Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
95 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a kọ orin ayọ̀ sí Olúwa
Ẹ jẹ́ kí a kígbe sókè sí àpáta ìgbàlà wa.
2 Ẹ jẹ́ kí a wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
kí a sì pòkìkí rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò
orin àti ìyìn.
3 Nítorí Olúwa Ọlọ́run títóbi ni,
ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.
4 Ní ọwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà,
ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe.
5 Tirẹ̀ ni Òkun, nítorí òun ni ó dá a
àti ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.
6 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a foríbalẹ̀ kí a sìn ín,
Ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú
Olúwa ẹni tí ó dá wa;
7 (A)Nítorí òun ni Ọlọ́run wa
àwa sì ni ènìyàn pápá rẹ̀,
àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ rẹ̀.
Lónìí tí ìwọ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
8 “Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Meriba,
àti bí ẹ ti ṣe ní ọjọ́ náà ní Massa ní aginjù,
9 Nígbà tí àwọn baba yín dán mi wò
tí wọn wádìí mi,
tí wọn sì rí iṣẹ́ mi
10 Fún ogójì ọdún ni èmi fi bínú sí ìran náà;
mo wí pé, ‘Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ọkàn wọn ṣáko lọ
wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’
11 Nítorí náà ni mo kéde ìbúra nínú ìbínú mi
‘Wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi.’ ”
Israẹli yóò dìde
8 Má ṣe yọ̀ mí, ìwọ ọ̀tá mi;
Bí mó bá ṣubú, èmi yóò dìde.
Nígbà tí mo bá jókòó sínú òkùnkùn
Olúwa yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún mi.
9 Nítorí èmi ti dẹ́ṣẹ̀ sí i,
Èmi yóò faradà ìbínú Olúwa,
títí òun yóò ṣe gba ẹjọ́ mi rò,
tí yóò sì ṣe ìdájọ́ mi.
Òun yóò sì mú mi wá sínú ìmọ́lẹ̀;
èmi yóò sì rí òdodo rẹ̀.
10 Nígbà náà ni ọ̀tá mi yóò rí i
ìtìjú yóò sì bo ẹni tí ó wí fún mi pé,
“Níbo ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wà?”
Ojú mi yóò rí ìṣubú rẹ̀;
nísinsin yìí ni yóò di ìtẹ̀mọ́lẹ̀
bí ẹrẹ̀ òpópó.
11 Ọjọ́ tí a ó mọ odi rẹ yóò dé,
ọjọ́ náà ni àṣẹ yóò jìnnà réré.
12 Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ
láti Asiria àti ìlú ńlá Ejibiti
àní láti Ejibiti dé Eufurate
láti Òkun dé Òkun
àti láti òkè ńlá dé òkè ńlá.
13 Ilẹ̀ náà yóò di ahoro fún àwọn olùgbé inú rẹ̀,
nítorí èso ìwà wọn.
Àdúrà àti ìyìn
14 Fi ọ̀pá rẹ bọ́ àwọn ènìyàn, agbo ẹran ìní rẹ,
èyí tí ó ń dágbé nínú igbó
ní àárín Karmeli;
Jẹ́ kí wọn jẹun ní Baṣani àti Gileadi
bí ọjọ́ ìgbàanì.
15 “Bí i ọjọ́ tí ó jáde kúrò ní Ejibiti wá,
ni èmi yóò fi ohun ìyanu hàn án.”
16 Orílẹ̀-èdè yóò rí i, ojú yóò sì tì wọ́n,
nínú gbogbo agbára wọn.
Wọn yóò fi ọwọ́ lé ẹnu wọn,
etí wọn yóò sì di.
17 Wọn yóò lá erùpẹ̀ bí ejò,
wọn yóò sì jáde kúrò nínú ihò wọn bí ekòló.
Wọn yóò bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa,
wọn yóò sì bẹ̀rù nítorí rẹ̀.
18 Ta ni Ọlọ́run bí rẹ̀,
ẹni tí ó dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì,
tí ó sì fojú fo ìrékọjá èyí tókù ìní rẹ̀?
Kì í dúró nínú ìbínú rẹ̀ láéláé
nítorí òun ní inú dídùn sí àánú.
19 Òun yóò tún padà yọ́nú sí wa;
òun yóò tẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́lẹ̀,
yóò sì fa gbogbo àìṣedéédéé wa sínú ibú Òkun.
20 (A)Ìwọ yóò fi òtítọ́ hàn sí Jakọbu
ìwọ yóò sì fi àánú hàn sí Abrahamu,
bí ìwọ ṣe búra fún àwọn baba wa
láti ọjọ́ ìgbàanì.
26 (A)Lẹ́yìn náà wọ́n kọ orin, wọ́n sì gun orí òkè olifi lọ.
Jesu sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Peteru yóò sẹ́ òun
27 (B)Jesu sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ ó sa kúrò lọ́dọ̀ mi, a ti kọ̀wé rẹ pé:
“ ‘Èmi yóò lu olùṣọ́-àgùntàn
àwọn agbo àgùntàn yóò sì fọ́nká.’
28 (C)Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà ti mo ba jíǹde tan, Èmi yóò síwájú yin lọ sí Galili.”
29 Ṣùgbọ́n Peteru dá a lóhùn, ó wí pé, “Bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ sá kúrò lẹ́yìn rẹ, èmi kò ní sá.”
30 (D)Jesu si wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń sọ òótọ́ fún ọ. Kí àkùkọ tó ó kọ lẹ́ẹ̀kejì ní òwúrọ̀ ọ̀la, ìwọ, pàápàá yóò ti sọ lẹ́ẹ̀mẹ́ta wí pe ìwọ kò mọ̀ mí rí.”
31 Ṣùgbọ́n Peteru fa ara ya, ó wí pé, “Bí mo tilẹ̀ ní láti kú pẹ̀lú rẹ̀, èmi kò jẹ́ sọ pé n kò mọ̀ ọ́n rí.” Ìlérí yìí kan náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.