Book of Common Prayer
Ti Solomoni
72 Fi ìdájọ́ fún àwọn ọba, Ọlọ́run,
ọmọ-aládé ni ìwọ fi òdodo rẹ fún
2 Yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú òdodo,
yóò sì máa fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn tálákà rẹ̀.
3 Àwọn òkè ńlá yóò máa mú àlàáfíà fún àwọn ènìyàn
àti òkè kéékèèkéé nípa òdodo
4 Yóò dáàbò bo àwọn tí a pọ́n lójú láàrín àwọn ènìyàn
yóò gba àwọn ọmọ aláìní;
yóò sì fa àwọn aninilára ya.
5 Àwọn òtòṣì àti aláìní
yóò máa fi ọ̀wọ̀ ńlá fún ọ nígbà gbogbo,
níwọ̀n ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá bá ń ràn,
yóò ti pẹ́ tó, láti ìrandíran.
6 Yóò dàbí òjò tí ó ń rọ̀ sórí pápá ìrẹ́mọ́lẹ̀
Bí ọwọ́ òjò tó ń rin ilẹ̀
7 Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀ ni ọjọ́ rẹ̀
ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà yóò sì wà;
títí tí òṣùpá kò fi ní sí mọ́.
8 Yóò máa jẹ ọba láti Òkun dé Òkun
àti láti odò Eufurate títí dé òpin ayé.
9 Àwọn tí ó wà ní aginjù yóò tẹríba fún un
àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò máa lá erùpẹ̀ ilẹ̀.
10 Àwọn ọba Tarṣiṣi àti ti erékùṣù
wọn yóò mú ọrẹ wá fún un;
àwọn ọba Ṣeba àti Seba
wọn ó mú ẹ̀bùn wá fún un.
11 Gbogbo ọba yóò tẹríba fún un
àti gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sìn ín.
12 Nítorí yóò gba àwọn aláìní
nígbà tí ó bá ń ké,
tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
13 Yóò káàánú àwọn aláìlera àti aláìní
yóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú.
14 Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipá
nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣọ̀wọ́n níwájú rẹ̀.
15 Yóò sì pẹ́ ní ayé!
A ó sì fún un ní wúrà Ṣeba.
Àwọn ènìyàn yóò sì máa gbàdúrà fún un nígbà gbogbo
kí a sì bùkún fún un lójoojúmọ́.
16 Kí ìkúnwọ́ ọkà wà lórí ilẹ̀;
ní orí òkè ni kí ó máa dàgbà
kí èso rẹ̀ kí o gbilẹ̀ bí ti Lebanoni
yóò máa gbá yìn bí i koríko ilẹ̀.
17 Kí orúkọ rẹ̀ kí ó wà títí láé;
orúkọ rẹ̀ yóò máa gbilẹ̀ níwọ̀n bí oòrùn yóò ti pẹ́ tó.
Wọn ó sì máa bùkún fún ara wọn nípasẹ̀ rẹ.
Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní yóò máa pè mí ní alábùkún fún.
18 Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli,
ẹnìkan ṣoṣo tí ó ń ṣe ohun ìyanu.
19 Olùbùkún ni orúkọ rẹ̀ tí ó lógo títí láé;
kí gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.
Àmín àti Àmín.
20 Èyí ni ìparí àdúrà Dafidi ọmọ Jese.
Ẹlẹgbẹ́ mi ni àwọn tó mọ òfin Olúwa
73 Ọwọ́ rẹ ni ó dá mi tí ó sì mọ mí;
fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ rẹ.
74 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ máa yọ̀ nígbà tí wọ́n bá rí mi,
nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
75 Èmi mọ, Olúwa, nítorí òfin rẹ òdodo ni,
àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú.
76 Kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi,
gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ.
77 Jẹ́ kí àánú rẹ kí ó tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè yè,
nítorí òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi.
