Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Tí ohùn “Má ṣe parun.” Saamu ti Asafu. Orin.
75 A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run,
a yìn ọ́, nítorí orúkọ rẹ súnmọ́ tòsí;
àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu rẹ.
2 Ìwọ wí pé, “Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀;
Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo.
3 Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì,
Èmi ni mo di òpó rẹ̀ mú ṣinṣin.
4 Èmí wí fún àwọn agbéraga pé
Ẹ má ṣe gbéraga mọ́;
àti sí ènìyàn búburú;
Ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè.
5 Ẹ má ṣe gbe ìwo yín sókè sí ọ̀run;
ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọrùn líle.”
6 Nítorí ìgbéga kò ti ìlà-oòrùn wá
tàbí ní ìwọ̀-oòrùn,
bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti gúúsù wá.
7 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdájọ́;
Ó ń rẹ ẹnìkan sílẹ̀, ó sì ń gbé ẹlòmíràn ga.
8 Ní ọwọ́ Olúwa ni ago kan wà,
ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú,
ó fún ọtí àdàlú tí a pò mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde,
àwọn ènìyàn búburú ayé gbogbo mú u pátápátá.
9 Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn rẹ títí láé;
Èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jakọbu.
10 Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú,
Ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Asafu. Orin.
76 Ní Juda ni a mọ Ọlọ́run;
orúkọ rẹ̀ sì lágbára ní Israẹli
2 Àgọ́ rẹ̀ wà ní Salẹmu,
ibùgbé rẹ̀ ni Sioni.
3 Níbẹ̀ ni ó ṣẹ́ ọfà,
asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun. Sela.
4 Ìwọ ni ògo àti ọlá
Ju òkè ńlá ìkógun wọ̀nyí lọ.
5 A kó àwọn alágídí ọkàn ní ìkógun
wọ́n sun oorun ìgbẹ̀yìn wọn;
kò sí ọ̀kan nínú àwọn akọni
tó lè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.
6 Ní ìfibú rẹ, Ọlọ́run Jakọbu,
àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.
7 Ìwọ nìkan ni ó yẹ kí a bẹ̀rù.
Ta ló lé dúró níwájú rẹ, nígbà tí ìwọ bá ń bínú?
8 Ìwọ ń ṣe ìdájọ́ láti ọ̀run,
ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ẹ́:
9 Nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run,
bá dìde láti ṣe ìdájọ́,
láti gba àwọn ẹni ìnilára ilẹ̀ náà. Sela.
10 Lóòótọ́, ìbínú rẹ sí àwọn ènìyàn ń mú ìyìn wá fún ọ,
ẹni tí ó yọ nínú ìbínú rẹ ní a dá nígbà tí ìwọ bá fi ìbínú ìyókù di ara rẹ ni àmùrè.
11 Jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì mú un ṣẹ;
kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká
mú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí ó tọ́ láti bẹ̀rù.
12 Ó ké ẹ̀mí àwọn aládé kúrò;
àwọn ọba ayé sì ń bẹ̀rù rẹ̀.
Saamu ti Dafidi.
23 Olúwa ni Olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.
2 (A)Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù
Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́;
3 Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò
Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo
nítorí orúkọ rẹ̀.
4 Bí mo tilẹ̀ ń rìn
Láàrín àfonífojì òjìji ikú,
èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan;
nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;
ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ
wọ́n ń tù mí nínú.
5 Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi
ní ojú àwọn ọ̀tá à mi;
ìwọ ta òróró sí mi ní orí;
ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.
6 Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn
ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo,
èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwa
títí láéláé.
Ti Dafidi.
27 Olúwa ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi;
ta ni èmi yóò bẹ̀rù?
Olúwa ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi,
ẹ̀rù ta ni yóò bà mí?
2 Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi
láti jẹ ẹran-ara mi,
àní àwọn ọ̀tá mi àti àwọn abínúkú mi,
wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.
3 Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi,
ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù;
bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi,
nínú èyí ni ọkàn mi yóò le.
4 Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa,
òhun ni èmi yóò máa wá kiri:
kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa
ní ọjọ́ ayé mi gbogbo,
kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa,
kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀.
5 Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú
òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀;
níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́;
yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta.
