Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 82

Saamu ti Asafu.

82 Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá,
    ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn “ọlọ́run òrìṣà”.

“Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìṣòdodo
    kí ó sì ṣe ojú ìṣáájú sí àwọn ènìyàn búburú?
Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba;
    ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára.
Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní;
    gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú.

“Wọn kò mọ̀ ohun kankan,
    wọn kò lóye ohun kankan.
Wọn ń rìn kiri nínú òkùnkùn;
    à si mí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé.

(A)“Mo wí pé, ‘Ẹyin ní “Ọlọ́run òrìṣà”;
    ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ.’
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ó kú bí ènìyàn lásán;
    ẹ̀yin ó ṣubú bí ọ̀kan nínú ọmọ-aládé.”

Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ayé,
    nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè ni ìní rẹ.

Amosi 1:1-2:3

Àwọn ọ̀rọ̀ Amosi, ọ̀kan lára àwọn olùṣọ́-àgùntàn Tekoa; ohun tí o rí nípa Israẹli ní ọdún méjì ṣáájú ilẹ̀-rírì, nígbà tí Ussiah ọba Juda àti Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi jẹ́ ọba ní ilẹ̀ Israẹli.

(A)Ó wí pé:

Olúwa yóò bú jáde láti Sioni
    ohùn rẹ̀ yóò sì sán bí àrá láti Jerusalẹmu wá;
Ibùgbé àwọn olùṣọ́-àgùntàn yóò sì ṣọ̀fọ̀,
    orí òkè Karmeli yóò sì rọ.”

Ìdájọ́ àwọn aládùúgbò Israẹli

(B)Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Damasku,
    àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà
Nítorí wọn fi ohun èlò ìpakà pa Gileadi.
    Pẹ̀lú ohun èlò irin tí ó ní eyín mímú
Èmi yóò rán iná sí ilé Hasaeli
    Èyí ti yóò jó àwọn ààfin Beni-Hadadi run.
Èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá ìdábùú Damasku;
    Èmi yóò sì pa ọba tí ó wà ní Àfonífojì Afeni run
àti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé mú ní Beti-Edeni.
    Àwọn ará a Aramu yóò lọ sí ìgbèkùn sí Kiri,”
    ni Olúwa wí.

(C)Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Gasa,
    àní nítorí mẹ́rin,
Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà
    Gẹ́gẹ́ bí í oníṣòwò ẹrú,
ó kó gbogbo àwọn ènìyàn mi ní ìgbèkùn.
    Ó sì tà wọ́n fún Edomu,
Èmi yóò rán iná sí ara odi Gasa
    tí yóò jó gbogbo ààfin rẹ̀ run
Èmi yóò ké àwọn olùgbé Aṣdodu kúrò,
    ti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé ní Aṣkeloni mú.
Èmi yóò yí ọwọ́ mi sí Ekroni
    títí tí ìyókù Filistini yóò fi ṣègbé,”
    ni Olúwa Olódùmarè wí.

(D)Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Tire
    àní nítorí mẹ́rin, Èmi kì yóò yí ìpinnu ìjìyà mi padà.
Nítorí wọ́n ta gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìgbèkùn fún Edomu
    Wọn kò sì nání májẹ̀mú ọbàkan,
10 Èmi yóò rán iná sí ara odi Tire
    Tí yóò jó gbogbo àwọn ààfin rẹ̀ run.”

11 (E)Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Edomu,
    àní nítorí mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà
Nítorí òhun fi idà lépa arákùnrin rẹ̀,
    Ó sì gbé gbogbo àánú sọnù
ìbínú rẹ̀ sì ń faniya títí
    ó sì pa ìbínú rẹ̀ bí èéfín mọ́
12 Èmi yóò rán iná sí orí Temani
    Tí yóò jó gbogbo ààfin Bosra run.”

13 (F)Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Ammoni
    àní mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà,
Nítorí wọn ti la inú àwọn aboyún Gileadi
    kí wọ́n ba à lè fẹ ilẹ̀ wọn sẹ́yìn.
14 Èmi yóò rán iná sí ara odi Rabba
    èyí tí yóò jó àwọn ààfin rẹ̀ run
pẹ̀lú ìhó ayọ̀ ní ọjọ́ ogun,
    pẹ̀lú ìjì líle ni ọjọ́ àjà.
15 Ọba wọn yóò sì lọ sí ìgbèkùn
    Òun àti àwọn ọmọ-aládé rẹ̀ lápapọ̀,”
    ni Olúwa wí.

(G)Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Moabu,
    àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà,
Nítorí ó ti sun ún, di eérú,
    egungun ọba Edomu
Èmi yóò rán iná sí orí Moabu
    èyí tí yóò jó àwọn ààfin Kerioti run.
Moabu yóò sì kú pẹ̀lú ariwo
    pẹ̀lú igbe àti pẹ̀lú ìró ìpè
Èmi yóò ké onídàájọ́ rẹ̀ kúrò
    Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn ọmọ-aládé rẹ́ nínú rẹ̀,”
    ni Olúwa wí.

Jakọbu 2:14-26

Ìgbàgbọ́ àti àwọn iṣẹ́

14 Èrè kí ni ó jẹ́, ará mi, bí ẹni kan wí pé òun ní ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí kò ní àwọn iṣẹ́ láti fihan? Ìgbàgbọ́ náà lè gbà á là bí? 15 Bí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá wà ní àìní aṣọ, tí ó sì ṣe àìní oúnjẹ òòjọ́, 16 Tí ẹni kan nínú yín sì wí fún pé, “Máa lọ ní àlàáfíà, kí ara rẹ kí ó má ṣe tutù, kí ó sì yó,” ṣùgbọ́n ẹ kò fi nǹkan wọ̀n-ọn-nì ti ara ń fẹ́ fún wọn; èrè kí ni ó jẹ́? 17 Bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbàgbọ́, bí kò bá ní iṣẹ́ rere, ó kú nínú ara rẹ̀.

18 Ṣùgbọ́n ẹnìkan lè wí pé, “Ìwọ ní ìgbàgbọ́, èmi sì ní iṣẹ́:”

Fi ìgbàgbọ́ rẹ hàn mí ní àìsí iṣẹ́, èmi ó sì fi ìgbàgbọ́ mi hàn ọ́ nípa iṣẹ́ rere mi. 19 Ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kan ní ó ń bẹ; ó dára! Àwọn ẹ̀mí èṣù pẹ̀lú gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n sì wárìrì.

20 Ṣùgbọ́n, ìwọ aláìmòye ènìyàn, ìwọ ha fẹ́ ní ìdánilójú pé, ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ rere asán ni? 21 (A)Kí ha í ṣe nípa iṣẹ́ ni a dá Abrahamu baba wa láre, nígbà tí ó fi Isaaki ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ lórí pẹpẹ? 22 Ìwọ rí i pé ìgbàgbọ́ rẹ bá iṣẹ́ rìn, àti pé nípa iṣẹ́ rere ni a sọ ìgbàgbọ́ di pípé. 23 (B)Ìwé Mímọ́ sì ṣẹ́ tí ó wí pé, “Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un,” a sì pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. 24 Ǹjẹ́ ẹ̀yin rí i pé nípa iṣẹ́ rere ni à ń dá ènìyàn láre, kì í ṣe nípa ìgbàgbọ́ nìkan.

25 (C)Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú kí a dá Rahabu panṣágà láre nípa iṣẹ́ bí, nígbà tí ó gba àwọn ayọ́lẹ̀wò, tí ó sì rán wọn jáde gba ọ̀nà mìíràn? 26 Nítorí bí ara ní àìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú ni ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ jẹ́ òkú.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.