Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Gẹnẹsisi 18-19

Àwọn àlejò mẹ́ta

18 Olúwa sì farahan Abrahamu nítòsí àwọn igi ńlá Mamre, bí ó ti jókòó ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, nígbà tí ọjọ́-kanrí tí oòrùn sì mú. (A)Abrahamu gbójú sókè, ó sì rí àwọn ọkùnrin mẹ́ta tí wọn dúró nítòsí rẹ̀. Nígbà tí ó rí wọn, ó sáré láti lọ pàdé wọn, ó sì tẹríba bí ó ti ń kí wọn.

Ó wí pé, “Bí mo bá rí ojúrere yín Olúwa mi, ẹ má ṣe lọ láì yà sọ́dọ̀ ìránṣẹ́ yín. Ẹ jẹ́ kí a bu omi díẹ̀ wá kí ẹ̀yin kí ó wẹ ẹsẹ̀ yín, kí ẹ sì sinmi lábẹ́ igi níhìn-ín. Ẹ jẹ́ kí n wá oúnjẹ wá fún un yín, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ, kí ara sì tù yín, kí ẹ si tẹ̀síwájú ní ọ̀nà yín, nígbà tí ẹ ti yà ní ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ yín.”

Wọn sì wí pé “Ó dára.”

Abrahamu sì yára tọ Sara aya rẹ̀ lọ nínú àgọ́, ó wí pé, “Tètè mú òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun dáradára mẹ́ta kí o sì pò ó pọ̀, kí o sì ṣe oúnjẹ.”

Abrahamu sì tún sáré lọ sí ibi agbo ẹran, ó sì mú ọmọ màlúù kan fún ìránṣẹ́ rẹ̀, ìránṣẹ́ náà sì tètè ṣè é. Ó sì mú wàrà àti mílíìkì àti màlúù tí ó ti pèsè, ó sì gbé síwájú wọn. Ó sì dúró nítòsí wọn lábẹ́ igi bí wọn ti ń jẹ ẹ́.

Wọn béèrè pé, “Sara aya rẹ ńkọ́?”

Ó dáhùn pé, “Ó wà nínú àgọ́.”

10 (B)Nígbà náà ni Olúwa wí fún un pé, “Èmi yóò sì tún padà tọ̀ ọ́ wá nítòótọ́ ní ìwòyí àmọ́dún; Sara aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan.”

Sara sì ń dẹtí gbọ́ láti ẹnu-ọ̀nà àgọ́ tí ó wà lẹ́yìn ọkùnrin náà. 11 Abrahamu àti Sara sì ti di arúgbó: Sara sì ti kọjá àsìkò ìbímọ. 12 (C)Nítorí náà, Sara rẹ́rìn-ín nínú ara rẹ̀ bí ó ti ń rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo ti di arúgbó tán tí olúwa mi pẹ̀lú sì ti gbó jọ̀kújọ̀kú, èmi yóò ha tún lè bímọ?”

13 Nígbà náà ni Olúwa wí fún Abrahamu pé, “Kín ló dé tí Sara fi rẹ́rìn-ín tí ó sì wí pé, ‘Èmi yóò ha bímọ nítòótọ́, nígbà tí mo di ẹni ogbó tán?’ 14 (D)Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tí ó ṣòro jù fún Olúwa? Èmi ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ìwòyí àmọ́dún, Sara yóò sì bí ọmọkùnrin.”

15 Ẹ̀rù sì ba Sara, ó sì sẹ́ pé òun kò rẹ́rìn-ín.

Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Dájúdájú ìwọ rẹ́rìn-ín.”

Abrahamu bẹ Olúwa nítorí Sodomu

16 Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà dìde láti máa lọ, wọn kọjú sí ọ̀nà Sodomu, Abrahamu sì sìn wọ́n dé ọ̀nà. 17 Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ǹjẹ́ èmi yóò ha pa ohun tí mo fẹ́ ṣe mọ́ fún Abrahamu bí? 18 (E)Dájúdájú Abrahamu yóò sá à di orílẹ̀-èdè ńlá àti alágbára, àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni a ó bùkún fún nípasẹ̀ rẹ̀. 19 Nítorí tí èmi ti yàn án láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ará ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, láti máa pa ọ̀nà Olúwa mọ nípa ṣíṣe olóòtítọ́ àti olódodo: kí Olúwa le è mú ìlérí rẹ̀ fún Abrahamu ṣẹ.”

