Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Gẹnẹsisi 16-17

Hagari àti Iṣmaeli

16 Sarai, aya Abramu kò bímọ fún un, ṣùgbọ́n ó ní ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin ará Ejibiti kan tí ń jẹ́ Hagari. Nítorí náà, Sarai wí fún Abramu pé, “Kíyèsi i Olúwa ti sé mi ní inú, èmi kò sì bímọ, wọlé tọ ọmọ ọ̀dọ̀ mi lọ, bóyá èmi yóò le ti ipasẹ̀ rẹ̀ ní ọmọ.”

Abramu sì gba ohun tí Sarai sọ. Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí Abramu ti ń gbé ni Kenaani ni Sarai mú ọmọbìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Hagari, tí í ṣe ará Ejibiti fún Abramu ọkọ rẹ̀ láti fi ṣe aya. Abramu sì bá Hagari lòpọ̀, ó sì lóyún.

Nígbà tí ó sì ti mọ̀ pé òun lóyún, ó bẹ̀rẹ̀ sì ní kẹ́gàn ọ̀gá rẹ̀. Nígbà náà ni Sarai wí fún Abramu pé, “Ìwọ ni ó jẹ́ kí ẹ̀gbin yìí máa jẹ mí, mo fa ọmọ ọ̀dọ̀ mi lé ọ lọ́wọ́, nígbà tí ó sì rí i pé òun lóyún, mo di ẹni ẹ̀gàn ní ojú rẹ̀. Kí Olúwa kí ó ṣe ìdájọ́ láàrín tèmi tìrẹ.”

Abramu dáhùn pé, “Ìwọ ló ni ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣe ohunkóhun tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ sí i.” Nígbà náà ni Sarai fi ìyà jẹ Hagari, ó sì sálọ.

Angẹli Olúwa sì rí Hagari ní ẹ̀gbẹ́ ìsun omi ní ijù, ìsun omi tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tí ó lọ sí Ṣuri. Ó sì wí pé, “Hagari, ìránṣẹ́ Sarai, níbo ni o ti ń bọ̀, níbo sì ni ìwọ ń lọ?”

Ó sì dáhùn pé, “Mo ń sálọ kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá mi Sarai ni.”

Angẹli Olúwa sì wí fún un pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ kí o sì tẹríba fún un.” 10 Angẹli Olúwa náà sì fi kún fún un pé, “Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, ìran rẹ kì yóò sì lóǹkà.”

11 Angẹli Olúwa náà sì wí fún un pé,

“Ìwọ ti lóyún, ìwọ yóò sì bí
    ọmọkùnrin kan,
ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Iṣmaeli,
    nítorí tí Olúwa ti rí ìpọ́njú rẹ.
12 Òun yóò jẹ́ oníjàgídíjàgan ènìyàn
    ọwọ́ rẹ̀ yóò wà lára ènìyàn gbogbo,
    ọwọ́ ènìyàn gbogbo yóò sì wà lára rẹ̀,
yóò sì máa gbé ní ìkanra
    pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀.”

13 Ó sì pe orúkọ Olúwa tí o bá sọ̀rọ̀ ní, “Ìwọ ni Ọlọ́run tí ó rí mi,” nítorí tí ó wí pé, “Mo ti ri ẹni tí ó rí mi báyìí.” 14 Nítorí náà ni a ṣe ń pe kànga náà ní Beeri-Lahai-Roi: kànga ẹni alààyè tí ó rí mi. Ó wà ní agbede-méjì Kadeṣi àti Beredi.

15 (A)Hagari sì bí ọmọkùnrin kan fún Abramu, Abramu sì pe orúkọ rẹ̀ ní Iṣmaeli. 16 Abramu jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndín-láàádọ́rùn-ún (86) nígbà tí Hagari bí Iṣmaeli fún un.

Májẹ̀mú Ilà abẹ́ kíkọ

17 Ní ìgbà tí Abramu di ẹni ọ̀kàn-dínlọ́gọ́rùnún (99) ọdún, Olúwa farahàn án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára (Eli-Ṣaddai), máa rìn níwájú mi, kí o sì jẹ́ aláìlábùkù. Èmi yóò sì fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ. Èmi yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀ gidigidi.”

