Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 83

Orin. Saamu ti Asafu.

83 Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́;
    Má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ẹ́.
Wo bí àwọn ọ̀tá rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ,
    bi àwọn ọ̀tá rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè.
Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ;
    wọn sí dìtẹ̀ mọ́ àwọn tí o fẹ́.
Wọn wí pé, “wá, ẹ jẹ́ kí á pa wọ́n run bí orílẹ̀-èdè,
    kí orúkọ Israẹli ma bá a sí ní ìrántí mọ́.”

Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan;
    wọ́n ṣe àdéhùn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ
Àgọ́ Edomu àti ti àwọn ará Iṣmaeli,
    ti Moabu àti ti Hagari
Gebali, Ammoni àti Amaleki,
    Filistia, pẹ̀lú àwọn ènìyàn Tire.
Asiria pẹ̀lú ti darapọ̀ mọ́ wọn
    láti ran àwọn ọmọ Lọti lọ́wọ́. Sela.

Ṣe sí wọn bí ìwọ ti ṣe sí Midiani
    bí o ti ṣe sí Sisera àti Jabini ní odò Kiṣoni,
10 Ẹni tí ó ṣègbé ní Endori
    tí wọn sì dàbí ààtàn ní orí ilẹ̀.
11 Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí Orebu àti Seebu,
    àwọn ọmọ-aládé wọn bí Seba àti Salmunna,
12 Tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbà ní ìní
    àní pápá oko tútù Ọlọ́run.”

13 Ìwọ Ọlọ́run, ṣe wọ́n bí ààjà,
    bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.
14 Bí iná ti í jó igbó,
    àti bí ọ̀wọ́-iná ti ń mú òkè ńlá gbiná,
15 Bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ẹ̀fúùfù líle rẹ lépa wọn
    dẹ́rùbà wọn lójú pẹ̀lú ìjì rẹ.
16 Fi ìtìjú kún ojú wọn,
    kí àwọn ènìyàn bá à lè ṣe àfẹ́rí orúkọ rẹ àti kí o fi ìjì líle rẹ dẹ́rùbà, ìwọ Olúwa.

17 Jẹ́ kí ojú kí ó tì wọ́n, kí wọ́n sì dààmú láéláé
    kí wọ́n ṣègbé sínú ẹ̀gàn
18 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa:
    pé ìwọ nìkan ní Ọ̀gá-ògo jùlọ lórí gbogbo ayé.

Saamu 42-43

ÌWÉ KEJÌ

Saamu 42–72

Fún adarí orin. Maskili ti àwọn ọmọ Kora.

42 Bí àgbọ̀nrín ti ń mí hẹlẹ sí ipa odò omi,
    bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń mí hẹlẹ sí ọ Ọlọ́run.
Òùngbẹ Ọlọ́run ń gbẹ ọkàn mi, fún Ọlọ́run alààyè.
    Nígbà wo ni èmi ó lọ bá Ọlọ́run?
Oúnjẹ mi ni omijé mi
    ní ọ̀sán àti ní òru,
    nígbà tí àwọn ènìyàn ń wí fún mi ní gbogbo ọjọ́ pé,
    “Ọlọ́run rẹ dà?”
Nígbà tí mo bá rántí nǹkan yìí,
    èmi tú ọkàn mi jáde nínú mi:
èmi ti bá ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn lọ,
    èmi bá wọn lọ sí ilé Ọlọ́run
pẹ̀lú ohùn ayọ̀ àti ìyìn,
    pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń pa ọjọ́ mímọ́ mọ́.

Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?
    Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?
Ìwọ ṣe ìrètí ní ti Ọlọ́run,
    nítorí èmi yóò sá à máa yìn ín,
    Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.

Ọlọ́run mi, ọkàn mi ń rẹ̀wẹ̀sì nínú mi:
    nítorí náà, èmi ó rántí rẹ
láti ilẹ̀ Jordani wá,
    láti Hermoni láti òkè Mibsari.
Ibú omi ń pe ibú omi
    nípa híhó omi ṣíṣàn rẹ̀
gbogbo rírú omi àti bíbì omi rẹ̀
    bò mí mọ́lẹ̀.

Ní ọ̀sán ní Olúwa ran ìfẹ́ rẹ̀,
    àti ni àṣálẹ́ ni orin rẹ̀ wà pẹ̀lú mi
àdúrà sí Ọlọ́run ayé mi.

