Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Eksodu 25-26

Ọrẹ ẹbọ fún àgọ́

25 (A)Olúwa sì wí fún Mose pé, (B)“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn mú ọrẹ wá fún mi, ìwọ yóò gba ọrẹ náà fún mi ni ọwọ́ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan ti ọkàn rẹ bá fẹ́ láti fi fún mi.

“Wọ̀nyí ni ọrẹ ti ìwọ yóò gbà ni ọwọ́ wọn:

“wúrà, fàdákà àti idẹ;

aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó, ọ̀gbọ̀;

irun ewúrẹ́.

Awọ àgbò tí a rẹ ní pupa àti awọ ewúrẹ́ igbó;

igi kasia;

Òróró olifi fún iná títàn;

òróró olóòórùn dídùn fún ìtasórí àti fún tùràrí olóòórùn dídùn;

àti òkúta óníkìsì àti òkúta olówó iyebíye ti a fi ṣe ọ̀ṣọ́ sí ara ẹ̀wù efodu àti ẹ̀wù ìgbàyà.

“Nígbà náà ni ìwọ yóò jẹ́ kí wọn kọ́ ibi mímọ́ fún mi. Èmi yóò sì máa gbé ní àárín wọn. Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí ti mo fihàn ọ́, nípa àpẹẹrẹ àgọ́, àti àpẹẹrẹ gbogbo ohun èlò inú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó sì ṣe é.

Àpótí ẹ̀rí

10 (C)“Wọn yóò sì fi igi ṣittimu ṣe àpótí, ìgbọ̀nwọ́ méjì ààbọ̀ ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni gíga rẹ̀. 11 Ìwọ ó sì fi ojúlówó wúrà, bò ó ní inú àti ní òde, ìwọ ó sì fi wúrà gbá etí rẹ̀ yíká. 12 Ìwọ ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún. Ìwọ ó sì fi wọ́n sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ẹsẹ̀ rẹ̀, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹgbẹ́ kejì. 13 Ìwọ ó sì fi igi kasia ṣe ọ̀pá mẹ́rin, ìwọ ó sì fi wúrà bò wọ́n. 14 ìwọ ó sì fi ọ̀pá náà bọ òrùka ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan àpótí ẹ̀rí náà láti fi gbé e. 15 Òpó náà yóò wá nínú òrùka lára àpótí ẹ̀rí; a kò ní yọ wọ́n kúrò. 16 Nígbà náà ni ìwọ yóò fi ẹ̀rí ti èmi yóò fi fún ọ sínú àpótí náà.

17 “Ìwọ ó sì fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú; ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ní fífẹ̀. 18 Ìwọ ó sì ṣe kérúbù méjì láti inú wúrà tí a fi òòlù sí igun ìtẹ́ àánú náà. 19 Ìwọ ó ṣe kérúbù kan sí igun kìn-ín-ní àti kérúbù kejì sí igun kejì, kí kérúbù náà jẹ́ irú kan náà ní igun méjèèjì pẹ̀lú ìbòrí wọn. 20 Àwọn kérúbù sì na ìyẹ́ apá wọn sókè, tí wọn yóò sì fi ìyẹ́ apá wọn ṣe ibòòji sí orí ìtẹ́ àánú. Àwọn kérúbù náà yóò kọ ojú sí ara wọn, wọn yóò máa wo ọ̀kánkán ìtẹ́. 21 Gbé ọmọrí orí àpótí ẹ̀rí kí o sì fi ẹ̀rí èyí tí èmí yóò fi fún ọ sínú àpótí ẹ̀rí. 22 Níbẹ̀, ni òkè ìtẹ́, ní àárín kérúbù méjèèjì ti ó wà ni orí àpótí ẹ̀rí ni èmi yóò ti pàdé rẹ, ti èmi yóò sì fún ọ ní àwọn òfin mi fún àwọn ọmọ Israẹli.

Tábìlì

23 (D)“Fi igi kasia kan tábìlì: ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ní gíga. 24 Ìwọ ó sì fi ojúlówó wúrà bò ó, ìwọ ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí i ká. 25 Ìwọ sì ṣe etí kan ní ìbú àtẹ́lẹwọ́ sí i yíká, ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí etí rẹ̀ ká. 26 Ìwọ ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún tábìlì náà, ìwọ ó sì fi òrùka kọ̀ọ̀kan sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. 27 Ní abẹ́ ìgbátí náà ni àwọn òrùka náà yóò wà fún ibi ọ̀pá láti máa fi gbé tábìlì náà. 28 Ìwọ ó sì fi igi kasia ṣe àwọn ọ̀pá, ìwọ ó sì fi wúrà bò wọ́n, láti máa fi wọ́n gbé tábìlì náà. 29 Ìwọ ó sì fi ojúlówó wúrà ṣe àwo àti ṣíbí rẹ̀, kí o sì ṣe àwokòtò àti ago pẹ̀lú fún dída ọrẹ jáde. 30 (E)Gbé àkàrà ìfihàn sí orí tábìlì yìí, kí ó le wà ní iwájú mi ni gbogbo ìgbà.

