Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Gẹnẹsisi 39-40

Josẹfu àti aya Potiferi

39 (A)Nígbà tí wọ́n mú Josẹfu dé Ejibiti, Potiferi, ará Ejibiti tí i ṣe ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè Farao. Òun ni olórí àwọn ọmọ-ogun Farao. Ó ra Josẹfu lọ́wọ́ àwọn ará Iṣmaeli tí wọ́n mú un lọ síbẹ̀.

Olúwa sì wà pẹ̀lú Josẹfu, ó sì bùkún un, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀gá rẹ̀ ará Ejibiti. Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ rí i pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀, àti pé Olúwa jẹ́ kí ó máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ rẹ̀ lé. Josẹfu sì rí ojúrere Potiferi, ó sì di aṣojú rẹ̀, Potiferi fi Josẹfu ṣe olórí ilé rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní. Láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu jẹ olórí ilé rẹ̀ àti ohun ìní rẹ̀ gbogbo, ni Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bùkún àwọn ará Ejibiti nítorí Josẹfu. Ìbùkún Olúwa wà lórí gbogbo ohun tí Potiferi ní, nílé àti lóko. Ó sì fi Josẹfu ṣe àkóso gbogbo ohun tí ó ní. Kò sì ṣe ìyọnu lórí ohunkóhun mọ àyàfi nípa oúnjẹ tí ó ń jẹ láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu ṣe àkóso ilé e rẹ̀.

Josẹfu sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin ní ìdúró àti ìrísí rẹ̀, lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya rẹ̀ ṣe àkíyèsí Josẹfu, ó sì wí fún un pé, “Wá bá mi lòpọ̀!”

Ṣùgbọ́n Josẹfu kọ̀, ó sì wí fún aya ọ̀gá rẹ̀ pé, “Kíyèsi, Olúwa mi kò fi ohunkóhun dù mi nínú ilé yìí, gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó fi lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó jù mi lọ nínú ilé yìí, ọ̀gá mi kò fi ohunkóhun dù mi àyàfi ìwọ, tí í ṣe aya rẹ̀. Báwo ni mo ṣe lè ṣe ohun búburú yìí, kí ń sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run?” 10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni ó ń tẹnumọ́ èyí fún Josẹfu, Josẹfu kọ̀ láti bá a lòpọ̀. Ó tilẹ̀ kọ̀ láti máa dúró ni ibi tí ó bá wà.

11 Ní ọjọ́ kan, Josẹfu lọ sínú ilé láti ṣe iṣẹ́, kò sì sí èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ ní tòsí. 12 Ó sì di aṣọ Josẹfu mú, ó sì wí pé, “Wá bá mi lòpọ̀!” Ṣùgbọ́n Josẹfu fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí i lọ́wọ́, ó sì sá jáde.

13 Nígbà tí ó rí i pé ó ti fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, ó sì ti sá jáde, 14 ó pe àwọn ìránṣẹ́ ilé náà, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkọ ọ̀ mi mú Heberu kan wọlé tọ̀ wá wá láti fi wá ṣe ẹlẹ́yà. Ó wọlé tọ̀ mí wá, láti bá mi lòpọ̀, ṣùgbọ́n mo kígbe. 15 Nígbà tí ó gbọ́ pé mo gbé ohùn mi sókè, tí mo sì kígbe, ó jọ̀wọ́ aṣọ rẹ̀ sọ́dọ̀ mi, ó sì sá, ó bọ́ sóde.”

16 Ó sì fi aṣọ náà sọ́dọ̀ títí tí ọkọ rẹ̀ fi dé. 17 Ó rò fún un pé, “Ẹrú ará Heberu tí o rà wá ilé láti fi wá ṣẹlẹ́yà wá láti bá mi lòpọ̀. 18 Ṣùgbọ́n bí mo ti kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ó sì sá kúrò nínú ilé.”

19 Nígbà tí Potiferi gbọ́ ọ̀rọ̀ aya rẹ̀ pé báyìí ni ẹrú rẹ̀ ṣe sí aya rẹ̀, ó bínú gidigidi. 20 Ó sì ju Josẹfu sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí a ń ju àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba sí.

Ṣùgbọ́n, nígbà tí Josẹfu wà nínú ẹ̀wọ̀n níbẹ̀, 21 (B)Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ṣàánú fún un, ó sì mú kí ó rí ojúrere àwọn alábojútó ọgbà ẹ̀wọ̀n (wọ́dà). 22 Nítorí náà, alábojútó ọgbà ẹlẹ́wọ̀n fi Josẹfu ṣe alákòóso ohun gbogbo tí ó wà nínú ẹ̀wọ̀n, àti ohun tí wọn ń ṣe níbẹ̀. 23 Wọ́dà náà kò sì mikàn nípa gbogbo ohun tí ó fi sí abẹ́ àkóso Josẹfu, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú Josẹfu, ó sì ń jẹ́ kí ó ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́lé.

