Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 22:25-31

25 Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìyìn mi yóò ti wá nínú àjọ ńlá;
    ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù rẹ̀
26 tálákà yóò jẹ yóò sì yó;
    àwọn tí n wá Olúwa yóò yin
    jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ wà láààyè títí ayérayé!

27 Gbogbo òpin ayé ni yóò rántí
    wọn yóò sì yípadà sí Olúwa,
àti gbogbo ìdílé orílẹ̀-èdè
    ni wọn yóò jọ́sìn níwájú rẹ̀,
28 Nítorí ìjọba ni ti Olúwa.
    Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè.

29 Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn olówó ayé wọn yóò ṣe àsè, wọn yóò sì sìn;
    gbogbo àwọn tí ó wọ inú ilẹ̀ lọ yóò kúnlẹ̀ ní iwájú rẹ̀
    àti ẹni tí kò lè pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ ni ààyè.
30 Irú-ọmọ rẹ̀ yóò sìn ín;
    a ó sọ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ nípa Olúwa,
31 Wọn yóò polongo òdodo rẹ̀
    sí àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí,
    wí pé, òun ni ó ṣe èyí.

Amosi 9:7-15

“Àbá ẹ̀yin ọmọ Israẹli
    kò ha dàbí àwọn ọmọ Kuṣi sí mi?”
    ni Olúwa wí.
“Èmi kò ha ti mú Israẹli gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá
    àti àwọn Filistini láti ilẹ̀ Kafitori
    àti àwọn ará Aramu láti Kiri?

“Dájúdájú, ojú Olúwa Olódùmarè
    ń bẹ̀ lára ilẹ̀ ọba tó kún fún ẹ̀ṣẹ̀.
Èmi yóò pa á run kúrò lórí ilẹ̀
    Síbẹ̀ Èmi kò nípa ilé Jakọbu run pátápátá,”
    ni Olúwa wí.
“Nítorí Èmi yóò pàṣẹ,
    Èmi yóò sì mi ilé Israẹli
    ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè
bí a ti ń jọ nǹkan nínú ajọ̀
    tí hóró kín ń kín kì yóò bọ́ sórí ilẹ̀.
10 Gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn mi
    ni yóò ti ipa idà kú
gbogbo àwọn ti ń wí pé,
    ‘Aburú kì yóò lé wa bá, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ká wa mọ́.’

Ìmúpadàbọ̀ Israẹli

11 (A)“Ní ọjọ́ náà ní
    Èmi yóò gbé àgọ́ Dafidi tí ó wó ró,
Èmi yóò dí odi rẹ̀ tí ó ya,
    Èmi yóò sì gbé ahoro rẹ̀ sókè,
    Èmi yóò sì kọ bí ti ọjọ́ ìgbàanì,
12 kí wọn le jogún ìyókù Edomu
    àti gbogbo àwọn kèfèrí, ti a ń pè nípa orúkọ mi,”
    ni Olúwa, ẹni tí yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí wí.

13 (B)“Ọjọ́ náà ń bọ,” ni Olúwa wí,

“tí ẹni tí ń tulẹ̀ yóò lé ẹni tí ń kórè bá
    Tí ẹni tí ń fún èso àjàrà yóò lé ẹni tí ń gbìn bá
Àwọn òkè ńlá yóò sì kán ọtí wáìnì sílẹ̀
    Tí yóò sì sàn láti ara àwọn òkè kéékèèkéé.
14     Èmi yóò si tún mú ìgbèkùn Israẹli ènìyàn mi padà bọ̀.

“Wọn yóò sì kọ́ ahoro ìlú, wọn yóò sì máa gbé inú wọn
    Wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì mu ọtí wáìnì wọn
    wọn yóò sì ṣe ọgbà pẹ̀lú, wọn yóò sì jẹ èso inú wọn
15 Èmi yóò gbin Israẹli sí orí ilẹ̀ rẹ̀.
    A kì yóò sì fà wọn tu mọ́ láéláé
    kúrò ni orí ilẹ̀ ti mo fi fún wọn,”

ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wí.

Marku 4:30-32

Òwe musitadi

30 (A)Jesu sì tún wí pé, “Kí ni kí èmi fi ìjọba Ọlọ́run wé? Òwe wo ni kí èmi fi ṣe àkàwé rẹ̀? 31 Ó dàbí èso hóró musitadi kan, lóòótọ́, ó jọ ọ̀kan nínú àwọn èso tí ó kéré jùlọ ti a gbìn sínú ilẹ̀. 32 Síbẹ̀, nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbàsókè, ó gbilẹ̀, ó sì di títóbi ju gbogbo ewéko inú ọgbà yòókù lọ. Ó sì yọ ẹ̀ka ńlá níbi tí àwọn ẹyẹ ọ̀run lè kọ́ ìtẹ́ wọn sí, kí wọn sì rí ìdáàbòbò.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.