Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 61-62

Fún adarí orin. Ohun èlò orin olókùn. Ti Dafidi.

61 Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run;
    Tẹ́tí sí àdúrà mi.

Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́,
    mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀;
    mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.
Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi,
    ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá.

Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé
    kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ.
Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run;
    Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.

Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn,
    ọdún rẹ̀ fún ìrandíran.
Kí ó máa jẹ ọba níwájú Ọlọ́run títí láé;
    pèsè àánú àti òtítọ́ rẹ tí yóò máa ṣe ìtọ́jú rẹ.

Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ títí láé
    kí n san ẹ̀jẹ́ mi ní ojoojúmọ́.

Fún adarí orin. Fun Jedutuni. Saamu Dafidi.

62 Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi;
    ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá.
Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi;
    Òun ni ààbò mi, a kì yóò sí mi ní ipò padà.

Ẹ̀yin ó ti máa kọ́lú ènìyàn kan pẹ́ tó?
    Gbogbo yín ni ó fẹ́ pa á,
    bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀, àti bí ọgbà tí ń wó lọ?
Kìkì èrò wọn ni láti bì ṣubú
    kúrò nínú ọlá rẹ̀;
    inú wọn dùn sí irọ́.
Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre,
    ṣùgbọ́n wọ́n ń gégùn ún nínú ọkàn wọn. Sela.

Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmi wà, ìwọ Ọlọ́run mi.
    Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.
Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi;
    Òun ni ààbò mi, a kì yóò ṣí mi ní ipò.
Ìgbàlà mi àti ògo mi dúró nínú Ọlọ́run;
    Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi.
Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn;
    tú ọkàn rẹ jáde sí i,
nítorí Ọlọ́run ni ààbò wa.

Nítòótọ́, asán ni àwọn ọmọ ènìyàn, èké
    sì ni àwọn olóyè, wọ́n gòkè nínú ìwọ̀n,
    lápapọ̀ wọ́n jẹ́ èémí.
10 Má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ìnilára,
    tàbí gbéraga nínú olè jíjà,
nítòótọ́ bí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i,
    má ṣe gbẹ́kẹ̀ rẹ lé wọn.

11 Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì, ni mo
    gbọ́ èyí pé, ti Ọlọ́run ni agbára
12 (A)Pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa, tìrẹ ni àánú
    nítorí tí ìwọ san án fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

Saamu 68

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Orin.

68 Kí Ọlọ́run kí ó dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó fọ́nká;
    kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó sá níwájú rẹ̀.
Bí ìjì ti ń fẹ́ èéfín lọ,
    kí ó fẹ́ wọn lọ;
bí ìda ti í yọ́ níwájú iná,
    kí olùṣe búburú ṣègbé níwájú Ọlọ́run.
Ṣùgbọ́n kí inú olódodo kí ó dùn
    kí ó sì kún fún ayọ̀ níwájú Ọlọ́run;
    kí inú wọn kí ó dùn, kí ó sì kún fún ayọ̀.

Ẹ kọrin sí Ọlọ́run,
    ẹ kọrin ìyìn sí i,
ẹ la ọ̀nà fún ẹni tí ń rékọjá ní aginjù.
    Olúwa ni orúkọ rẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀.
Baba àwọn aláìní baba àti onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ní ibùgbé
    rẹ̀ mímọ́
Ọlọ́run gbé aláìlera
    kalẹ̀ nínú ìdílé,
ó darí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú orin,
    ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ní ń gbé nínú ilẹ̀ gbígbẹ.

Nígbà tí ìwọ bá jáde lónìí níwájú àwọn ènìyàn rẹ, Ọlọ́run,
    tí ń kọjá lọ láàrín aginjù, Sela.
Ilẹ̀ mì títí,
    àwọn ọ̀run ń rọ òjò jáde,
níwájú Ọlọ́run,
    ẹni Sinai,
níwájú Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli.
Ìwọ fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò, Ọlọ́run;
    ìwọ tu ilẹ̀ ìní rẹ̀ lára nígbà tí ó rẹ̀ ẹ́ tan.
10 Àwọn ènìyàn rẹ tẹ̀dó síbẹ̀
    nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní rẹ, Ọlọ́run, ìwọ pèsè fún àwọn aláìní.

