Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Ìwòsàn Naamani adẹ́tẹ̀
5 Naamani jẹ́ olórí ogun ọba Aramu. Ó jẹ́ ènìyàn ńlá níwájú ọ̀gá rẹ̀, wọ́n sì bu ọlá fún un, nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ ni Olúwa ti fi ìṣẹ́gun fún Aramu. Òun jẹ́ alágbára, akọni ọkùnrin ṣùgbọ́n, ó dẹ́tẹ̀.
2 Nísinsin yìí ẹgbẹgbẹ́ láti Aramu ti jáde lọ láti mú ọmọ obìnrin kékeré kan ní ìgbèkùn láti Israẹli, ó sì sin ìyàwó Naamani. 3 Ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ obìnrin pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ọ̀gá mi lè rí wòlíì tí ó wà ní Samaria! Yóò wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”
4 Naamani lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ ó sì wí fún un ohun tí ọmọbìnrin Israẹli ti sọ. 5 “Ní gbogbo ọ̀nà, lọ,” ọba Aramu dá a lóhùn pé, “Èmi yóò fi ìwé ránṣẹ́ sí ọba Israẹli.” Bẹ́ẹ̀ ni Naamani lọ, ó sì mú pẹ̀lú rẹ̀ tálẹ́ǹtì fàdákà mẹ́wàá, ẹgbẹ̀ta ìwọ̀n wúrà (6,000) àti ìpààrọ̀ aṣọ mẹ́wàá. 6 Ìwé tí ó mú lọ sọ́dọ̀ ọba Israẹli kà pé: “Pẹ̀lú ìwé yìí èmi ń rán ìránṣẹ́ mi Naamani sí ọ pé o lè wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”
7 Bí ọba Israẹli ti ka ìwé náà ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wí pé, “Èmi ha jẹ́ Ọlọ́run? Ǹjẹ́ èmi le pa kí n sì mú wá sí ààyè padà? Kí ni ó dé tí eléyìí rán ènìyàn sí mi láti wo ààrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ sàn, kí ẹ wo bí ó ti ń wá ọ̀nà láti wá ìjà pẹ̀lú mi!”
8 Nígbà tí Eliṣa ènìyàn Ọlọ́run gbọ́ pé ọba Israẹli ti ya aṣọ rẹ̀, ó sì rán iṣẹ́ yìí sí i pé: “Kí ni ó dé tí o fi fa aṣọ rẹ ya? Jẹ́ kí ọkùnrin náà wá sí ọ̀dọ̀ mi. Òun yóò sì mọ̀ pé wòlíì wà ní Israẹli.” 9 Bẹ́ẹ̀ ni Naamani sì lọ pẹ̀lú ẹṣin rẹ̀ àti kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà ilé Eliṣa. 10 Eliṣa rán ìránṣẹ́ láti lọ sọ fún un pé, “Lọ, wẹ̀ ara rẹ ní ìgbà méje ní odò Jordani, ẹran-ara rẹ yóò sì tún padà bọ̀ sípò, ìwọ yóò sì mọ́.”
11 Ṣùgbọ́n Naamani lọ pẹ̀lú ìbínú ó sì wí pé, “Mo lérò pé yóò sì dìde jáde wá nítòótọ́ sí mi, yóò sì pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run, fi ọwọ́ rẹ̀ lórí ibẹ̀ kí ó sì wo ẹ̀tẹ̀ mi sàn. 12 Abana àti Fapari, odò Damasku kò ha dára ju gbogbo omi Israẹli lọ? Ṣé èmi kò le wẹ̀ nínú wọn kí n sì mọ́?” Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà, ó sì lọ pẹ̀lú ìrunú.
13 Ìránṣẹ́ Naamani lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi, tí wòlíì bá ti sọ fún ọ láti ṣe ohun ńlá kan, ṣé ìwọ kì bá ti ṣe, mélòó mélòó nígbà náà, nígbà tí ó sọ fún ọ pé, ‘Wẹ̀ kí o sì mọ́’!” 14 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ ó sì tẹ ara rẹ̀ bọ inú odò Jordani ní ìgbà méje, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run ti sọ fún un, ẹran-ara rẹ̀ sì tún padà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin kékeré.
