Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 85

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.

85 Ìwọ fi ojúrere hàn fún ilé rẹ, Olúwa;
    ìwọ mú ohun ìní Jakọbu bọ̀ sí ipò.
Ìwọ dárí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn rẹ jì
    ìwọ sì bó ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. Sela.
Ìwọ fi àwọn ìbínú rẹ sápá kan
    ìwọ sì yípadà kúrò nínú ìbínú gbígbóná rẹ.

Yí wa padà, Ọlọ́run ìgbàlà wa,
    kí o sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ wa.
Ìwọ yóò ha máa bínú sí wa títí láé?
    Ìwọ yóò ha mú ìbínú rẹ pẹ́ yí gbogbo ìran ká?
Ìwọ kì yóò ha sọ wá jí padà mọ́,
    pé kí àwọn ènìyàn rẹ lè yọ nínú rẹ?
Fi ìfẹ́ rẹ tí kò le è kùnà hàn wá, Olúwa,
    Kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ.

Èmi ó gbọ́ ohun tí Olúwa Ọlọ́run yóò wí;
    ó ṣèlérí àlàáfíà fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àní ẹni mímọ́ rẹ̀:
Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn padà sí àìmoye.
Nítòótọ́ ìgbàlà rẹ̀ súnmọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
    pé kí ògo rẹ̀ kí ó lè gbé ní ilẹ̀ wa.

10 Ìfẹ́ àti òtítọ́ parapọ̀;
    òdodo àti àlàáfíà fẹnu ko ara wọn.
11 Òtítọ́ ń sun jáde láti ilẹ̀ wá
    òdodo sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run.
12 Olúwa yóò fi ohun dídára fún ni nítòótọ́,
    ilẹ̀ wa yóò sì mú ìkórè rẹ̀ jáde.
13 Òdodo síwájú rẹ lọ
    o sì pèsè ọ̀nà fún ìgbésẹ̀ rẹ̀.

Hosea 1:11-2:15

11 Àwọn ènìyàn Juda àti àwọn ènìyàn Israẹli yóò parapọ̀, wọn yóò sì yan olórí kan tí yóò jáde láti ilẹ̀ náà, nítorí pé ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jesreeli yóò jẹ́.

“Sọ fún àwọn arákùnrin rẹ, ‘Ènìyàn mi,’ kí o sì wí fún àwọn arábìnrin rẹ ‘àyànfẹ́ mi.’

Ẹ̀sùn tí a fi kan ìyàwó aláìṣòótọ́

“Ẹ bá ìyá yín wí, ẹ bá a wí,
    nítorí pé kì í ṣe ìyàwó mi,
    Èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀.
Jẹ́ kí ó yọ àgbèrè rẹ̀ kúrò lójú rẹ̀
    àti àìṣòótọ́ kúrò ní àyà rẹ̀.
Àìṣe bẹ́ẹ̀ èmi yóò tú u sí ìhòhò
    Èmi yóò sì gbé e kalẹ̀ bí ọjọ́ tí a bí i.
Èmi yóò ṣe ọ́ bí i aṣálẹ̀ ilẹ̀,
    Èmi yóò sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀
    Èmi yóò sì fi òǹgbẹ gbẹ ẹ́.
Èmi kò ní fi àánú mi hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀
    nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n jẹ́
Nítorí ìyá wọn ti hùwà àgbèrè,
    ó sì lóyún wọn nínú ìtìjú.
Ó wí pé, ‘èmi ó tún tọ́ àwọn àyànfẹ́ mi lẹ́yìn,
    tó ń fún mi ní oúnjẹ àti omi,
    ní irun àgùntàn mi àti ọ̀gbọ̀ mi,
    òróró mi àti ohun mímu mi.’
Nítorí náà, èmi ó fi ẹ̀gún dì í lọ́nà
    Èmi ó mọ odi yí i ká kí ó má ba à rọ́nà lọ.
Yóò sáré lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n kò ní bá wọn;
    Yóò wá wọn ṣùgbọ́n kò ní rí wọn.
Nígbà náà ni yóò sọ pé,
    ‘Èmi ó padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ mi àkọ́kọ́
    nítorí pé ó dára fún mi nígbà náà ju ìsinsin yìí lọ.’
Nítorí pé kò tí ì mọ̀ pé èmi ni
    àti ẹni tó fún un ní ọkà,
ọtí wáìnì tuntun àti òróró
    ẹni tí ó fún un ní fàdákà àti wúrà lọ́pọ̀lọpọ̀ Èyí tí wọ́n lò fún Baali.

