Old/New Testament
Ní orí òkè Sinai
19 Ní oṣù kẹta tí àwọn Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, ni ọjọ́ náà gan an ni wọ́n dé aginjù Sinai. 2 Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n gbéra kúrò ní Refidimu, wọ́n wọ ijù Sinai, wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀, níbẹ̀ ni Israẹli sì dó sí ní iwájú òkè ńlá.
3 Mose sì gòkè tọ Ọlọ́run lọ. Olúwa sì ké pè é láti orí òkè náà wá pé, “Èyí ni ìwọ yóò sọ fún ilé Jakọbu àti ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Israẹli: 4 ‘Ẹ̀yin ti rí ohun tí mo ti ṣe sí àwọn ará Ejibiti, àti bí mo ti gbé e yín ní apá ìyẹ́ idì. 5 (A)Nísinsin yìí, bí ẹ̀yin bá ṣe ìgbọ́ràn sí mi dé ojú ààmì, tí ẹ sì pa májẹ̀mú mi mọ́, nígbà náà ni ẹ̀yin ó jẹ́ ìṣúra fún mi ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ayé ni tèmi. 6 Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ilẹ̀ ọba àwọn àlùfáà fún mi, orílẹ̀-èdè mímọ́.’ Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ ti ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Israẹli.”
7 Mose sì tọ àwọn ènìyàn wá, ó sí pe àwọn àgbàgbà láàrín àwọn ènìyàn jọ. Ó sì gbé gbogbo ọ̀rọ̀ ti Olúwa pàṣẹ fún un láti sọ ní iwájú wọn. 8 Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì pa ohùn wọn pọ̀ wọ́n sì dáhùn wí pé, “Àwa yóò ṣe ohun gbogbo ti Olúwa wí.” Mose sì mú ìdáhùn wọn padà tọ Olúwa lọ.
9 Olúwa sọ fún Mose pé, “Èmi yóò tọ̀ ọ́ wá nínú ìkùùkuu ṣíṣú dudu, kí àwọn ènìyàn lè gbọ́ ohùn mi nígbà ti mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọn kí ó lè máa gbà ọ́ gbọ́.” Nígbà náà ni Mose sọ ohun tí àwọn ènìyàn wí fún Olúwa.
10 Olúwa sì wí fún Mose pé, “Tọ àwọn ènìyàn lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ ni òní àti ni ọ̀la. Jẹ́ kí wọn kí ó fọ aṣọ wọn. 11 Kí wọn kí ó sì múra di ọjọ́ kẹta, nítorí ni ọjọ́ náà ni Olúwa yóò sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Sinai ni ojú gbogbo àwọn ènìyàn. 12 (B)Kí ìwọ kí ó ṣe ààlà fún àwọn ènìyàn, kí ìwọ kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ kíyèsí ara yín, kí ẹ má ṣe gun orí òkè lọ, kí ẹ má tilẹ̀ fi ọwọ́ ba etí rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè náà, ó dájú, pípa ni a ó pa á: 13 A ó sọ ọ́ ní òkúta tàbí kí a ta á ní ọfà, ọwọ́kọ́wọ́ kò gbọdọ̀ kàn án. Ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko, òun kì yóò wà láààyè.’ Nígbà ti ìpè bá dún nìkan ni kí wọn ó gun òkè wá.”
14 Mose sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, ó yà wọ́n sí mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. 15 Ó sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ múra sílẹ̀ di ọjọ́ kẹta; Ẹ má ṣe bá aya yín lòpọ̀.”
16 (C)(D) Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kẹta, àrá àti mọ̀nàmọ́ná sì wà pẹ̀lú ìkùùkuu tí ó ṣú dudu ní orí òkè, ìpè ńlá sì dún kíkankíkan tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ó wà ni ibùdó wárìrì. 17 Mose sì kó àwọn ènìyàn tí ó jáde láti ibùdó wá pàdé Ọlọ́run, wọ́n dúró nítòsí òkè. 18 Èéfín sì bo òkè Sinai nítorí Olúwa sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ nínú iná. Èéfín náà sì ń ru sókè bí èéfín iná ìléru, gbogbo òkè náà sì mì tìtì. 19 Ohùn ìpè sì ń rinlẹ̀ dòdò. Mose sọ̀rọ̀, Ọlọ́run sì fi àrá dá a lóhùn.
