Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin olókùn. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi.
6 Olúwa, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ
kí ìwọ má ṣe nà mí nínú gbígbóná ìrunú rẹ
2 Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń kú lọ;
Olúwa, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira.
3 Ọkàn mi wà nínú ìrora.
Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa, yóò ti pẹ́ tó?
4 Yípadà, Olúwa, kí o sì gbà mí;
gbà mí là nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í ṣákì í.
5 Ẹnikẹ́ni kò ni rántí rẹ nígbà tí ó bá kú.
Ta ni yóò yìn ọ́ láti inú isà òkú?
6 Agara ìkérora mi dá mi tán.
Gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkún,
mo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé.
7 Ojú mi di aláìlera pẹ̀lú ìbànújẹ́;
wọ́n kùnà nítorí gbogbo ọ̀tá mi.
8 (A)Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi,
nítorí Olúwa ti gbọ́ igbe mi.
9 Olúwa ti gbọ́ ẹkún mi fún àánú;
Olúwa ti gba àdúrà mi.
10 Gbogbo àwọn ọ̀tá mi lójú yóò tì, wọn yóò sì dààmú;
wọn yóò sì yípadà nínú ìtìjú àìròtẹ́lẹ̀.
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi.
12 Ràn wá lọ́wọ́, Olúwa, nítorí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kò sí mọ́;
Olóòtítọ́ tí pòórá kúrò láàrín àwọn ènìyàn.
2 Olúkúlùkù ń parọ́ fún aládùúgbò rẹ̀;
ètè èké wọn ń sọ ẹ̀tàn.
3 Kí Olúwa kí ó gé ètè èké wọn
àti gbogbo ahọ́n ìfọ́nnu
4 tí ó wí pé,
“Àwa ó borí pẹ̀lú ahọ́n wa;
àwa ní ètè wa: Ta ni ọ̀gá wa?”
5 “Nítorí ìnilára àwọn aláìlágbára àti ìkérora àwọn aláìní,
Èmi yóò dìde nísinsin yìí” ni Olúwa wí.
“Èmi yóò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe àrankàn wọn.”
6 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì jẹ aláìlábùkù,
gẹ́gẹ́ bí fàdákà tí a yọ́ nínú ìléru amọ̀,
tí a sọ di mímọ́ nígbà méje.
7 Olúwa, ìwọ yóò pa wá mọ́
kí o sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí títí láé.
8 Àwọn ènìyàn búburú ń rin ìrìn fáàrí kiri
nígbà tí wọn ń bọ̀wọ̀ fún òsì láàrín àwọn ènìyàn.
94 Olúwa Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san,
Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san.
2 Gbé ara rẹ sókè, ìwọ onídàájọ́ ayé;
san ẹ̀san fún agbéraga
ohun tí ó yẹ wọ́n.
3 Báwo ní yóò ti pẹ́ tó,
Olúwa
tí àwọn ẹni búburú
yóò kọ orin ayọ̀?
4 Wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga jáde;
gbogbo àwọn olùṣe búburú
kún fún ìṣògo.
5 Wọ́n fọ́ àwọn ènìyàn rẹ túútúú, Olúwa:
wọ́n pọ́n ilẹ̀ ìní rẹ̀ lójú.
6 Wọ́n pa àwọn opó àti àlejò,
wọ́n sì pa àwọn ọmọ aláìní baba,
7 Wọ́n sọ pé, “Olúwa kò rí i;
Ọlọ́run Jakọbu kò sì kíyèsi i.”
8 Kíyèsi i, ẹ̀yin aláìlóye nínú àwọn ènìyàn
ẹ̀yin aṣiwèrè, nígbà wo ni ẹ̀yin yóò lóye?
9 Ẹni tí ó gbin etí, ó lè ṣe aláìgbọ́ bí?
Ẹni tí ó dá ojú?
Ó ha lè ṣe aláìríran bí?
10 Ẹni tí ń bá orílẹ̀-èdè wí, ṣé kò lè tọ́ ni ṣọ́nà bí?
Ẹni tí ń kọ́ ènìyàn ha lè ṣàìní ìmọ̀ bí?