“Nítorí náà, èmi yóò mú ọkà mi kúrò nígbà tó bá pọ́n,
    èmi yóò sì mú wáìnì mi kúrò ní àsìkò rẹ̀.
Èmi yóò sì gba irun àgùntàn àti ọ̀gbọ̀ mi padà
    ti mo ti fi fún un láti bo ìhòhò rẹ̀.
10 Èmi yóò sì fi ìwà ìtìjú rẹ̀ hàn
    lójú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀
    kò sí ẹni tí yóò gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi
11 Èmi yóò mú gbogbo ayọ̀ rẹ̀ wá sí òpin:
    àjọ̀dún ọdọọdún rẹ̀, oṣù tuntun rẹ̀,
    ọjọ́ ìsinmi, àti gbogbo àwọn àjọ̀dún tí a yàn.
12 Èmi yóò pa àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ run,
    èyí tí ó pè ní èrè rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀,
Èmi yóò sọ wọ́n di igbó,
    àwọn ẹranko búburú yóò sì jẹ́ wọn run.
13 Èmi yóò bẹ̀ ọjọ́ Baalimu wò ní ara rẹ̀
    nínú èyí tó ń fi tùràrí jóná fún Baali;
tí ó fi òrùka etí àti ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́,
    tó sì tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ.
    Ṣùgbọ́n èmi ni òun gbàgbé,”
    ni Olúwa wí.

14 “Nítorí náà, èmi yóò tàn án
    Èmi ó sì mú u lọ sí ilẹ̀ aṣálẹ̀
    Èmi ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá a sọ̀rọ̀
15 Níbẹ̀ ni èmi yóò ti dá ọgbà àjàrà rẹ̀ padà fún un,
    Èmi yóò fi Àfonífojì Akori ṣe ìlẹ̀kùn ìrètí fún un.
Yóò sì kọrin níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀
    gẹ́gẹ́ bí ìgbà tó kúrò ní Ejibiti.

Luku 8:22-25

Jesu bá rírú omi okun wí

22 (A)Ní ọjọ́ kan, ó sì wọ ọkọ̀ ojú omi kan lọ òun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. O sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí a rékọjá lọ sí ìhà kejì adágún.” Wọ́n sì ṣíkọ̀ láti lọ. 23 Bí wọ́n sì ti ń lọ, ó sùn; ìjì ńlá sì dé, ó ń fẹ́ lójú adágún; omi si wọ inú ọkọ, wọ́n sì wà nínú ewu.

24 (B)Wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá wọ́n sì jí i, wí pé, “Olùkọ́, Olùkọ́, àwa yóò ṣègbé!”

Nígbà náà ni ó dìde, ó sì bá ìjì líle àti ríru omi wí; wọ́n sì dúró, ìdákẹ́rọ́rọ́ sì dé. 25 Ó sì wí fún wọn pé, “Ìgbàgbọ́ yín dà?”

Bí ẹ̀rù ti ń ba gbogbo wọn, tí hà sì ń ṣe wọ́n, wọ́n ń bi ara wọn pé, “Irú ọkùnrin wo ni èyí, nítorí ó bá ìjì líle àti ríru omi wí, wọ́n sì gbọ́ tirẹ̀?”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.