20 Olúwa sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Sinai, o sì pe Mose wá sí orí òkè náà. Mose sì gun orí òkè. 21 Olúwa sọ fún Mose pé, “Sọ̀kalẹ̀, kí ó sì kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, kí wọn má ṣe fi tipátipá wá ọ̀nà láti wo Olúwa, bí wọn bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ wọn yóò ṣègbé. 22 Kódà àwọn àlùfáà tí ó ń wá síwájú Olúwa gbọdọ̀ ya ara wọn sí mímọ́ bí bẹ́ẹ̀ kọ́. Olúwa yóò kọlù wọ́n.”
23 Mose wí fún Olúwa pé, “Àwọn ènìyàn kì yóò lè wá sí orí òkè Sinai, nítorí ìwọ fúnrarẹ̀ ti kìlọ̀ fún wa pé, ‘Ṣe ààlà yí òkè ká, kí o sì yà á sí mímọ́.’ ”
24 Olúwa sì wí fún Mose pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, mú Aaroni gòkè wá pẹ̀lú rẹ. Ṣùgbọ́n kí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn má ṣe fi tipátipá gòkè tọ Olúwa. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò kọlù wọ́n.”
25 Mose sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn ènìyàn lọ. Ó sì sọ ohun tí Olúwa wí fún wọn.
Òfin mẹ́wàá
20 Ọlọ́run sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí pé:
2 (E)“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti, láti oko ẹrú jáde wá.
3 (F)“Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi.
4 (G)Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara yín, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ ní òkè ọ̀run, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀. 5 (H)Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n; nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run owú ni mí, tí ń bẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wò lára àwọn ọmọ, láti ìran kẹta títí dé ẹ̀kẹrin nínú àwọn tí ó kórìíra mi. 6 Èmi a sì máa fi àánú hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ó fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́.
7 (I)Ẹ má ṣe ṣi orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín lò, torí pé ẹnikẹ́ni tí o bá ṣi orúkọ rẹ̀ lò kì yóò lọ láìjẹ̀bi.
8 (J)Rántí ọjọ́ ìsinmi láti yà á sí mímọ́. 9 Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò fi ṣiṣẹ́, kí ìwọ kí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ, 10 Ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi Olúwa Ọlọ́run rẹ: nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan: ìwọ, àti ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, àti ẹran ọ̀sìn rẹ, àti àlejò rẹ, tí ń bẹ nínú ibodè rẹ. 11 Nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Olúwa dá ọ̀run àti ayé, òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn, ó sì sinmi ní ọjọ́ keje: nítorí náà ni Olúwa ṣe bùkún ọjọ́ ìsinmi tí ó sì yà á sí mímọ́.
12 (K)(L) Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ, kí ọjọ́ rẹ kí ó lè pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.
13 (M)(N) Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn.
14 (O)Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.
15 (P)Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.
16 (Q)Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ.
17 (R)Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ẹnìkéjì rẹ. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí aya ẹnìkéjì rẹ, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọ màlúù rẹ̀ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ àti ohun gbogbo tí í ṣe ti ẹnìkéjì rẹ.”
18 Nígbà tí àwọn ènìyàn náà rí mọ̀nàmọ́ná tí wọ́n sí gbọ́ ohùn ìpè àti èéfín tí ń rú láti orí òkè, tí wọ́n sì gbọ́ sísán àrá, dídún ìpè kíkankíkan; wọ́n dúró ní òkèrè wọ́n sì ń gbọ̀n ṣìgàṣìgà fún ìbẹ̀rù. 19 Wọ́n wí fún Mose pé, “Ìwọ fúnrarẹ̀ máa bá wa sọ̀rọ̀, àwa yóò sì gbọ́. Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ kí ó bá wa sọ̀rọ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò kú.”
20 Mose sì sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Ọlọ́run wá láti dán an yín wò, kí ẹ̀rù Ọlọ́run kí ó lè máa wà ní ara yín, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣẹ̀.”
21 Àwọn ènìyàn sì dúró ní òkèèrè nígbà tí Mose súnmọ́ ibi òkùnkùn biribiri níbi tí Ọlọ́run wà.
22 Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ará Israẹli: ‘Ẹ̀yin ti rí i fúnrayín bí èmi ti bá a yín sọ̀rọ̀ láti ọ̀run wá. 23 (S)Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ sin ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi: ẹ̀yin kò gbọdọ̀ rọ ọlọ́run fàdákà tàbí ọlọ́run wúrà fún ara yín.
