Book of Common Prayer
95 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a kọ orin ayọ̀ sí Olúwa
Ẹ jẹ́ kí a kígbe sókè sí àpáta ìgbàlà wa.
2 Ẹ jẹ́ kí a wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
kí a sì pòkìkí rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò
orin àti ìyìn.
3 Nítorí Olúwa Ọlọ́run títóbi ni,
ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.
4 Ní ọwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà,
ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe.
5 Tirẹ̀ ni Òkun, nítorí òun ni ó dá a
àti ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.
6 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a foríbalẹ̀ kí a sìn ín,
Ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú
Olúwa ẹni tí ó dá wa;
7 (A)Nítorí òun ni Ọlọ́run wa
àwa sì ni ènìyàn pápá rẹ̀,
àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ rẹ̀.
Lónìí tí ìwọ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
8 “Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Meriba,
àti bí ẹ ti ṣe ní ọjọ́ náà ní Massa ní aginjù,
9 Nígbà tí àwọn baba yín dán mi wò
tí wọn wádìí mi,
tí wọn sì rí iṣẹ́ mi
10 Fún ogójì ọdún ni èmi fi bínú sí ìran náà;
mo wí pé, ‘Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ọkàn wọn ṣáko lọ
wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’
11 Nítorí náà ni mo kéde ìbúra nínú ìbínú mi
‘Wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi.’ ”
Ti Dafidi. Maskili.
32 (A)Ìbùkún ni fún àwọn
tí a dárí ìrékọjá wọn jì,
tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.
2 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà
ẹni tí Ọlọ́run kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí i lọ́rùn
àti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.
3 Nígbà tí mo dákẹ́,
egungun mi di gbígbó dànù
nípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́.
4 Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru
ọwọ́ rẹ̀ wúwo sí mi lára;
agbára mi gbẹ tán
gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn. Sela.
5 Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ
àti pé èmi kò sì fi àìṣòdodo mi pamọ́.
Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́
ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,”
ìwọ sì dárí
ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Sela.
6 Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọ
ní ìgbà tí a lè rí ọ;
nítòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè,
wọn kì yóò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀.
7 Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi;
ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu;
ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela.
8 Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà tí ìwọ yóò rìn
èmi yóò máa gbà ọ́ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ.
9 Má ṣe dàbí ẹṣin tàbí ìbáaka,
tí kò ní òye
ẹnu ẹni tí a gbọdọ̀ fi ìjánu bọ̀,
kí wọn má ba à súnmọ́ ọ.
10 Ọ̀pọ̀ ìkáàánú ní yóò wà fún ènìyàn búburú,
ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa tí ó dúró ṣinṣin
ni yóò yí àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ká.
11 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, kí ẹ sì ní inú dídùn, ẹ̀yìn olódodo;
ẹ sì máa kọrin, gbogbo ẹ̀yìn tí àyà yín dúró ṣinṣin.
Saamu ti Dafidi.
143 Olúwa gbọ́ àdúrà mi,
fetísí igbe mi fún àánú;
nínú òtítọ́ àti òdodo rẹ, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi
2 (A)Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìdájọ́,
nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè
tí ó ṣe òdodo níwájú rẹ.
3 Ọ̀tá ń lépa mi,
ó fún mi pamọ́ ilẹ̀;
ó mú mi gbé nínú òkùnkùn
bí àwọn tí ó ti kú ti pẹ́.
4 Nítorí náà ẹ̀mí mi ṣe rẹ̀wẹ̀sì nínú mi;
ọkàn mi nínú mi ṣì pòruurù.
5 Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́;
èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ
mo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ rẹ ti ṣe.
6 Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ:
òǹgbẹ rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀. Sela.
7 Dá mi lóhùn kánkán, Olúwa;
ó rẹ ẹ̀mí mi tán.
Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lára mi
kí èmi má ba à dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò
8 Mú mi gbọ́ ìṣeun ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀:
nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé.
Fi ọ̀nà tí èmi i bá rìn hàn mí,
nítorí èmi gbé ọkàn mi sókè sí ọ.
9 Gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Olúwa,
nítorí èmi fi ara mi pamọ́ sínú rẹ.
10 Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ rẹ,
nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi
jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ dídára
darí mi sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.
11 Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa, sọ mi di ààyè;
nínú òdodo rẹ, mú ọkàn mi jáde nínú wàhálà.
12 Nínú ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà, ké àwọn ọ̀tá mi kúrò,
run gbogbo àwọn tí ń ni ọkàn mi lára,
nítorí pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ.
Àdúrà olùpọ́njú tí àárẹ̀ mú, tí ó sí ọkàn rẹ̀ payá níwájú Olúwa
102 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa:
Jẹ́ kí igbe ẹ̀bẹ̀ mi kí ó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ
2 Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi
ní ọjọ́ tí èmi wà nínú ìpọ́njú.
