Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì ti Májẹ̀mú.” Ti Safu. Saamu.
80 Gbọ́ tiwa, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn Israẹli;
ìwọ tí ó darí Josẹfu bí ọ̀wọ́ ẹran;
ìwọ tí o jókòó lórí ìtẹ́ láàrín Kérúbù, tàn jáde
2 Níwájú Efraimu, Benjamini àti Manase.
Ru agbára rẹ̀ sókè;
wá fún ìgbàlà wa.
3 Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run;
jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,
kí a bá à lè gbà wá là.
4 Olúwa Ọlọ́run alágbára,
ìbínú rẹ̀ yóò ti pẹ́ tó
sí àdúrà àwọn ènìyàn rẹ?
5 Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọn
ìwọ ti mú wọn wa ẹkún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́
6 Ìwọ sọ wá di ẹlẹ́yà fún àwọn aládùúgbò wa,
àwọn ọ̀tá wa sì ń yọ̀ wá.
7 Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run alágbára;
jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa,
kí a ba à lè gbà wá là.
8 Ìwọ mú àjàrà jáde láti Ejibiti;
ìwọ lé àwọn kèfèrí jáde, o sì gbìn ín.
9 Ìwọ ṣí ààyè sílẹ̀ fún un,
ìwọ sì mu ta gbòǹgbò jinlẹ̀
ó sì kún ilẹ̀ náà.
10 A bò àwọn òkè mọ́lẹ̀ òkè pẹ̀lú òjìji rẹ̀,
ẹ̀ka rẹ̀ dàbí kedari Ọlọ́run.
11 O yọ ẹ̀ka rẹ̀ sínú Òkun,
ọwọ́ rẹ̀ sí odò ńlá nì.
12 Èéṣe tí ìwọ fi wó odi rẹ̀
tí àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá fi ń ṣa èso rẹ̀?
13 Ìmàdò láti inú igbó ń bá a jẹ́
àti ẹranko igbó ń jẹ ẹ́ run.
14 Yípadà sí wa, àwa ń bẹ̀ ọ́, Ọlọ́run alágbára!
Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì wò ó!
Kí o sì bẹ àjàrà yìí wò,
15 Gbòǹgbò èyí tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ti gbìn,
àti ẹ̀ka tí ìwọ ti mú lágbára fún ara rẹ.
16 A gé àjàrà rẹ lulẹ̀, a ti fi iná sun ún;
ní ìfibú, àwọn ènìyàn rẹ̀ ń ṣègbé.
17 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára ọkùnrin tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,
ọmọ ènìyàn tí ìwọ tí gbé kalẹ̀ fún ara rẹ.
18 Nígbà náà àwa kí yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ;
mú wa yè, àwa o sì máa pe orúkọ rẹ.
19 Tún wa yípadà, Olúwa Ọlọ́run alágbára;
kí ojú rẹ̀ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,
kí á ba à lè gbà wá là.
Orin ọgbà àjàrà náà
5 (A)Èmi yóò kọrin fún ẹni tí mo fẹ́ràn
orin kan nípa ọgbà àjàrà rẹ̀;
Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kan
ní ẹ̀gbẹ́ òkè ẹlẹ́tù lójú.
2 Ó tu ilẹ̀ rẹ̀, ó ṣa òkúta ibẹ̀ kúrò
ó sì gbin àyànfẹ́ àjàrà sí i.
Ó kọ́ ilé ìṣọ́ sí inú rẹ̀
ó sì ṣe ìfúntí kan síbẹ̀ pẹ̀lú.
Lẹ́yìn náà, ó ń retí èso àjàrà dáradára,
ṣùgbọ́n èso búburú ni ó ti ibẹ̀ wá.
3 “Ní ìsinsin yìí ẹ̀yin olùgbé Jerusalẹmu
àti ẹ̀yin ènìyàn Juda
ẹ ṣe ìdájọ́ láàrín èmi àti
ọgbà àjàrà mi.
4 Kín ni ó kù tí n ò bá túnṣe sí ọgbà àjàrà mi.
Ju èyí tí mo ti ṣe lọ?
Nígbà tí mo ń wá èso dáradára,
èéṣe tí ó fi so kíkan?
5 Ní ìsinsin yìí, èmi yóò wí fún ọ
ohun tí n ó ṣe sí ọgbà àjàrà mi:
Èmi yóò gé igi inú rẹ̀ kúrò,
a ó sì pa á run,
Èmi yóò wó ògiri rẹ̀ lulẹ̀
yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.
6 Èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro
láì kọ ọ́ láì ro ó,
ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún ni yóò hù níbẹ̀.
Èmi yóò sì pàṣẹ fún kurukuru
láti má ṣe rọ̀jò sórí i rẹ̀.”
7 Ọgbà àjàrà Olúwa àwọn ọmọ-ogun
ni ilé Israẹli
àwọn ọkùnrin Juda
sì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀.
Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọ́n, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni ó rí,
Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ́ ẹkún ìpayínkeke.
Ìyè nípa ti ẹ̀mí
16 Ǹjẹ́ mo ní, Ẹ máa rìn nípa ti Ẹ̀mí, ẹ̀yin kì yóò sì mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara ṣẹ. 17 (A)Nítorí ti ara ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lòdì sí Ẹ̀mí, àti Ẹ̀mí lòdì sí ara: àwọn wọ̀nyí sì lòdì sí ara wọn; kí ẹ má ba à lè ṣe ohun tí ẹ̀yin ń fẹ́. 18 Ṣùgbọ́n bí a bá ń ti ọwọ́ Ẹ̀mí ṣamọ̀nà yín, ẹ̀yin kò sí lábẹ́ òfin.
19 (B)Ǹjẹ́ àwọn iṣẹ́ tí ara farahàn, tí í ṣe wọ̀nyí; panṣágà, àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà, 20 Ìbọ̀rìṣà, oṣó, ìkórìíra, ìjà, ìlara, ìbínú, ìmọtaraẹni nìkan, ìyapa, ẹ̀kọ́ òdì. 21 Àrankàn, ìpànìyàn, ìmutípara, ìréde òru, àti irú ìwọ̀nyí; àwọn ohun tí mo ń wí fún yín tẹ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún yín tẹ́lẹ̀ rí pé, àwọn tí ń ṣe nǹkan báwọ̀nyí kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.
22 Ṣùgbọ́n èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwà pẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́, 23 ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni níjanu: òfin kan kò lòdì sí irú wọ̀nyí, 24 Àwọn tí í ṣe ti Kristi Jesu ti kan ara wọn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀. 25 Bí àwa bá wà láààyè sípa ti Ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí a sì máa rìn nípa ti Ẹ̀mí. 26 Ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa ṣe ògo asán, kí a má mú ọmọnìkejì wa bínú, kí a má ṣe ìlara ọmọnìkejì wa.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.