Saamu. Orin. Fún ìyàsímímọ́ Tẹmpili. Ti Dafidi.
30 Èmi yóò kókìkí i rẹ, Olúwa,
nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékè
tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí.
2 Olúwa Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́, fún ìrànlọ́wọ́
ìwọ sì ti wò mí sàn.
3 Olúwa, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú,
mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò.
4 Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ẹ̀yin olódodo;
kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́.
5 Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀,
ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé;
Ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́,
Ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀.
6 Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé,
“a kì yóò ṣí mi ní ipò padà.”
7 Nípa ojúrere rẹ, Olúwa,
ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára;
ìwọ pa ojú rẹ mọ́,
àyà sì fò mí.
8 Sí ọ Olúwa, ni mo ké pè é;
àti sí Olúwa ni mo sọkún fún àánú:
9 “Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi,
nínú lílọ sí ihò mi?
Eruku yóò a yìn ọ́ bí?
Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo rẹ?
10 Gbọ́, Olúwa, kí o sì ṣàánú fún mi;
ìwọ Olúwa, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi.”
11 Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi;
ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí,
12 nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí o má sì ṣe dákẹ́.
Ìwọ Olúwa Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.
Ṣíṣe dáradára sí gbogbo ènìyàn
6 Ará, bí a tilẹ̀ mú ènìyàn nínú ẹ̀ṣẹ̀ kan, kí ẹ̀yin tí í ṣe ti Ẹ̀mí mú irú ẹni bẹ́ẹ̀ bọ̀ sípò nínú ẹ̀mí ìwà tútù; kí ìwọ tìkára rẹ̀ máa kíyèsára, kí a má ba à dán ìwọ náà wò pẹ̀lú. 2 Ẹ máa ru ẹrù ọmọnìkejì yín, kí ẹ sì fi bẹ́ẹ̀ mú òfin Kristi ṣẹ. 3 Nítorí bí ènìyàn kan bá ń ro ara rẹ̀ sí ẹnìkan, nígbà tí kò jẹ́ nǹkan, ó ń tan ara rẹ̀ jẹ. 4 Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù yẹ iṣẹ́ ara rẹ̀ wò, nígbà náà, ohun ìmú-ṣogo rẹ̀ yóò jẹ́ nínú ti ara rẹ̀ nìkan, kì yóò sì jẹ nínú ti ọmọnìkejì rẹ̀. 5 Nítorí pé olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ara rẹ̀. 6 Ṣùgbọ́n kí ẹni tí a ń kọ́ nínú ọ̀rọ̀ náà máa pèsè ohun rere gbogbo fún ẹni tí ń kọ́ni.
7 Kí a má ṣe tàn yín jẹ; a kò lè gan Ọlọ́run: nítorí ohunkóhun tí ènìyàn bá fúnrúgbìn, òhun ni yóò sì ká. 8 Nítorí ẹni tí ó bá ń fúnrúgbìn sípa ti ara yóò ká ìdíbàjẹ́ ti ara ṣùgbọ́n ẹni tí ń fúnrúgbìn sípa ti ẹ̀mí yóò ti inú ẹ̀mí ká ìyè àìnípẹ̀kun. 9 Ẹ má sì jẹ́ kí àárẹ̀ ọkàn mú wa ní ṣíṣe rere, nítorí tí a ó kórè nígbà tí àkókò bá dé, bí a kò bá ṣe àárẹ̀. 10 Ǹjẹ́ bí a ti ń rí àǹfààní gba, ẹ jẹ́ kí a máa ṣoore fún gbogbo ènìyàn, àti pàápàá fún àwọn tí í ṣe ará ilé ìgbàgbọ́.