Dẹ etí rẹ sí mi;
nígbà tí mo bá pè, dá mi lóhùn kíákíá.
3 Nítorí tí ọjọ́ mi run bí èéfín;
egungun mi sì jóná bí ààrò
4 Àyà mi lù, ó sì rọ bí i koríko;
mo gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi.
5 Nítorí ohùn ìkérora mi,
egungun mi lẹ̀ mọ́ ẹran-ara mi.
6 Èmi dàbí ẹyẹ igún ní ijù:
èmi dàbí òwìwí ibi ahoro.
7 Èmi dìde; èmi dàbí ẹyẹ lórí ilé.
8 Ní ọjọ́ gbogbo, àwọn ọ̀tá ológoṣẹ́ mi ń gàn mí;
àwọn tí ń ṣe ìkanra sí mi ń fi orúkọ mi bú.
9 Èmi jẹ eérú gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ mi, èmi sì da ohun mímu mi pọ̀ pẹ̀lú omijé.
10 Nítorí ìbínú ríru rẹ, nítorí ìwọ ti gbé mi sókè, ìwọ sì gbé mi ṣánlẹ̀.
11 Ọjọ́ mi dàbí òjìji àṣálẹ́
èmi sì rọ bí koríko.
12 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, ni yóò dúró láéláé;
ìrántí rẹ láti ìran dé ìran.
13 Ìwọ ó dìde ìwọ ó sì ṣàánú fún Sioni,
nítorí ìgbà àti ṣe ojúrere sí i;
àkókò náà ti dé.
14 Nítorí tí àwọn òkúta jẹ́ inú dídùn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ;
wọ́n sì káàánú erùpẹ̀ rẹ.
15 Àwọn kèfèrí yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa,
gbogbo ọba ayé yóò máa bẹ̀rù ògo rẹ.
16 Torí tí Olúwa yóò gbé Sioni ró, yóò farahàn nínú ògo rẹ̀.
17 Yóò dáhùn àdúrà àwọn aláìní;
kì yóò sì gan ẹ̀bẹ̀ wọn.
18 Jẹ́ kí a kọ èyí fún ìran tí ń bọ̀,
àwọn ènìyàn tí a kò tí ì dá yóò yin Olúwa:
19 “Olúwa wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá
láti ọ̀run wá ni ó bojú wo ayé,
20 Láti gbọ́ ìrora ará túbú, láti tú
àwọn tí a yàn sí ikú sílẹ̀.”
21 Kí a lè sọ orúkọ Olúwa ní Sioni
àti ìyìn rẹ̀ ní Jerusalẹmu.
22 Ní ìgbà tí a kó àwọn ènìyàn àti
ìjọba pọ̀ láti máa sìn Olúwa.
23 Ní ipa ọ̀nà mi, ó rẹ agbára mi sílẹ̀,
ó gé ọjọ́ mi kúrú.
24 Èmi sì wí pé;
“Ọlọ́run mi, má ṣe mú mi kúrò ní agbede-méjì ọjọ́ mi; ọdún rẹ̀ ń lọ láti ìran dé ìran.
25 (A)Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,
ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
26 Wọn yóò ṣègbé, wọn yóò parun, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà;
gbogbo wọn ni yóò gbó bí aṣọ.
Bí ẹ̀wù ni ìwọ yóò pààrọ̀ wọn
wọn yóò sì di àpatì.
27 Ṣùgbọ́n ìwọ wà digbí síbẹ̀,
ọdún rẹ kò sì ní òpin.
28 Àwọn ọmọ ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò dúró ní iwájú rẹ pẹ́;
a ó sì fi ẹsẹ̀ irú-ọmọ wọn sọlẹ̀ ní iwájú rẹ.”
Orin fún ìgòkè.
130 Láti inú ibú wá ni
èmi ń ké pè é ọ́ Olúwa
2 Olúwa, gbóhùn mi,
jẹ́ kí etí rẹ kí o tẹ́ sílẹ̀ sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
3 (A)Olúwa, ìbá ṣe pé kí ìwọ máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀,
Olúwa, tá ni ìbá dúró.
4 Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ,
kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.
5 Èmi dúró de Olúwa, ọkàn mi dúró,
àti nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí
6 Ọkàn mi dúró de Olúwa,
ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ,
àní ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.
7 Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa:
nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà,
àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáǹdè wà.
8 Òun ó sì dá Israẹli ní ìdè
kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbogbo.
Jona lọ si Ninefe
3 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jona wá nígbà kejì wí pé: 2 “Dìde lọ sí Ninefe, ìlú ńlá a nì, kí o sì kéde sí i, ìkéde tí mo sọ fún ọ.”
