Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 31

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

31 Nínú rẹ̀, Olúwa ni mo ti rí ààbò;
    Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí;
    gbà mí nínú òdodo rẹ.
Tẹ́ etí rẹ sí mi,
    gbà mí kíákíá;
jẹ́ àpáta ààbò mi,
    jẹ́ odi alágbára láti gbà mí.
Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi,
    nítorí orúkọ rẹ, máa ṣe olùtọ́ mi, kí o sì ṣe amọ̀nà mi.
Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi,
    nítorí ìwọ ni ìsádi mi.
Ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé;
    ìwọ ni o ti rà mí padà, Olúwa, Ọlọ́run òtítọ́.

Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fiyèsí òrìṣà tí kò níye lórí;
    ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.
Èmi yóò yọ̀, inú mi yóò dùn nínú ìfẹ́ ńlá rẹ,
    nítorí ìwọ ti rí ìbìnújẹ́ mi
    ìwọ ti mọ̀ ọkàn mi nínú ìpọ́njú.
Pẹ̀lú, ìwọ kò sì fà mi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́
    ìwọ ti fi ẹsẹ̀ mi lé ibi ààyè ńlá.

Ṣàánú fún mi, ìwọ Olúwa, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú;
    ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn,
    ọkàn àti ara mi pẹ̀lú.
10 Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ mi
    àti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn;
agbára mi ti kùnà nítorí òsì mi,
    egungun mi sì ti rún dànù.
11 Èmi di ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ọ̀tá mi gbogbo,
    pẹ̀lúpẹ̀lú láàrín àwọn aládùúgbò mi,
mo sì di ẹ̀rù fún àwọn ojúlùmọ̀ mi;
    àwọn tí ó rí mi ní òde ń yẹra fún mi.
12 Èmi ti di ẹni ìgbàgbé kúrò ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti kú;
    Èmi sì dàbí ohun èlò tí ó ti fọ́.
13 (A)Nítorí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpayà tí ó yí mi ká;
    tí wọn gbìmọ̀ pọ̀ sí mi,
wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi
    láti gba ẹ̀mí mi.

14 Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ Olúwa
    Mo sọ wí pé, “Ìwọ ní Ọlọ́run mi.”
15 Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;
    gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi
    àti àwọn onínúnibíni.
16 Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ lára;
    Gbà mí nínú ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.
17 Má ṣe jẹ́ kí ojú ki ó tì mí, Olúwa;
    nítorí pé mo ké pè ọ́;
jẹ́ kí ojú kí ó ti ènìyàn búburú;
    jẹ́ kí wọ́n lọ pẹ̀lú ìdààmú sí isà òkú.
18 Jẹ́ kí àwọn ètè irọ́ kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́,
    pẹ̀lú ìgbéraga àti ìkẹ́gàn,
    wọ́n sọ̀rọ̀ àfojúdi sí olódodo.

19 Báwo ni títóbi oore rẹ̀ ti pọ̀ tó,
    èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,
èyí tí ìwọ rọ̀jò rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn
    tí wọ́n fi ọ́ ṣe ibi ìsádi wọn.
20 Ní abẹ́ ìbòòji iwájú rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ sí
    kúrò nínú ìdìmọ̀lù àwọn ènìyàn;
ní ibùgbé rẹ, o mú wọn kúrò nínú ewu
    kúrò nínú ìjà ahọ́n.

21 Olùbùkún ni Olúwa,
    nítorí pé ó ti fi àgbà ìyanu ìfẹ́ tí ó ní sí mi hàn,
    nígbà tí mo wà ní ìlú tí wọ́n rọ̀gbà yíká.
22 Èmí ti sọ nínú ìdágìrì mi,
    “A gé mi kúrò ní ojú rẹ!”
Síbẹ̀ ìwọ ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú
    nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.

23 Ẹ fẹ́ Olúwa, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́!
    Olúwa pa olódodo mọ́,
    ó sì san án padà fún agbéraga ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
24 Jẹ́ alágbára, yóò sì mú yín ní àyà le
    gbogbo ẹ̀yin tí ó dúró de Olúwa.

Saamu 35

Ti Dafidi.

35 Olúwa, gbógun ti àwọn tí ń gbóguntì mí;
    kí o sì kọ ojú ìjà sí àwọn tí ó ń bá mi í jà!
Di asà àti àpáta mú,
    kí o sì dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi!
Fa idà àti ọ̀kọ̀ yọ
    kí o sì dojúkọ àwọn tí ń lé mi.
Sọ fún ọkàn mi pé,
    “Èmi ni ìgbàlà rẹ.”