Agbọ́tí àti alásè

40 Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí, ni agbọ́tí ọba àti alásè rẹ̀ ṣẹ̀ ọba Ejibiti, olúwa wọn. Farao sì bínú sí méjì nínú àwọn ìjòyè rẹ̀, olórí agbọ́tí àti olórí alásè, Ó sì fi wọ́n sí ìhámọ́ ní ilé olórí ẹ̀ṣọ́, ní inú ẹ̀wọ̀n ibi tí Josẹfu pẹ̀lú wà. Olórí ẹ̀ṣọ́ sì yan Josẹfu láti máa ṣe ìránṣẹ́ wọn.

Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wà ní ìhámọ́ fún ìgbà díẹ̀. Ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọkùnrin méjèèjì náà—olórí agbọ́tí àti olórí alásè ọba Ejibiti, tí a dè sínú túbú, lá àlá ní òru kan náà, àlá kọ̀ọ̀kan sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀.

Nígbà tí Josẹfu dé ọ̀dọ̀ wọn ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó ṣe àkíyèsí pé, inú wọn kò dùn. Ó sì bi àwọn ìjòyè Farao tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìhámọ́, nínú ilé olúwa rẹ̀ léèrè pé, “Èéṣe tí ojú yín fi fàro bẹ́ẹ̀ ní òní, tí inú yín kò sì dùn?”

Wọ́n wí pé, “Àwa méjèèjì ni a lá àlá, kò sì sí ẹni tí yóò túmọ̀ rẹ̀.”

Josẹfu sì wí fún wọn pé, “Ọlọ́run nìkan ni ó ni ìtumọ̀. Ẹ sọ àwọn àlá yín fún mi.”

Olórí agbọ́tí sì ṣọ́ àlá rẹ̀ fún Josẹfu, wí pé, “Ní ojú àlá mi, mo rí àjàrà kan (tí wọn ń fi èso rẹ̀ ṣe wáìnì) níwájú mi, 10 Mo sì rí ẹ̀ka mẹ́ta lórí àjàrà náà, ó yọ ẹ̀ka tuntun, ó sì tanná, láìpẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní í ní èso tí ó ti pọ́n. 11 Ife Farao sì wà lọ́wọ́ mi, mo sì mú àwọn èso àjàrà náà, mo sì fún un sínú ife Farao, mo sì gbé ife náà fún Farao.”

12 Josẹfu wí fún un pé, “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ. Ẹ̀ka mẹ́ta náà dúró fún ọjọ́ mẹ́ta. 13 Láàrín ọjọ́ mẹ́ta Farao yóò mú ọ jáde nínú ẹ̀wọ̀n padà sí ipò rẹ, ìwọ yóò sì tún máa gbé ọtí fún un, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ àtẹ̀yìnwá. 14 Ṣùgbọ́n nígbà tí ohun gbogbo bá dára fún ọ, rántí mi kí o sì fi àánú hàn sí mi. Dárúkọ mi fún Farao, kí o sì mú mi jáde kúrò ní ìhín. 15 Nítorí á jí mi gbé tà kúrò ní ilẹ̀ àwọn Heberu ni, àti pé níhìn-ín èmi kò ṣe ohunkóhun tí ó fi yẹ kí èmi wà ní ìhámọ́ bí mo ti wà yìí.”

16 Nígbà tí olórí alásè rí i wí pé ìtumọ̀ tí Josẹfu fún àlá náà dára, ó wí fún Josẹfu pé, “Èmi pẹ̀lú lá àlá: Mo ru agbọ̀n oúnjẹ mẹ́ta lórí, 17 Nínú agbọ̀n tí ó wà lókè, onírúurú oúnjẹ ló wà níbẹ̀ fún Farao, ṣùgbọ́n àwọn ẹyẹ sì ń ṣà wọ́n jẹ láti inú apẹ̀rẹ̀ náà tí ó wà lórí mi.”

18 Josẹfu dáhùn, “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ. Agbọ̀n mẹ́ta náà túmọ̀ sí ọjọ́ mẹ́ta. 19 Láàrín ọjọ́ mẹ́ta, Farao yóò tú ọ sílẹ̀, yóò sì bẹ́ orí rẹ, yóò sì gbé ara rẹ kọ́ sí orí igi. Àwọn ẹyẹ yóò sì jẹ ara rẹ.”

20 Ọjọ́ kẹta sì jẹ́ ọjọ́ ìbí Farao, ó sì ṣe àsè fún gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀. Ó sì mú olórí agbọ́tí àti olórí alásè jáde kúrò nínú ẹ̀wọ̀n. 21 Ó dá olórí agbọ́tí padà sí ipò tí ó wà tẹ́lẹ̀, kí ó ba à le máa fi ago lé Farao ní ọwọ́, 22 Ṣùgbọ́n, ó so olórí alásè kọ́ sórí igi, gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti sọ fún wọn nínú ìtumọ̀ rẹ̀ sí àlá wọn.

23 Ṣùgbọ́n, olórí agbọ́tí kò rántí Josẹfu mọ́, kò tilẹ̀ ronú nípa rẹ̀.