3 Jona sì dìde ó lọ sí Ninefe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa. Ninefe jẹ́ ìlú títóbi gidigidi, ó tó ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. 4 Jona sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ ìlú náà lọ ní ìrìn ọjọ́ kan, ó sì ń kéde, ó sì wí pé, “Níwọ́n ogójì ọjọ́ sí i, a ó bi Ninefe wó.” 5 Àwọn ènìyàn Ninefe sì gba Ọlọ́run gbọ́. Wọ́n sì kéde àwẹ̀, gbogbo wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, bẹ̀rẹ̀ láti orí ọmọdé títí dé orí àgbà wọn.
6 Ọ̀rọ̀ náà sì dé ọ̀dọ̀ ọba Ninefe, ó sì dìde kúrò lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì bọ́ aṣọ ìgúnwà rẹ̀ kúrò lára rẹ̀, ó sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì jókòó nínú eérú. 7 Nígbà náà ní ó kéde rẹ̀ ni Ninefe pé:
“Kí a la Ninefe já nípa àṣẹ ọba, àti àwọn àgbàgbà rẹ̀ pé:
“Má ṣe jẹ́ kí ènìyàn, tàbí ẹranko, ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo ẹran, tọ́ ohunkóhun wò: má jẹ́ kí wọn jẹ tàbí mu omi. 8 Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn àti ẹranko da aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara, kí wọn sì kígbe kíkan sí Ọlọ́run, sì jẹ́ kí wọn yípadà, olúkúlùkù kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀ àti kúrò ní ìwà ìpa tí ó wà lọ́wọ́ wọn. 9 (A)Ta ni ó lè mọ̀ bí Ọlọ́run yóò yípadà kí ó sì ronúpìwàdà, kí ó sì yípadà kúrò ní ìbínú gbígbóná rẹ̀, kí àwa má ṣègbé?”
10 Ọlọ́run sì rí ìṣe wọn pé wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀nà ibi wọn: Ọlọ́run sì ronúpìwàdà ibi tí òun ti wí pé òun yóò ṣe sí wọn, òun kò sì ṣe e mọ́.
Jona bínú sí àánú tí Olúwa fihàn
4 Ṣùgbọ́n ó ba Jona nínú jẹ́ gidigidi, ó sì bínú púpọ̀. 2 (B)Ó sì gbàdúrà sí Olúwa, ó sì wí pé, “Èmí bẹ̀ ọ́, Olúwa, ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ti mo sọ kọ́ ni èyí nígbà tí mo wà ní ilẹ̀ mi? Nítorí èyí ni mo ṣé sálọ sí Tarṣiṣi ní ìṣáájú: nítorí èmi mọ̀ pé, Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́ ní ìwọ, àti aláàánú, O lọ́ra láti bínú, O sì ṣeun púpọ̀, O sì ronúpìwàdà ibi náà. 3 Ǹjẹ́ báyìí, Olúwa, èmi bẹ̀ ọ, gba ẹ̀mí mi kúrò lọ́wọ́ mi nítorí ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láààyè lọ.”
4 Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ìwọ́ ha ni ẹ̀tọ́ láti bínú bí?”
5 Jona sì jáde kúrò ní ìlú náà, ó sì jókòó níhà ìlà-oòrùn ìlú náà. Ó sì pa àgọ́ kan níbẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì jókòó ni òjìji ní abẹ́ rẹ̀ títí yóò fi rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ìlú náà. 6 Olúwa Ọlọ́run sì pèsè ìtàkùn kan, ó ṣe é kí ó gòkè wá sórí Jona; kí ó lè ṣe ìji bò ó lórí; láti gbà á kúrò nínú ìbànújẹ́ rẹ̀. Jona sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìtàkùn náà. 7 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run pèsè kòkòrò kan nígbà tí ilẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kejì, ó sì jẹ ìtàkùn náà ó sì rọ. 8 Ó sì ṣe, nígbà tí oòrùn yọ, Ọlọ́run pèsè ẹ̀fúùfù gbígbóná tí ìlà-oòrùn; oòrùn sì pa Jona lórí tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi rẹ̀ ẹ́. Ó sì fẹ́ nínú ara rẹ̀ láti kú, ó sì wí pé, “Ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láààyè lọ.”
9 Ọlọ́run sì wí fún Jona pé, “O ha tọ́ fún ọ láti bínú nítorí ìtàkùn náà?”
Òun sì wí pé, “Mo ni ẹ̀tọ́, o tọ́ fún mi láti bínú títí dé ikú.”
10 Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ìwọ kẹ́dùn ìtàkùn náà, nítorí èyí tí ìwọ kò ṣiṣẹ́ fun, tí ìwọ kò mu dàgbà; tí ó hù jáde ní òru kan tí ó sì kú ni òru kan. 11 Ṣùgbọ́n Ninefe ní jù ọ̀kẹ́ mẹ́fà (12,000) ènìyàn nínú rẹ̀, tí wọn kò mọ ọwọ́ ọ̀tún wọn yàtọ̀ sí ti òsì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọ̀sìn pẹ̀lú. Ṣé èmí kò ha ní kẹ́dùn nípa ìlú ńlá náà?”