78 Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraga
nítorí wọn pa mí lára láìnídìí
ṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
79 Kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yí padà sí mi,
àwọn tí ó ní òye òfin rẹ.
80 Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin rẹ,
kí ojú kí ó má ṣe tì mí.
Wíwá àlàáfíà
81 Ọkàn mi ń fojú ṣọ́nà nítorí ìgbàlà rẹ,
ṣùgbọ́n èmi ti fi ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
82 Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wíwo ìpinnu rẹ;
èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?”
83 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí awọ-wáìnì lójú èéfín,
èmi kò gbàgbé ìlànà rẹ.
84 Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó?
Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọn
tí ń ṣe inúnibíni sí mi wí?
85 Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi,
tí ó lòdì sí òfin rẹ.
86 Gbogbo àṣẹ rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé:
ràn mí lọ́wọ́, nítorí ènìyàn
ń ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí.
87 Wọ́n fẹ́rẹ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé,
ṣùgbọ́n èmi kò kọ ẹ̀kọ́ rẹ.
88 Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ,
èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu rẹ̀ gbọ́.
Ọ̀rọ̀ Olúwa dúró títí láé
89 Ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa, títí láé ni;
ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run
90 Òtítọ́ rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran;
ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin.
91 Òfin rẹ dúró di òní
nítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́.
92 Bí òfin rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi,
èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi.
93 Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ láé,
nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́
94 Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹ
èmi ti wá ẹ̀kọ́ rẹ.
95 Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run,
ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsi ẹ̀rí rẹ.
96 Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin;
ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ aláìlópin ni.
Ògo ọjọ́ iwájú ti Sioni
54 (A)“Kọrin, ìwọ obìnrin àgàn,
ìwọ tí kò tí ì bímọ rí;
bú sí orin, ẹ hó fún ayọ̀,
ẹ̀yin tí kò tí ì rọbí rí;
nítorí pé púpọ̀ ni ọmọ àwọn obìnrin ìsọdahoro
ju ti ẹni tí ó ní ọkọ,”
ni Olúwa wí.
2 Fẹ ibi àgọ́ rẹ lójú sí i,
fẹ aṣọ àgọ́ rẹ kí ó gbòòrò sí i,
má ṣe dá a dúró;
sọ okùn rẹ di gígùn,
mú òpó rẹ lágbára sí i.
3 Nítorí ìwọ ó fẹ̀ sọ́tùn àti sí òsì;
ìrandíran rẹ yóò jogún àwọn orílẹ̀-èdè,
wọn yóò sì dó sí ahoro àwọn ìlú wọn.
4 “Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́.
Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù.
Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe e rẹ
Ìwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìgba-opo rẹ mọ́.
5 Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀
Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ;
a sì ń pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.
6 Olúwa yóò pè ọ́ padà
àfi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀
tí a sì bà lọ́kàn jẹ́
obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́,
tí a sì wá jákulẹ̀” ni Olúwa wí.
7 “Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóò
mú ọ padà wá.
8 Ní ríru ìbínú.
Mo fi ojú pamọ́ fún ọ fún ìṣẹ́jú kan,
ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú àìnípẹ̀kun
Èmi yóò ṣíjú àánú wò ọ́,”
ni Olúwa Olùdáǹdè rẹ wí.
9 “Sí mi, èyí dàbí i àwọn ọjọ́ Noa,
nígbà tí mo búra pé àwọn omi
Noa kì yóò tún bo ilẹ̀ ayé mọ́.
Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí mo ti búra láti má ṣe bínú sí ọ,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá ọ wí mọ́.
10 Bí a tilẹ̀ mi àwọn òkè ńlá
tí a sì ṣí àwọn òkè kékeré nídìí,
Síbẹ̀síbẹ̀ ìfẹ́ àìkùnà mi fún ọ kì yóò yẹ̀ láéláé
tàbí májẹ̀mú àlàáfíà ni a ó mú kúrò,”
ni Olúwa, ẹni tí ó ṣíjú àánú wò ọ́ wí.
