Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Gẹnẹsisi 13-15

Ìpinyà Abramu àti Lọti

13 Abramu sì gòkè láti Ejibiti lọ sí ìhà gúúsù, pẹ̀lú aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní àti Lọti pẹ̀lú. Abramu sì ti di ọlọ́rọ̀ gidigidi; ní ẹran ọ̀sìn, ó ní fàdákà àti wúrà.

Láti gúúsù, ó ń lọ láti ibìkan sí ibòmíràn títí ó fi dé ilẹ̀ Beteli, ní ibi tí àgọ́ rẹ̀ ti wà ní ìṣáájú rí, lágbedeméjì Beteli àti Ai. Ní ibi pẹpẹ tí ó ti tẹ́ síbẹ̀ ní ìṣáájú, níbẹ̀ ni Abramu sì ń ké pe orúkọ Olúwa.

Àti Lọti pẹ̀lú, tí ó ń bá Abramu rìn kiri, ní agbo ẹran, ọ̀wọ́ ẹran àti àgọ́. Ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà kò le gbà wọ́n tí wọ́n bá ń gbé pọ̀, nítorí, ohun ìní wọn pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, dé bi wí pé wọn kò le è gbé pọ̀. Èdè-àìyedè sì bẹ̀rẹ̀ láàrín àwọn darandaran Abramu àti ti Lọti. Àwọn ará Kenaani àti àwọn ará Peresi sì ń gbé ní ilẹ̀ náà nígbà náà.

Abramu sì wí fún Lọti pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí èdè-àìyedè kí ó wà láàrín èmi àti ìrẹ, àti láàrín àwọn darandaran wa, nítorí pé ẹbí kan ni àwa ṣe. Gbogbo ilẹ̀ ha kọ́ nìyí níwájú rẹ? Jẹ́ kí a pínyà. Bí ìwọ bá lọ sí apá ọ̀tún, èmi yóò lọ sí apá òsì, bí ó sì ṣe òsì ni ìwọ lọ, èmi yóò lọ sí apá ọ̀tún.”

10 (A)Lọti sì gbójú sókè, ó sì ri wí pé gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani ni omi rin dáradára bí ọgbà Olúwa, bí ilẹ̀ Ejibiti, ní ọ̀nà Soari. (Èyí ní ìṣáájú kí Olúwa tó pa Sodomu àti Gomorra run). 11 Nítorí náà Lọti yan gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani yìí fún ara rẹ̀, ó sì ń lọ sí ọ̀nà ìlà-oòrùn. Òun àti Abramu sì pínyà. 12 Abramu ń gbé ni ilẹ̀ Kenaani, Lọti sì jókòó ní ìlú agbègbè Àfonífojì náà, ó sì pàgọ́ rẹ̀ títí dé Sodomu. 13 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Sodomu jẹ́ ènìyàn búburú, wọn sì ń dẹ́ṣẹ̀ gidigidi ni iwájú Olúwa.

14 Olúwa sì wí fún Abramu lẹ́yìn ìpinyà òun àti Lọti pé, “Gbé ojú rẹ sókè nísinsin yìí, kí o sì wò láti ibi tí o gbé wà a nì lọ sí ìhà àríwá àti sí ìhà gúúsù, sí ìlà-oòrùn àti sí ìwọ̀ rẹ̀. 15 (B)Gbogbo ilẹ̀ tí ìwọ ń wò o nì ni èmi ó fi fún ọ àti irú-ọmọ rẹ láéláé. 16 Èmi yóò mú kí irú-ọmọ rẹ kí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó bá ṣe pé ẹnikẹ́ni bá le è ka erùpẹ̀ ilẹ̀, nígbà náà ni yóò tó lè ka irú-ọmọ rẹ. 17 Dìde, rìn òró àti ìbú ilẹ̀ náà já, nítorí ìwọ ni Èmi yóò fi fún.”

18 Nígbà náà ni Abramu kó àgọ́ rẹ̀, ó sì wá, ó sì jókòó ní ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó Mamre, tí ó wà ní Hebroni. Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan sí fún Olúwa.

Abramu gba Lọti là

14 Ní àsìkò yìí ni Amrafeli ọba Ṣinari, Arioku ọba Ellasari, Kedorlaomeri ọba Elamu àti Tidali ọba Goyimu jáde lọ láti bá Bera ọba Sodomu, Birṣa ọba Gomorra, Ṣenabu ọba Adma, Ṣemeberi ọba Ṣeboimu àti ọba Bela (èyí nì ni Soari) jagun. Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí ni ó kó ogun wọn jọ pọ̀ sí Àfonífojì Siddimu (Òkun iyọ̀). Fún ọdún méjìlá gbáko ni wọ́n ti ń sin Kedorlaomeri bí ẹrú. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di ọdún kẹtàlá wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i.

