Add parallel Print Page Options

Ó jẹ́ ìdùnnú fún mi láti fi iṣẹ́ ààmì àti ìyanu tí Ọlọ́run Ọ̀gá-Ògo ti ṣe fún mi hàn.

Read full chapter

22 (A)Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn wòlíì èké ni yóò wá, wọn yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu tí yóò tan ènìyàn jẹ hàn. Bí ó bá ṣe é ṣe, wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ pàápàá jẹ.

Read full chapter

19 Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn lójú ọ̀run,
    àti àwọn ààmì nísàlẹ̀ ilẹ̀;
    ẹ̀jẹ̀ àti iná àti rírú èéfín;

Read full chapter

30 Kí ìwọ sì fi nína ọwọ́ rẹ ṣe ìmúláradá, àti kí iṣẹ́ ìyanu máa ṣẹ̀ ní orúkọ Jesu ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ.”

Read full chapter

19 (A)nípa agbára iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu, nípa agbára Ẹ̀mí Ọlọ́run, tó bẹ́ẹ̀ láti Jerusalẹmu àti yíkákiri, àní títí fi dé Illirikoni, mo ti polongo ìhìnrere Kristi ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

Read full chapter

Ọlọ́run jẹ́rìí sí i nípa àwọn iṣẹ́ ààmì àti ìyanu àti oríṣìíríṣìí iṣẹ́ agbára àti nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ tí a pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀.

Read full chapter