Kí wọn kí ó dààmú,
    kí a sì ti àwọn tí ń lépa ọkàn mi lójú;
kí a sì mú wọn padà,
    kí a sì dààmú àwọn tí ń gbèrò ìpalára mi.
Jẹ́ kí wọn dàbí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́,
    kí angẹli Olúwa kí ó máa lé wọn kiri.
Jẹ́ kí ọ̀nà wọn kí ó ṣókùnkùn, kí ó sì máa yọ́,
    kí angẹli Olúwa kí ó máa lépa wọn!

Nítorí pé, ní àìnídìí ni wọ́n dẹ àwọ̀n wọn sílẹ̀ fún mi,
    ní àìnídìí ni wọ́n wa kòtò sílẹ̀ fún ọkàn mi.
Kí ìparun kí ó wá sí orí rẹ̀ ní òjijì.
    Àwọ̀n rẹ̀ tí ó dẹ, kí ó mú òun tìkára rẹ̀;
    kí wọn ṣubú sínú kòtò sí ìparun ara rẹ̀.
Nígbà náà ni ọkàn mi yóò yọ̀ nínú Olúwa,
    àní, yóò sì máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ̀.
10 Gbogbo egungun mi yóò wí pé,
    “Ta ni ó dàbí ì ìwọ Olúwa?
O gba tálákà lọ́wọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ,
    tálákà àti aláìní lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ṣe ìkógun?”

11 Àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde;
    wọ́n ń bi mi ní ohun tí èmi kò mọ̀.
12 Wọ́n fi búburú san ìre fún mi;
    láti sọ ọkàn mi di òfo.
13 Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni, nígbà tí wọn ń ṣe àìsàn, mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀;
    mo fi àwẹ̀ pọ́n ara mi lójú.
Mo gba àdúrà pẹ̀lú ìtẹríba ní oókan àyà mi;
14     èmí ń lọ kiri bí ẹni ń ṣọ̀fọ̀
    bí i ẹni wí pé fún ọ̀rẹ́ tàbí ẹ̀gbọ́n mi ni.
Èmí tẹríba nínú ìbànújẹ́
    bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ìyà rẹ̀.
15 Ṣùgbọ́n nínú ìkọ̀sẹ̀ mi wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì kó ara wọn jọ;
    wọ́n kó ara wọn jọ sí mi; àní àwọn tí èmi kò mọ̀.
    Wọ́n fà mí ya wọ́n kò sì dákẹ́.
16 Bí àwọn àgàbàgebè tí ń ṣe ẹlẹ́yà ní àpèjẹ
    wọ́n pa eyín wọn keke sí mi.

17 Yóò ti pẹ́ tó Olúwa, tí ìwọ yóò máa wò wọ́n lọ?
    Yọ mí kúrò nínú ìparun wọn,
    àní ẹ̀mí ì mi kúrò lọ́wọ́ kìnnìún.
18 Nígbà náà ni èmi yóò ṣọpẹ́ fún Ọ nínú àjọ ńlá;
    èmi yóò máa yìn Ọ́ ní àwùjọ ọ̀pọ̀ ènìyàn.
19 (A)Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi
    kí ó yọ̀ lórí ì mi;
bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe àwọn tí ó kórìíra mi
    ní àìnídìí máa ṣẹ́jú sí mi.
20 Nítorí pé wọn kò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà,
    ṣùgbọ́n wọ́n lóyún ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn
    sí àwọn ènìyàn dídákẹ́ ilẹ̀ náà.
21 Wọ́n ya ẹnu wọn gbòòrò sí mi; wọ́n wí pé, “Háà! Háà!
    Ojú wa sì ti rí i.”

22 Ìwọ́ ti rí i Olúwa; má ṣe dákẹ́!
    Olúwa má ṣe jìnnà sí mi!
23 Dìde! ru ara rẹ̀ sókè fún ààbò mi,
    àti sí ọ̀ràn mi, Ọlọ́run mi àti Olúwa mi!
24 Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa Ọlọ́run mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ,
    kí o má sì ṣe jẹ́ kí wọn kí ó yọ̀ lórí mi!
25 Má ṣe jẹ́ kí wọn wí nínú ara wọn pé, “Háà! A ti rí ohun tí ọkàn wa ń fẹ́!”
    Má ṣe jẹ́ kí wọn kí ó wí pé, “A ti gbé e mì.”

26 Kí ojú kí ó tì wọ́n,
    kí wọn kí ó sì dààmú pọ̀,
àní àwọn tí ń yọ̀ sí ìyọnu mi
    kí a fi ìtìjú àti àbùkù wọ̀ wọ́n ní aṣọ tí ń gbéraga sí mi.
27 Jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ìdáláre mi
    fò fún ayọ̀ àti ìdùnnú;
kí wọn máa sọ ọ́ títí lọ, “Pé gbígbéga ni Olúwa,
    sí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ̀.”