Ní ọdún kẹrìnlá, ni Kedorlaomeri àti àwọn ọba tí wọ́n ti jọ ni májẹ̀mú àṣepọ̀ wá, wọ́n ṣígun, wọ́n sì ṣẹ́gun ará Refaimu ní Aṣteroti-Karnaimu, àwọn ará Susimu ni Hamu, àwọn ará Emimu ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kiriataimu, àti àwọn ará Hori ní orí òkè wọ̀n-ọn-nì Seiri, títí ó fi dé Eli-Parani ní etí ijù. Wọ́n sì tún yípadà lọ sí En-Miṣpati (èyí yìí ni Kadeṣi), wọ́n sì ṣẹ́gun gbogbo ilẹ̀ àwọn Amaleki, àti àwọn ará Amori tí ó tẹ̀dó sí Hasason Tamari pẹ̀lú.

Nígbà náà ni ọba Sodomu, ọba Gomorra, ọba Adma, ọba Ṣeboimu àti ọba Bela (èyí ni Soari), kó àwọn ọmọ-ogun wọn, wọ́n sì pa ibùdó ogun wọn sí Àfonífojì Siddimu, láti kojú ìjà sí Kedorlaomeri ọba Elamu, Tidali ọba Goyimu, Amrafeli ọba Ṣinari àti Arioku ọba Ellasari (ọba mẹ́rin kọjú ìjà sí ọba márùn-ún). 10 Àfonífojì Siddimu sì kún fún kòtò ọ̀dà-ilẹ̀, nígbà tí ọba Sodomu àti ọba Gomorra sì sá, díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin ogun náà ṣubú sínú àwọn kòtò náà, àwọn tókù sì sálọ sì orí òkè. 11 Àwọn ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà sì kó gbogbo ẹrù Sodomu àti Gomorra àti oúnjẹ wọn; wọ́n sì lọ. 12 Wọ́n sì mú Lọti ọmọ arákùnrin Abramu tí ń gbé ní Sodomu àti gbogbo ohun ìní rẹ̀.

13 Ẹnìkan tí ó sá àsálà sì wá ròyìn fún Abramu, ará Heberu ni. Abramu sá ti tẹ̀dó sí ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó Mamre ará Amori, arákùnrin Eṣkolu àti Aneri: àwọn ẹni tí ó ń bá Abramu ní àṣepọ̀. 14 Nígbà tí Abramu gbọ́ wí pé, a di Lọti ní ìgbèkùn, ó kó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí a bí sí ilẹ̀ rẹ̀ tí ó sì ti kọ́ ni ogun jíjà jáde, wọ́n jẹ́ okòó-lé-lọ́ọ̀dúnrún ó dín méjì ènìyàn (318), ó sì lépa wọn títí dé Dani. 15 Ní ọ̀gànjọ́ òru, Abramu pín àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sí méjì, ó sì kọlù wọ́n, ó sì ṣẹ́gun wọn, ó sì lé wọn títí dé Hoba tí ó wà ní apá òsì Damasku. 16 Gbogbo ìkógun ni ó rí gbà padà àti ọmọ arákùnrin rẹ̀, Lọti pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀, àti àwọn obìnrin pẹ̀lú àwọn ènìyàn tókù.

17 (C)Nígbà tí Abramu ti ṣẹ́gun Kedorlaomeri àti àwọn ọba tí ó pẹ̀lú rẹ̀, ọba Sodomu lọ pàdé rẹ̀ ní Àfonífojì Ṣafe (èyí tí ó túmọ̀ sí Àfonífojì Ọba).

18 Melkisedeki ọba Salẹmu (Jerusalẹmu) sì mú oúnjẹ àti ọtí wáìnì jáde wá. Òun ni àlùfáà Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo. 19 Ó sì súre fún Abramu wí pé,

“Ìbùkún ni fún Abramu ti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo
    Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.
20 Ìbùkún sì ni fún Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ,
    tí ó fi àwọn ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́.”

Abramu sì fún un ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo.

21 Ọba Sodomu sì wí fún Abramu pé, “Kó àwọn ènìyàn mi fún mi, ṣùgbọ́n mú àwọn ẹrù fún ara rẹ.”