11 Olúwa ti pàṣẹ ọ̀rọ̀,
    púpọ̀ ní ogun àwọn ẹni tí ó ń ròyìn rẹ̀.
12 “Àwọn ọba àti àwọn ológun yára sálọ;
    Obìnrin tí ó sì jókòó ni ilé ní ń pín ìkógun náà.
13 Nígbà tí ẹ̀yin dùbúlẹ̀ láàrín agbo ẹran,
    nígbà náà ni ẹ̀yin ó dàbí ìyẹ́ àdàbà ti a bò ní fàdákà,
    àti ìyẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú wúrà pupa.”
14 Nígbà tí Olódùmarè fọ́n àwọn ọba ká ní ilẹ̀ náà,
    ó dàbí òjò dídi ní Salmoni.

15 Òkè Baṣani jẹ́ òkè Ọlọ́run;
    òkè tí ó ní orí púpọ̀ ni òkè Baṣani.
16 Kí ló dé tí ẹ̀yin fi ń ṣe ìlara,
    ẹ̀yin òkè wúwo, òkè tí Ọlọ́run ti fẹ́ láti jẹ ọba
    níbi tí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ yóò máa gbé títí láé?
17 Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ni kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́run
    ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún;
    Olúwa ń bẹ láàrín wọn, ní Sinai ni ibi mímọ́ rẹ̀.
18 Ìwọ ti gòkè sí ibi gíga
    ìwọ ti di ìgbèkùn ní ìgbèkùn lọ;
    ìwọ ti gba ẹ̀bùn fún ènìyàn:
nítòótọ́, fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ pẹ̀lú,
    Olúwa Ọlọ́run lè máa bá wọn gbé.

19 Olùbùkún ni Olúwa,
    Ọlọ́run Olùgbàlà wa,
ẹni tí ó ń fi ojoojúmọ́ gba ẹrù wa rù. Sela.
20 Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run tó ń gbàlà
    àti sí Olúwa Olódùmarè ni ó ń gbà wá lọ́wọ́ ikú.

21 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò tẹ orí àwọn ọ̀tá rẹ̀,
    àti agbárí onírun àwọn tó ń tẹ̀síwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn
22 Olúwa wí pé, “Èmi ó mú wọn wá láti Baṣani;
    èmi ó mú wọn wá láti ibú omi Òkun,
23 Kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó le pọ́n ní inú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá rẹ,
    àti ahọ́n àwọn ajá rẹ ní ìpín tiwọn lára àwọn ọ̀tá rẹ.”

24 Wọ́n ti rí ìrìn rẹ, Ọlọ́run,
    ìrìn Ọlọ́run mi àti ọba mi ní ibi mímọ́ rẹ̀.
25 Àwọn akọrin ní iwájú,
    tí wọn ń lu ṣaworo
26 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa ní ẹgbẹgbẹ́;
    àní fún Olúwa ẹ̀yin tí ó ti orísun Israẹli wá.
27 Níbẹ̀ ní ẹ̀yà kékeré Benjamini wà, tí ó ń darí wọn,
    níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Juda,
    níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Sebuluni àti tí Naftali.

28 Pàṣẹ agbára rẹ, Ọlọ́run;
    fi agbára rẹ hàn wá, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe ní ìṣáájú.
29 Nítorí tẹmpili rẹ ni Jerusalẹmu
    àwọn ọba yóò mú ẹ̀bùn wá fún ọ.
30 Bá àwọn ẹranko búburú wí,
    tí ń gbé láàrín eèsún
ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọ màlúù
    pẹ̀lú àwọn ọmọ màlúù
títí olúkúlùkù yóò fi foríbalẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀n fàdákà:
    tú àwọn ènìyàn tí ń ṣe inú dídùn sí ogun ká
31 Àwọn ọmọ-aládé yóò wá láti Ejibiti;
    Etiopia yóò na ọwọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run.

