Book of Common Prayer
Òfin Olúwa ni ìfẹ́ pípé
97 Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó!
Èmi ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀
ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá.
98 Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,
nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé.
99 Èmi ní iyè inú ju gbogbo olùkọ́ mi lọ,
nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin rẹ.
100 Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ,
nítorí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.
101 Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibi
nítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ rẹ.
102 Èmi kò yà kúrò nínú òfin rẹ,
nítorí ìwọ fúnrarẹ̀ ni ó kọ́ mi.
103 Báwo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó,
ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi!
104 Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ rẹ;
nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́.
Òfin Olúwa ni fìtílà mi
105 Ọ̀rọ̀ rẹ ni fìtílà sí ẹsẹ̀ mi
àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi
106 Èmi ti ṣe ìbúra èmi sì ti tẹnumọ́ ọn
wí pé èmi yóò máa tẹ̀lé òfin òdodo rẹ.
107 A pọ́n mi lójú gidigidi;
Olúwa, sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ
108 Olúwa, gba ìyìn àtinúwá ẹnu mi,
kí o sì kọ́ mi ní òfin rẹ̀.
109 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé mi wà ni ọwọ́ mi
nígbà gbogbo,
èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
110 Àwọn ẹni búburú ti dẹ okùn sílẹ̀ fún mi,
ṣùgbọ́n èmi kò ṣìnà kúrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
111 Òfin rẹ ni ogún mi láéláé;
àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi.
112 Ọkàn mi ti lé pípa òfin rẹ mọ́
láé dé òpin.
Òfin Olúwa ni Ààbò mi
113 Èmi kórìíra àwọn ọlọ́kàn méjì,
ṣùgbọ́n èmi fẹ́ òfin rẹ.
114 Ìwọ ni ààbò mi àti asà mi;
èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
115 Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin olùṣe búburú,
kí èmi lè pa àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́!
116 Gbé mi sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ,
kí èmi kí ó lè yè
Má sì jẹ́ kí ojú ìrètí mi kí ó tì mí.
117 Gbé mi sókè, èmí yóò sì wa láìléwu;
nígbà gbogbo ni èmi yóò máa júbà òfin rẹ.
118 Ìwọ kọ gbogbo àwọn tí ó ṣìnà kúrò nínú òfin rẹ,
nítorí ẹ̀tàn wọn asán ni.
119 Gbogbo àwọn ẹni búburú ní ayé ni ìwọ yọ kúrò bí i ìdàrọ́;
nítorí náà, èmi fẹ́ òfin rẹ̀.
120 Ara mi wárìrì ní ìbẹ̀rù nítorí rẹ̀:
èmi dúró ní ìbẹ̀rù òfin rẹ.
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti Asafu.
81 Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa
Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jakọbu!
2 Ẹ mú orin mímọ́, kí ẹ sì mú ìlù wá,
tẹ dùùrù dídùn pẹ̀lú ohun èlò orin mímọ́.
3 Ẹ fún ìpè ní oṣù tuntun
àní nígbà tí a yàn;
ní ọjọ́ àjọ wa tí ó ní ìrònú.
4 Èyí ni àṣẹ fún Israẹli,
àti òfin Ọlọ́run Jakọbu.
5 Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Josẹfu
nígbà tí ó la ilẹ̀ Ejibiti já.
Níbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa.
6 Ó wí pé, “Mo gbé àjàgà kúrò ní èjìká yín,
a tú ọwọ́ wọn sílẹ̀ kúrò nínú apẹ̀rẹ̀.
7 Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là,
mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá,
mo dán an yín wò ní odò Meriba. Sela.
8 “Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín,
bí ìwọ bá fetí sí mi, ìwọ Israẹli.
9 Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrín yín;
ẹ̀yin kì yóò foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run àjèjì.
10 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
ẹni tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti.
Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un.
11 “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi;
Israẹli kò ní tẹríba fún mi.
12 Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn
láti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn.
