Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
150 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ rẹ̀
Ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run rẹ̀.
2 Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára rẹ̀.
Ẹ yìn ín fún títóbi rẹ̀ tí ó tayọ̀.
3 Ẹ fi ohùn ìpè yìn ín.
Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín.
4 Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín
fi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín
5 Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè,
Ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro.
6 Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin Olúwa.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ìmúpadà sípò Israẹli
30 Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, wí pé: 2 “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí, pé: ‘Ìwọ kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti bá ọ sọ sínú ìwé kan. 3 Ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí ń ó mú àwọn ènìyàn mi, àwọn ọmọ Israẹli àti Juda kúrò nínú ìgbèkùn, tí n ó sì dá wọn padà sí orí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá wọn láti ní,’ ni Olúwa Ọlọ́run wí.”
4 Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run sí Israẹli àti Juda: 5 “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“ ‘Igbe ẹ̀rù àti ìwárìrì ni a gbọ́
láìṣe igbe àlàáfíà.
6 Béèrè kí o sì rí:
Ǹjẹ́ ọkùnrin le dá ọmọ bí?
Èéṣe tí mo fi ń rí àwọn alágbára ọkùnrin
tí wọ́n fi ọwọ́ wọn mú inú wọn bí obìnrin tó ń rọbí,
tí ojú gbogbo wọ́n sì fàro fún ìrora?
7 Ọjọ́ náà yóò ha ti burú tó!
Kò sí ọjọ́ tí yóò dàbí rẹ̀,
Ọjọ́ náà yóò jẹ́ àkókò ìdààmú fún Jakọbu
ṣùgbọ́n yóò rí ìgbàlà kúrò nínú ìdààmú náà.
8 “ ‘Ní ọjọ́ náà,’ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé;
‘Èmi yóò gbé àjàgà kúrò lọ́rùn wọn,
Èmi yóò sì tú ìdè wọn sọnù.
Àwọn àjèjì kì yóò sì mú ọ sìn wọ́n mọ́
9 Dípò bẹ́ẹ̀ wọn yóò máa sin Olúwa Ọlọ́run wọn
àti Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba wọn,
ẹni tí èmi yóò gbé dìde fún wọn.
10 “ ‘Nítorí náà, má ṣe bẹ̀rù, Ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi,
má sì ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, Ìwọ Israẹli,’
ni Olúwa wí.
‘Èmi yóò gbà ọ́ kúrò láti ọ̀nà jíjìn wá,
àní àwọn ìran rẹ láti ilẹ̀ àtìpó wọn.
Jakọbu yóò sì tún ní àlàáfíà àti ààbò rẹ̀ padà,
kò sì ṣí ẹni tí yóò ṣẹ̀rù bà á mọ́.
11 Èmi wà pẹ̀lú rẹ, n ó sì gbà ọ́,’
ni Olúwa wí.
‘Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run,
nínú èyí tí mo ti fọ́n ọn yín ká,
síbẹ̀ èmi kì yóò pa yín run pátápátá.
Èmi yóò bá yín wí pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo nìkan;
Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìjìyà.’
10 Nínú èyí ni àwọn ọmọ Ọlọ́run ń farahàn, àti àwọn ọmọ èṣù; ẹnikẹ́ni tí kò ba ń ṣe òdodo, àti ẹni tí kò fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ kì í ṣe ti Ọlọ́run.
Fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ
11 (A)Nítorí èyí ni iṣẹ́ tí ẹ̀yin tí gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé ki àwa fẹ́ràn ara wa. 12 Kì í ṣe bí Kaini, tí í ṣe ẹni búburú, tí o sì pa arákùnrin rẹ̀. Nítorí kín ni ó sì ṣe pa á? Nítorí tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́ búburú ṣùgbọ́n tí arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ òdodo. 13 (B)Kì ẹnu má ṣe yà yín, ẹ̀yin ará mi, bí ayé bá kórìíra yín. 14 (C)Àwa mọ̀ pé àwa tí rékọjá láti inú ikú sínú ìyè, nítorí tí àwa fẹ́ràn àwọn ará. Ẹni tí kò ba ni ìfẹ́, ó ń gbé inú ikú. 15 Ẹnikẹ́ni tí ó ba kórìíra arákùnrin rẹ̀ apànìyàn ni: ẹ̀yin sì mọ́ pé kò sí apànìyàn tí ó ni ìyè àìnípẹ̀kun láti máa gbé inú rẹ̀.
16 (D)Nípa èyí ni àwa mọ ìfẹ́ nítorí tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa: ó sì yẹ kí àwa fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún àwọn ará.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.