Book of Common Prayer
137 Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòó
àwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni.
2 Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílò,
tí ó wà láàrín rẹ̀.
3 Nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn
tí ó kó wa ní ìgbèkùn béèrè orin lọ́wọ́ wa,
àti àwọn tí ó ni wá lára béèrè ìdárayá wí pé;
ẹ kọ orin Sioni kan fún wa.
4 Àwa ó ti ṣe kọ orin
Olúwa ní ilẹ̀ àjèjì
5 Jerusalẹmu, bí èmi bá gbàgbé rẹ
jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò rẹ̀.
6 Bí èmi kò bá rántí rẹ,
jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi;
bí èmi kò bá fi Jerusalẹmu ṣáájú
olórí ayọ̀ mi gbogbo.
7 Olúwa rántí ọjọ́ Jerusalẹmu,
lára àwọn ọmọ Edomu,
àwọn ẹni tí ń wí pé,
“Wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!”
8 Ìwọ, ọmọbìnrin Babeli, ẹni tí a ó parun;
ìbùkún ni fún ẹni tí ó san án fún ọ
bí ìwọ ti rò sí wa.
9 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó mú ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ
tí ó sì fi wọ́n ṣán òkúta.
Ti Dafidi.
144 Ìyìn sí Olúwa àpáta mi,
ẹni tí ó kọ́ ọwọ́ mi fún ogun,
àti ìka mi fún ìjà.
2 Òun ni Ọlọ́run ìfẹ́ mi àti odi alágbára mi,
ibi gíga mi àti olùgbàlà mi, asà mi,
ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé,
ẹni tí ó tẹrí àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi.
3 Olúwa, kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún un,
tàbí ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa rẹ̀?
4 Ènìyàn rí bí èmi;
ọjọ́ rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ.
5 Tẹ ọ̀run rẹ ba, Olúwa, kí o sì sọ̀kalẹ̀;
tọ́ àwọn òkè ńlá wọn yóò sí rú èéfín.
6 Rán mọ̀nàmọ́ná kí ó sì fọ́n àwọn ọ̀tá ká;
ta ọfà rẹ kí ó sì dà wọ́n rú.
7 Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti ibi gíga;
gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu
kúrò nínú omi ńlá:
kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì.
8 Ẹnu ẹni tí ó kún fún èké
ẹni tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jẹ́ ìrẹ́jẹ.
9 Èmi yóò kọ orin tuntun sí ọ
Ọlọ́run; lára ohun èlò orin
olókùn mẹ́wàá èmi yóò
kọ orin sí ọ
10 Òun ni ó fi ìgbàlà fún àwọn ọba,
ẹni tí ó gba Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ idà ìpanilára.
Lọ́wọ́ pípanirun. 11 Gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu
kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì
tí ẹnu wọn kún fún èké,
tí ọwọ́ ọ̀tún wọn jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké.
12 Kí àwọn ọmọkùnrin wa
kí ó dàbí igi gbígbìn tí ó dàgbà ni ìgbà èwe wọn,
àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilé
tí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin.
13 Àká wa yóò kún
pẹ̀lú gbogbo onírúurú oúnjẹ
àgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún,
ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa:
14 Àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwo
kí ó má sí ìkọlù,
kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn,
kí ó má sí i igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa.
15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà tí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀,
Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà,
tí ẹni tí Ọlọ́run Olúwa ń ṣe.
ÌWÉ KEJÌ
Saamu 42–72
Fún adarí orin. Maskili ti àwọn ọmọ Kora.
42 Bí àgbọ̀nrín ti ń mí hẹlẹ sí ipa odò omi,
bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń mí hẹlẹ sí ọ Ọlọ́run.
2 Òùngbẹ Ọlọ́run ń gbẹ ọkàn mi, fún Ọlọ́run alààyè.
Nígbà wo ni èmi ó lọ bá Ọlọ́run?
3 Oúnjẹ mi ni omijé mi
ní ọ̀sán àti ní òru,
nígbà tí àwọn ènìyàn ń wí fún mi ní gbogbo ọjọ́ pé,
“Ọlọ́run rẹ dà?”