13 “Bí àwọn ènìyàn mi yóò bá gbọ́ tèmi
bí Israẹli yóò bá tẹ̀lé ọ̀nà mi,
14 Ní kánkán ni èmi yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn
kí n sì yí ọwọ́ mi padà sí ọ̀tá wọn!
15 Àwọn tí ó kórìíra Olúwa yóò tẹríba níwájú rẹ̀.
Ìjìyà wọn yóò sì pẹ́ títí láé
16 Ṣùgbọ́n a ó fi ọkà tí ó dára bọ́ ọ yín
èmi ó tẹ́ ẹ yín lọ́rùn pẹ̀lú oyin inú àpáta.”
Saamu ti Asafu.
82 Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá,
ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn “ọlọ́run òrìṣà”.
2 “Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìṣòdodo
kí ó sì ṣe ojú ìṣáájú sí àwọn ènìyàn búburú?
3 Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba;
ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára.
4 Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní;
gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú.
5 “Wọn kò mọ̀ ohun kankan,
wọn kò lóye ohun kankan.
Wọn ń rìn kiri nínú òkùnkùn;
à si mí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé.
6 (A)“Mo wí pé, ‘Ẹyin ní “Ọlọ́run òrìṣà”;
ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ.’
7 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ó kú bí ènìyàn lásán;
ẹ̀yin ó ṣubú bí ọ̀kan nínú ọmọ-aládé.”
8 Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ayé,
nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè ni ìní rẹ.
18 Olùtùnú mi, nígbà tí ìbànújẹ́ ọkàn mi
rẹ̀wẹ̀sì nínú mi.
19 Fetí sí ẹkún àwọn ènìyàn mi láti ilẹ̀ jíjìnnà wá:
“Olúwa kò ha sí ní Sioni bí?
Ọba rẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́ ni?”
“Èéṣe tí wọ́n fi mú mi bínú pẹ̀lú ère wọn, pẹ̀lú àwọn
òrìṣà àjèjì tí wọn kò níláárí?”
20 “Ìkórè ti rékọjá,
ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti parí
síbẹ̀ a kò gbà wá là.”
21 Níwọ́n ìgbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run, èmi náà run pẹ̀lú,
èmi ṣọ̀fọ̀, ìrora sì mú mi káká.
22 Kò ha sí ìkunra ní Gileadi bí?
Kò ha sí àwọn oníṣègùn níbẹ̀?
Kí ló ha dé tí kò fi sí ìwòsàn
fún ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi?
9 Háà! Orí ìbá jẹ́ orísun omi
kí ojú mi sì jẹ́ orísun omijé!
Èmi yóò sì sọkún tọ̀sán tòru
nítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.
2 Háà, èmi ìbá ní ni aginjù
ilé àgbàwọ̀ fún àwọn arìnrìn-àjò,
kí n ba à lè fi àwọn ènìyàn mi sílẹ̀
kí n sì lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn:
nítorí gbogbo wọn jẹ́ panṣágà
àjọ aláìṣòótọ́ ènìyàn.
3 Wọ́n ti pèsè ahọ́n wọn sílẹ̀
bí ọfà láti fi pa irọ́;
kì í ṣe nípa òtítọ́
ni wọ́n fi borí ní ilẹ̀ náà.
Wọ́n ń lọ láti inú ẹ̀ṣẹ̀ kan sí òmíràn;
wọn kò sì náání mi,
ní Olúwa wí.
4 Ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ;
má ṣe gbẹ́kẹ̀lé àwọn arákùnrin rẹ.
Nítorí pé oníkálùkù arákùnrin jẹ́ atannijẹ,
oníkálùkù ọ̀rẹ́ sì jẹ́ abanijẹ́.
5 Ọ̀rẹ́ ń dalẹ̀ ọ̀rẹ́. Kò sì ṣí ẹni
tó sọ òtítọ́, wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn
láti máa purọ́. Wọ́n sọ ara wọn
di onírẹ̀wẹ̀sì pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀
6 Ó ń gbé ní àárín ẹ̀tàn
wọ́n kọ̀ láti mọ̀ mí nínú
ẹ̀tàn wọn,
ni Olúwa wí.