24 (T)“ ‘Pẹpẹ erùpẹ̀ ni kí ìwọ mọ fún mi. Ní orí pẹpẹ yìí ni kí ìwọ ti máa rú ẹbọ sísun rẹ sí mi àti ẹbọ àlàáfíà rẹ, àgùntàn rẹ, ewúrẹ́ àti akọ màlúù rẹ. Ní ibi gbogbo tí mo gbé fi ìrántí orúkọ mi sí, èmi yóò sì máa tọ̀ ọ́ wá, èmi yóò sì máa bùkún ọ níbẹ̀. 25 (U)Bí ìwọ bá ṣe pẹpẹ òkúta fún mi, má ṣe fi òkúta tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ kọ́ ọ, nítorí bí ìwọ bá lo ohun ọnà rẹ lórí rẹ̀, ìwọ sọ ọ di àìmọ́. 26 Ìwọ kò gbọdọ̀ gun àkàsọ̀ lọ sí ibi pẹpẹ mi, kí àwọn ènìyàn má ba à máa wo ìhòhò rẹ láti abẹ́ aṣọ tí ìwọ wọ̀ nígbà tí ìwọ bá ń gòkè lọ sí ibi pẹpẹ.’
Òwe aláìláàánú ọmọ ọ̀dọ̀
21 (A)Nígbà náà ni Peteru wá sọ́dọ̀ Jesu, ó béèrè pé, “Olúwa, nígbà mélòó ni arákùnrin mi yóò ṣẹ̀ mi, tí èmi yóò sì dáríjì í? Tàbí ní ìgbà méje ni?”
22 Jesu dáhùn pé, “Mo wí fún ọ, kì í ṣe ìgbà méje, ṣùgbọ́n ní ìgbà àádọ́rin méje.
23 (B)“Nítorí náà, ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan tí ó fẹ́ ṣe ìṣirò pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. 24 Bí ó ti ń ṣe èyí, a mú ajigbèsè kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ẹgbàárùn-ún (10,000) tálẹ́ǹtì. 25 Nígbà tí kò tì í ní agbára láti san án, nígbà náà ni olúwa rẹ̀ pàṣẹ pé kí a ta òun àti ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní láti fi san gbèsè náà.
26 (C)“Nígbà náà ni ọmọ ọ̀dọ̀ náà wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ. ‘Ó bẹ̀bẹ̀ pé, mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san gbogbo rẹ̀ fún ọ.’ 27 Nígbà náà, ni olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì ṣàánú fún un. Ó tú u sílẹ̀, ó sì fi gbèsè náà jì í.
28 “Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà ti jáde lọ, ó rí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún owó idẹ, ó gbé ọwọ́ lé e, ó fún un ní ọrùn, ó wí pé, ‘san gbèsè tí o jẹ mí lójú ẹsẹ̀.’
29 “Ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ náà sì wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ̀, ò ń bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san án fún ọ.’
30 “Ṣùgbọ́n òun kọ̀ fún un. Ó pàṣẹ kí a mú ọkùnrin náà, kí a sì jù ú sínú túbú títí tí yóò fi san gbèsè náà tán pátápátá. 31 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí wọn gidigidi, wọ́n lọ láti lọ sọ fún olúwa wọn, gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.
32 “Nígbà tí olúwa rẹ̀ pè ọmọ ọ̀dọ̀ náà wọlé, ó wí fún un pé, ‘Ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, níhìn-ín ni mo ti dárí gbogbo gbèsè rẹ jì ọ́ nítorí tí ìwọ bẹ̀ mi. 33 Kò ha ṣe ẹ̀tọ́ fún ọ láti ṣàánú fún àwọn ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti ṣàánú fún ọ?’ 34 Ní ìbínú, olówó rẹ̀ fi í lé àwọn onítúbú lọ́wọ́ láti fi ìyà jẹ ẹ́, títí tí yóò fi san gbogbo gbèsè èyí ti ó jẹ ẹ́.
35 (D)“Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run yóò sí ṣe sì ẹnìkọ̀ọ̀kan, bí ẹ̀yin kò bá fi tọkàntọkàn dárí ji àwọn arákùnrin yín.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.