20 Olúwa sì wí pé, igbe Sodomu àti Gomorra pọ̀ púpọ̀ àti pé ẹ̀ṣẹ̀ wọn burú jọjọ. 21 “Èmi yóò sọ̀kalẹ̀ síbẹ̀ láti ṣe ìwádìí igbe tí ó dé sí etí ìgbọ́ mi nípa wọn, kí èmi sì mọ òtítọ́ tí ó wà níbẹ̀.”

22 Àwọn ọkùnrin náà yí padà, wọ́n sì ń lọ sí ìhà Sodomu. Ṣùgbọ́n Abrahamu dúró níbẹ̀ níwájú Olúwa. 23 Nígbà náà ni Abrahamu súnmọ́ ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì wí pé, “Ìwọ yóò ha pa olódodo ènìyàn àti ènìyàn búburú run papọ̀ bí?” 24 “Bí ó bá ṣe pé Ìwọ rí àádọ́ta olódodo nínú ìlú náà, Ìwọ yóò ha run ún, Ìwọ kì yóò ha dá ìlú náà sí nítorí àwọn àádọ́ta olódodo tí ó wà nínú rẹ̀ náà? 25 Kò jẹ́ rí bẹ́ẹ̀! Dájúdájú Ìwọ kì yóò ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀, láti pa olódodo pẹ̀lú àwọn ènìyàn rere àti àwọn ènìyàn búburú. Dájúdájú, Ìwọ kì yóò ṣe èyí tí ó tọ́ bi?”

26 Olúwa wí pé, “Bí mo bá rí àádọ́ta (50) olódodo ní ìlú Sodomu, èmi yóò dá ìlú náà sí nítorí tiwọn.”

27 Abrahamu sì tún tẹ̀síwájú pé, “Wò ó nísinsin yìí, níwọ̀n bí èmi ti ní ìgboyà láti bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ níwájú Olúwa, èmi ẹni tí í ṣe erùpẹ̀ àti eérú, 28 bí ó bá ṣe pe olódodo márùn-dínláàádọ́ta (45) ni ó wà nínú ìlú, Ìwọ yóò ha pa ìlú náà run nítorí ènìyàn márùn-ún bí?”

Olúwa dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo márùn-dínláàádọ́ta nínú rẹ̀.”

29 Òun sì tún wí lẹ́ẹ̀kan si pé, “Bí ó bá ṣe pé ogójì (40) ni ńkọ́?”

Olúwa sì tún wí pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo ogójì nínú rẹ̀.”

30 Abrahamu sì tún bẹ Olúwa pé, “Kí Olúwa má ṣe bínú, ṣùgbọ́n èmi yóò sọ̀rọ̀. Bí ó bá ṣe pé ọgbọ̀n (30) ni a rí níbẹ̀ ńkọ́?”

Olúwa dáhùn pé, “Bí mó bá rí ọgbọ̀n, Èmi kì yóò pa ìlú run.”

31 Abrahamu wí pé, “Níwọ́n bí mo ti ní ìgboyà láti bá Olúwa sọ̀rọ̀ báyìí, jẹ́ kí n tẹ̀síwájú. Bí o bá ṣe pé olódodo ogún péré ni ó wà nínú ìlú náà ńkọ́?”

Olúwa sì dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa á run nítorí ogún ènìyàn náà.”

32 Abrahamu sì wí pé, “Jọ̀wọ́ má ṣe bínú Olúwa. Jẹ́ kí ń béèrè lẹ́ẹ̀kan si. Bí ó bá ṣe pé ènìyàn mẹ́wàá ni ó jẹ́ olódodo ńkọ́?”

Olúwa wí pé, “Nítorí ènìyàn mẹ́wàá náà, Èmi kì yóò pa á run.”