11 (B)Ìwọ ìlú tí a pọ́n lójú, tí ìjì ń gbá kiri
tí a kò sì tù nínú,
Èmi yóò fi òkúta Tikuosi kọ́ ọ
àti ìpìlẹ̀ rẹ pẹ̀lú safire.
12 Èmi yóò fi iyùn ṣe odi rẹ,
àwọn ẹnu-ọ̀nà ni a ó fi ohun èlò dáradára fún,
àti àwọn ògiri rẹ pẹ̀lú òkúta iyebíye.
13 (C)Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ ni Olúwa yóò kọ́,
àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò jẹ́ ńlá àti púpọ̀.
14 Ní òdodo ni a ó fi ìdí rẹ kalẹ̀
ìwà ipá yóò jìnnà sí ọ
o kò ní bẹ̀rù ohunkóhun
Ìpayà la ó mú kúrò pátápátá;
kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.
15 Bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ bá ọ jà, kò ní jẹ́ láti ọwọ́ mi;
ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ọ jà ni yóò túúbá fún ọ.
16 “Kíyèsi i, èmi ni ó dá alágbẹ̀dẹ
tí ń fẹ́ iná èédú iná
tí ó sì ń mú ohun èlò wá tí ó bá iṣẹ́ rẹ mu.
Èmi náà sì ni ẹni tí ó dá apanirun láti ṣe iṣẹ́ ibi;
17 Kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yóò lè ṣe nǹkan,
àti gbogbo ahọ́n tí ó dìde sí ọ ní ìdájọ́
ni ìwọ ó dá ní ẹ̀bi.
Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ Olúwa,
èyí sì ni ìdáláre wọn láti ọ̀dọ̀ mi,”
ni Olúwa wí.
Hagari àti Sara
21 Ẹ wí fún mi, ẹ̀yin tí ń fẹ́ wà lábẹ́ òfin, ẹ ko ha gbọ́ òfin ohun ti òfin sọ. 22 (A)Nítorí a ti kọ ọ́ pé, Abrahamu ní ọmọ ọkùnrin méjì, ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ ẹrúbìnrin, àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ òmìnira obìnrin. 23 (B)Ṣùgbọ́n a bí èyí tí ṣe ti ẹrúbìnrin nípa ti ara: ṣùgbọ́n èyí ti òmìnira obìnrin ni a bí nípa ìlérí.
24 Nǹkan wọ̀nyí jẹ́ àpẹẹrẹ: nítorí pé àwọn obìnrin wọ̀nyí ní májẹ̀mú méjèèjì; ọ̀kan láti orí òkè Sinai wá, tí a bí lóko ẹrú, tí í ṣe Hagari. 25 Nítorí Hagari yìí ni òkè Sinai Arabia, tí ó sì dúró fún Jerusalẹmu tí ó wà nísinsin yìí, tí ó sì wà lóko ẹrú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀. 26 Ṣùgbọ́n Jerusalẹmu ti òkè jẹ́ òmìnira, èyí tí í ṣe ìyá wa. 27 (C)Nítorí a ti kọ ọ́ pé,
“Máa yọ̀, ìwọ obìnrin àgàn
tí kò bímọ,
bú sí ayọ̀ kí o sì kígbe sókè,
ìwọ tí kò rọbí rí;
nítorí àwọn ọmọ obìnrin náà tí a kọ̀sílẹ̀
yóò pọ̀ ju ti obìnrin tó ní ọkọ lọ.”
28 Ǹjẹ́ ará, ọmọ ìlérí ni àwa gẹ́gẹ́ bí Isaaki. 29 (D)Ṣùgbọ́n bí èyí tí a bí nípa ti ara ti ṣe inúnibíni nígbà náà sí èyí tí a bí nípa ti Ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ sì ni nísinsin yìí. 30 (E)Ṣùgbọ́n ìwé mímọ́ ha ti wí, “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrúbìnrin kì yóò bá ọmọ òmìnira obìnrin jogún pọ̀.” 31 Nítorí náà, ará, àwa kì í ṣe ọmọ ẹrúbìnrin bí kò ṣe ti òmìnira obìnrin.