32 Kọrin sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ìjọba ayé,
    kọrin ìyìn sí Olúwa, Sela.
33 Sí ẹni tí ń gun ọ̀run dé ọ̀run àtijọ́ lókè,
    tó ń fọhùn rẹ̀, ohùn ńlá.
34 Kéde agbára Ọlọ́run,
    ọláńlá rẹ̀ wà lórí Israẹli,
    tí agbára rẹ̀ wà lójú ọ̀run.
35 Ìwọ ní ẹ̀rù, Ọlọ́run, ní ibi mímọ́ rẹ;
    Ọlọ́run Israẹli fi agbára àti okun fún àwọn ènìyàn rẹ.

Olùbùkún ní Ọlọ́run!

Jeremiah 2:1-13

Israẹli kọ Ọlọ́run sílẹ̀

Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé: “Lọ kí o sì kéde sí etí Jerusalẹmu pé:

“Báyìí ni Olúwa wí,

“ ‘Èmi rántí ìṣeun ìgbà èwe rẹ,
    ìfẹ́ ìgbéyàwó rẹ
àti nígbà tí ìwọ tẹ̀lé mi nínú ijù,
    nínú ìyàngbẹ ilẹ̀.
Israẹli jẹ́ mímọ́ sí Olúwa,
    àkọ́kọ́ èso ìkórè rẹ̀,
gbogbo ẹnikẹ́ni tí ó jẹ run ni a ó dá lẹ́bi,
    ibi yóò sì wá sí orí wọn,’ ”
    bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.

Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ìdílé Jakọbu
    àti gbogbo ẹ̀yin ará ilé Israẹli.

Báyìí ni Olúwa wí:

“Irú àìṣedéédéé wo ni baba yín rí lọ́wọ́ mi?
Tí wọ́n fi jìnnà sí mi?
    Wọ́n tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán,
    àwọn fúnrawọn sì di asán.
Wọn kò béèrè, ‘Níbo ni Olúwa wà,
    tí ó mú wa jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá,
tí ó mú wa la aginjù já,
    tí ó mú wa la àárín pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ihò,
ìyàngbẹ ilẹ̀ àti òkùnkùn biribiri,
    ilẹ̀ ibi tí ẹnikẹ́ni kò là kọjá, tí ẹnikẹ́ni kò sì tẹ̀dó sí?’
Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ ọlọ́ràá
    láti máa jẹ èso ibẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀,
ṣùgbọ́n ẹ̀yin wọ inú rẹ̀, ẹ sì bà á jẹ́,
    ẹ sì sọ ogún mi di ohun ìríra.
Àwọn àlùfáà kò béèrè wí pé,
    ‘Níbo ni Olúwa wà?’
Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òfin kò si mọ̀ mí,
    àwọn olùṣọ́ sì ṣẹ̀ sí mi.
Àwọn wòlíì sì ń sọtẹ́lẹ̀ nípa òrìṣà Baali,
    wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán.

“Nítorí náà, mo fi ẹ̀sùn kàn yín lẹ́ẹ̀kan sí i,”
    ni Olúwa wí.
    “Èmi ó sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ọwọ́ rẹ
10 Rékọjá lọ sí erékùṣù àwọn ara Kittimu, kí ẹ sì wò ó,
    ránṣẹ́ lọ sí Kedari, kí ẹ sì kíyèsi gidigidi
kí ẹ wò bí irú nǹkan báyìí bá ń bẹ níbẹ̀?
11 Orílẹ̀-èdè kan ha á pa Ọlọ́run rẹ̀ dà?
    (Síbẹ̀, wọ́n kì í ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run)
àwọn ènìyàn mi ti pààrọ̀
    ògo wọn fún àwọn ère tí kò níyì.
12 Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì
    kí ẹ sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù ńlá,”
    ni Olúwa wí.
13 “Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì
    Wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, Èmi
orísun omi ìyè, wọ́n sì ti
    ṣe àmù, àmù fífọ́ tí kò lè
    gba omi dúró.

Romu 1:16-25

16 (A)Èmi kò tijú ìhìnrere Jesu, nítorí agbára Ọlọ́run ní ín ṣe láti gba gbogbo àwọn tí ó bá gbàgbọ́ là, ọ̀rọ̀ yìí ni a kọ́kọ́ wàásù sí àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nísinsin yìí fún àwọn Helleni pẹ̀lú. 17 (B)Nítorí nínú ìhìnrere ni òdodo Ọlọ́run ti farahàn, òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé Mímọ́ pé, “Olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.”

