Book of Common Prayer
113 Ẹ máa yin Olúwa.
Yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa,
ẹ yin orúkọ Olúwa.
2 Fi ìbùkún fún orúkọ Olúwa láti
ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
3 Láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀
orúkọ Olúwa ni kí a máa yìn.
4 Olúwa ga lórí gbogbo orílẹ̀-èdè,
àti ògo rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run.
5 Ta ló dàbí Olúwa Ọlọ́run wa,
tí ó gbé ní ibi gíga.
6 Tí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti wò
òun tí ó ń bẹ lọ́run, àti nínú ayé!
7 Ó gbé òtòṣì dìde láti inú erùpẹ̀, àti pé
ó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá.
8 Kí ó le mú un jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé
àní pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àwọn ènìyàn rẹ̀.
9 Ó mú àgàn obìnrin gbé inú ilé,
àti láti jẹ́ aláyọ̀ ìyá fún àwọn ọmọ rẹ̀.
Ẹ yin Olúwa.
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.
122 Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé
Ẹ jẹ́ kí á lọ sílé Olúwa.
2 Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè rẹ,
ìwọ Jerusalẹmu.
3 Jerusalẹmu, ìwọ tí a kọ́ bí ìlú
tí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan
4 Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ,
àwọn ẹ̀yà Olúwa,
ẹ̀rí fún Israẹli, láti
máa dúpẹ́ fún orúkọ Olúwa.
5 Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀,
àwọn ìtẹ́ ilé Dafidi.
6 Gbàdúrà fún àlàáfíà Jerusalẹmu;
àwọn tí ó fẹ́ ọ yóò ṣe rere.
7 Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi rẹ̀,
àti ìre nínú ààfin rẹ̀.
8 Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mi
èmi yóò wí nísinsin yìí pé,
kí àlàáfíà kí ó wà nínú rẹ̀;
9 Nítorí ilé Olúwa Ọlọ́run wa,
èmi yóò máa wá ìre rẹ̀.
20 Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ rẹ̀ pé, lẹ́yìn ìgbà tí Hana lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Samuẹli, pé, “Nítorí tí mo béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ Olúwa.”
A ya Samuẹli sí mímọ́ fún Olúwa
21 Ọkùnrin náà Elkana, àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, gòkè lọ láti rú ẹbọ ọdún sí Olúwa, àti láti sán ẹ̀jẹ́ rẹ̀. 22 Ṣùgbọ́n Hana kò gòkè lọ; nítorí tí ó sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Ó di ìgbà tí mo bá gba ọmú lẹ́nu ọmọ náà, nígbà náà ni èmi yóò mú un lọ, kí òun lè fi ara hàn níwájú Olúwa, kí ó sí máa gbé ibẹ̀ títí láé.”
23 Elkana ọkọ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ. Dúró títí ìwọ yóò fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀; ṣùgbọ́n kí Olúwa sá à mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin náà sì jókòó, ó sì fi ọmú fún ọmọ rẹ̀ títí ó fi gbà á lẹ́nu rẹ̀.
24 Nígbà tí ó sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, ó sì mú un gòkè lọ pẹ̀lú ara rẹ̀. Pẹ̀lú ẹgbọrọ màlúù mẹ́ta, àti ìyẹ̀fun efa kan, àti ìgò ọtí wáìnì kan, ó sì mú un wá sí ilé Olúwa ní Ṣilo: ọmọ náà sì wà ní ọmọdé. 25 Wọ́n pa ẹgbọrọ màlúù, wọ́n sì mú ọmọ náà tọ Eli wá. 26 Hana sì wí pé, “Olúwa mi, bí ọkàn rẹ ti wà láààyè, Olúwa mi, èmi ni obìnrin náà tí ó dúró lẹ́bàá ọ̀dọ̀ rẹ níhìn-ín tí ń tọrọ lọ́dọ̀ Olúwa. 27 Ọmọ yìí ni mo ń tọrọ; Olúwa sì fi ìdáhùn ìbéèrè tí mo béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ fún mi. 28 Nítorí náà pẹ̀lú, èmi fi í fún Olúwa; ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀: nítorí tí mo ti béèrè rẹ̀ fún Olúwa.” Wọn si wólẹ̀ sin Olúwa níbẹ̀.
14 (A)Nítorí pé, iye àwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń darí ni ọmọ Ọlọ́run. 15 (B)Nítorí ẹ̀yin kò tún gba ẹ̀mí ẹrú láti máa bẹ̀rù mọ́; ṣùgbọ́n ẹ̀yin gba ẹ̀mí ìsọdọmọ, nípa èyí tí àwa fi ń ké pé “Ábbà, Baba.” 16 (C)Nítorí ẹ̀mí mímọ́ ń sọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú ọkàn wa, ó sì ń sọ fún wa pé, nítòótọ́, àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. 17 (D)Níwọ́n ìgbà tí a jẹ́ ọmọ rẹ̀, ǹjẹ́ ajogún ni àwa, ajogún Ọlọ́run, àti àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi, bí ó bá ṣe àwa jìyà, kí a sì le ṣe wá lógo pẹ̀lú rẹ̀.
Ìgbádùn tí ń bọ̀ àti ìjìyà ìsìn yìí
18 (E)Síbẹ̀síbẹ̀, ìyà tí a ń jẹ nísinsin yìí kò jámọ́ nǹkan nígbà tí a bá fiwé ògo tí yóò fún wa ní ìkẹyìn. 19 (F)Nítorí ẹ̀dá ń dúró ní ìfojúsọ́nà de ìfihàn àwọn ọmọ Ọlọ́run. 20 (G)Nítorí a tẹrí ẹ̀dá ba fún asán, kì í ṣe bí òun ti fẹ́, ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ẹni tí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní ìrètí. 21 (H)Nítorí a ó sọ ẹ̀dá tìkára rẹ̀ di òmìnira kúrò nínú ẹrú ìdíbàjẹ́, sí òmìnira ògo àwọn ọmọ Ọlọ́run.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.