11 (A)Olúwa mọ èrò inú ènìyàn;
ó mọ̀ pé asán ni wọ́n.
12 Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí
ìwọ bá wí, Olúwa,
ẹni tí ìwọ kọ́ nínú òfin rẹ;
13 Ìwọ gbà á kúrò nínú ọjọ́ ibi,
títí a ó fi wa ihò sílẹ̀ fún ẹni búburú.
14 Nítorí Olúwa kò ní kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀;
Òun kò sì ní kọ ilẹ̀ ìní rẹ̀ sílẹ̀.
15 Ìdájọ́ yóò padà sí òdodo,
àti gbogbo àwọn ọlọ́kàn
dídúró ṣinṣin yóò tẹ̀lé e lẹ́yìn.
16 Ta ni yóò dìde fún mi
sí àwọn olùṣe búburú?
Tàbí ta ni yóò dìde sí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún mi?
17 Bí kò ṣe pé Olúwa fún mi ní ìrànlọ́wọ́,
èmi fẹ́rẹ̀ máa gbé ní ilẹ̀ tí ó dákẹ́
18 Nígbà tí mo sọ pé “Ẹsẹ̀ mi ń yọ̀”,
Olúwa, ìfẹ́ rẹ̀ ni ó tì mí lẹ́yìn.
19 Nígbà tí àníyàn ńlá wà nínú mi,
ìtùnú rẹ̀ mú ayọ̀ sí ọkàn mi.
20 Ìjọba ìbàjẹ́ ha lè kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú rẹ
ẹni tí ń fi òfin dì mọ́ ìwà ìkà?
21 Wọ́n kó ara wọn jọ sí olódodo
wọ́n sì ń dá àwọn aláìṣẹ̀ lẹ́bi sí ikú.
22 Ṣùgbọ́n, Olúwa ti di odi alágbára mi,
àti Ọlọ́run mi ni àpáta nínú ẹni
tí mo ti ń gba ààbò.
23 Òun yóò san ẹ̀san ibi wọn fún wọn
yóò sì pa wọ́n run nítorí búburú wọn
Olúwa Ọlọ́run wa yóò pa wọ́n run.
10 Háà! Ó ṣe tí ìyá mi bí mi:
ọkùnrin tí gbogbo ilẹ̀ dojúkọ tí wọ́n sì bá jà,
èmi kò wínni, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yá lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni
síbẹ̀, gbogbo ènìyàn ló ń fi mí ré.
11 Olúwa sọ pé,
“Dájúdájú èmi ò dá ọ sí fún ìdí kan pàtó.
Dájúdájú mo mú kí àwọn ọ̀tá rẹ
tẹríba níwájú rẹ nígbà ibi àti ìpọ́njú.
12 “Ǹjẹ́ ẹnìkan lè fi ọwọ́ ṣẹ́ irin
irin láti àríwá tàbí idẹ?
13 “Gbogbo ọlá àti ìṣúra rẹ
ni èmi ó fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun láìgba
nǹkan kan nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ
jákèjádò orílẹ̀-èdè rẹ.
14 Èmi yóò fi ọ́ ṣẹrú fún àwọn ọ̀tá rẹ
ní ìlú tí ìwọ kò mọ̀ nítorí ìbínú
mi yóò rán iná tí yóò jó ọ.”
15 Ó yé ọ, ìwọ Olúwa rántí mi kí o
sì ṣe ìtọ́jú mi; gbẹ̀san mi lára
àwọn tó dìtẹ̀ mi. Ìwọ ti jìyà fún
ìgbà pípẹ́, má ṣe mú mi lọ, nínú bí
mo ṣe jìyà nítorí tìrẹ.
16 Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ dé, mo jẹ wọ́n
Àwọn ni ìdùnnú àti ayọ̀ ọkàn mi
Nítorí pé orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí
Ìwọ Olúwa Ọlọ́run Alágbára.
17 Èmi kò fìgbà kan jókòó láàrín àwọn ẹlẹ́gàn.
N ko bá wọn yọ ayọ̀ pọ̀;
mo dá jókòó torí pé ọwọ́ rẹ wà
lára mi, ìwọ sì ti fi ìbínú rẹ kún inú mi.