4 Nígbà tí mo bá rántí nǹkan yìí,
èmi tú ọkàn mi jáde nínú mi:
èmi ti bá ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn lọ,
èmi bá wọn lọ sí ilé Ọlọ́run
pẹ̀lú ohùn ayọ̀ àti ìyìn,
pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń pa ọjọ́ mímọ́ mọ́.
5 Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?
Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?
Ìwọ ṣe ìrètí ní ti Ọlọ́run,
nítorí èmi yóò sá à máa yìn ín,
Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.
6 Ọlọ́run mi, ọkàn mi ń rẹ̀wẹ̀sì nínú mi:
nítorí náà, èmi ó rántí rẹ
láti ilẹ̀ Jordani wá,
láti Hermoni láti òkè Mibsari.
7 Ibú omi ń pe ibú omi
nípa híhó omi ṣíṣàn rẹ̀
gbogbo rírú omi àti bíbì omi rẹ̀
bò mí mọ́lẹ̀.
8 Ní ọ̀sán ní Olúwa ran ìfẹ́ rẹ̀,
àti ni àṣálẹ́ ni orin rẹ̀ wà pẹ̀lú mi
àdúrà sí Ọlọ́run ayé mi.
9 Èmi wí fún Ọlọ́run àpáta mi,
“Èéṣe tí ìwọ fi gbàgbé mi?
Èéṣe tí èmi o fi máa rìn nínú ìbànújẹ́,
nítorí ìnilára ọ̀tá?”
10 Bí ẹni pé idà egungun mi ni ẹ̀gàn tí
àwọn ọ̀tá mi ń gàn mí,
Bí wọn ti ń béèrè ní gbogbo ọjọ́.
“Níbo ni Ọlọ́run rẹ wà?”
11 Èéṣe tí ìwọ fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?
Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?
Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,
nítorí èmi yóò sì máa yìn ín, Òun ni
Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.
43 Dá mi láre, Ọlọ́run mi,
kí o sì gba ọ̀rọ̀ mi rò lọ́dọ̀ àwọn aláìláàánú orílẹ̀-èdè:
yọ mí kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti àwọn ènìyàn búburú.
2 Ìwọ ni Ọlọ́run ibi agbára mi.
Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mi sílẹ̀?
Èéṣe tí èmi yóò máa rìn nínú ìbìnújẹ́,
nítorí ìnilára lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá?
3 Rán ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ rẹ jáde,
jẹ́ kí wọn ó máa dáàbò bò mí;
jẹ́ kí wọn mú mi wá sí òkè mímọ́ rẹ,
sí ibi tí ìwọ ń gbé.
4 Nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọ́run,
sí Ọlọ́run ayọ̀ mi àti ìdùnnú mi,
èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú dùùrù,
ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run mi.
5 Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mí?
Èéṣe tí ó fi ń ru sókè nínú mi?
Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,
nítorí èmi yóò máa yìn ín, Òun ni
Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.
27 “Wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “nígbà tí èmi yóò gbin ilé Israẹli àti ilé Juda pẹ̀lú irúgbìn ọmọ ènìyàn àti ẹranko. 28 Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń ṣọ́ wọn, láti fàtu, àti láti wó lulẹ̀, àti láti gba ìṣàkóso, láti bàjẹ́ àti láti mú ibi wá, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣọ́ wọn láti kọ́ àti láti gbìn,” ni Olúwa wí. 29 “Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ènìyàn kò ní sọ mọ́ pé:
“ ‘Àwọn baba ti jẹ èso àjàrà àìpọ́n
àti pé eyín kan àwọn ọmọdé.’
30 Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ èso kíkan ni eyín yóò kan.
31 (A)(B) “Ìgbà kan ń bọ̀,” ni Olúwa wí,
“tí Èmi yóò bá ilé Israẹli
àti ilé Juda dá májẹ̀mú tuntun.
32 Kò ní dàbí májẹ̀mú
tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá,
nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́,
tí mo mú wọn jáde ní Ejibiti
nítorí wọ́n da májẹ̀mú mi.
Lóòótọ́ ọkọ ni èmi jẹ́ fún wọn,”
ni Olúwa wí.
33 “Èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli dá
lẹ́yìn ìgbà náà,” ni Olúwa wí pé:
“Èmi yóò fi òfin mi sí ọkàn wọn,
èmi ó sì kọ ọ́ sí àyà wọn.
