Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí Doegi ará Edomu tọ Saulu lọ láti sọ fún pé, “Dafidi wà ní ilé Ahimeleki.”
52 Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe féfé nínú ìwà ìkà, ìwọ alágbára ọkùnrin?
Èéṣe tí ìwọ fi ń gbéraga nígbà gbogbo,
ìwọ ẹni ẹ̀gàn níwájú Ọlọ́run?
2 Ahọ́n rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun;
ó dàbí abẹ mímú,
ìwọ ẹni tí ń hùwà ẹ̀tàn.
3 Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ìre lọ,
àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ.
4 Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo,
ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!
5 Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé,
yóò sì dì ọ́ mú,
yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó rẹ,
yóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Sela.
6 Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rù
wọn yóò sì rẹ́rìn-ín rẹ̀, wí pé,
7 “Èyí ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára rẹ̀,
bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé,
ó sì mu ara rẹ̀ le nínú ìwà búburú rẹ̀.”
8 Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi Olifi
tí ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run;
Èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnà
láé àti láéláé.
9 Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe;
èmi ní ìrètí nínú orúkọ rẹ,
nítorí orúkọ rẹ dára.
Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́.
Ọjọ́ Olúwa
18 Ègbé ni fún ìwọ tí ó pẹ́
nítorí ọjọ́ Olúwa
kí ni ìwọ fi pẹ́ fún ọjọ́ Olúwa?
Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn ní ojú ọjọ́
19 Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ó sá fún kìnnìún,
tí ó padà wá bọ́ sí ẹnu àmọ̀tẹ́kùn.
Yóò dàbí ẹni tí ó wọ ilé rẹ̀ lọ
tí ó sinmi lé ògiri ilé rẹ̀
tí ejò sì bù ú ṣán.
20 Ǹjẹ́ ọjọ́ Olúwa kò ha ní ṣókùnkùn dípò kí ó ní ìmọ́lẹ̀?
Tí yóò sì ṣókùnkùn dúdú láìsí ìmọ́lẹ̀ kankan níbẹ̀.
21 “Mo kórìíra, mo kẹ́gàn àwọn àsè ẹ̀sìn in yín
Èmi kò sì ní inú dídùn sí àpéjọ yín
22 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà wá
Èmi kò ní tẹ́wọ́ gbà wọ́n
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú àṣàyàn ọrẹ àlàáfíà wá.
Èmi kò ní náání wọn.
23 Ẹ gbé ariwo orin yín sẹ́yìn
Èmi kò ní fetísí ohun èlò orin yín.
24 Jẹ́ kí òtítọ́ sàn bí odò
àti òdodo bí ìsun tí kò lé è gbẹ!
25 (A)“Àbí ẹ̀yin mú ẹbọ àti ọrẹ tọ̀ mí wá
ní ogójì ọdún ní aginjù ìwọ ilé Israẹli?
26 Ẹ̀yin ti gbé ibi ìrúbọ àwọn ọba yín sókè
ibùgbé àwọn òrìṣà yín
àní, ti àwọn òrìṣà yín tí ó níyì jùlọ,
èyí tí ẹ̀yin fi ọwọ́ ara yín ṣe.
27 Nítorí náà èmi yóò rán an yín lọ sí ìgbèkùn ní ìkọjá Damasku,”
ni Olúwa wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọ́run alágbára.
Àdúrà fún àwọn ará Efesu
14 Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń fi eékún mi kúnlẹ̀ fún Baba Olúwa wa Jesu Kristi. 15 Orúkọ ẹni tí a fi ń pe gbogbo ìdílé tí ń bẹ ni ọ̀run àti ní ayé. 16 Kí òun kí ó lè fi agbára rẹ̀ fún ẹni inú yín ní okun, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. 17 Kí Kristi lè máa gbé inú ọkàn yín nípa ìgbàgbọ́; pé bí ẹ ti ń fi gbòǹgbò múlẹ̀ tí ẹ sì ń fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìfẹ́; 18 kí ẹ̀yin lè ní agbára láti mọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ohun tí ìbú, àti gígùn, àti jíjìn, àti gíga ìfẹ́ Kristi jẹ́. 19 Àti láti mọ̀ ìfẹ́ Kristi yìí tí ó ta ìmọ̀ yọ, kí a lè fi gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run kún yín.
20 Ǹjẹ́ ẹni tí o lè ṣe lọ́pọ̀lọpọ̀ ju gbogbo èyí tí a ń béèrè tàbí tí a ń rò lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára tí ń ṣiṣẹ́ nínú wa. 21 Òun ni kí a máa fi ògo fún nínú ìjọ àti nínú Kristi Jesu láti ìrandíran gbogbo àní, ayé àìnípẹ̀kun, Àmín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.