Matiu 11

Jesu àti Johanu onítẹ̀bọmi

11 (A)Lẹ́yìn ìgbà tí Jesu sì ti parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá, ó ti ibẹ̀ rékọjá láti máa kọ́ni àti láti máa wàásù ní àwọn ìlú Galili gbogbo.

(B)Nígbà tí Johanu gbọ́ ohun tí Kristi ṣe nínú ẹ̀wọ̀n, ó rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ (C)láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣe ìwọ ni ẹni tó ń bọ̀ wá tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?”

Jesu dáhùn ó wí pé, “Ẹ padà lọ, ẹ sì sọ fún Johanu ohun tí ẹ̀yin gbọ́, àti èyí tí ẹ̀yin rí. Àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúnkùn ún rìn, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ wọn, àwọn adití ń gbọ́rọ̀, a ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòṣì. Alábùkún fún ni ẹni tí kò rí ohun ìkọ̀sẹ̀ nípa mi.”

Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ti lọ tán, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn nípa ti Johanu: “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ wò ní aginjù? Ewéko tí afẹ́fẹ́ ń mi? Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, kí ni ẹ̀yin lọ òde lọ í wò? Ọkùnrin tí a wọ̀ ni aṣọ dáradára? Rárá àwọn ti ó wọ aṣọ dáradára wà ní ààfin ọba. Àní kí ní ẹ jáde láti lọ wò? Wòlíì? Bẹ́ẹ̀ ni, mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ.” 10 Èyí ni ẹni tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:

“ ‘Èmi yóò rán ìránṣẹ́ mi síwájú rẹ,
    ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe níwájú rẹ.’

11 Lóòótọ́ ni mó wí fún yín, nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí ẹni tí ó tí í dìde tí ó ga ju Johanu onítẹ̀bọmi lọ, síbẹ̀ ẹni tí ó kéré jù ní ìjọba ọ̀run ni ó pọ̀jù ú lọ. 12 Láti ìgbà ọjọ́ Johanu onítẹ̀bọmi títí di àkókò yìí ni ìjọba ọ̀run ti di à fi agbára wọ̀, àwọn alágbára ló ń fi ipá gbà á. 13 Nítorí náà gbogbo òfin àti wòlíì ni ó sọtẹ́lẹ̀ kí Johanu kí ó tó dé. 14 Bí ẹ̀yin yóò bá gbà á, èyí ni Elijah tó ń bọ̀ wá. 15 Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́.

16 (D)“Kí ni èmi ìbá fi ìran yìí wé? Ó dàbí àwọn ọmọ kékeré tí ń jókòó ní ọjà tí wọ́n sì ń ké pe àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn:

17 “ ‘Àwa ń fun fèrè fún yín,
    ẹ̀yin kò jó;
àwa kọrin ọ̀fọ̀
    ẹ̀yin kò káàánú.’

18 Nítorí Johanu wá kò bá a yín jẹ bẹ́ẹ̀ ni kò mu, ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù.’ 19 Ọmọ ènìyàn wá bá a yín jẹun, ó sì bá yin mu, wọ́n wí pé, ọ̀jẹun àti ọ̀mùtí; ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n a dá ọgbọ́n láre nípa ìṣe rẹ̀.”

Ègbé ni fún àwọn ìlú tí kò ronúpìwàdà

20 (E)Nígbà náà ni Jesu bẹ̀rẹ̀ sí í bá ìlú tí ó ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ wí, nítorí wọn kò ronúpìwàdà. 21 Ó wí pé, “Ègbé ni fún ìwọ Koraṣini, ègbé ni fún ìwọ Betisaida! Ìbá ṣe pé a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú yín ní a ṣe ni Tire àti Sidoni, àwọn ènìyàn wọn ìbá ti ronúpìwàdà ti pẹ́ nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú. 22 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Tire àti Sidoni ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín. 23 Àti ìwọ Kapernaumu, a ó ha gbé ọ ga sókè ọ̀run? Rárá, a ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ sí ipò òkú. Nítorí, ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú rẹ ní Sodomu, òun ìbá wà títí di òní. 24 Lóòótọ́ yóò sàn fún ilẹ̀ Sodomu ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún ìwọ lọ.”

Ìsinmi fún aláàárẹ̀

25 (F)(G) Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Mo yìn ọ Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, nítorí ìwọ ti fi òtítọ́ yìí pamọ́ fún àwọn tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti amòye, Ìwọ sì ti fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ wẹ́wẹ́. 26 Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí ó wù ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

27 (H)“Ohun gbogbo ni Baba mi ti fi sí ìkáwọ́ mi. Kò sí ẹni tí ó mọ ọmọ bí kò ṣe Baba, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí ó mọ Baba, bí kò ṣe ọmọ, àti àwọn tí ọmọ yan láti fi ara hàn fún.

28 “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ tí a sì di ẹrù wíwúwo lé lórí, èmi yóò sì fún yín ní ìsinmi. 29 Ẹ gbé àjàgà mi wọ̀. Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi nítorí onínútútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmi, ẹ̀yin yóò sì ri ìsinmi fún ọkàn yín. 30 Nítorí àjàgà mi rọrùn ẹrù mi sì fúyẹ́.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.