Èmi ó jẹ́ Olúwa wọn;
àwọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi.
34 Kò ní sí pé ọkùnrin kan ń kọ́ àwọn ará ilé rẹ̀
tàbí ọkùnrin ń kọ́ arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ Olúwa,’
nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí
láti ẹni kékeré wọn títí dé ẹni ńlá,”
ni Olúwa wí.
“Nítorí èmi ó dárí àìṣedéédéé wọn jì,
èmi kò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”
Gbogbo Israẹli tòótọ́ ni yóò ní ìgbàlà
25 (A)Ará, èmi kò ṣá fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó wà ní òpè ní ti ohun ìjìnlẹ̀ yìí, kí ẹ̀yin má ba á ṣe ọlọ́gbọ́n ní ojú ara yín, pé ìfọ́jú bá Israẹli ní apá kan, títí kíkún àwọn Kèfèrí yóò fi dé. 26 (B)Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gba gbogbo Israẹli là, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:
“Ní Sioni ni Olùgbàlà yóò ti jáde wá,
yóò sì yìí àìwà-bí-Ọlọ́run kúrò lọ́dọ̀ Jakọbu.
27 (C)Èyí sì ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn.
Nígbà tí èmi yóò mú ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò.”
28 Nípa ti ìhìnrere, ọ̀tá ni wọ́n nítorí yín; bí ó sì ṣe ti ìyànfẹ́ ni, olùfẹ́ ni wọ́n nítorí ti àwọn baba. 29 Nítorí àìlábámọ̀ ni ẹ̀bùn àti ìpè Ọlọ́run. 30 Nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin kò ti gba Ọlọ́run gbọ́ rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí tí ẹ̀yin rí àánú gbà nípa àìgbàgbọ́ wọn. 31 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn wọ̀nyí tí ó ṣe àìgbọ́ràn nísinsin yìí, kí àwọn pẹ̀lú bá le rí àánú gbà nípa àánú tí a fihàn yín. 32 (D)Nítorí Ọlọ́run sé gbogbo wọn mọ́ pọ̀ sínú àìgbàgbọ́, kí ó le ṣàánú fún gbogbo wọn.
Ìyìn fún Ọlọ́run
33 (E)A! Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run!
Àwámárídìí ìdájọ́ rẹ̀ ti rí,
ọ̀nà rẹ̀ sì jù àwárí lọ!
34 (F)“Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa?
Tàbí ta ni í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀?”
35 (G)“Tàbí ta ni ó kọ́ fi fún un,
tí a kò sì san padà fún un?”
36 (H)Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti nípa rẹ̀, àti fún un ni ohun gbogbo;
ẹni tí ògo wà fún láéláé! Àmín.
28 Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó lọ, ó sì pe Maria arábìnrin rẹ̀ sẹ́yìn wí pé, “Olùkọ́ dé, ó sì ń pè ọ́.” 29 Nígbà tí ó gbọ́, ó dìde lọ́gán, ó sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 30 Jesu kò tí ì wọ ìlú, ṣùgbọ́n ó wà ní ibi kan náà tí Marta ti pàdé rẹ̀. 31 Nígbà tí àwọn Júù tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú ilé, tí wọ́n ń tù ú nínú rí Maria tí ó dìde kánkán, tí ó sì jáde, wọ́n tẹ̀lé, wọ́n ṣe bí ó ń lọ sí ibojì láti sọkún níbẹ̀.
32 (A)Nígbà tí Maria sì dé ibi tí Jesu wà, tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.”
33 Nígbà tí Jesu rí i, tí ó ń sọkún, àti àwọn Júù tí ó bá a wá ń sọkún pẹ̀lú rẹ̀, ó kérora nínú ẹ̀mí, inú rẹ̀ sì bàjẹ́. 34 Ó sì wí pé, “Níbo ni ẹ̀yin gbé tẹ́ ẹ sí?”
Wọ́n sì wí fún un pé, “Olúwa, wá wò ó.”
35 (B)Jesu sọkún.
36 Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Sá wò ó bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!”
