Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
135 Ẹ yin Olúwa.
Ẹ yin orúkọ Olúwa;
ẹ yìn ín, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa.
2 Ẹ̀yin tí ń dúró ní ilé Olúwa,
nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run wa.
3 Ẹ yin Olúwa: nítorí tí Olúwa ṣeun;
ẹ kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ̀; nítorí tí ó dùn.
4 Nítorí tí Olúwa ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀;
àní Israẹli fún ìṣúra ààyò rẹ̀.
5 Nítorí tí èmi mọ̀ pé Olúwa tóbi,
àti pé Olúwa jù gbogbo òrìṣà lọ.
6 Olúwa ṣe ohunkóhun tí ó wù ú,
ní ọ̀run àti ní ayé,
ní Òkun àti ní ọ̀gbun gbogbo.
7 Ó mú ìkùùkuu gòkè láti òpin ilẹ̀ wá:
ó dá mọ̀nàmọ́ná fún òjò:
ó ń mú afẹ́fẹ́ ti inú ilẹ̀ ìṣúra rẹ̀ wá.
8 Ẹni tí ó kọlu àwọn àkọ́bí Ejibiti,
àti ti ènìyàn àti ti ẹranko.
9 Ẹni tí ó rán iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu sí àárín rẹ̀, ìwọ Ejibiti,
sí ara Farao àti sí ara àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.
10 Ẹni tí ó kọlu àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀,
tí ó sì pa àwọn alágbára ọba.
11 Sihoni, ọba àwọn ará Amori, àti Ogu,
ọba Baṣani, àti gbogbo ìjọba Kenaani:
12 Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní,
ìní fún Israẹli, ènìyàn rẹ̀.
13 Olúwa orúkọ rẹ dúró láéláé;
ìrántí rẹ Olúwa, láti ìrandíran.
14 (A)Nítorí tí Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀,
yóò sì ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀.
15 Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà,
iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni.
16 Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀;
wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.
17 Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀;
bẹ́ẹ̀ ni kò si èémí kan ní ẹnu wọn
18 Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn:
gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.
19 Ẹ̀yin ara ilé Israẹli, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa,
ẹ̀yin ará ilé Aaroni, fi ìbùkún fún Olúwa.
20 Ẹ̀yin ará ilé Lefi, fi ìbùkún fún Olúwa;
ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, fi ìbùkún fún Olúwa.
21 Olùbùkún ni Olúwa, láti Sioni wá,
tí ń gbé Jerusalẹmu.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Orin ìyìn kan
26 Ní ọjọ́ náà ni a ó kọ orin yìí ní ilẹ̀ Juda:
Àwa ní ìlú alágbára kan,
Ọlọ́run fi ìgbàlà ṣe
ògiri àti ààbò rẹ̀.
2 Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn
kí àwọn olódodo orílẹ̀-èdè kí ó lè wọlé,
orílẹ̀-èdè tí ó pa ìgbàgbọ́ mọ́.
3 Ìwọ yóò pa á mọ́ ní àlàáfíà pípé
ọkàn ẹni tí ó dúró ṣinṣin,
nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
4 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa títí láé,
nítorí Olúwa, Olúwa ni àpáta
ayérayé náà.
5 Ó sọ àwọn tí ó ń gbé ní òkè di onírẹ̀lẹ̀
ó rẹ ìlú agbéraga náà nílẹ̀;
ó sọ ọ́ di ilẹ̀ pẹrẹsẹ
ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.
6 Ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀
ẹsẹ̀ aninilára n nì,
ipasẹ̀ àwọn òtòṣì.
7 Ipa ọ̀nà àwọn olódodo tẹ́jú
Ìwọ tó dúró ṣinṣin, ìwọ mú ọ̀nà
àwọn olódodo ṣe geere.
8 Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, rírìn ní ọ̀nà òfin rẹ
àwa dúró dè ọ́;
orúkọ rẹ àti òkìkí rẹ
àwọn ni ohun tí ọkàn wa ń fẹ́.
9 Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru;
ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ.