18 Èéṣe tí ìrora mi kò lópin,
tí ọgbẹ́ mi kò sì ṣe é wòsàn?
Ní òtítọ́ ìwọ yóò dàbí kànga ẹ̀tàn sí mi,
gẹ́gẹ́ bí ìsun tó kọ̀ tí kò sun?
19 Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí:
“Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padà
wá kí o lè máa sìn mí. Tí ó bá
sọ ọ̀rọ̀ tó dára ìwọ yóò di agbẹnusọ
mi. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ;
ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn
20 Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbára
sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó bá ọ jà
ṣùgbọ́n, wọn kò ní lè borí rẹ
nítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹ láti gbà ọ́ là,
kí n sì dáàbò bò ọ́,”
ni Olúwa wí.
21 “Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn
ìkà ènìyàn, Èmi yóò sì rà ọ́
padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.”
15 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí àwa tí a dàgbà nípa ti ẹ̀mí ni èrò yìí; bí ẹ̀yin bá sì ní èrò mìíràn nínú ohunkóhun, èyí náà pẹ̀lú ni Ọlọ́run yóò fihàn yín. 16 Kìkì pé, ki a ma gbe ìgbé ayé gẹ́gẹ́ bi èyí ti a ri gba.
17 (A)Ará, ẹ jùmọ̀ ṣe àfarawé mi, ẹ ṣe àkíyèsí àwọn tí ń rìn bẹ́ẹ̀, àní bí ẹ ti ní wa fún àpẹẹrẹ. 18 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ń rìn, nípasẹ̀ àwọn ẹni tí mo ti ń wí fún yín nígbàkúgbà, àní, tí mo sì ń sọkún bí mo ti ń wí fún yín nísinsin yìí, pé, ọ̀tá àgbélébùú Kristi ni wọ́n: 19 Ìgbẹ̀yìn wọn ni ìparun, ikùn wọn sì ni Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń ṣògo nínú ìtìjú wọn, àwọn ẹni tí ń tọ́jú ohun ti ayé. 20 Nítorí ìlú ìbílẹ̀ wá ń bẹ̀ ní ọ̀run: láti ibi ti àwa pẹ̀lú gbé ń fojúsọ́nà fún Olùgbàlà, Jesu Kristi Olúwa. 21 (B)Ẹni tí yóò sọ ara ìrẹ̀lẹ̀ wa di ọ̀tún kí ó lè bá ara ògo rẹ̀ mu, nípa agbára tí ó mú kí ó ṣe é ṣe fún un láti tẹ orí ohun gbogbo bá fún ara rẹ̀.
Jesu sọ nípa ikú rẹ̀
20 (A)Àwọn Giriki kan sì wà nínú àwọn tí ó gòkè wá láti sìn nígbà àjọ: 21 (B)Àwọn wọ̀nyí ni ó tọ Filipi wá, ẹni tí í ṣe ará Betisaida tí Galili, wọ́n sì ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, pé, “Alàgbà, àwa ń fẹ́ rí Jesu!” 22 Filipi wá, ó sì sọ fún Anderu; Anderu àti Filipi wá, wọ́n sì sọ fún Jesu.
23 (C)Jesu sì dá wọn lóhùn pé, “Wákàtí náà dé, tí a ó ṣe Ọmọ ènìyàn lógo. 24 (D)Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé alikama bá bọ́ sí ilẹ̀, tí ó bá sì kú, ó wà ní òun nìkan; ṣùgbọ́n bí ó bá kú, yóò sì so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso. 25 (E)Ẹni tí ó bá fẹ́ ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù; ẹni tí ó bá sì kórìíra ẹ̀mí rẹ̀ láyé yìí ni yóò sì pa á mọ́ títí ó fi di ìyè àìnípẹ̀kun. 26 Bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, kí ó máa tọ̀ mí lẹ́yìn: àti pe níbi tí èmi bá wà, níbẹ̀ ni ìránṣẹ́ mi yóò wà pẹ̀lú: bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, òun ni Baba yóò bu ọlá fún.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.