Abramu sì dojúbolẹ̀, Ọlọ́run sì wí fún un pé. “Ní ti èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ nìyí. Ìwọ yóò di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀. (B)A kì yóò pe orúkọ rẹ̀ ní Abramu mọ́, bí kò ṣe Abrahamu, nítorí, mo ti sọ ọ́ di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀. Èmi yóò mú ọ bí si lọ́pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni èmi yóò sì mú ti ara rẹ jáde wá, àwọn ọba pẹ̀lú yóò sì ti inú rẹ jáde. (C)Èmi yóò sì gbé májẹ̀mú mi kalẹ̀ láàrín tèmi tìrẹ, ní májẹ̀mú ayérayé àti láàrín irú-ọmọ rẹ ní ìran-ìran wọn, láti máa ṣe Ọlọ́run rẹ àti ti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ. (D)Gbogbo ilẹ̀ Kenaani níbi tí ìwọ ti ṣe àjèjì ni èmi yóò fi fún ọ àti fún irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ láéláé, Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.”

Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Abrahamu pé, “Ìwọ máa pa májẹ̀mú mi mọ́, ìwọ àti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ àti àwọn ìran tí ó ń bọ̀. 10 (E)Èyí ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ àti ìran rẹ lẹ́yìn rẹ, májẹ̀mú tí ẹ̀yin yóò máa pamọ́. Gbogbo ọkùnrin yín ni a gbọdọ̀ kọ ní ilà. 11 (F)Ẹ̀yin yóò kọ ara yín ní ilà, èyí ni yóò jẹ́ ààmì májẹ̀mú láàrín tèmi tiyín. 12 Ní gbogbo ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn, gbogbo ọkùnrin ni a gbọdọ̀ kọ ni ilà ní ọjọ́ kẹjọ tí a bí wọn, àti àwọn tí a bí ní ilé rẹ, tàbí tí a fi owó rà lọ́wọ́ àwọn àjèjì, àwọn tí kì í ṣe ọmọ rẹ̀. Èyí yóò sì jẹ́ májẹ̀mú láéláé tí yóò wà láàrín Èmi àti irú-ọmọ rẹ. 13 Ìbá à ṣe ẹni tí a bí nínú ilé rẹ, tàbí ẹni tí o fi owó rà, a gbọdọ̀ kọ wọ́n ní ilà; májẹ̀mú mí lára yín yóò jẹ́ májẹ̀mú ayérayé. 14 Gbogbo ọmọkùnrin tí kò bá kọ ilà, tí a kò kọ ní ilà abẹ́, ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ó da májẹ̀mú mi.”

15 Ọlọ́run wí fún Abrahamu pé, “Ní ti Sarai, aya rẹ̀, ìwọ kì yóò pè é ní Sarai mọ́, bí kò ṣe Sara. 16 Èmi yóò bùkún fún un, Èmi yóò sì fun ọ ní ọmọkùnrin kan nípasẹ̀ rẹ̀. Èmi yóò bùkún un, yóò sì di ìyá àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì ti ara rẹ̀ jáde wá.”

17 Abrahamu sì dojúbolẹ̀, ó rẹ́rìn-ín, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “A ó ha bí ọmọ fún ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún? Sara tí í ṣe ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún yóò ha bímọ bí?” 18 Abrahamu sì wí fún Ọlọ́run pé, “Sá à jẹ́ kí Iṣmaeli kí ó wà láààyè lábẹ́ ìbùkún rẹ.”