33 Olúwa sì bá tirẹ̀ lọ, nígbà tí ó bá Abrahamu sọ̀rọ̀ tán, Abrahamu sì padà sílé.

Ìparun Sodomu àti Gomorra

19 Ní àṣálẹ́, àwọn angẹli méjì sì wá sí ìlú Sodomu, Lọti sì jókòó ní ẹnu ibodè ìlú. Bí ó sì ti rí wọn, ó sì dìde láti pàdé wọn, ó kí wọn, ó sì foríbalẹ̀ fún wọn. Ó wí pé, “Ẹ̀yin olúwa mi, èmi bẹ̀ yín, ẹ yà sí ilé ìránṣẹ́ yín kí ẹ sì wẹ ẹsẹ̀ yín, kí n sì gbà yín lálejò, ẹ̀yin ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ láti máa bá ìrìnàjò yín lọ.”

Wọ́n sì wí pé, “Rárá o, àwa yóò dúró ní ìgboro ní òru òní.”

Ṣùgbọ́n Lọti rọ̀ wọ́n gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n gbà láti bá a lọ sì ilé. Ó sì ṣe àsè fún wọn, ó sì dín àkàrà aláìwú fún wọ́n, wọ́n sì jẹ. Ṣùgbọ́n kí ó tó di pé wọ́n lọ sùn, àwọn ọkùnrin ìlú Sodomu tọmọdé tàgbà yí ilé náà ká. (F)Wọ́n pe Lọti pé, “Àwọn ọkùnrin tí ó wọ̀ sí ilé rẹ lálẹ́ yìí ńkọ́? Mú wọn jáde fún wa, kí a le ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú wọn.”

Lọti sì jáde láti pàdé wọn, ó sì ti ìlẹ̀kùn lẹ́yìn rẹ̀ bí ó ti jáde. Ó sì wí pé; “Rárá, ẹ̀yin ará mi, ẹ má ṣe ṣe ohun búburú yìí, kíyèsi i, mo ní ọmọbìnrin méjì tí kò mọ ọkùnrin rí, ẹ jẹ́ kí n mú wọn tọ̀ yín wá kí ẹ sì ṣe ohun tí ẹ fẹ́ pẹ̀lú wọn. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ṣe àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ní ibi kan nítorí wọ́n wá wọ̀ lábẹ́ ààbò ní ilé mi.”

Wọ́n sì wí fún pé, “Bì sẹ́yìn fún wa. Èyí yìí wá ṣe àtìpó láàrín wa, òun sì fẹ́ ṣe onídàájọ́! Aburú tí a ó fi ṣe ọ́ yóò pọ̀ ju tí wọn lọ.” Wọn rọ́ lu Lọti, wọ́n sì súnmọ́ ọn láti fọ́ ìlẹ̀kùn.

10 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà nawọ́ fa Lọti wọlé, wọ́n sì ti ìlẹ̀kùn. 11 (G)Wọ́n sì bu ìfọ́jú lu àwọn ọkùnrin tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà ilé náà, àti èwe àti àgbà: wọ́n kò sì rí ẹnu-ọ̀nà mọ́.

12 Àwọn ọkùnrin náà sì wí fún Lọti pé, “Ǹjẹ́ ó ní ẹlòmíràn ní ìlú yìí bí? Àna rẹ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tàbí ẹnikẹ́ni tí ìwọ ní ní ìlú yìí, kó wọn jáde kúrò ní ibí yìí, 13 nítorí a ó pa ìlú yìí run, nítorí igbe iṣẹ́ búburú wọn ń dí púpọ̀ níwájú Olúwa, Olúwa sì rán wa láti pa á run.”

14 Nígbà náà ni Lọti jáde, ó sì wí fún àwọn àna rẹ̀ ọkùnrin tí ó ti bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣe kánkán, kí ẹ jáde ní ìlú yìí, nítorí Olúwa fẹ́ pa ìlú yìí run!” Ṣùgbọ́n àwọn ọkọ ọmọ rẹ̀ wọ̀nyí rò pé àwàdà ló ń ṣe.