Ìbáwí àwọn ọmọ Ọlọ́run
12 Nítorí náà bí a ti fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ tí o kún fún àwọn ẹlẹ́rìí tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tì sí apá kan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa, 2 (A)Kí a máa wo Jesu Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ, tí o faradà àgbélébùú láìka ìtìjú sí, tí ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run. 3 Máa ro ti ẹni tí ó faradà irú ìṣọ̀rọ̀-òdì yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ si ara rẹ̀, kí ẹ má ba á rẹ̀wẹ̀sì ni ọkàn yín, kí àárẹ̀ si mu yín.
4 Ẹ̀yin kò sá à tí ì kọ ojú ìjà si ẹ̀ṣẹ̀ títí dé títa ẹ̀jẹ̀ yín sílẹ̀ nínú ìjàkadì yín. 5 (B)Ẹ̀yin sì ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó n ba yin sọ̀rọ̀ bí ọmọ pé,
“Ọmọ mi, ma ṣe aláìnání ìbáwí Olúwa,
kí o má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí a bá ń ti ọwọ́ rẹ̀ ba ọ wí:
6 Nítorí pé ẹni ti Olúwa fẹ́, òun ni i bá wí,
a sì máa na olúkúlùkù ọmọ tí òun tẹ́wọ́gbà.”
7 Ẹ máa ní sùúrù lábẹ́ ìbáwí: Ọlọ́run bá wa lò bí ọmọ ni; nítorí pé ọmọ wo ni ń bẹ ti baba kì í bá wí? 8 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ba wà láìsí ìbáwí, nínú èyí tí gbogbo ènìyàn ti jẹ alábápín, ǹjẹ́ ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í sì ṣe ọmọ. 9 Pẹ̀lúpẹ̀lú àwa ni baba wa nípa ti ara tí o ń tọ́ wa, àwa sì ń bu ọlá fún wọn: kò ha yẹ kí a kúkú tẹríba fún Baba àwọn ẹ̀mí, kí a sì yè? 10 Nítorí wọ́n tọ́ wa fún ọjọ́ díẹ̀ bí o bá ti dára lójú wọn; ṣùgbọ́n òun (tọ́ wa) fún èrè wa, kí àwa lè ṣe alábápín ìwà mímọ́ rẹ̀. 11 Gbogbo ìbáwí kò dàbí ohun ayọ̀ nísinsin yìí bí kò ṣe ìbànújẹ́; ṣùgbọ́n níkẹyìn yóò so èso àlàáfíà fún àwọn tí a tọ́ nípa rẹ̀, àní èso òdodo.
12 (C)Nítorí náà, ẹ na ọwọ́ tí ó rọ, àti eékún àìlera; 13 (D)“Kí ẹ sì ṣe ipa ọ̀nà tí ó tọ́ fún ẹsẹ̀ yin,” kí èyí tí ó rọ má bá a kúrò lórí ike ṣùgbọ́n kí a kúkú wò ó sàn.
Ìkìlọ̀ lòdì sí kíkọ Ọlọ́run
14 Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú ènìyàn gbogbo, àti ìwà mímọ́, láìsí èyí yìí kò sí ẹni tí yóò rí Olúwa:
Òwe Farisi àti agbowó òde
9 Ó sì pa òwe yìí fún àwọn kan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ara wọn pé, àwọn ni olódodo, tí wọ́n sì ń gan àwọn ẹlòmíràn; 10 Pé, “Àwọn ọkùnrin méjì gòkè lọ sí tẹmpili láti gbàdúrà, ọ̀kan jẹ́ Farisi, èkejì sì jẹ́ agbowó òde. 11 (A)Èyí Farisi dìde, ó sì ń gbàdúrà nínú ara rẹ̀ báyìí pé, ‘Ọlọ́run mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí èmi kò rí bí àwọn ará ìyókù, àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà, aláìṣòótọ́, panṣágà, tàbí bí agbowó òde yìí. 12 (B)Èmi ń gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì ní ọ̀sẹ̀, mo ń san ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí mo ní.’
13 “Ṣùgbọ́n agbowó òde dúró lókèèrè, kò tilẹ̀ jẹ́ gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ṣùgbọ́n ó lu ara rẹ̀ ní oókan àyà, ó wí pé, ‘Ọlọ́run ṣàánú fún mi, èmi ẹlẹ́ṣẹ̀!’
14 (C)“Mo wí fún yín, ọkùnrin yìí sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀ ní ìdáláre ju èkejì lọ: nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, òun ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá sì rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ òun ni a ó gbéga.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.