28 Nígbà náà ni ahọ́n mi yóò máa sọ̀rọ̀ òdodo rẹ,
    àti ìyìn rẹ ní gbogbo ọjọ́.

Jeremiah 24

Agbọ̀n èso ọ̀pọ̀tọ́ méjì

24 Lẹ́yìn tí Nebukadnessari ọba Babeli ti kó Jekoniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda àti àwọn ìjòyè wọn, àwọn oníṣọ̀nà àti oníṣẹ́ ọwọ́ ti Juda lọ sí ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí ilẹ̀ àjèjì Babeli tán. Olúwa fi agbọ̀n èso ọ̀pọ̀tọ́ méjì hàn mí tí a gbé sí iwájú pẹpẹ Olúwa. Agbọ̀n kan ni èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó dára bí èyí tí ó tètè pọ́n; èkejì sì ní èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó burú rékọjá tí kò sì le è ṣe é jẹ.

Nígbà náà ni Olúwa bi mí pé, “Kí ni ìwọ rí Jeremiah?”

Mo dáhùn pe “Èso ọ̀pọ̀tọ́” Mo dáhùn. “Èyí tí ó dáradára púpọ̀, ṣùgbọ́n èyí tí ó burú burú rékọjá tí kò sì ṣe é jẹ.”

Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Gẹ́gẹ́ bí àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ dáradára yìí ni Èmi yóò ka àwọn tí wọ́n lọ sí ilẹ̀ àjèjì láti Juda sí tí èmi rán jáde kúrò ní ibí yìí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kaldea Ojú mi yóò máa ṣọ́ wọn lọ fún rere; Èmi yóò gbé wọn ró, n kò ní já wọn lulẹ̀. Èmi yóò gbìn wọ́n, n kò sì ní fà wọ́n tu. Èmi yóò fún wọn ní ọkàn láti mọ̀ mí pé, Èmi ni Olúwa. Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi; Èmi ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn; nítorí pé wọn yóò padà sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.

“ ‘Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí kò dára, tí ó burú tí kò ṣe é jẹ,’ ni Olúwa wí, ‘bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò ṣe pẹ̀lú Sedekiah ọba Juda, àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn tí ó yẹ ní Jerusalẹmu, yálà wọ́n wà lórí ilẹ̀ yìí tàbí wọ́n ń gbé Ejibiti. Èmi yóò sọ wọ́n di ìwọ̀sí àti ẹni ibi nínú gbogbo ìjọba ayé, láti di ẹni ìfibú àti ẹni òwe, ẹni ẹ̀sín, àti ẹni ẹ̀gàn ní ibi gbogbo tí Èmi ó lé wọn sí. 10 Èmi yóò rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn sí wọn, títí tí gbogbo wọn yóò parun lórí ilẹ̀ tí a fún wọn àti fún àwọn baba wọn.’ ”

Romu 9:19-33

19 Ìwọ ó sì wí fún mi pé, “Kín ni ó ha tún bá ni wí sí? Nítorí ta ni ó ń de ìfẹ́ rẹ lọ́nà?” 20 (A)Bẹ́ẹ̀ kọ́, ìwọ ènìyàn, tà ni ìwọ tí ń dá Ọlọ́run lóhùn? “Ohun tí a mọ, a ha máa wí fún ẹni tí ó mọ ọ́n pé, ‘Èéṣe tí ìwọ fi mọ mi báyìí?’ ” 21 (B)Amọ̀kòkò kò ha ni agbára lórí amọ̀, nínú ìṣù kan náà láti ṣe apá kan nínú ohun èlò sí ọlá, àti apá kan nínú ohun èlò sí àìlọ́lá?

22 (C)Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá fẹ́ fi ìbínú rẹ̀ hàn ńkọ́? Tí ó sì fẹ́ sọ agbára rẹ̀ di mí mọ̀, tí ó sì mú sùúrù púpọ̀ fún àwọn ohun èlò ìbínú tí a ṣe fún ìparun; 23 (D)Àti kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ ògo rẹ̀ di mí mọ̀ lára àwọn ohun èlò àánú tí ó ti pèsè ṣáájú fún ògo, 24 (E)Àní àwa, tí ó ti pè, kì í ṣe nínú àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nínú àwọn Kèfèrí pẹ̀lú? 25 (F)Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hosea pé,

“Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ènìyàn mi,
    àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní àyànfẹ́.”

26 (G)Yóò sì ṣe,

“Ní ibi ti a gbé ti sọ fún wọn pé,
    ‘ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’
    níbẹ̀ ni a ó gbé pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ ”

27 (H)Isaiah sì kígbe nítorí Israẹli pé:

“Bí iye àwọn ọmọ Israẹli bá rí bí iyanrìn Òkun,
    apá kan ni ó gbàlà.
28 Nítorí Olúwa yóò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé,
    yóò parí rẹ̀, yóò sì ké e kúrò ní òdodo.”