15 Ní àfẹ̀mọ́júmọ́, àwọn angẹli náà rọ Lọti pé, “Ṣe wéré, mú aya rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì tí ó wà níhìn-ín, àìṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò parun pẹ̀lú ìlú yìí nígbà tí wọ́n bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

16 (H)Nígbà tí ó ń jáfara, àwọn ọkùnrin náà nawọ́ mú un lọ́wọ́, wọ́n sì nawọ́ mú aya rẹ̀ náà lọ́wọ́ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì, wọ́n sì mú wọn jáde sẹ́yìn odi ìlú, nítorí Olúwa ṣàánú fún wọn. 17 Ní kété tí wọ́n mú wọn jáde sẹ́yìn odi tán, ọ̀kan nínú wọn wí pé, “Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ! Má ṣe wo ẹ̀yìn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó má ṣe dúró ní gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀! Sá àsálà lọ sí orí òkè, kí ìwọ ó má ba ṣègbé!”

18 Ṣùgbọ́n Lọti wí fún wọn pé, “Rárá, ẹ̀yin Olúwa mi, ẹ jọ̀wọ́! 19 Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ ti rí ojúrere rẹ, tí o sì ti fi àánú rẹ hàn nípa gbígba ẹ̀mí mi là, Èmi kò le è sálọ sórí òkè, kí búburú yìí má ba à lé mi bá, kí n sì kú. 20 Wò ó, ìlú kékeré kan nìyí ní tòsí láti sá sí: jẹ́ kí n sálọ síbẹ̀, ìlú kékeré ha kọ́? Ẹ̀mí mi yóò sì yè.”

21 Ó sì wí fún un pé, “Ó dára, mo gba ẹ̀bẹ̀ rẹ. Èmi kì yóò run ìlú náà tí ìwọ sọ̀rọ̀ rẹ̀. 22 Tètè! Sálọ síbẹ̀, nítorí èmi kò le ṣe ohun kan àyàfi tí ó bá dé ibẹ̀,” (ìdí nìyí tí a fi ń pe ìlú náà ní Soari).

23 Nígbà tí Lọti yóò fi dé ìlú Soari, oòrùn ti yọ. 24 (I)Nígbà náà ni Olúwa rọ̀jò iná àti Sulfuru (òkúta iná) sórí Sodomu àti Gomorra—láti ọ̀run lọ́dọ̀ Olúwa wá. 25 Báyìí ni ó run àwọn ìlú náà àti gbogbo ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wà ní ìlú ńláńlá wọ̀n-ọn-nì àti ohun gbogbo tí ó hù jáde nílẹ̀. 26 (J)Ṣùgbọ́n aya Lọti bojú wo ẹ̀yìn, ó sì di ọ̀wọ́n iyọ̀.

27 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Abrahamu sì dìde ó sì padà lọ sí ibi tí ó gbé dúró níwájú Olúwa. 28 (K)Ó sì wo ìhà Sodomu àti Gomorra àti àwọn ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì, ó sì rí èéfín tí ń ti ibẹ̀ jáde bí èéfín iná ìléru.

29 Ọlọ́run sì rántí Abrahamu, nígbà tí ó run ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì tan, ó sì mú Lọti jáde kúrò láàrín ìparun náà, tí ó kọlu ìlú tí Lọti ti gbé.

Lọti àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin

30 Lọti àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin méjèèjì sì kúrò ní Soari, wọ́n sì ń lọ gbé ní orí òkè ní inú ihò àpáta, nítorí ó bẹ̀rù láti gbé ní ìlú Soari. 31 Ní ọjọ́ kan, èyí ẹ̀gbọ́n sọ fún àbúrò rẹ̀ pé, “Baba wa ti dàgbà, kò sì sí ọkùnrin kankan ní agbègbè yìí tí ìbá bá wa lòpọ̀, bí ìṣe gbogbo ayé. 32 Wá, jẹ́ kí a mú baba wa mu ọtí yó, kí ó ba à le bá wa lòpọ̀, kí àwa kí ó lè bí ọmọ, kí ìran wa má ba à parẹ́.”

33 Ní òru ọjọ́ náà, wọ́n rọ baba wọn ní ọtí yó. Èyí ẹ̀gbọ́n sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bá a lòpọ̀, baba wọn kò mọ̀ ìgbà tí ó sùn ti òun àti ìgbà tí ó dìde.