11 (A)Àwọn Farisi tọ Jesu wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Láti dán an wò, wọ́n béèrè fún ààmì láti ọ̀run. 12 Jesu mí kanlẹ̀, nígbà tí ó gbọ́ ìbéèrè wọn. Ó sì dáhùn wí pé, “Èéṣe tí ìran yìí fi ń wá ààmì? Lóòótọ́ ni mo sọ fún un yín kò si ààmì tí a ó fi fún ìran yín.” 13 (B)Nígbà náà ni ó padà sínú ọkọ̀ ojú omi ó fi àwọn ènìyàn sílẹ̀, ó sì rékọjá sí apá kejì Òkun náà.
Ìwúkàrà àwọn Farisi àti Herodu
14 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbàgbé láti mú àkàrà tí yóò tó wọn ọ́n jẹ lọ́wọ́. Ẹyọ ìṣù àkàrà kan ṣoṣo ni ó wà nínú ọkọ̀ wọn. 15 (C)Bí wọ́n sì ti ń rékọjá, Jesu kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ máa ṣọ́ra nítorí ìwúkàrà àwọn Farisi àti ìwúkàrà Herodu.”
16 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ronú èyí láàrín ara wọn wí pé, “Torí pé a kò mú àkàrà lọ́wọ́ ni?”
17 (D)Jesu mọ ohun tí wọ́n sọ láàrín ara wọn, ó sì dá wọn lóhùn pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe àròyé pé ẹ̀yin kò mú àkàrà lọ́wọ́? Ẹ̀yin kò kíyèsi i títí di ìsinsin yìí, ẹ kò sì ti mòye, àbí ọkàn yín le ni. 18 Ẹ̀yin ní ojú, ẹ kò fi ríran? Ẹ̀yin ni etí ẹ kò sí gbọ́ran? Ẹ̀yin kò sì rántí? 19 (E)Nígbà ti mo bu ìṣù àkàrà márùn-ún fún ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (5,000) ènìyàn, agbọ̀n mélòó ni ó kún fún àjẹkù tí ẹ ṣàjọ?”
Wọ́n wí pé, “Méjìlá.”
20 (F)“Bákan náà, nígbà tí mo bọ́ ẹgbàajì (4,000) pẹ̀lú ìṣù àkàrà méje, agbọ̀n mélòó ló kù sílẹ̀ lẹ́yìn àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn wọn?”
Wọ́n dáhùn pé, “Ó ku ẹ̀kún agbọ̀n méje.”
21 Ó sì wí fún wọn pé, “Èéha ti ṣe tí kò fi yé yin?”
Ìwòsàn ọkùnrin afọ́jú ní Betisaida
22 (G)(H) Nígbà tí wọ́n dé Betisaida, àwọn ènìyàn kan mú afọ́jú kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó fi ọwọ́ kàn án, kí ó sì wò ó sàn. 23 (I)Jesu fa ọkùnrin náà lọ́wọ́, ó sì mú un jáde lọ sí ẹ̀yìn ìlú. Ó tu itọ́ sí i lójú. Ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú náà. Ó sì bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ ìwọ lè rí ohunkóhun nísinsin yìí?”
24 Ọkùnrin náà wo àyíká rẹ̀, ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, mo rí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n n kò rí wọn kedere, wọ́n n rìn kiri bí àgékù igi.”
25 Nígbà náà, Jesu tún gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé àwọn ojú ọkùnrin náà, bí ọkùnrin náà sì ti ranjú mọ́ ọn, a dá ìran rẹ̀ padà, ó sì rí gbogbo nǹkan kedere. 26 Jesu sì rán an sí àwọn ẹbí rẹ̀. Ó kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe lọ sí ìlú, kí o má sì sọ fún ẹnikẹ́ni ní ìlú.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.