Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 85

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.

85 Ìwọ fi ojúrere hàn fún ilé rẹ, Olúwa;
    ìwọ mú ohun ìní Jakọbu bọ̀ sí ipò.
Ìwọ dárí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn rẹ jì
    ìwọ sì bó ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. Sela.
Ìwọ fi àwọn ìbínú rẹ sápá kan
    ìwọ sì yípadà kúrò nínú ìbínú gbígbóná rẹ.

Yí wa padà, Ọlọ́run ìgbàlà wa,
    kí o sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ wa.
Ìwọ yóò ha máa bínú sí wa títí láé?
    Ìwọ yóò ha mú ìbínú rẹ pẹ́ yí gbogbo ìran ká?
Ìwọ kì yóò ha sọ wá jí padà mọ́,
    pé kí àwọn ènìyàn rẹ lè yọ nínú rẹ?
Fi ìfẹ́ rẹ tí kò le è kùnà hàn wá, Olúwa,
    Kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ.

Èmi ó gbọ́ ohun tí Olúwa Ọlọ́run yóò wí;
    ó ṣèlérí àlàáfíà fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àní ẹni mímọ́ rẹ̀:
Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn padà sí àìmoye.
Nítòótọ́ ìgbàlà rẹ̀ súnmọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
    pé kí ògo rẹ̀ kí ó lè gbé ní ilẹ̀ wa.

10 Ìfẹ́ àti òtítọ́ parapọ̀;
    òdodo àti àlàáfíà fẹnu ko ara wọn.
11 Òtítọ́ ń sun jáde láti ilẹ̀ wá
    òdodo sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run.
12 Olúwa yóò fi ohun dídára fún ni nítòótọ́,
    ilẹ̀ wa yóò sì mú ìkórè rẹ̀ jáde.
13 Òdodo síwájú rẹ lọ
    o sì pèsè ọ̀nà fún ìgbésẹ̀ rẹ̀.

Hosea 5

Ìdájọ́ n bọ̀ lórí Israẹli àti Juda

“Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yìn àlùfáà!
    Ẹ fetísílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ Israẹli!
Ẹ gbọ́, ẹ̀yìn ilé ọba!
    Ìdájọ́ yìí kàn yín:
Ẹ ti jẹ́ ẹ̀bìtì ní Mispa
    àwọ̀n ti a nà sílẹ̀ lórí Tabori
Àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti gbilẹ̀ nínú ìpànìyàn
    gbogbo wọn ni èmi ó bá wí,
Mo mọ ohun gbogbo nípa Efraimu
    Israẹli kò sì pamọ́ fún mi
Efraimu, ní báyìí ó ti ṣe àgbèrè
    Israẹli sì ti díbàjẹ́.

“Ìṣe wọn kò gbà wọ́n láààyè
    láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọn.
Ẹ̀mí àgbèrè wà ni ọkàn wọn,
    wọn kò sì mọ Olúwa.
Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí lé wọn;
    Àwọn ọmọ Israẹli, àti Efraimu pàápàá kọsẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
    Juda náà sì kọsẹ̀ pẹ̀lú wọn.
Nígbà tí wọ́n bá lọ pẹ̀lú agbo ẹran
    àti ọ̀wọ́ ẹran wọn láti wá Olúwa,
wọn kò ní rí i,
    ó ti yọ ara rẹ̀ kúrò láàrín wọn.
Wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Olúwa
    wọ́n sì bí àwọn àjèjì ọmọ.
Nísinsin yìí, ọdún oṣù tuntun wọn,
    ni yóò pa wọn run pẹ̀lú ìpín wọn.

“Fọn fèrè ní Gibeah,
    kí ẹ sì fun ìpè ní Rama.
Ẹ pariwo ogun ní Beti-Afeni
    máa wárìrì, ìwọ Benjamini.
Efraimu yóò di ahoro
    ní ọjọ́ ìbáwí
láàrín àwọn ẹ̀yà Israẹli
    Mo sọ ohun tí ó dájú.
10 Àwọn olórí Juda dàbí àwọn tí í
    máa yí òkúta ààlà kúrò.
Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi lé
    wọn lórí bí ìkún omi.
11 A ni Efraimu lára,
    A sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ìdájọ́
    nítorí pé, ó pinnu láti tẹ̀lé òrìṣà
12 Mo dàbí kòkòrò aṣọ sí Efraimu
    Mo sì dàbí ìdin ara Juda.