34 Ní ọjọ́ kejì èyí ẹ̀gbọ́n wí fún àbúrò rẹ̀ pé, “Ní àná mo sùn ti baba mi. Jẹ́ kí a tún wọlé tọ̀ ọ́, kí a lè ní irú-ọmọ láti ọ̀dọ̀ baba wa.” 35 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún fún baba wọn ní ọtí mu yó ni alẹ́ ọjọ́ náà, èyí àbúrò náà sì wọlé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bá a lòpọ̀, kò sì tún mọ ìgbà tí ó wọlé sùn ti òun tàbí ìgbà tí ó dìde.

36 Àwọn ọmọbìnrin Lọti méjèèjì sì lóyún fún baba wọn. 37 Èyí ẹ̀gbọ́n sì bí ọmọkùnrin, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Moabu. Òun ni baba ńlá àwọn ará Moabu lónìí. 38 Èyí àbúrò náà sì bí ọmọkùnrin, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Bene-Ami. Òun ni baba ńlá àwọn ará Ammoni lónìí.

Matiu 6:1-18

Ìtọrẹ àánú

(A)“Ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe iṣẹ́ rere yín níwájú àwọn ènìyàn nítorí kí a le rí yín, Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin kò ni èrè kankan lọ́dọ̀ Baba yín ní ọ̀run.

“Nítorí náà, nígbà ti ẹ́ bá ti ń fún aláìní, ẹ má ṣe fi fèrè kéde rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn àgàbàgebè ti í ṣe ní Sinagọgu àti ní ìta gbangba; kí àwọn ènìyàn le yìn wọ́n. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè tí wọn ní kíkún. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń fi fún aláìní, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe, kí ìfúnni rẹ má ṣe jẹ́ mí mọ̀. Nígbà náà ni Baba rẹ̀, tí ó sì mọ ohun ìkọ̀kọ̀ gbogbo, yóò san án fún ọ.

Àdúrà

(B)“Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe ṣe bí àwọn àgàbàgebè, nítorí wọn fẹ́ràn láti máa dúró gbàdúrà ní Sinagọgu àti ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tí ènìyàn ti lè rí wọ́n. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní kíkún. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, wọ inú iyàrá rẹ lọ, sé ìlẹ̀kùn mọ́ ara rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ ẹni tí ìwọ kò rí. Nígbà náà ni Baba rẹ tí ó mọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ rẹ, yóò san án fún ọ. Ṣùgbọ́n nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ má ṣe àtúnwí asán bí àwọn aláìkọlà, nítorí wọn rò pé a ó tìtorí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ gbọ́ tiwọn. Ẹ má ṣe dàbí i wọn, nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ ohun tí ẹ ṣe aláìní, kí ẹ tilẹ̀ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.

(C)“Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ ṣe máa gbàdúrà:

“ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run,
ọ̀wọ̀ fún orúkọ yín,
10 Kí ìjọba yín dé,
Ìfẹ́ tiyín ni kí a ṣe
    ní ayé bí ti ọ̀run.
11 Ẹ fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí
12 Ẹ dárí gbèsè wa jì wá,
    Bí àwa ti ń dáríji àwọn ajigbèsè wa,
13 (D)Ẹ má ṣe fà wá sínú ìdánwò,
    Ṣùgbọ́n ẹ gbà wá lọ́wọ́ ibi.
    Nítorí ìjọba ni tiyín, àti agbára àti ògo, láéláé, Àmín.’

14 (E)Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá dárí jí àwọn tó ṣẹ̀ yín, baba yín ọ̀run náà yóò dáríjì yín. 15 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jì wọ́n, baba yín kò ní í dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.

Àwẹ̀

16 (F)“Nígbà tí ẹ̀yin bá gbààwẹ̀, ẹ má ṣe fa ojú ro bí àwọn àgàbàgebè ṣe máa ń ṣe nítorí wọn máa ń fa ojú ro láti fihàn àwọn ènìyàn pé àwọn ń gbààwẹ̀. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín wọn ti gba èrè wọn ní kíkún. 17 Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá gbààwẹ̀, bu òróró sí orí rẹ, kí ó sì tún ojú rẹ ṣe dáradára. 18 Kí ó má ṣe hàn sí ènìyàn pé ìwọ ń gbààwẹ̀, bí kò ṣe sì í Baba rẹ, ẹni tí ìwọ kò rí, àti pé, Baba rẹ tí ó rí ohun tí o ṣe ni ìkọ̀kọ̀, yóò san án fún ọ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.