Èmi wí fún Ọlọ́run àpáta mi,
    “Èéṣe tí ìwọ fi gbàgbé mi?
Èéṣe tí èmi o fi máa rìn nínú ìbànújẹ́,
    nítorí ìnilára ọ̀tá?”
10 Bí ẹni pé idà egungun mi ni ẹ̀gàn tí
    àwọn ọ̀tá mi ń gàn mí,
Bí wọn ti ń béèrè ní gbogbo ọjọ́.
    “Níbo ni Ọlọ́run rẹ wà?”

11 Èéṣe tí ìwọ fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?
    Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?
Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,
    nítorí èmi yóò sì máa yìn ín, Òun ni
    Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.
43 Dá mi láre, Ọlọ́run mi,
    kí o sì gba ọ̀rọ̀ mi rò lọ́dọ̀ àwọn aláìláàánú orílẹ̀-èdè:
yọ mí kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti àwọn ènìyàn búburú.
Ìwọ ni Ọlọ́run ibi agbára mi.
    Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mi sílẹ̀?
Èéṣe tí èmi yóò máa rìn nínú ìbìnújẹ́,
    nítorí ìnilára lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá?
Rán ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ rẹ jáde,
    jẹ́ kí wọn ó máa dáàbò bò mí;
jẹ́ kí wọn mú mi wá sí òkè mímọ́ rẹ,
    sí ibi tí ìwọ ń gbé.
Nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọ́run,
    sí Ọlọ́run ayọ̀ mi àti ìdùnnú mi,
èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú dùùrù,
    ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run mi.

Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mí?
    Èéṣe tí ó fi ń ru sókè nínú mi?
Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,
    nítorí èmi yóò máa yìn ín, Òun ni
    Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.

Saamu 85-86

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.

85 Ìwọ fi ojúrere hàn fún ilé rẹ, Olúwa;
    ìwọ mú ohun ìní Jakọbu bọ̀ sí ipò.
Ìwọ dárí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn rẹ jì
    ìwọ sì bó ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. Sela.
Ìwọ fi àwọn ìbínú rẹ sápá kan
    ìwọ sì yípadà kúrò nínú ìbínú gbígbóná rẹ.

Yí wa padà, Ọlọ́run ìgbàlà wa,
    kí o sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ wa.
Ìwọ yóò ha máa bínú sí wa títí láé?
    Ìwọ yóò ha mú ìbínú rẹ pẹ́ yí gbogbo ìran ká?
Ìwọ kì yóò ha sọ wá jí padà mọ́,
    pé kí àwọn ènìyàn rẹ lè yọ nínú rẹ?
Fi ìfẹ́ rẹ tí kò le è kùnà hàn wá, Olúwa,
    Kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ.

Èmi ó gbọ́ ohun tí Olúwa Ọlọ́run yóò wí;
    ó ṣèlérí àlàáfíà fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àní ẹni mímọ́ rẹ̀:
Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn padà sí àìmoye.
Nítòótọ́ ìgbàlà rẹ̀ súnmọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
    pé kí ògo rẹ̀ kí ó lè gbé ní ilẹ̀ wa.

10 Ìfẹ́ àti òtítọ́ parapọ̀;
    òdodo àti àlàáfíà fẹnu ko ara wọn.
11 Òtítọ́ ń sun jáde láti ilẹ̀ wá
    òdodo sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run.
12 Olúwa yóò fi ohun dídára fún ni nítòótọ́,
    ilẹ̀ wa yóò sì mú ìkórè rẹ̀ jáde.
13 Òdodo síwájú rẹ lọ
    o sì pèsè ọ̀nà fún ìgbésẹ̀ rẹ̀.

Adúra ti Dafidi.

86 Gbọ́, Olúwa, kí o sì dá mi lóhùn,
    nítorí mo jẹ́ tálákà àti aláìní.
Dáàbò bò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ:
    ìwọ ni Ọlọ́run mi,
gbà ìránṣẹ́ rẹ là
    tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
Ṣàánú fún mi, Olúwa,
    nítorí èmi ń pè ọ́ ní gbogbo ọjọ́.
Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ rẹ,
    nítorí ìwọ, Olúwa,
    ni mo gbé ọkàn mí sókè sí.

Ìwọ ń dáríjì, ìwọ sì dára, Olúwa,
    ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́,
Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa;
    tẹ́tí sí ẹkún mi fún àánú.
Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi èmi yóò pè ọ́,
    nítorí ìwọ yóò dá mi lóhùn.

Nínú àwọn òrìṣà kò sí ẹni tí ó dàbí i rẹ, Olúwa:
    kò sí àwọn iṣẹ́ tí a lè fiwé tìrẹ.
Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ dá
    yóò wá, láti wá jọ́sìn níwájú rẹ, Olúwa;
    wọn ó mú ògo wà fún orúkọ rẹ̀.
10 Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ sì ń ṣe ohun ìyanu;
    ìwọ nìkan ni Ọlọ́run.

