Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí Doegi ará Edomu tọ Saulu lọ láti sọ fún pé, “Dafidi wà ní ilé Ahimeleki.”
52 Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe féfé nínú ìwà ìkà, ìwọ alágbára ọkùnrin?
Èéṣe tí ìwọ fi ń gbéraga nígbà gbogbo,
ìwọ ẹni ẹ̀gàn níwájú Ọlọ́run?
2 Ahọ́n rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun;
ó dàbí abẹ mímú,
ìwọ ẹni tí ń hùwà ẹ̀tàn.
3 Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ìre lọ,
àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ.
4 Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo,
ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!
5 Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé,
yóò sì dì ọ́ mú,
yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó rẹ,
yóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Sela.
6 Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rù
wọn yóò sì rẹ́rìn-ín rẹ̀, wí pé,
7 “Èyí ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára rẹ̀,
bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé,
ó sì mu ara rẹ̀ le nínú ìwà búburú rẹ̀.”
8 Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi Olifi
tí ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run;
Èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnà
láé àti láéláé.
9 Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe;
èmi ní ìrètí nínú orúkọ rẹ,
nítorí orúkọ rẹ dára.
Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́.
10 Ìwọ kórìíra ẹni tí ń bá ni wí ní ẹnu ibodè
ó sì ń pẹ̀gàn ẹni tí ń sọ òtítọ́.
11 Ìwọ ń tẹ tálákà mọ́lẹ̀
o ń fi ipá gba ọkà lọ́wọ́ wọn
Nítorí náà, ìwọ ti fi òkúta tí a gbẹ́ kọ́lé
ṣùgbọ́n ẹ kò sì ní gbé inú wọn
Nítòótọ́ ìwọ ti gbin ọgbà àjàrà tí ó lẹ́wà.
Ìwọ kò ní mu wáìnì inú wọn
12 Nítorí mo mọ iye àìṣedéédéé rẹ
mo sì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí tóbi tó.
Ìwọ ni olódodo lára, ìwọ sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀
o sì ń fi òtítọ́ du tálákà ní ilé ẹjọ́
13 Àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò wọ̀nyí,
nítorí búburú ni gbogbo ọjọ́.
14 Wá rere, má ṣe wá búburú
kí ìwọ ba à le yè
Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun yóò wà pẹ̀lú rẹ.
Òun yóò sì wà pẹ̀lú rẹ bí ìwọ ṣe wí
15 Kórìíra búburú kí o sì fẹ́ rere
dúró ní orí òtítọ́ ní ilé ẹjọ́
bóyá Olúwa Ọlọ́run alágbára
yóò ṣíjú àánú wo ọmọ Josẹfu tó ṣẹ́kù.
16 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí:
“Ẹkún yóò wà ní àwọn òpópónà
igbe ìnira yóò sì wà ní àwọn gbàgede ìlú
A ó kó àwọn àgbẹ̀ jọ láti sọkún
àti àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ láti pohùnréré ẹkún
17 Ìpohùnréré ẹkún yóò wà ní gbogbo ọgbà àjàrà
Nítorí èmi yóò la àárín yín kọjá,”
ni Olúwa wí.
5 Nítorí olórí àlùfáà kọ̀ọ̀kan tí a yàn nínú àwọn ènìyàn, ní a fi jẹ nítorí iṣẹ́ ìsìn àwọn ènìyàn sí Ọlọ́run láti máa mú ẹ̀bùn àti ẹbọ wá nítorí ẹ̀ṣẹ̀. 2 Ẹni tí ó lè ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ pẹ̀lú àwọn aláìmòye, tí ó sì lé bá àwọn tí ó ti yapa kẹ́dùn, nítorí a fi àìlera yí òun náà ká pẹ̀lú. 3 Nítorí ìdí èyí ni ó ṣe yẹ, bí ó ti ń rú ẹbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ní ń ṣe fún ara rẹ̀ náà. 4 Kọ sí ẹni tí o gba ọlá yìí fún ara rẹ̀, bí kò ṣe ẹni tí a pè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá gẹ́gẹ́ bí a ti pe Aaroni.
5 (A)Bẹ́ẹ̀ ni Kristi pẹ̀lú kò sì ṣe ara rẹ̀ lógo láti jẹ́ olórí àlùfáà; bí kò ṣe ẹni tí o wí fún ún pé,
“Ìwọ ni ọmọ mi,
lónìí ni mo bí ọ.”
6 (B)Bí ó ti wí pẹ̀lú ní ibòmíràn pé,
“Ìwọ ni àlùfáà títí láé
ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.