Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
98 Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa,
nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu;
ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti apá mímọ́ rẹ̀
o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un
2 Olúwa ti sọ ìgbàlà rẹ̀ di mí mọ̀
o fi òdodo rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè.
3 Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ fún àwọn ará ilé Israẹli;
gbogbo òpin ayé ni ó ti rí
iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa.
4 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé,
ẹ bú sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn
5 Ẹ fi dùùrù kọrin sí Olúwa, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́,
6 Pẹ̀lú ìpè àti fèrè
ẹ hó fún ayọ̀ níwájú Olúwa ọba.
7 Jẹ́ kí Òkun kí ó hó pẹ̀lú gbogbo
ohun tí ó wà nínú rẹ̀,
Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
8 Ẹ jẹ́ kí odo kí ó ṣápẹ́,
ẹ jẹ́ kí òkè kí ó kọrin pẹ̀lú ayọ̀;
9 Ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú Olúwa
Nítorí tí yóò wá ṣèdájọ́ ayé
bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodo
àti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú.
5 (A)Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí
Ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run tí ó sì tẹ́ wọ́n sóde,
tí ó tẹ́ ilẹ̀ ayé àti ohun gbogbo tí ó jáde nínú wọn,
Ẹni tí ó fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní èémí
àti ẹ̀mí fún gbogbo àwọn tí ń rìn nínú rẹ̀:
6 (B)“Èmi, Olúwa, ti pè ọ́ ní òdodo;
Èmi yóò di ọwọ́ rẹ mú.
Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́
láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn
àti ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà
7 (C)láti la àwọn ojú tí ó fọ́,
láti tú àwọn òǹdè kúrò nínú túbú
àti láti tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n
àwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn.
8 “Èmi ni Olúwa; orúkọ mi nìyìí!
Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn
tàbí ìyìn mi fún ère òrìṣà.
9 Kíyèsi i, àwọn nǹkan àtijọ́ ti wáyé,
àti àwọn nǹkan tuntun ni mo ti wí pé;
kí wọn tó hù jáde
mo ti kéde rẹ̀ fún ọ.”
34 Peteru sì ya ẹnu rẹ, ó sì wí pé, “Nítòótọ́ mo wòye pé, Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn. 35 Ṣùgbọ́n ni gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, ti ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo, ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni lọ́dọ̀ rẹ̀. 36 Ẹyin mọ ọrọ̀ tí Ọlọ́run rán sí àwọn ọmọ Israẹli láti kéde ìròyìn ayọ̀ àlàáfíà nípasẹ̀ Jesu Kristi, ẹni ti ṣe Olúwa ohun gbogbo 37 Ẹ̀yin náà mọ ọ̀rọ̀ náà tí a kéde rẹ̀ yíká gbogbo Judea, tí a bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ láti Galili, lẹ́yìn bamitiisi ti Johanu wàásù rẹ̀. 38 Àní Jesu ti Nasareti, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti da Ẹ̀mí Mímọ́ àti agbára le lórí; ẹni tí ó ń kiri ṣe oore, ó ń ṣe ìmúláradá gbogbo àwọn tí èṣù sì ń pọ́n lójú; nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.
39 “Àwa sì ni ẹlẹ́rìí gbogbo ohun tí ó ṣe, ní ilẹ̀ àwọn Júù, àti ni Jerusalẹmu. Ẹni tí wọ́n pa nípa gbígbékọ́ sí orí igi. 40 Òun ni Ọlọ́run jí dìde ni ọjọ́ kẹta ó sì fi i hàn gbangba. 41 Kì í ṣe fún gbogbo ènìyàn ni o ri, bí kò ṣe fún àwa ti a jẹ́ ẹlẹ́rìí ti a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn tẹ̀lé, ti a bá a jẹ, ti a sì bá à mu lẹ́yìn ìgbà ti ó jíǹde kúrò nínú òkú. 42 Ó sì pàṣẹ fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn, àti láti jẹ́rìí pé, òun ni a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn ṣe onídàájọ́ ààyè àti òkú. 43 Òun ni gbogbo àwọn wòlíì jẹ́rìí sì pé, ẹnikẹ́ni ti ó bá gbà á gbọ́ yóò rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà nípa orúkọ rẹ̀.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.