Àlàáfíà àti ayọ̀
5 (A)Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nípa ìgbàgbọ́, àwa ní àlàáfíà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. 2 (B)Nípasẹ̀ ẹni tí àwa sì ti rí ọ̀nà gbà nípa ìgbàgbọ́ sí inú oore-ọ̀fẹ́ yìí nínú èyí tí àwa gbé dúró. Àwa sì ń yọ̀ nínú ìrètí ògo Ọlọ́run. 3 (C)Kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa tún ń ṣògo nínú ìjìyà pẹ̀lú: bí a ti mọ̀ pé ìjìyà ń ṣiṣẹ́ sùúrù; 4 àti pé sùúrù ń ṣiṣẹ́ ìwà rere; àti pé ìwà rere ń ṣiṣẹ́ ìrètí: 5 (D)Ìrètí kì í sì í dójúti ni nítorí a ti dá ìfẹ́ Ọlọ́run sí wa lọ́kàn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a fi fún wa.
6 Nítorí ìgbà tí àwa jẹ́ aláìlera, ní àkókò tí ó yẹ, Kristi kú fún àwa aláìwà-bí-Ọlọ́run. 7 Nítorí ó ṣọ̀wọ́n kí ẹnìkan tó kú fún olódodo: ṣùgbọ́n fún ènìyàn rere bóyá ẹlòmíràn tilẹ̀ lè dábàá láti kú. 8 (E)Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ òun pàápàá sí wa hàn nínú èyí pé, nígbà tí àwa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.
9 (F)Mélòó mélòó sì ni tí a dá wa láre nísinsin yìí nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni a ó gbà wá là kúrò nínú ìbínú nípasẹ̀ rẹ̀. 10 (G)Ǹjẹ́, nígbà tí àwa wà ní ọ̀tá, a mú wa, ba Ọlọ́run làjà nípa ikú Ọmọ rẹ̀, mélòó mélòó, nígbà tí a là wá ní ìjà tan, ni a ó gbà wá là nípa ìyè rẹ̀. 11 (H)Kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa ń ṣògo nínú Ọlọ́run nípa Olúwa wa Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí àwa ti rí ìlàjà gbà nísinsin yìí.
Ẹ̀rí Jesu dájú
12 (A)Jesu sì tún sọ fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé, ẹni tí ó bá tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.”
13 (B)Nítorí náà àwọn Farisi wí fún un pé, “Ìwọ ń jẹ́rìí ara rẹ; ẹ̀rí rẹ kì í ṣe òtítọ́.”
14 Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo tilẹ̀ ń jẹ́rìí fún ara mi, òtítọ́ ni ẹ̀rí mi: nítorí tí mo mọ ibi tí mo ti wá, mo sì mọ ibi tí mo ń lọ; ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò lè mọ ibi tí mo ti wá, àti ibi tí mo ń lọ. 15 (C)Ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ nípa ti ara; èmi kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni. 16 (D)Ṣùgbọ́n bí èmi bá sì ṣe ìdájọ́, òtítọ́ ni: nítorí èmi nìkan kọ́, ṣùgbọ́n èmi àti Baba tí ó rán mi. 17 (E)A sì kọ ọ́ pẹ̀lú nínú òfin pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí ènìyàn méjì. 18 Èmi ni ẹni tí ń jẹ́rìí ara mi, Baba tí ó rán mi sì ń jẹ́rìí mi.”
19 (F)Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Níbo ni Baba rẹ wà?”
Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ Baba mi: ìbá ṣe pé ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá sì ti mọ Baba mi pẹ̀lú.” 20 (G)Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Jesu sọ níbi ìṣúra, bí ó ti ń kọ́ni ní tẹmpili: ẹnikẹ́ni kò sì mú un; nítorí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.