11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,
    èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ;
fún mi ní ọkàn tí kì í yapa,
    kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ.
12 Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;
    èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé
13 Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi;
    ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú.

14 Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run;
    àti ìjọ àwọn alágbára ń wá
ọkàn mi kiri,
    wọn kò sì fi ọ́ pè.
15 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere,
    Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́.
16 Yípadà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi;
    fún àwọn ènìyàn rẹ ní agbára
    kí o sì gba ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin rẹ là.
17 Fi ààmì hàn mí fún rere,
    kí àwọn tí ó kórìíra mi lè ri,
kí ojú lè tì wọ́n, nítorí ìwọ Olúwa
    ni ó ti tù mí nínú.

Jeremiah 10:11-24

11 “Sọ èyí fún wọn: ‘Àwọn ọlọ́run kéékèèkéé tí kò dá ọ̀run àti ayé ni yóò ṣègbé láti ayé àti ní abẹ́ ọ̀run.’ ”

12 Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀,
    ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀,
    ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ síta nípa òye rẹ̀.
13 Nígbà tí ó bá sán àrá, àwọn omi
    lọ́run a sì pariwo, ó mú kí ìkùùkuu ru
sókè láti òpin ayé: ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò,
    ó sì ń mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀.

14 Gbogbo ènìyàn jẹ́ aṣiwèrè àti aláìnímọ̀,
    ojú ti gbogbo alágbẹ̀dẹ níwájú ère rẹ̀,
nítorí ère dídá rẹ̀ èké ni,
    kò sì ṣí ẹ̀mí nínú rẹ̀.
15 Asán ni wọ́n, iṣẹ́ ìṣìnà;
    nígbà ìbẹ̀wò wọn, wọn yóò ṣègbé.
16 Ẹni tí ó bá jẹ́ ìpín Jakọbu kò sì dàbí èyí,
    nítorí òun ni ó ṣẹ̀dá ohun gbogbo
àti Israẹli tí ó jẹ́ ẹ̀yà ìjogún rẹ̀.
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

Ìparun tí n bọ̀ wá

17 Kó ẹrù rẹ kúrò láti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀
    ìwọ tí o ń gbé ní ìlú tí a dó tì.
18 Nítorí èyí ni Olúwa wí:
    “Ní àkókò yìí,
    èmi yóò gbọn àwọn tí ó ń gbé
ilẹ̀ náà jáde. Èmi yóò mú ìpọ́njú
    bá wọn, kí wọn kí ó lè rí wọn mú.”

19 Ègbé ni fún mi nítorí ìpalára mi!
    Ọgbẹ́ mi jẹ́ èyí tí kò lè sàn,
bẹ́ẹ̀ ni mọ sọ fún ara mi,
    “Èyí ni àìsàn mi, mo sì gbọdọ̀ fi orí tì í.”
20 Àgọ́ mi bàjẹ́,
    gbogbo okùn rẹ̀ sì já.
    Àwọn ọmọ mi ti lọ lọ́dọ̀ mi, wọn kò sì sí mọ́
Kò sí ẹnìkankan tí yóò na àgọ́ mi ró mọ́,
    tàbí yóò ṣe ibùgbé fún mi
21 Àwọn olùṣọ́-àgùntàn jẹ́ aṣiwèrè,
    wọn kò sì wá Olúwa:
nítorí náà wọn kì yóò ṣe rere
    àti pé gbogbo agbo wọn ni yóò túká.
22 Fetísílẹ̀! ariwo igbe ń bọ̀,
    àti ìdàrúdàpọ̀ ńlá láti ilẹ̀ àríwá wá!
Yóò sì sọ ìlú Juda di ahoro,
    àti ihò ọ̀wàwà.

Àdúrà Jeremiah

23 Èmi mọ̀ Olúwa wí pé ọ̀nà ènìyàn kì í ṣe ti ara rẹ̀,
    kì í ṣe fún ènìyàn láti tọ́ ìgbésẹ̀ ara rẹ̀.
24 Tún mi ṣe Olúwa, pẹ̀lú ìdájọ́ nìkan
    kí o má sì ṣe é nínú ìbínú rẹ,
    kí ìwọ má ṣe sọ mí di òfo.