Ọ̀pá fìtílà

31 (F)“Ìwọ ó sì ojúlówó wúrà, lù ú dáradára, ṣe ọ̀pá fìtílà kan, ìsàlẹ̀ àti apá rẹ̀, kọ́ọ̀bù rẹ̀ ti ó dàbí òdòdó, ìṣọ àti ìtànná rẹ̀ yóò jẹ́ ara kan náà pẹ̀lú rẹ̀. 32 Ẹ̀ka mẹ́fà ni yóò yọ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pá fìtílà: mẹ́ta ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní mẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ kejì. 33 Àwo mẹ́ta ni kí a ṣe bí ìtànná almondi, tí ó ṣọ tí ó sì tanná ni yóò wà ni ẹ̀ka kan, mẹ́ta yóò sì wà ní ẹ̀ka kejì, àti bẹ́ẹ̀ fún àwọn ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí ó jáde lára ọ̀pá fìtílà. 34 Ní ara ọ̀pá fìtílà ni àwo mẹ́rin ti a ṣe gẹ́gẹ́ bí òdòdó almondi ti ó ni ìṣọ àti ìtànná yóò wà. 35 Irúdì kan yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì àkọ́kọ́ tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà, irúdì kejì ó sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kejì, irúdì kẹta yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kẹta: ẹ̀ka mẹ́fà ní àpapọ̀. 36 Irúdì wọn àti ẹ̀ka wọn kí ó rí bákan náà, kí gbogbo rẹ̀ kí ó jẹ́ lílù ojúlówó wúrà.

37 “Nígbà náà ni ìwọ yóò ṣe fìtílà méje. Ìwọ yóò sì gbe ka orí rẹ̀, kí wọn kí ó lè máa ṣe ìmọ́lẹ̀ sí iwájú rẹ̀. 38 Àti alumagaji rẹ̀, àti àwo alimagaji rẹ̀, kí ó jẹ́ kìkì wúrà. 39 Tálẹ́ǹtì kìkì wúrà ni ó fi ṣe é, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò wọ̀nyí. 40 (G)Kíyèsí i, kí ìwọ kí ó ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ wọn, ti a fi hàn ọ́ ni orí òkè.

Àgọ́ náà

26 (H)“Ṣe àgọ́ náà pẹ̀lú aṣọ títa mẹ́wàá, aṣọ ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ àti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, àti ti òdòdó, pẹ̀lú àwọn kérúbù ni kí ó ṣe iṣẹ́ ọlọ́nà sí wọn. Gbogbo aṣọ títa náà ni kí ó jẹ́ ìwọ̀n kan náà: ìgbọ̀nwọ́ méjì-dínlọ́gbọ̀n ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ni fífẹ̀. Aṣọ títa márùn-ún ni kí a so papọ̀ mọ́ ara wọn, àti aṣọ títa márùn-ún ni kí a so papọ̀ mọ́ ara wọn. Ìwọ yóò ṣì ṣe ajábó aṣọ aláró sí aṣọ títa kan láti ìṣẹ́tí rẹ̀ wá níbi ìsopọ̀, àti bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìwọ yóò ṣe ni etí ìkangun aṣọ títa kejì, ni ibi ìsopọ̀ kejì. Àádọ́ta ajábó ní ó pa lára aṣọ títa kan, àti àádọ́ta ajábó ni ó sì lò pa ní etí aṣọ títa tí ó wà ní ìsolù kejì, ajábó náà sì wà ní ọ̀kánkán ara wọn. Ó sì ṣe àádọ́ta ìkọ́ wúrà, ó sì lò ìkọ́ wọ̀n-ọn-nì láti fi aṣọ títa kan kọ́ èkejì, bẹ́ẹ̀ ó sì di odidi àgọ́ kan.