37 (C)Àwọn kan nínú wọn sì wí pé, “Ọkùnrin yìí, ẹni tí ó la ojú afọ́jú, kò lè ṣe é kí ọkùnrin yìí má kú bí?”
Jesu jí òkú Lasaru dìde
38 (D)Nígbà náà ni Jesu tún kérora nínú ara rẹ̀, ó wá sí ibojì, ó sì jẹ́ ihò, a sì gbé òkúta lé ẹnu rẹ̀. 39 Jesu wí pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò!”
Marta, arábìnrin ẹni tí ó kú náà wí fún un pé, “Olúwa, ó ti ń rùn nísinsin yìí: nítorí pé ó di ọjọ́ kẹrin tí ó tí kú.”
40 Jesu wí fún un pé, “Èmi kò ti wí fún ọ pé, bí ìwọ bá gbàgbọ́, ìwọ yóò rí ògo Ọlọ́run?”
41 (E)Nígbà náà ni wọ́n gbé òkúta náà kúrò (níbi tí a tẹ́ ẹ sí). Jesu sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wí pé, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí tí ìwọ gbọ́ tèmi. 42 (F)Èmi sì ti mọ̀ pé, ìwọ a máa gbọ́ ti èmi nígbà gbogbo: ṣùgbọ́n nítorí ìjọ ènìyàn tí ó dúró yìí ni mo ṣe wí i, kí wọn ba à lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi.”
43 Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó kígbe lóhùn rara pé, “Lasaru, jáde wá.” 44 (G)Ẹni tí ó kú náà sì jáde wá, tí a fi aṣọ òkú dì tọwọ́ tẹsẹ̀ a sì fi gèlè dì í lójú.
Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ!”
Àwọn júù n tẹ̀síwájú nínú àìgbàgbọ́
37 Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ààmì tó báyìí lójú wọn, wọn kò gbà á gbọ́. 38 (A)Kí ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah lè ṣẹ, èyí tí ó sọ pé:
“Olúwa, ta ni ó gba ìwàásù wa gbọ́
Àti ta ni a sì fi apá Olúwa hàn fún?”
39 Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Isaiah sì tún sọ pé:
40 (B)“Ó ti fọ́ wọn lójú,
Ó sì ti sé àyà wọn le;
kí wọn má ba à fi ojú wọn rí,
kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀,
kí wọn má ba à yípadà, kí èmi má ba à mú wọn láradá.”
41 (C)Nǹkan wọ̀nyí ni Isaiah wí, nítorí ó ti rí ògo rẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀.
42 (D)Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nínú àwọn olórí gbà á gbọ́ pẹ̀lú; ṣùgbọ́n nítorí àwọn Farisi wọn kò jẹ́wọ́ rẹ̀, kí a má ba à yọ wọ́n kúrò nínú Sinagọgu: 43 Nítorí wọ́n fẹ́ ìyìn ènìyàn ju ìyìn ti Ọlọ́run lọ.
44 (E)Jesu sì kígbe ó sì wí pé, “Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, èmi kọ́ ni ó gbàgbọ́ ṣùgbọ́n ẹni tí ó rán mi. 45 (F)Ẹni tí ó bá sì rí mi, ó rí ẹni tí ó rán mi. 46 (G)Èmi ni ìmọ́lẹ̀ tí ó wá sí ayé, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ má ṣe wà nínú òkùnkùn.
47 (H)“Bí ẹnikẹ́ni bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò sì pa wọ́n mọ́, èmi kì yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ nítorí tí èmi kò wá láti ṣe ìdájọ́ ayé, bí kò ṣe láti gba ayé là. 48 (I)Ẹni tí ó bá kọ̀ mí, tí kò sì gba ọ̀rọ̀ mi, ó ní ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀; ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ, òun náà ni yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn. 49 Nítorí èmi kò dá ọ̀rọ̀ sọ fún ara mi, ṣùgbọ́n Baba tí ó rán mi, ni ó ti fún mi ní àṣẹ, ohun tí èmi ó sọ, àti èyí tí èmi ó wí. 50 Èmi sì mọ̀ pé ìyè àìnípẹ̀kun ni òfin rẹ̀: nítorí náà, àwọn ohun tí mo bá wí, gẹ́gẹ́ bí Baba ti sọ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni mo wí!”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.