6 Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè
ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká;
èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀;
èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí Olúwa.
7 Gbọ́ ohùn mi nígbà tí ẹ̀mí bá à ń pè, Háà! Olúwa,
ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn;
8 “Wá,” ọkàn mi wí pé, “wá ojú u rẹ̀.”
Ojú rẹ, Olúwa, ni èmí ń wá.
9 Má ṣe fi ojú rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi,
má ṣe fi ìbínú sá ìránṣẹ́ rẹ tì;
ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi,
Má ṣe fi mí sílẹ̀, má sì ṣe kọ̀ mí,
háà! Ọlọ́run ìgbàlà mi.
10 Bí ìyá àti baba bá kọ̀ mí sílẹ̀,
Olúwa yóò tẹ́wọ́ gbà mí.
11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,
kí o sì sìn mi lọ sí ọ̀nà tí ó tẹ́jú
nítorí àwọn ọ̀tá mi.
12 Má ṣe fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́,
nítorí àwọn ẹlẹ́rìí èké ti dìde sí mi,
wọ́n sì mí ìmí ìkà.
13 Èmi ní ìgbàgbọ́ pé,
èmi yóò rí ìre Olúwa
ní ilẹ̀ alààyè.
14 Dúró de Olúwa;
kí ó jẹ alágbára, kí o sì mú ọkàn le
àní dúró de Olúwa.
20 “Kéde èyí fún ilé Jakọbu,
kí ẹ sì polongo rẹ̀ ní Juda.
21 (A)Gbọ́ èyí, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n ènìyàn,
tí ó lójú ti kò fi ríran
tí ó létí ti kò fi gbọ́rọ̀.
22 Kò ha yẹ kí ẹ bẹ̀rù mi?” ni Olúwa wí.
“Kò ha yẹ kí ẹ̀yin ó wárìrì níwájú mi bí?
Mo fi yanrìn pààlà Òkun,
èyí tí kò le è rékọjá rẹ̀ láéláé.
Ìjì lè jà, kò le è borí rẹ̀;
wọ́n le è bú, wọn kò le è rékọjá rẹ̀.
23 Ṣùgbọ́n, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọkàn líle àti ọkàn ọ̀tẹ̀,
wọ́n ti yípadà, wọ́n sì ti lọ.
24 Wọn kò sọ fún ara wọn pé,
‘Ẹ jẹ́ ká a bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa,
ẹni tí ó fún wa ní òjò àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní ìgbà rẹ̀,
tí ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa ìkórè ọ̀sẹ̀ déédé.’
25 Àìṣedéédéé yín mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí kúrò,
ẹ̀ṣẹ̀ yín sì mú kí a fi nǹkan rere dù yín.
26 “Láàrín ènìyàn mi ni ìkà ènìyàn wà
tí ó wà ní ibùba bí ẹni tí ó ń dẹ ẹyẹ,
àti bí àwọn tí ó ń dẹ pàkúté láti mú ènìyàn.
27 Bí àgò tí ó kún fún ẹyẹ,
ilé wọn sì kún fún ẹ̀tàn.
Wọ́n ti di ọlọ́lá àti alágbára,
28 Wọ́n sanra wọ́n sì ń dán.
Ìwà búburú wọn kò sì lópin;
wọn kò bẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ àwọn aláìní baba láti borí rẹ̀.
Wọn kò jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà.
29 Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n fún èyí bí?”
ni Olúwa wí.
“Èmi kì yóò wá gbẹ̀san ara mi
lára orílẹ̀-èdè bí èyí bí?
30 “Nǹkan ìbànújẹ́ àti ohun ìtara
ti ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà.
31 Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké,
àwọn àlùfáà sì ń ṣe àkóso pẹ̀lú àṣẹ ara wọn,
àwọn ènìyàn mi sì ní ìfẹ́ sí èyí,
kí ni ẹ̀yin yóò ṣe ní òpin?
19 (A)Àwa sì mọ̀ pé ohunkóhun tí òfin bá wí, ó ń wí fún àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin: kí gbogbo ẹnu bá à lè dákẹ́ àti kí a lè mú gbogbo aráyé wá sábẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run. 20 (B)Nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin, a kì yóò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú rẹ̀: nítorí nípa òfin ni ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ti wá.