13 “Nígbà ti Efraimu ri àìsàn rẹ̀,
    tí Juda sì rí ojú egbò rẹ̀
ni Efraimu bá tọ ará Asiria lọ,
    ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá náà fún ìrànlọ́wọ́
Ṣùgbọ́n kò le è wò ó sàn
    bẹ́ẹ̀ ni kò le wo ojú egbò rẹ̀ jinná
14 Nítorí pé, èmi ó dàbí kìnnìún sí Efraimu,
    bí i kìnnìún ńlá sí ilé Juda.
Èmi ó fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ èmi ó sì lọ;
    Èmi ó gbé wọn lọ, láìsí ẹni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀.
15 Nígbà náà ni èmi ó padà lọ sí ààyè mi
    títí di ìgbà tí wọn ó fi gbà pé àwọn jẹ̀bi
wọn yóò sì wá ojú mi
    nínú ìpọ́njú wọn, wọn ó fi ìtara wá mi.”

Ìṣe àwọn Aposteli 2:22-36

22 “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Jesu tí Nasareti, ọkùnrin tí a mọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá nípa iṣẹ́ agbára àti tí ìyanu, àti ààmì ti Ọlọ́run ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrín yín, bí ẹ̀yin tìkára yín ti mọ̀ pẹ̀lú. 23 Ẹni tí a ti fi lé yín lọ́wọ́ nípa ìpinnu ìmọ̀ àti ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run; àti ẹ̀yin pẹ̀lú, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú kàn mọ́ àgbélébùú, tí a sì pa á. 24 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, gbà á kúrò nínú ìrora ikú: nítorí tí kò ṣe é ṣe fún ikú láti dìímú. 25 (A)Dafidi tí wí nípa tirẹ̀ pé:

“ ‘Mo rí Olúwa nígbà gbogbo níwájú mí,
    nítorí tí ó ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún mi,
    a kì ó ṣí mi ní ipò.
26 Nítorí náà inú mi dùn, ahọ́n mi sì yọ̀:
    pẹ̀lúpẹ̀lú ara mi yóò sì sinmi ní ìrètí.
27 Nítorí tí ìwọ kí yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ ni isà òkú,
    bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.
28 Ìwọ mú mi mọ ọ̀nà ìyè,
    ìwọ yóò mú mi kún fún ayọ̀ ni iwájú rẹ.’

29 “Ará, èmí lè sọ fún yín pẹ̀lú ìgboyà pé Dafidi baba ńlá kú, a sì sin ín, ibojì rẹ̀ sì ń bẹ lọ́dọ̀ wa títí di òní yìí. 30 (B)Ṣùgbọ́n ó jẹ́ wòlíì, àti bí ó mọ́ pé, Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún òun nínú ìbúra pé nínú irú-ọmọ inú rẹ̀, òun yóò mú ọ̀kan jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. 31 (C)Ní rí rí èyí tẹ́lẹ̀, ó sọ ti àjíǹde Kristi, pé a kò fi ọkàn rẹ̀ sílẹ̀ ni isà òkú, bẹ́ẹ̀ ni ara rẹ̀ kò rí ìdíbàjẹ́. 32 Jesu náà yìí ni Ọlọ́run ti jí dìde sí ìyè, àwa pẹ̀lú sì jẹ́rìí sí èyí. 33 A ti gbéga sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, ó ti gba ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba, ó tu èyí tí ẹ̀yin rí àti gbọ́ nísinsin yìí síta. 34 (D)Nítorí Dafidi kò gòkè lọ sí ọ̀run ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ wí pé,

“ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé:
    “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
35 títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
    dí àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ.” ’

36 “Ǹjẹ́ kí gbogbo ilé Israẹli mọ̀ dájúdájú pé: Ọlọ́run ti fi Jesu náà, ti ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, ṣe Olúwa àti Kristi.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.