹ.
Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò yí mi káàkiri
    nítorí ìwọ yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ba mi ṣe.

Jeremiah 26:1-16

Wọ́n fi ikú halẹ̀ mọ́ Jeremiah

26 Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìjọba ọba Jehoiakimu ọmọ Josiah tí ń ṣe ọba Juda, ọ̀rọ̀ yìí wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa: “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Dúró ní àgbàlá ilé Olúwa, kí o sì sọ fún gbogbo ènìyàn ilẹ̀ Juda tí ó ti wá láti wá jọ́sìn ní ilé Olúwa: sọ gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún ọ; má ṣaláìsọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà. Bóyá gbogbo wọn máa gbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yóò kúrò nínú ìwà búburú wọn. Èmi ó yí ọkàn padà, n kò sì ní fi ibi tí mo ti rò sí wọn ṣe wọ́n. Sọ fún wọn wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Tí ẹ kò bá fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò sì gbọ́ òfin mi, ti mo gbé kalẹ̀ níwájú yín, àti tí ẹ kò bá gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì tí mo rán sí i yín léraléra (ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọ́), nígbà náà ni èmi yóò ṣe ilé yìí bí Ṣilo, èmi yóò sì ṣe ìlú yìí ní ìfibú sí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.’ ”

Àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo ènìyàn ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jeremiah tí ó sọ ní ilé Olúwa. Ṣùgbọ́n ní kété tí Jeremiah ti parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí Olúwa pàṣẹ láti sọ; àwọn àlùfáà, àti gbogbo ènìyàn dìímú, wọ́n sì wí pé, “Kíkú ni ìwọ yóò kú! Kí ló dé tí ìwọ ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ Olúwa pé, ilé yìí yóò dàbí Ṣilo, orílẹ̀-èdè yìí yóò sì di ahoro tí kì yóò ní olùgbé.” Gbogbo àwọn ènìyàn sì kójọpọ̀ pẹ̀lú Jeremiah nínú ilé Olúwa.

10 Nígbà tí àwọn aláṣẹ Juda gbọ́ nípa nǹkan wọ̀nyí, wọ́n lọ láti ààfin ọba sí ilé Olúwa, wọ́n sì mú ààyè wọn, wọ́n jókòó ní ẹnu-ọ̀nà tuntun ilé Olúwa. 11 Àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì sọ fún àwọn aláṣẹ àti gbogbo ènìyàn pé, “Arákùnrin yìí gbọdọ̀ gba ìdájọ́ ikú nítorí pé ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórí ìlú yìí: bí ẹ̀yin ti fi etí yín gbọ́!”

12 Nígbà náà ni Jeremiah sọ fún gbogbo àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn wí pé: “Olúwa rán mi láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé yìí àti ìlú yìí, gbogbo ohun tí ẹ ti gbọ́. 13 Nísinsin yìí, tún ọ̀nà rẹ ṣe àti ìṣe rẹ, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run yín. Olúwa yóò yí ọkàn rẹ̀ padà, kò sì ní mú ohun gbogbo tí ó ti sọ jáde ní búburú ṣẹ lórí yín. 14 Bí ó bá ṣe tèmi ni, èmi wà ní ọwọ́ yín, ẹ ṣe ohun tí ẹ̀yin bá rò pé ó dára, tí ó sì tọ́ lójú yín fún mi. 15 Ẹ mọ̀ dájú pé tí ẹ bá pa mí, ẹ ó mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ wá sórí ara yín, sórí ìlú yìí àti àwọn olùgbé inú rẹ̀; nítorí pé nítòótọ́ ni Olúwa ti rán mi láti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un yín.”

16 Nígbà náà ni àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì pé, “Ẹ má ṣe pa ọkùnrin yìí nítorí ó ti bá wa sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.”

Romu 11:1-12

Àwọn Israẹli tó ṣẹ́kù

11 (A)Ǹjẹ́ mo ní: Ọlọ́run ha ta àwọn ènìyàn rẹ̀ nù bí? Kí a má ri. Nítorí Israẹli ni èmi pẹ̀lú, láti inú irú-ọmọ Abrahamu, ni ẹ̀yà Benjamini. (B)Ọlọ́run kò ta àwọn ènìyàn rẹ̀ nù ti ó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Tàbí ẹ̀yin kò mọ bí ìwé mímọ́ ti wí ní ti Elijah? Bí ó ti ń bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run fún Israẹli, wí pé: “Olúwa, wọ́n ti pa àwọn wòlíì rẹ, wọn sì ti wó àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀; èmi nìkan ṣoṣo ni ó sì kù, wọ́n sì ń wá ẹ̀mí mi.” (C)Ṣùgbọ́n ìdáhùn wo ni Ọlọ́run fi fún un? “Mo ti ṣẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ènìyàn kù sílẹ̀ fún ara mi, àwọn tí kò tẹ eékún ba fún Baali.” (D)Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni, ní àkókò yìí àṣẹ́kù àwọn ènìyàn kan wà nípa ìyànfẹ́ ti oore-ọ̀fẹ́. (E)Bí ó bá sì ṣe pé nípa ti oore-ọ̀fẹ́ ni, ǹjẹ́ kì í ṣe ti iṣẹ́ mọ́; bí bẹ́ẹ̀ kọ́ oore-ọ̀fẹ́ kì yóò jẹ́ oore-ọ̀fẹ́ mọ́. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe pé nípa ti iṣẹ́ ni, ǹjẹ́ kì í ṣe ti oore-ọ̀fẹ́ mọ́; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, iṣẹ́ kì í ṣe iṣẹ́ mọ́.