Nígbà tí ìdájọ́ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayé
àwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo.
10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi oore-ọ̀fẹ́ hàn sí àwọn ìkà
wọn kò kọ́ láti sọ òdodo;
kódà ní ilẹ̀ àwọn tí ó dúró ṣinṣin wọ́n
tẹ̀síwájú láti máa ṣe ibi
wọn kò sì ka ọláńlá Olúwa sí.
11 Olúwa, ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè
ṣùgbọ́n àwọn kò rí i.
Jẹ́ kí wọ́n rí ìtara rẹ fún àwọn ènìyàn rẹ
kí ojú kí ó tì wọ́n;
jẹ́ kí iná tí a fi pamọ́ fún àwọn
ọ̀tá rẹ jó wọn run.
12 Olúwa, ìwọ fi àlàáfíà lélẹ̀ fún wa;
ohun gbogbo tí a ti ṣe yọrí ìwọ ni
ó ṣe é fún wa.
13 Olúwa Ọlọ́run wa, àwọn olúwa mìíràn
lẹ́yìn rẹ ti jẹ ọba lé wa lórí,
ṣùgbọ́n orúkọ rẹ nìkan ni àwa fi ọ̀wọ̀ fún.
14 Wọ́n ti kú báyìí, wọn ò sí láààyè mọ́;
gbogbo ẹ̀mí tí ó ti kọjá lọ wọ̀nyí kò le dìde mọ́.
Ìwọ jẹ́ wọ́n ní ìyà o sì sọ wọ́n di asán,
Ìwọ pa gbogbo ìrántí wọn rẹ́ pátápátá.
15 Ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè gbòòrò, Olúwa;
ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè bí sí i.
Ìwọ ti gba ògo fún ara rẹ;
ìwọ ti sún gbogbo àwọn ààlà ilẹ̀ sẹ́yìn.
Ìgbéyàwó ní àjíǹde
18 (A)Àwọn Sadusi tún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn wọ̀nyí kò gbàgbọ́ pé àjíǹde ń bẹ. Ìbéèrè wọn ni pé, 19 (B)“Olùkọ́, Mose fún wa ní òfin pé: Nígbà tí ọkùnrin kan bá kú láìbí ọmọ, arákùnrin rẹ̀ gbọdọ̀ ṣú ìyàwó náà lópó kí wọn sì bímọ ní orúkọ ọkọ tí ó kú náà. 20 Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan wà, èyí tí ó dàgbà jùlọ gbéyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ. 21 Arákùnrin rẹ̀ kejì ṣú obìnrin tí ó fi sílẹ̀ lópó, láìpẹ́, òun pẹ̀lú tún kú láìbímọ. Arákùnrin kẹta tó ṣú obìnrin yìí lópó tún kú bákan náà láìbímọ. 22 Àwọn méjèèje sì ṣú u lópó, wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀. Ní ìkẹyìn gbogbo wọn, obìnrin náà kú pẹ̀lú. 23 Ǹjẹ́ ní àjíǹde, nígbà tí wọ́n bá jíǹde, aya ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Àwọn méjèèje ni ó sá ni ní aya?”
24 Jesu dáhùn ó wí fún wọn pé, “Kì í há ṣe nítorí èyí ni ẹ ṣe ṣìnà, pé ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́, tàbí agbára Ọlọ́run. 25 Nítorí pé, nígbà tí àwọn arákùnrin méje yìí àti obìnrin náà bá jí dìde nínú òkú, a kò ní ṣe ìgbéyàwó fún wọn. Wọn yóò dàbí àwọn angẹli tí ń bẹ ní ọ̀run. 26 (C)Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa bóyá àjíǹde yóò wà. Àbí ẹ̀yin kò ì tí ka ìwé Eksodu, nípa Mose àti pápá tí ń jó? Ọlọ́run sọ fún Mose pé, ‘Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu.’ 27 Òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú bí kò ṣe Ọlọ́run àwọn alààyè: nítorí ẹ̀yin ṣe àṣìṣe gidigidi.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.