Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
5 Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì, àwọn olórí wọn àti àwọn alàgbà àti àwọn olùkọ́ni ní òfin péjọ sí Jerusalẹmu. 6 Àti Annasi olórí àlùfáà, àti Kaiafa, àti Johanu, àti Aleksanderu, àti iye àwọn tí i ṣe ìbátan olórí àlùfáà. 7 Wọ́n mú Peteru àti Johanu dúró níwájú wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Nípa agbára tàbí orúkọ wo ni ẹ̀yin fi ṣe èyí?”
8 Nígbà náà ni Peteru kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin olórí àti ẹ̀yin alàgbà àwọn ènìyàn! 9 Bí ó bá ṣe pé a ń wádìí wa lónìí ní tí iṣẹ́ rere ti a ṣe lára abirùn náà, bí a ti ṣe mú ọkùnrin yìí láradá, 10 Kí èyí yé gbogbo yín àti gbogbo ènìyàn Israẹli pé, ni orúkọ Jesu Kristi ti Nasareti, tí ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, tí Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, nípa rẹ̀ ni ọkùnrin yìí fi dúró níwájú yín ni ara dídá-ṣáṣá. 11 (A)Èyí ni
“ ‘òkúta tí a ti ọwọ́ ẹ̀yin ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
tí ó sì di pàtàkì igun ilé.’
12 Kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlòmíràn; nítorí kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run ti a fi fún ni nínú ènìyàn, nípa èyí tí a lè fi gbà wá là.”
Saamu ti Dafidi.
23 Olúwa ni Olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.
2 (A)Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù
Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́;
3 Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò
Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo
nítorí orúkọ rẹ̀.
4 Bí mo tilẹ̀ ń rìn
Láàrín àfonífojì òjìji ikú,
èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan;
nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;
ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ
wọ́n ń tù mí nínú.
5 Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi
ní ojú àwọn ọ̀tá à mi;
ìwọ ta òróró sí mi ní orí;
ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.
6 Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn
ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo,
èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwa
títí láéláé.
16 (A)Nípa èyí ni àwa mọ ìfẹ́ nítorí tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa: ó sì yẹ kí àwa fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún àwọn ará. 17 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ni ohun ìní ayé, tí ó sì ri arákùnrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí ó sì sé ìlẹ̀kùn ìyọ́nú rẹ̀ mọ́ ọn, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ń gbé inú rẹ̀? 18 (B)Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi ọ̀rọ̀ tàbí ahọ́n fẹ́ràn, bí kò ṣe ni ìṣe àti ní òtítọ́.
19 Àti nípa èyí ni àwa ó mọ̀ pé àwa jẹ́ ti òtítọ́, àti pé àwa ó sì fi ọkàn ara wa balẹ̀ níwájú rẹ̀. 20 Nínú ohunkóhun tí ọkàn wa bá ń dá wa lẹ́bi; nítorí pé Ọlọ́run tóbi ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo. 21 (C)Olùfẹ́, bí ọkàn wa kò bá dá wa lẹ́bi, ǹjẹ́ àwa ni ìgboyà níwájú Ọlọ́run? 22 Àti ohunkóhun tí àwa bá béèrè, ni àwa ń rí gbà lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí tí àwa ń pa òfin rẹ̀ mọ́, àwa sì ń ṣe àwọn nǹkan tí ó dára lójú rẹ̀. 23 (D)Èyí sì ni òfin rẹ̀, pé kí àwa gba orúkọ Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀ gbọ́, kí a sì fẹ́ràn ara wá gẹ́gẹ́ bí ó tí fi òfin fún wa. 24 (E)Ẹni tí ó bá sì pa òfin rẹ̀ mọ́ ń gbé inú rẹ̀, àti òun nínú rẹ̀. Àti nípa èyí ni àwa mọ̀ pé ó ń gbé inú wa, nípa Ẹ̀mí tí ó fi fún wa.
11 (A)“Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere: olùṣọ́-àgùntàn rere fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. 12 Ṣùgbọ́n alágbàṣe, tí kì í ṣe olùṣọ́-àgùntàn, ẹni tí àwọn àgùntàn kì í ṣe tirẹ̀, ó rí ìkookò ń bọ̀, ó sì fi àgùntàn sílẹ̀, ó sì fọ́n wọn ká kiri. 13 Òun sálọ nítorí tí ó jẹ́ alágbàṣe, kò sì náání àwọn àgùntàn.
14 “Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere, mo sì mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi sì mọ̀ mí. 15 (B)Gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi sì mọ Baba; mo sì fi ọkàn mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. 16 (C)Èmi sì ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kì í ṣe agbo yìí: àwọn ni èmi yóò mú wá pẹ̀lú, wọn yóò sì gbọ́ ohùn mi; wọn ó sì jẹ́ agbo kan, olùṣọ́-àgùntàn kan. 17 Nítorí náà ni Baba mi ṣe fẹ́ràn mi, nítorí tí mo fi ẹ̀mí mi lélẹ̀, kí èmi lè tún gbà á. 18 (D)Ẹnìkan kò gbà á lọ́wọ́ mi, ṣùgbọ́n mo fi í lélẹ̀, mo sì lágbára láti tún gbà á. Àṣẹ yìí ni mo ti gbà wá láti ọ̀dọ̀ Baba mi.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.