“Ìwọ ó sì ṣe aṣọ títa irun ewúrẹ́ láti fi ṣe ìbò sórí àgọ́ náà—aṣọ títa mọ́kànlá ni ìwọ ó ṣe é. Gbogbo aṣọ títa mọ́kọ̀ọ̀kànlá náà jẹ́ ìwọ̀n kan náà, ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní fífẹ̀. Ìwọ ó so aṣọ títa márùn-ún pọ̀ mọ́ ara wọn se ọ̀kan, ó sì tún so mẹ́fà tókù mọ́ ara wọn se ọ̀kan. Ìwọ ó sì ṣẹ́ aṣọ títa kẹfà po sí méjì níwájú àgọ́ náà. 10 Ìwọ ó sì pa àádọ́ta ajábó sí ìṣẹ́tí ìkangun aṣọ títa ní apá kan, wọ́n sì tún pa ajábó mìíràn sí ìṣẹ́tí ìkangun aṣọ títa ní apá kejì. 11 Nígbà náà ṣe àádọ́ta ìkọ́ idẹ kí o sì kó wọn sínú ọ̀jábó láti fi so àgọ́ náà pọ̀ kí ó lè jẹ́ ọ̀kan. 12 Àti ìyókù tí ó kù nínú aṣọ títa àgọ́ náà, ìdajì aṣọ títa tí ó kù, yóò rọ̀ sórí ẹ̀yìn àgọ́ náà. 13 Aṣọ títa àgọ́ náà yóò jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan gígùn ní ìhà méjèèjì; Èyí tí ó kù yóò rọ̀ sórí ìhà àgọ́ náà láti fi bò ó. 14 Ìwọ ó sì ṣe ìbòrí awọ àgbò tí a rì ní pupa fún àgọ́ náà, kí ó sì ṣe ìbòrí awọ seali sórí rẹ̀.

15 “Ìwọ ó sì ṣe pákó igi kasia tí ó dúró òró fún àgọ́ náà. 16 (I)Kí pákó kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní fífẹ̀. 17 Pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ méjì ni kí ó kọjú sí ara wọn. Ṣe gbogbo àwọn pákó àgọ́ náà bí èyí. 18 Ìwọ ó sì ṣe ogún (20) pákó sí ìhà gúúsù àgọ́ náà, 19 Ìwọ ó sì ṣe ogójì (40) ìhà ìtẹ̀bọ̀ fàdákà kí ó lọ sí ìsàlẹ̀ wọn, méjì fún pákó kọ̀ọ̀kan, ọ̀kan ní ìsàlẹ̀ ìtẹ̀bọ̀ kọ̀ọ̀kan. 20 Àti ìhà kejì, ni ìhà àríwá àgọ́ náà, ṣe ogún pákó síbẹ̀ 21 àti ogójì ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà méjì ní abẹ́ pákó kọ̀ọ̀kan. 22 kí ìwọ kí ó ṣe pákó mẹ́fà sì ìkangun, ní ìkangun ìhà ìwọ̀-oòrùn àgọ́ náà, 23 kí o sì ṣe pákó méjì fún igun ní ìhà ẹ̀yìn. 24 Ní igun méjèèjì yìí, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ méjì láti ìdí dé orí rẹ̀, a ó sì so wọ́n pọ̀ sí òrùka kan: méjèèjì yóò sì rí bákan náà. 25 Wọn ó sì jẹ́ pákó mẹ́jọ, àti ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà mẹ́rìnlélógún, méjì wà ní ìsàlẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan.

26 “Ìwọ ó sì ṣe ọ̀pá ìdábùú igi kasia; márùn-ún fún pákó ìhà kan àgọ́ náà, 27 Márùn-ún fún àwọn ìhà kejì, àti márùn-ún fún pákó ni ìhà ìwọ̀-oòrùn ní ìhà ẹ̀yìn àgọ́ náà. 28 Ọ̀pá ìdábùú àárín ni agbede-méjì gbọdọ̀ tàn láti ìkangun dé ìkangun pákó náà. 29 Ìwọ́ ó sì bo àwọn pákó náà pẹ̀lú wúrà, kí o sì ṣe òrùka wúrà kí ó lè di ọ̀pá ìdábùú mu. Kí o sì tún bo ọ̀pá ìdábùú náà pẹ̀lú wúrà.

30 “Gbé àgọ́ náà ró gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a fihàn ọ́ lórí òkè.

31 (J)“Ìwọ ó sì ṣe aṣọ ìgélé aláró, àti elése àlùkò, àti òdòdó, àti ọ̀gbọ̀ olókùn wẹ́wẹ́ tí í ṣe ọlọ́nà, tí òun ti àwọn kérúbù ni kí á ṣe é. 32 Ìwọ yóò sì fi rọ̀ sára òpó tí ó di igi kasia mẹ́rin ró tí a fi wúrà bò, tí ó dúró lórí ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́rin mẹ́rin. 33 Ṣo aṣọ títa náà sí ìsàlẹ̀ àwọn ìkọ́, kí o sì gbé àpótí ẹ̀rí sí ẹ̀gbẹ́ aṣọ títa náà. Aṣọ títa náà yóò pínyà ibi mímọ́ kúrò ní ibi mímọ́ tí ó ga jùlọ. 34 Fi ìtẹ́ àánú bo àpótí ẹ̀rí náà ni ibi mímọ́ tí ó ga jùlọ. 35 Gbé tábìlì náà sí ìta aṣọ títa náà sí ìhà gúúsù àgọ́ náà, kí o sì gbé ọ̀pá fìtílà sí òdìkejì rẹ̀ ní ìhà àríwá.