22 Ṣùgbọ́n Abramu dá ọba Sodomu lóhùn pé, “Mo ti búra fún Olúwa, Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, tí ó dá ọ̀run àti ayé, mo sì ti gbọ́wọ́ sókè, 23 pé, èmi kì yóò mú láti fọ́nrán òwú títí dé okùn bàtà, àti pé, èmi kí yóò mú ohun kan tí ṣe tìrẹ, kí ìwọ kí ó má ba à wí pé, ‘Mo sọ Abramu di ọlọ́rọ̀.’ 24 Èmi kì yóò gba ohunkóhun yàtọ̀ sí ohun tí àwọn ọkùnrin mi ti jẹ́, ṣùgbọ́n fi ìpín fún àwọn ọkùnrin tí ó bá mi lọ, Aneri, Eṣkolu àti Mamre. Jẹ́ kí wọn kí ó gba ìpín wọn.”

Májẹ̀mú Ọlọ́run pẹ̀lú Abramu

15 Lẹ́yìn èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Abramu wá lójú ìran pé:

“Abramu má ṣe bẹ̀rù,
    Èmi ni ààbò rẹ,
    Èmi sì ni èrè ńlá rẹ.”

Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “Olúwa Olódùmarè, kí ni ìwọ yóò fi fún mi níwọ̀n ìgbà tí èmi kò bímọ, Elieseri ará Damasku ni yóò sì jogún mi,” Abramu sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ìwọ kò fún mi ní ọmọ, nítorí náà ẹrú nínú ilé mi sì ni yóò jẹ́ àrólé mi.”

(D)Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ ọ́ wá pé: “Ọkùnrin yìí kọ́ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ bí kò ṣe ọmọ tí ìwọ bí fúnrarẹ̀ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ.” (E)Olúwa sì mú Abramu jáde sí ìta ó sì wí fún un pé, “Gbé ojú sókè sí ọ̀run kí o sì ka àwọn ìràwọ̀ bí ó bá ṣe pé ìwọ le è kà wọ́n.” Ó sì wí fun un pé, “Nítorí náà, báyìí ni irú-ọmọ rẹ yóò rí.”

(F)Abramu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.

Ó sì tún wí fún un pé, “Èmi ni Olúwa tí ó mú ọ jáde láti Uri ti Kaldea láti fún ọ ní ilẹ̀ yìí láti jogún.”

Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “Olúwa Olódùmarè, báwo ni mo ṣe lè mọ̀ pé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ ohun ìní mi?”

Nítorí náà, Olúwa wí fún un pé, “Mú abo màlúù, ewúrẹ́ àti àgbò ọlọ́dún mẹ́ta mẹ́ta wá, àti àdàbà kan àti ọmọ ẹyẹlé kan.”

10 Abramu sì mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, ó sì là wọ́n sí méjì méjì, ó sì fi ẹ̀là èkínní kọjú sí èkejì, ṣùgbọ́n kò la àwọn ẹyẹ ní tiwọn. 11 Àwọn ẹyẹ igún sì ń wá sórí òkú ẹran náà, Abramu sì ń lé wọn.

12 (G)Bí oòrùn ti ń wọ̀, Abramu sùn lọ fọnfọn, òkùnkùn biribiri tí ó kún fún ẹ̀rù sì bò ó. 13 (H)(I)Nígbà náà ni Olúwa wí fún Abramu pé, “Mọ èyí dájú pé, irú-ọmọ rẹ yóò ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì, wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú fún irínwó ọdún (400). 14 Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóò máa sìn, ni èmi ó dá lẹ́jọ́, lẹ́yìn náà ni wọn ó sì jáde pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀. 15 Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ àwọn baba rẹ lọ ni àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò sì di arúgbó kí a tó gbé ọ sin. 16 Ní ìran kẹrin àwọn ìran rẹ yóò padà wá sí ibi. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Amori kò ì tí ì kún òṣùwọ̀n.”

17 Nígbà tí oòrùn wọ̀ tí ilẹ̀ sì ṣú, ìkòkò iná tí ń ṣèéfín àti ọwọ́ iná sì ń kọjá láàrín ẹ̀là ẹran náà. 18 (J)Ní ọjọ́ náà gan an ni Olúwa dá májẹ̀mú pẹ̀lú Abramu, ó sì wí pé, “Àwọn ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ejibiti dé odò ńlá Eufurate: 19 ilẹ̀ àwọn ará Keni, àti ti ará Kenissiti, àti ará Kadmoni, 20 àti ti ará Hiti, àti ti ará Peresi, àti ti ará Refaimu. 21 Àti ti ará Amori, àti ti ará Kenaani, àti ti ará Girgaṣi àti ti ará Jebusi.”

Matiu 5:1-26

Ìwàásù orí òkè

(A)Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó gun orí òkè lọ ó sì jókòó. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ si tọ̀ ọ́ wá. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn.

