Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Ohun ìyanu tí o wà nínú òfin rẹ̀
17 Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ, èmi yóò sì wà láààyè;
èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ.
18 La ojú mi kí èmi lè ríran rí
ohun ìyanu tí ó wà nínú òfin rẹ.
19 Àlejò ní èmi jẹ́ láyé;
Má ṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fún mi.
20 Ọkàn mi pòruurù pẹ̀lú ìfojúsọ́nà
nítorí òfin rẹ nígbà gbogbo.
21 Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn ún
tí ó ṣìnà kúrò nínú àṣẹ rẹ.
22 Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi,
nítorí èmi pa òfin rẹ mọ́.
23 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọpọ̀, wọ́n
ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi,
ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ rẹ.
24 Òfin rẹ ni dídùn inú mi;
àwọn ní olùbádámọ̀ràn mi.
Àdúrà láti ní òye ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
25 Ọkàn mí lẹ̀ mọ́ erùpẹ̀;
ìwọ sọ mí di ààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
26 Èmi tún ọ̀nà mi ṣírò ìwọ sì dá mi lóhùn;
kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
27 Jẹ́ kí n mọ ẹ̀kọ́ ìlànà rẹ:
nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu rẹ.
28 Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́;
fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
29 Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tàn
fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ nípa òfin rẹ.
30 Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́
èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin rẹ.
31 Èmi yára di òfin rẹ mú. Olúwa
má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
32 Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ,
nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀.
5 Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
ẹni ti ó fi ọwọ́ kan ilẹ̀ náà tí ó sì yọ́, tí àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò sì ṣọ̀fọ̀;
gbogbo orílẹ̀-èdè yóò si ru sókè bí ríru odò Naili
tiwọn yóò sì tẹ̀rì bí odò Ejibiti.
6 Òun ni ẹni tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run
ti ó sì fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ ní ilé ayé
Ẹni ti ó pe àwọn omi Òkun
ti ó sì tú wọn jáde si orí ilé ayé
Olúwa ni orúkọ rẹ̀.
7 “Àbá ẹ̀yin ọmọ Israẹli
kò ha dàbí àwọn ọmọ Kuṣi sí mi?”
ni Olúwa wí.
“Èmi kò ha ti mú Israẹli gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá
àti àwọn Filistini láti ilẹ̀ Kafitori
àti àwọn ará Aramu láti Kiri?
8 “Dájúdájú, ojú Olúwa Olódùmarè
ń bẹ̀ lára ilẹ̀ ọba tó kún fún ẹ̀ṣẹ̀.
Èmi yóò pa á run kúrò lórí ilẹ̀
Síbẹ̀ Èmi kò nípa ilé Jakọbu run pátápátá,”
ni Olúwa wí.
9 “Nítorí Èmi yóò pàṣẹ,
Èmi yóò sì mi ilé Israẹli
ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè
bí a ti ń jọ nǹkan nínú ajọ̀
tí hóró kín ń kín kì yóò bọ́ sórí ilẹ̀.
10 Gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn mi
ni yóò ti ipa idà kú
gbogbo àwọn ti ń wí pé,
‘Aburú kì yóò lé wa bá, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ká wa mọ́.’
Ìmúpadàbọ̀ Israẹli
11 (A)“Ní ọjọ́ náà ní
Èmi yóò gbé àgọ́ Dafidi tí ó wó ró,
Èmi yóò dí odi rẹ̀ tí ó ya,
Èmi yóò sì gbé ahoro rẹ̀ sókè,
Èmi yóò sì kọ bí ti ọjọ́ ìgbàanì,
12 kí wọn le jogún ìyókù Edomu
àti gbogbo àwọn kèfèrí, ti a ń pè nípa orúkọ mi,”
ni Olúwa, ẹni tí yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí wí.
13 (B)“Ọjọ́ náà ń bọ,” ni Olúwa wí,
“tí ẹni tí ń tulẹ̀ yóò lé ẹni tí ń kórè bá
Tí ẹni tí ń fún èso àjàrà yóò lé ẹni tí ń gbìn bá
Àwọn òkè ńlá yóò sì kán ọtí wáìnì sílẹ̀
Tí yóò sì sàn láti ara àwọn òkè kéékèèkéé.
14 Èmi yóò si tún mú ìgbèkùn Israẹli ènìyàn mi padà bọ̀.
“Wọn yóò sì kọ́ ahoro ìlú, wọn yóò sì máa gbé inú wọn
Wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì mu ọtí wáìnì wọn
wọn yóò sì ṣe ọgbà pẹ̀lú, wọn yóò sì jẹ èso inú wọn
15 Èmi yóò gbin Israẹli sí orí ilẹ̀ rẹ̀.
A kì yóò sì fà wọn tu mọ́ láéláé
kúrò ni orí ilẹ̀ ti mo fi fún wọn,”
ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wí.
41 Nígbà náà ni àwọn Júù ń kùn sí i, nítorí tí ó wí pé, “Èmi ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá.” 42 (A)Wọ́n sì wí pé, “Jesu ha kọ́ èyí, ọmọ Josẹfu, baba àti ìyá ẹni tí àwa mọ̀? Báwo ni ó ṣe wí pé, ‘Èmi ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá’?”
43 Nítorí náà Jesu dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe kùn láàrín yín! 44 (B)Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, bí kò ṣe pé Baba tí ó rán mi fà á: Èmi ó sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́. 45 (C)A sá à ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé, ‘A ó sì kọ́ gbogbo wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá,’ nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gbọ́, tí a sì ti ọ̀dọ̀ Baba kọ́, òun ni ó ń tọ̀ mí wá. 46 (D)Kì í ṣe pé ẹnìkan ti rí Baba bí kò ṣe ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, òun ni ó ti rí Baba. 47 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, ó ní ìyè àìnípẹ̀kun. 48 Èmi ni oúnjẹ ìyè. 49 Àwọn baba yín jẹ manna ní aginjù, wọ́n sì kú. 50 Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, kí ènìyàn lè máa jẹ nínú rẹ̀ kí ó má sì kú. 51 Èmi ni oúnjẹ ìyè náà tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá: bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò yè títí láéláé: oúnjẹ náà tí èmi ó sì fi fún ni fún ìyè aráyé ni ara mi.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.