Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
25 Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìyìn mi yóò ti wá nínú àjọ ńlá;
ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù rẹ̀
26 tálákà yóò jẹ yóò sì yó;
àwọn tí n wá Olúwa yóò yin
jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ wà láààyè títí ayérayé!
27 Gbogbo òpin ayé ni yóò rántí
wọn yóò sì yípadà sí Olúwa,
àti gbogbo ìdílé orílẹ̀-èdè
ni wọn yóò jọ́sìn níwájú rẹ̀,
28 Nítorí ìjọba ni ti Olúwa.
Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè.
29 Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn olówó ayé wọn yóò ṣe àsè, wọn yóò sì sìn;
gbogbo àwọn tí ó wọ inú ilẹ̀ lọ yóò kúnlẹ̀ ní iwájú rẹ̀
àti ẹni tí kò lè pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ ni ààyè.
30 Irú-ọmọ rẹ̀ yóò sìn ín;
a ó sọ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ nípa Olúwa,
31 Wọn yóò polongo òdodo rẹ̀
sí àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí,
wí pé, òun ni ó ṣe èyí.
Agbọ̀n èso pípọ́n
8 Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè fihàn mi: agbọ̀n èso pípọ́n. 2 Ó béèrè pé, “Amosi kí ni ìwọ rí.”
Mo sì dáhùn pé, “Agbọ̀n èso pípọ́n.”
Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, “Àsìkò náà pọ́n tó fún àwọn ènìyàn mi Israẹli; Èmi kì yóò dá wọn sí mọ́.”
3 Olúwa Olódùmarè wí pé, “Ní ọjọ́ náà, àwọn orin tẹmpili yóò yí padà sí ohùn réré ẹkún. Ọ̀pọ̀, àní ọ̀pọ̀ ara òkú ni yóò wà ni ibi gbogbo! Àní ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́!”
4 Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ń tẹ aláìní lórí ba,
tí ẹ sì ń sọ tálákà di ilẹ̀.
5 Tí ẹ ń wí pé,
“Nígbà wo ni oṣù tuntun yóò parí
kí àwa bá à lè ta ọkà
kí ọjọ́ ìsinmi kí ó lè dópin
kí àwa bá à le ta jéró?”
Kí a sì dín ìwọ̀n wa kù
kí a gbéraga lórí iye tí a ó tà á
kí a sì fi òṣùwọ̀n èké yàn wọ́n jẹ
6 Kí àwa lè fi fàdákà ra àwọn tálákà
kí a sì fi bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì ra aláìní
kí a sì ta jéró tí a kó mọ́ ilẹ̀.
7 Olúwa ti fi ìgbéraga Jakọbu búra pé: “Èmi kì yóò gbàgbé ọ̀kan nínú ohun tí wọ́n ṣe.
8 (A)Saulu sì wà níbẹ̀, ó sì fi àṣẹ sí ikú rẹ̀.
Wọ́n ṣe inúnibíni sí ìjọ, wọ́n sì túká
Ní àkókò náà, inúnibíni ńlá kan dìde sí ìjọ tí ó wà ni Jerusalẹmu, gbogbo wọn sì túká káàkiri agbègbè Judea àti Samaria, àyàfi àwọn aposteli. 2 Àwọn ènìyàn olùfọkànsìn kan sì gbé òkú Stefanu lọ sin, wọ́n sì pohùnréré ẹkún kíkan sórí rẹ̀. 3 Ṣùgbọ́n Saulu bẹ̀rẹ̀ sí da ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rú. Ó ń wọ ilé dé ilé, ó sì ń mú àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ó sì ń fi wọn sínú túbú.
Filipi ní Samaria
4 Àwọn tí wọ́n sì túká lọ sí ibi gbogbo ń wàásù ọ̀rọ̀ náà. 5 Filipi sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú Samaria, ó ń wàásù Kristi fún wọn. 6 Nígbà tí ìjọ àwọn ènìyàn gbọ́, tí wọn sì rí iṣẹ́ ààmì tí Filipi ń ṣe, gbogbo wọn sì fi ọkàn kan fiyèsí ohun tí ó ń sọ. 7 Nítorí tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ń kígbe sókè bí wọ́n ti ń jáde kúrò lára àwọn ènìyàn, ọ̀pọ̀ àwọn arọ àti amúnkùn ún ni ó sì gba ìmúláradá. 8 Ayọ̀ púpọ̀ sì wà ni ìlú náà.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.