29 (I)Àti bí Isaiah ti wí tẹ́lẹ̀:

“Bí kò ṣe bí Olúwa àwọn Ọmọ-ogun
    ti fi irú-ọmọ sílẹ̀ fún wa,
àwa ìbá ti dàbí Sodomu,
    a bá sì ti sọ wá dàbí Gomorra.”

30 (J)Ǹjẹ́ kí ni àwa ó ha wí? Pé àwọn Kèfèrí, tí kò lépa òdodo, ọwọ́ wọn tẹ òdodo, ṣùgbọ́n òdodo tí ó ti inú ìgbàlà wá ni. 31 (K)Ṣùgbọ́n Israẹli ti ń lépa òfin òdodo, ọwọ́ wọn kò tẹ òfin òdodo. 32 (L)Nítorí kí ni? Nítorí wọn kò wá a nípa ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni pé nípa iṣẹ́ òfin. Nítorí wọn kọsẹ̀ lára òkúta ìkọ̀sẹ̀ ni; 33 (M)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Kíyèsi, mo gbé òkúta ìkọ̀sẹ̀ kalẹ̀ ní Sioni
    àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú,
ẹnikẹ́ni ti ó bá sì gbà a gbọ́, ojú kì yóò tì í.”

Johanu 9:1-17

Jesu la ojú ẹni tí a bí ní afọ́jú

Bí ó sì ti ń kọjá lọ, ó rí ọkùnrin kan tí ó fọ́jú láti ìgbà ìbí rẹ̀ wá. (A)Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi í léèrè, pé, “Rabbi, ta ní ó dẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin yìí tàbí àwọn òbí rẹ̀, tí a fi bí i ní afọ́jú?”

(B)Jesu dáhùn pé, “Kì í ṣe nítorí pé ọkùnrin yìí dẹ́ṣẹ̀, tàbí àwọn òbí rẹ̀: ṣùgbọ́n kí a ba à lè fi iṣẹ́ Ọlọ́run hàn lára rẹ̀. (C)Èmi ní láti ṣe iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi, níwọ̀n ìgbà tí ó bá ti jẹ́ ọ̀sán: òru ń bọ̀ wá nígbà tí ẹnìkan kì yóò lè ṣe iṣẹ́. (D)Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè, èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.”

(E)Nígbà tí ó ti wí bẹ́ẹ̀ tan, ó tutọ́ sílẹ̀, ó sì fi itọ́ náà ṣe amọ̀, ó sì fi amọ̀ náà ra ojú afọ́jú náà. (F)Ó sì wí fún un pé, “Lọ wẹ̀ nínú adágún Siloamu!” (Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí ni “rán”). Nítorí náà ó gba ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó wẹ̀, ó sì dé, ó ń ríran.

Ǹjẹ́ àwọn aládùúgbò àti àwọn tí ó rí i nígbà àtijọ́ pé alágbe ni ó jẹ́, wí pé, “Ẹni tí ó ti ń jókòó ṣagbe kọ́ yìí?” Àwọn kan wí pé òun ni.

Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ó jọ ọ́ ni.”

Ṣùgbọ́n òun wí pé, “Èmi ni.”

10 Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Bá wo ni ojú rẹ ṣe là?”

11 Ó dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jesu ni ó ṣe amọ̀, ó sì fi kun ojú mí, ó sì wí fún mi pé, ‘Lọ sí adágún Siloamu, kí o sì wẹ̀,’ èmi sì lọ, mo wẹ̀, mo sì ríran.”

12 Wọ́n sì wí fún un pé, “Òun náà ha dà?”

Ó sì wí pé, “Èmi kò mọ̀.”

Àwọn Farisi wádìí ìwòsàn

13 Wọ́n mú ẹni tí ojú rẹ̀ ti fọ́ rí wá sọ́dọ̀ àwọn Farisi. 14 Ọjọ́ ìsinmi ni ọjọ́ náà nígbà tí Jesu ṣe amọ̀, tí ó sì là á lójú. 15 Nítorí náà àwọn Farisi pẹ̀lú tún bi í léèrè, bí ó ti ṣe ríran. Ọkùnrin náà fèsì, “Ó fi amọ̀ lé ojú mi, mo sì wẹ̀, báyìí mo sì ríran.”

16 (G)Nítorí náà àwọn kan nínú àwọn Farisi wí pé, “Ọkùnrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, nítorí tí kò pa ọjọ́ ìsinmi mọ́.”

Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Ọkùnrin tí í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò ha ti ṣe lè ṣe irú iṣẹ́ ààmì wọ̀nyí?” Ìyapa sì wà láàrín wọn.

17 Nítorí náà, wọ́n sì tún wí fún afọ́jú náà pé, “Kí ni ìwọ ní wí nípa rẹ̀, nítorí tí ó là ọ́ lójú?”

Ó sì wí pé, “Wòlíì ní í ṣe.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.