Ó wí pé:

(B)“Alábùkún fún ni àwọn òtòṣì ní ẹ̀mí,
    nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run.
(C)Alábùkún fún ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀,
    nítorí a ó tù wọ́n nínú.
(D)Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn tútù,
    nítorí wọn yóò jogún ayé.
(E)Alábùkún fún ni àwọn tí ebi ń pa
    tí òǹgbẹ ń gbẹ́ nítorí òdodo, nítorí wọn yóò yó.
Alábùkún fún ni àwọn aláàánú,
    nítorí wọn yóò rí àánú gbà.
(F)Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn mímọ́,
    nítorí wọn yóò rí Ọlọ́run.
Alábùkún fún ni àwọn onílàjà,
    nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n.
10 (G)Alábùkún fún ni àwọn ẹni tí a ṣe inúnibíni sí,
    nítorí tí wọ́n jẹ́ olódodo
    nítorí tiwọn ní ìjọba ọ̀run.

11 “Alábùkún fún ni ẹ̀yin nígbà tí àwọn ènìyàn bá fi àbùkù kàn yín tí wọn bá ṣe inúnibíni sí yín, tiwọn fi ètè èké sọ̀rọ̀ búburú gbogbo sí yín nítorí mi. 12 (H)Ẹ yọ̀, kí ẹ̀yin sì fò fún ayọ̀, nítorí ńlá ni èrè yín ní ọ̀run, nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ń bẹ ṣáájú yín.

Iyọ̀ àti ìmọ́lẹ̀

13 (I)“Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé. Ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu kí ni a ó fi mú un dùn? Kò tún wúlò fún ohunkóhun mọ́, bí kò ṣe pé kí a dàánù, kí ó sì di ohun tí ènìyàn ń fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

14 (J)“Ẹyin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè kò lè fi ara sin. 15 (K)Bẹ́ẹ̀ ni a kì í tan fìtílà tán, kí a sì gbé e sí abẹ́ òṣùwọ̀n; bí kò ṣe sí orí ọ̀pá fìtílà, a sì tan ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú ilé. 16 Bákan náà, ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín kí ó mọ́lẹ̀ níwájú ènìyàn, kí wọ́n lè máa rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run lógo.

Ìmúṣẹ òfin

17 “Ẹ má ṣe rò pé, èmí wá láti pa òfin àwọn wòlíì run, èmi kò wá láti pa wọn rẹ́, bí kò ṣe láti mú wọn ṣẹ. 18 (L)Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, títí ọ̀run òun ayé yóò fi kọjá, ààmì kínkínní tí a fi gègé ṣe kan kì yóò parẹ́ kúrò nínú gbogbo òfin tó wà nínú ìwé òfin títí gbogbo rẹ̀ yóò fi wá sí ìmúṣẹ. 19 (M)Ẹnikẹ́ni ti ó bá rú òfin tí ó tilẹ̀ kéré jùlọ, tí ó sì kọ́ ẹlòmíràn láti ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóò kéré jùlọ ní ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe wọ́n, tí ó sì ń kọ́ wọn, ni yóò jẹ́ ẹni ńlá ní ìjọba ọ̀run. 20 Nítorí náà ni mo ti wí fún yín pé àfi bí òdodo yín bá ju ti àwọn Farisi àti ti àwọn olùkọ́ òfin lọ, dájúdájú ẹ̀yin kì yóò le wọ ìjọba ọ̀run.

Ìpànìyàn

21 (N)“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ẹnikẹ́ni tí ó bá pànìyàn yóò wà nínú ewu ìdájọ́.’ 22 Ṣùgbọ́n èmi wí fún un yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bínú sí arákùnrin rẹ̀ yóò wà nínú ewu ìdájọ́. Ẹnikẹ́ni ti ó ba wí fun arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ráákà,’ yóò fi ara hàn níwájú ìgbìmọ̀ àwọn àgbà Júù; ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá wí pé, ‘Ìwọ wèrè!’ yóò wà nínú ewu iná ọ̀run àpáàdì.

23 “Nítorí náà, nígbà tí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ wá síwájú pẹpẹ, bí ìwọ bá sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ̀ ni ohùn kan nínú sí ọ. 24 Fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níwájú pẹpẹ. Ìwọ kọ́kọ́ lọ ṣe ìlàjà láàrín ìwọ àti arákùnrin rẹ̀ na. Lẹ́yìn náà, wá kí ó sì fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀.

25 (O)“Bá ọ̀tá rẹ làjà kánkán, ẹni tí ó ń gbé ọ lọ sílé ẹjọ́. Ṣe é nígbà ti ó wà ní ọ̀nà pẹ̀lú rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò fà ọ́ lé onídàájọ́ lọ́wọ́, onídàájọ́ yóò sí fá ọ lé àwọn ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́, wọ́n a sì sọ ọ́ sínú túbú. 26 Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, ìwọ kì yóò jáde kúrò níbẹ̀ títí tí ìwọ yóò fi san ẹyọ owó kan tí ó kù.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.