Ìṣòdodo nípa ìgbàgbọ́
21 (C)Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, a ti fi òdodo Ọlọ́run hàn láìsí òfin, tí a ti ń jẹ́rìí sí nípa òfin àti nípa àwọn wòlíì; 22 (D)Àní òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, sí gbogbo ènìyàn àti gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́: nítorí tí kò sí ìyàtọ̀ láàrín Júù àti Helleni. 23 (E)Gbogbo ènìyàn ni ó ṣá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run: 24 (F)Àwọn ẹni tí a ń dá láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kristi Jesu: 25 Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run: 26 (G)Láti fi òdodo rẹ̀ hàn ní ìgbà ìsinsin yìí: kí ó lè jẹ́ olódodo àti olùdáláre ẹni tí ó gba Jesu gbọ́.
27 Ọ̀nà ìṣògo dà? A ti mú un kúrò. Nípa òfin wo? Nípa iṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ kọ́: Ṣùgbọ́n nípa òfin ìgbàgbọ́. 28 (H)Nítorí náà a parí rẹ̀ sí pé nípa ìgbàgbọ́ ni a ń dá ènìyàn láre láìsí iṣẹ́ òfin. 29 (I)Ọlọ́run àwọn Júù nìkan ha ni bí? Kì í ha ṣe ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú? Bẹ́ẹ̀ ni, ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú: 30 (J)Bí ó ti jẹ́ pé Ọlọ́run kan ni, yóò dá àwọn akọlà láre nípa Ìgbàgbọ́ àti àwọn aláìkọlà nípa ìgbàgbọ́ wọn. 31 (K)Àwa ha ń sọ òfin dasán nípa ìgbàgbọ́ bí? Kí a má rí i: ṣùgbọ́n a ń fi òfin múlẹ̀.
Jesu lọ sí àjọ ìpàgọ́
7 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Jesu ń rìn ní Galili: nítorí tí kò fẹ́ rìn ní Judea, nítorí àwọn Júù ń wá a láti pa. 2 (A)Àjọ àwọn Júù tí í ṣe àjọ àgọ́ súnmọ́ etílé tan. 3 (B)Nítorí náà, àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, “Lọ kúrò níhìn-ín-yìí, kí o sì lọ sí Judea, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pẹ̀lú lè fi iṣẹ́ rẹ hàn fún aráyé. 4 Nítorí pé kò sí ẹnikẹ́ni tí í ṣe ohunkóhun níkọ̀kọ̀, tí òun tìkára rẹ̀ sì ń fẹ́ kí a mọ òun ní gbangba. Bí ìwọ bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, fi ara rẹ hàn fún aráyé.” 5 Nítorí pé àwọn arákùnrin rẹ̀ pàápàá kò tilẹ̀ gbà á gbọ́.
6 (C)Nítorí náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Àkókò gan an fún mi kò tí ì dé; fún ẹ̀yin, gbogbo àkókò ni ó dára fún yín. 7 (D)Ayé kò lè kórìíra yín; ṣùgbọ́n èmi ni ó kórìíra, nítorí tí mo jẹ́rìí gbé é pé, iṣẹ́ rẹ̀ burú. 8 Ẹ̀yin ẹ gòkè lọ sí àjọ yìí: èmi kì yóò tí ì gòkè lọ sí àjọ yìí; nítorí tí àkókò mi kò ì tí ì dé.” 9 Nígbà tí ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn tan, ó dúró ní Galili síbẹ̀.
10 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ gòkè lọ tan, nígbà náà ni òun sì gòkè lọ sí àjọ náà pẹ̀lú, kì í ṣe ní gbangba, ṣùgbọ́n bí ẹni pé níkọ̀kọ̀. 11 Nígbà náà ni àwọn Júù sì ń wá a kiri nígbà àjọ wí pé, “Níbo ni ó wà?”
12 (E)Ìkùnsínú púpọ̀ sì wà láàrín àwọn ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀: nítorí àwọn kan wí pé, “Ènìyàn rere ní í ṣe.”
Àwọn mìíràn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n òun ń tan ènìyàn jẹ ni.” 13 (F)Ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní gbangba nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.