Kì í ṣe ìkọlà bí kò ṣe ẹ̀dá tuntun
11 (A)Ẹ wo bí mo ti fi ọwọ́ ara mi kọ̀wé gàdàgbà-gàdàgbà sí yín.
12 Iye àwọn tí ń fẹ́ ṣe àṣehàn ni ara wọn ń rọ yín láti kọlà; kìkì nítorí pé kí a má ba à ṣe inúnibíni sí wọn nítorí àgbélébùú Kristi. 13 Nítorí àwọn tí a kọ ní ilà pàápàá kò pa òfin mọ́, ṣùgbọ́n wọ́n ń fẹ́ mú yin kọlà, kí wọn lè máa ṣògo nínú ara yín. 14 Ṣùgbọ́n kí a má ṣe rí i pé èmi ń ṣògo, bí kò ṣe nínú àgbélébùú Jesu Kristi Olúwa wa, nípasẹ̀ ẹni tí a ti kan ayé mọ́ àgbélébùú fún mi, àti èmi fún ayé. 15 Nítorí pé nínú Kristi Jesu, ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà, bí kò ṣe ẹ̀dá tuntun. 16 (B)Kí àlàáfíà àti àánú wà lórí gbogbo àwọn tí ń rìn ní ìlànà yìí, àti lórí Israẹli Ọlọ́run.
Jesu rán àádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn jáde
10 (A)Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Olúwa sì yan àádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn pẹ̀lú, ó sì rán wọn ní méjì méjì lọ ṣáájú rẹ̀, sí gbogbo ìlú àti ibi tí òun tìkára rẹ̀ yóò sì dé. 2 (B)Ó sì wí fún wọn pé, “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan, nítorí náà ẹ bẹ Olúwa ìkórè, kí ó lè rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀. 3 (C)Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n: sá wò ó, èmi rán yín lọ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sáàrín ìkookò. 4 Ẹ má ṣe mú àpò, ẹ má ṣe mú àpamọ́wọ́, tàbí bàtà: ẹ má sì ṣe kí ẹnikẹ́ni lọ́nà.
5 (D)“Ní ilékílé tí ẹ̀yin bá wọ̀, kí ẹ kọ́ wí pé, ‘Àlàáfíà fún ilé yìí!’ 6 Bí ọmọ àlàáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín yóò bà lé e: ṣùgbọ́n bí kò bá sí, yóò tún padà sọ́dọ̀ yín. 7 (E)Ẹ dúró sínú ilé náà, kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ohunkóhun tí wọ́n bá fi fún yín; nítorí ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i, Ẹ má ṣe lọ láti ilé dé ilé.
8 “Ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá wọ̀, tí wọ́n bá sì gbà yín, ẹ jẹ ohunkóhun tí a bá gbé ka iwájú yín: 9 Ẹ sì mú àwọn aláìsàn tí ń bẹ nínú rẹ̀ láradá, kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀ sí yín!’ 10 Ṣùgbọ́n ní ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, tí wọn kò bá sì gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá sì jáde ní ìgboro ìlú náà, kí ẹ̀yin sì wí pé, 11 (F)‘Eruku ìlú yín tí ó kù sí wa lẹ́sẹ̀, a gbọ̀n ọ́n sílẹ̀ fún yín! Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀.’
16 (A)“Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ yín, ó kọ̀ mi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ mi, ó kọ ẹni tí ó rán mi.”
17 Àwọn àádọ́rin náà sì fi ayọ̀ padà, wí pé, “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù tilẹ̀ foríbalẹ̀ fún wa ní orúkọ rẹ.”
18 (B)Ó sì wí fún wọn pé, “Èmí rí Satani ṣubú bí mọ̀nàmọ́ná láti ọ̀run wá. 19 Kíyèsi i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèe mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá: kò sì ṣí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára. 20 (C)Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe yọ̀ nítorí èyí pé, àwọn ẹ̀mí ń foríbalẹ̀ fún yín; ṣùgbọ́n ẹ kúkú yọ̀, pé; a kọ̀wé orúkọ yín ní ọ̀run!”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.