Ìbínú Ọlọ́run sí orílẹ̀ ayé

18 (C)Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ hàn láti ọ̀run wá sí gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti gbogbo àìṣòdodo ènìyàn, àwọn tí ń fi ìwà búburú dènà ìmọ̀ òtítọ́ lọ́dọ̀ ènìyàn. 19 Nítorí pé, nǹkan gbogbo tí a lè mọ nípa Ọlọ́run ni a ti fihàn fún wọn, nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn. 20 (D)Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀: bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí.

21 (E)Lóòótọ́, wọn ní òye nípa Ọlọ́run dáradára, ṣùgbọ́n wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, wọ́n kò sí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀; wọ́n ń ro èrò asán, ọkàn aṣiwèrè wọn sì ṣókùnkùn. 22 Níwọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n pe ara wọn ní ọlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n wọ́n di òmùgọ̀ pátápátá, 23 (F)wọ́n sì yí ògo Ọlọ́run tí kì í díbàjẹ́ sí àwọn àwòrán ère bí i ti ènìyàn tí í díbàjẹ́ àti ti ẹyẹ, àti ti ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti ti ẹranko afàyàfà.

24 Nítorí náà Ọlọ́run fà wọ́n lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun ìríra pẹ̀lú ara wọn èyí tí kò tọ́. 25 Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọ́run sí èké, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ láti máa sin ẹ̀dá dípò ẹlẹ́dàá—ẹni tí ìyìn tọ́ sí láéláé. Àmín.

Johanu 4:43-54

Jesu wo ọmọkùnrin ọlọ́lá san

43 Lẹ́yìn ọjọ́ méjì ó sì ti ibẹ̀ kúrò, ó lọ sí Galili. 44 (A)Nítorí Jesu tìkára rẹ̀ ti jẹ́rìí wí pé, Wòlíì kì í ní ọlá ní ilẹ̀ òun tìkára rẹ̀. 45 Nítorí náà nígbà tí ó dé Galili, àwọn ará Galili gbà á, nítorí ti wọ́n ti rí ohun gbogbo tí ó ṣe ní Jerusalẹmu nígbà àjọ ìrékọjá; nítorí àwọn tìkára wọn lọ sí àjọ pẹ̀lú.

46 (B)Bẹ́ẹ̀ ni Jesu tún wá sí Kana ti Galili, níbi tí ó gbé sọ omi di wáìnì. Ọkùnrin ọlọ́lá kan sì wá, ẹni tí ara ọmọ rẹ̀ kò dá ní Kapernaumu. 47 Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ti Judea wá sí Galili, ó tọ̀ ọ́ wá, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, kí ó lè sọ̀kalẹ̀ wá kí ó mú ọmọ òun láradá: nítorí tí ó wà ní ojú ikú.

48 (C)Nígbà náà ni Jesu wí fún un pé, “Bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá rí ààmì àti iṣẹ́ ìyanu, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́ láé.”

49 Ọkùnrin ọlọ́lá náà wí fún un pé, “Olúwa, sọ̀kalẹ̀ wá kí ọmọ mi tó kú.”

50 Jesu wí fún un pé, “Máa bá ọ̀nà rẹ lọ; ọmọ rẹ yóò yè.”

Ọkùnrin náà sì gba ọ̀rọ̀ Jesu gbọ́, ó sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 51 Bí ó sì ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pàdé rẹ̀, wọ́n sì wí fún un pé, ọmọ rẹ ti yè. 52 Nígbà náà ni ó béèrè wákàtí tí ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yá lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì wí fún un pé, “Ní àná, ní wákàtí keje ni ibà náà fi í sílẹ̀.”

53 (D)Bẹ́ẹ̀ ni baba náà mọ̀ pé ní wákàtí kan náà ni, nínú èyí tí Jesu wí fún un pé “Ọmọ rẹ̀ yè.” Òun tìkára rẹ̀ sì gbàgbọ́, àti gbogbo ilé rẹ̀.

54 (E)Èyí ni iṣẹ́ ààmì kejì tí Jesu ṣe nígbà tí ó ti Judea jáde wá sí Galili.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.