36 “Fún ti ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà, ìwọ yóò ṣe aṣọ títa aláró, elése àlùkò, ti òdódó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe. 37 Ìwọ ó sì ṣe ìkọ́ wúrà fún aṣọ títa yìí, àti òpó igi ṣittimu márùn-ún tí a sì fi wúrà bò. Kí o sì dà ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ márùn-ún fún wọn.

Matiu 20:17-34

Jesu tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀

17 (A)Bí Jesu ti ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí apá kan ó sì wí pé, 18 “Wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Ó sọ fún wọn pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin lọ́wọ́, wọn yóò sì dá mi lẹ́bi ikú. 19 Wọn yóò sì fà á lé àwọn kèfèrí lọ́wọ́ láti fi ṣe ẹlẹ́yà àti láti nàa án, àti láti kàn mi mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta, yóò jí dìde.”

Ẹ̀bẹ̀ ìyá

20 (B)(C) Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọ Sebede bá àwọn ọmọ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jesu, ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, o béèrè fún ojúrere rẹ̀.

21 (D)Jesu béèrè pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”

Ó sì dáhùn pé, “Jẹ́ kí àwọn ọmọ mi méjèèjì jókòó ní apá ọ̀tún àti apá òsì lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ?”

22 (E)Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn ó sì wí pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohun tí ẹ̀yin ń béèrè, ẹ̀yin ha le mu nínú ago tí èmi ó mu?”

Wọ́n dáhùn pé, “Àwa lè mu ún.”

23 (F)Jesu sì wí fún wọn pé, “Dájúdájú, ẹ̀yin yóò mu nínú ago mi, ṣùgbọ́n èmi kò ní àṣẹ láti sọ irú ènìyàn tí yóò jókòó ní apá ọ̀tún tàbí apá òsì. Baba mi ti pèsè ààyè wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀ fún kìkì àwọn tí ó yàn.”

24 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá ìyókù sì gbọ́ èyí, wọ́n bínú sí àwọn arákùnrin méjì yìí. 25 (G)Ṣùgbọ́n Jesu pé wọ́n papọ̀, ó wí pé, “Dájúdájú, ẹ̀yin mọ̀ pé àwọn ọba aláìkọlà a máa lo agbára lórí wọn, àwọn ẹni ńlá láàrín wọn a sì máa fi ọlá tẹrí àwọn tí ó wà lábẹ́ wọn ba. 26 Ṣùgbọ́n èyí yàtọ̀ láàrín yín. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹni tí ó bá ń fẹ́ ṣe olórí láàrín yín, ní láti ṣe bí ìránṣẹ́ fún yín ni, 27 Àti ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe olórí nínú yín, ẹ jẹ́ kí ó máa ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ yin. 28 Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ènìyàn kò ṣe wá sí ayé, kí ẹ lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, ṣùgbọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún yín, àti láti fi ẹ̀mí rẹ ṣe ìràpadà ọ̀pọ̀ ènìyàn.”

Afọ́jú méjì ríran

29 (H)Bí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń fi ìlú Jeriko sílẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì wọ́ tẹ̀lé e lẹ́yìn. 30 Àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì sì jókòó lẹ́bàá ọ̀nà, nígbà tí wọ́n sí gbọ́ pé Jesu ń kọjá lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé, “Olúwa, Ọmọ Dafidi, ṣàánú fún wa!”

31 Àwọn ènìyàn sí bá wọn wí pé kí wọn dákẹ́, ṣùgbọ́n wọ́n kígbe sókè sí i. “Olúwa, ọmọ Dafidi, ṣàánú fún wa!”

32 Jesu dúró lójú ọ̀nà, ó sì pè wọ́n, Ó béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin fẹ́ kí èmi ṣe fún yín?”

33 Wọ́n dáhùn pé, “Olúwa, àwa fẹ́ kí a ríran.”

34 Àánú wọn sì ṣe Jesu, ó fi ọwọ́ kan ojú wọn. Lójúkan náà, wọ́n sì ríran, wọ́n sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.