(F)Kí ha ni? Ohun tí Israẹli ń wá kiri, òun náà ni kò rí; ṣùgbọ́n àwọn ẹni àyànfẹ́ ti rí i, a sì sé àyà àwọn ìyókù le. (G)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Ọlọ́run ti fún wọn ní ẹ̀mí oorun,
    àwọn ojú tí kò le ríran
    àti àwọn etí tí kò le gbọ́rọ̀,
títí ó fi di òní olónìí yìí.”

(H)Dafidi sì wí pé:

“Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó di ìdẹ̀kùn àti tàkúté,
    ohun ìkọ̀sẹ̀ àti ẹ̀san fún wọn;
10 Jẹ́ kí ojú wọn ṣókùnkùn, kí wọn kí ó má le ríran,
    Kí wọn kí ó sì tẹ ẹ̀yìn wọn ba nígbà gbogbo.”

Ìran aláìkọlà pín nínú ìgbàlà àwọn ọmọ Israẹli

11 (I)Ǹjẹ́ mo ní, wọ́n ha kọsẹ̀ kí wọn kí ó lè ṣubú? Kí a má ri i, ṣùgbọ́n nípa ìṣubú wọn, ìgbàlà dé ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí, láti mú Israẹli jowú. 12 Ṣùgbọ́n bí ìṣubú wọn bá di ọrọ̀ ayé, àti bí ìfàsẹ́yìn wọn bá di ọrọ̀ àwọn Kèfèrí; mélòó mélòó ni kíkún ọrọ̀ wọn?

Johanu 10:19-42

19 (A)Nítorí náà ìyapa tún wà láàrín àwọn Júù nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. 20 (B)Ọ̀pọ̀ nínú wọn sì wí pé, “Ó ní ẹ̀mí èṣù, orí rẹ̀ sì dàrú; èéṣe tí ẹ̀yin fi ń gbọ́rọ̀ rẹ̀?”

21 (C)Àwọn mìíràn wí pé, “Ìwọ̀nyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ẹ̀mí èṣù lè la ojú àwọn afọ́jú bí?”

Àìgbàgbọ́ àwọn Júù

22 Àkókò náà sì jẹ́ àjọ̀dún ìyàsímímọ́ ní Jerusalẹmu, ni ìgbà òtútù. 23 (D)Jesu sì ń rìn ní tẹmpili, ní ìloro Solomoni, 24 Nítorí náà àwọn Júù wá dúró yí i ká, wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ó ti mú wa ṣe iyèméjì pẹ́ tó? Bí ìwọ bá ni Kristi náà, wí fún wa gbangba.”

25 (E)Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ti wí fún yín, ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́; iṣẹ́ tí èmi ń ṣe lórúkọ Baba mi, àwọn ni ó ń jẹ́rìí mi. 26 (F)Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbàgbọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí nínú àwọn àgùntàn mi, gẹ́gẹ́ bí mo tí wí fún yín. 27 Àwọn àgùntàn mi ń gbọ́ ohùn mi, èmi sì mọ̀ wọ́n, wọn a sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn: 28 (G)Èmi sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun; wọn kì yóò sì ṣègbé láéláé, kò sí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ mi. 29 Baba mi, ẹni tí ó fi wọ́n fún mi pọ̀ ju gbogbo wọn lọ; kò sì ṣí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ Baba mi. 30 (H)Ọ̀kan ni èmi àti Baba mi.”

31 (I)Àwọn Júù sì tún mú òkúta, láti sọ lù ú. 32 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ rere ni mo fihàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá; nítorí èwo nínú iṣẹ́ wọ̀nyí ni ẹ̀yin ṣe sọ mí ní òkúta?”

33 (J)Àwọn Júù sì dá a lóhùn pé, “Àwa kò sọ ọ́ lókùúta nítorí iṣẹ́ rere, ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀-òdì: àti nítorí ìwọ tí í ṣe ènìyàn ń fi ara rẹ pe Ọlọ́run.”

34 (K)Jesu dá wọn lóhùn pé, “A kò ha tí kọ ọ́ nínú òfin yín pé, ‘Mo ti wí pé, Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́’? 35 Bí ó bá pè wọ́n ní Ọlọ́run, àwọn ẹni tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún, a kò sì lè ba ìwé mímọ́ jẹ́. 36 Kín ni ẹyin ha ń wí ní ti ẹni tí Baba yà sọ́tọ̀, tí ó sì rán sí ayé kín lo de ti ẹ fi ẹ̀sùn kàn mi pé mò ń sọ̀rọ̀-òdì nítorí pé mo sọ pé, ‘Èmi ni ọmọ Ọlọ́run.’ 37 Bí èmi kò bá ṣe iṣẹ́ Baba mi, ẹ má ṣe gbà mí gbọ́. 38 Ṣùgbọ́n bí èmi bá ṣe wọ́n, bí ẹ̀yin kò tilẹ̀ gbà mí gbọ́, ẹ gbà iṣẹ́ náà gbọ́: kí ẹ̀yin ba à lè mọ̀, kí ó sì lè yé yín pé, Baba wà nínú mi, èmi sì wà nínú rẹ̀.” 39 (L)Wọ́n sì tún ń wá ọ̀nà láti mú un: ó sì bọ́ lọ́wọ́ wọn.

40 (M)Ó sì tún kọjá lọ sí apá kejì Jordani sí ibi tí Johanu ti kọ́kọ́ ń bamitiisi; níbẹ̀ ni ó sì jókòó. 41 Àwọn ènìyàn púpọ̀ sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Johanu kò ṣe iṣẹ́ ààmì kan: Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni ohun gbogbo tí Johanu sọ nípa ti ọkùnrin yìí.” 42 (N)Àwọn ènìyàn púpọ̀ níbẹ̀ sì gbà á gbọ́.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.