Romu 5:12-21

Ikú nípasẹ̀ Adamu, iyè nípasẹ̀ Jesu

12 (A)Nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipa ọ̀dọ̀ ènìyàn kan wọ ayé, àti ikú nípa ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ikú sì kọjá sórí ènìyàn gbogbo, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí gbogbo ènìyàn ti dẹ́ṣẹ̀:

13 Nítorí kí òfin tó dé, ẹ̀ṣẹ̀ ti wà láyé; ṣùgbọ́n a kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí ni lọ́rùn nígbà tí òfin kò sí. 14 (B)Ṣùgbọ́n ikú jẹ ọba láti ìgbà Adamu wá títí fi di ìgbà ti Mose, àti lórí àwọn tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò dàbí irú ìrékọjá Adamu, ẹni tí í ṣe àpẹẹrẹ ẹni tí ń bọ̀.

15 (C)Ṣùgbọ́n ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kò dàbí ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí bí nípa ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí bí o bá jẹ pé ẹnìkan ẹni púpọ̀ kú, mélòó mélòó ni oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, àti ẹ̀bùn nínú oore-ọ̀fẹ́ ọkùnrin kan, Jesu Kristi, di púpọ̀ fún ẹni púpọ̀. 16 (D)Kì í ṣe nípa ẹnìkan tí ó sẹ̀ ni ẹ̀bùn náà: Nítorí ìdájọ́ ti ipasẹ̀ ẹnìkan wá fún ìdálẹ́bi, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ti inú ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ wá fún ìdáláre, 17 Ǹjẹ́ bí o bá jẹ pé nípa ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin kan, ikú jẹ ọba nípasẹ̀ ẹnìkan náà; mélòó mélòó ni àwọn tí ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bùn òdodo yóò jẹ ọba nínú ìyè nípasẹ̀ ẹnìkan, Jesu Kristi.

18 Ǹjẹ́ bí o bá jẹ pé nípa ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan ìdájọ́ dé bá gbogbo ènìyàn sí ìdálẹ́bi; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni nípa ìwà òdodo ẹnìkan, ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ dé sórí gbogbo ènìyàn fún ìdáláre sí ìyè. 19 (E)Nítorí gẹ́gẹ́ bí nípa àìgbọ́ràn ọkùnrin kan, ènìyàn púpọ̀ di ẹlẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni nípa ìgbọ́ràn ẹnìkan, a ó sọ ènìyàn púpọ̀ di olódodo.

20 (F)Ṣùgbọ́n òfin bọ́ sí inú rẹ̀, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè di púpọ̀, ṣùgbọ́n ni ibi ti ẹ̀ṣẹ̀ di púpọ̀, oore-ọ̀fẹ́ di púpọ̀ rékọjá. 21 (G)Pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti jẹ ọba nípa ikú bẹ́ẹ̀ ni kí oore-ọ̀fẹ́ sì lè jẹ ọba nípa òdodo títí ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa.

Johanu 8:21-32

21 (A)Nítorí náà ó tún wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ, ẹ̀yin yóò sì wá mi, ẹ ó sì kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín: ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá.”

22 Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Òun ó ha pa ara rẹ̀ bí? Nítorí tí ó wí pé, ‘Ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá’?”

23 (B)Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ìsàlẹ̀ wá; èmi ti òkè wá; ẹ̀yin jẹ́ ti ayé yìí; èmi kì í ṣe ti ayé yìí. 24 (C)Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín: nítorí bí kò ṣe pé ẹ bá gbàgbọ́ pé èmi ni, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín.”

25 Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ jẹ́?”

Jesu sì wí fún un pé, “Èmi ni èyí tí mo ti wí fún yín ní àtètèkọ́ṣe. 26 Mo ní ohun púpọ̀ láti sọ, àti láti ṣe ìdájọ́ nípa yín: ṣùgbọ́n olóòtítọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ohun tí èmi sì ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, wọ̀nyí ni èmi ń sọ fún aráyé.”

27 Kò yé wọn pé ti Baba ni ó ń sọ fún wọn. 28 (D)Lẹ́yìn náà Jesu wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ mọ̀ pé, nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ ènìyàn sókè, nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ pé èmi ni àti pé èmi kò dá ohunkóhun ṣe fún ara mi; ṣùgbọ́n bí Baba ti kọ́ mi, èmí ń sọ nǹkan wọ̀nyí. 29 Ẹni tí ó rán mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi: kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan; nítorí tí èmi ń ṣe ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo.” 30 (E)Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà á gbọ́.

Àwọn ọmọ Abrahamu

31 (F)Nítorí náà Jesu wí fún àwọn Júù tí ó gbà á gbọ́, pé, “Bí ẹ bá tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ mi ẹ ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi nítòótọ́. 32 (G)Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì sọ yín di òmìnira.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.