19 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí pé, “Mo gbọ́, ṣùgbọ́n Sara aya rẹ̀ yóò bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Isaaki, èmi yóò fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní májẹ̀mú ayérayé àti àwọn irú-ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀. 20 Ṣùgbọ́n ní ti Iṣmaeli, mo gbọ́ ohun tí ìwọ wí, èmi yóò bùkún fún un nítòótọ́, èmi ó sì mú un bí sí i, yóò sì pọ̀ sí i, òun yóò sì jẹ́ baba fún àwọn ọmọ ọba méjìlá, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá. 21 Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú Isaaki, ẹni tí Sara yóò bí fún ọ ni ìwòyí àmọ́dún.” 22 Nígbà tí ó ti bá Abrahamu sọ̀rọ̀ tán, Ọlọ́run sì gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

23 Ní ọjọ́ náà gan an ni Abrahamu mú Iṣmaeli ọmọ rẹ̀ àti àwọn ẹrú tí a bí ní ilé rẹ̀ àti àwọn tí ó fi owó rà, ó sì kọ wọ́n ní ilà. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì kọ gbogbo ọkùnrin tí ń bẹ ní ilé rẹ̀ ní ilà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ọlọ́run. 24 Abrahamu jẹ́ ẹni ọ̀kàn-dínlọ́gọ́rùnún (99) ọdún nígbà tí a kọ ọ́ ní ilà. 25 Iṣmaeli ọmọ rẹ̀ jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlá (13). 26 Ní ọjọ́ náà gan an ni a kọ Abrahamu ní ilà pẹ̀lú Iṣmaeli ọmọ rẹ̀ ọkùnrin. 27 Àti gbogbo ọkùnrin tí ó wà ní ilé Abrahamu, ìbá à ṣe èyí tí a bí ní ilé rẹ̀ tàbí èyí tí a fi owó rà lọ́wọ́ àlejò ni a kọ ní ilà pẹ̀lú rẹ̀.

Matiu 5:27-48

Panṣágà

27 (A)“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.’ 28 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obìnrin kan ní ìwòkuwò, ti bà ṣe panṣágà nínú ọkàn rẹ̀. 29 Bí ojú ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè fún ọ kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé, ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì. 30 Bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e kúrò, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì.

Ìkọ̀sílẹ̀

31 (B)“A ti wí pẹ̀lú pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, jẹ́ kí ó fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀ lé e lọ́wọ́.’ 32 Ṣùgbọ́n èmi sọ èyí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìṣe pé nítorí àgbèrè, ó mú un ṣe àgbèrè, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé ẹni tí a kọ̀ ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà.

Ìbúra

33 (C)“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ búra èké bí kò ṣe pé kí ìwọ kí ó mú ìbúra rẹ̀ fún Olúwa ṣẹ.’ 34 Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín, ẹ má ṣe búra rárá: ìbá à ṣe fífi ọ̀run búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọ́run ni. 35 Tàbí fi ayé búra, nítorí àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run ni; tàbí Jerusalẹmu, nítorí olórí ìlú ọba Ńlá ni. 36 Má ṣe fi orí rẹ búra, nítorí ìwọ kò lè sọ irun ẹyọ kan di funfun tàbí di dúdú. 37 Ẹ jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ ni yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àti bẹ́ẹ̀ kọ́ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́, ohunkóhun tí ó ba ju ìwọ̀nyí lọ, wá láti ọ̀dọ̀ ẹni ibi.

Ojú fún ojú

38 (D)“Ẹ̀yin tí gbọ́ bí òfin tí wí pé, ‘Ojú fún ojú àti eyín fún eyín.’ 39 Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ má ṣe tako ẹni ibi. Bí ẹnìkan bá gbá ọ lẹ́rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí ẹ̀rẹ̀kẹ́ òsì sí olúwa rẹ̀ pẹ̀lú. 40 Bí ẹnìkan bá fẹ́ gbé ọ lọ sílé ẹjọ́, tí ó sì fẹ́ gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, jọ̀wọ́ agbádá rẹ fún un pẹ̀lú. 41 Bí ẹni kan bá fẹ́ fi agbára mú ọ rìn ibùsọ̀ kan, bá a lọ ní ibùsọ̀ méjì. 42 Fi fún ẹni tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń fẹ́ wín lọ́wọ́ rẹ, má ṣe mú ojú kúrò.

Fẹ́ràn ọ̀tá rẹ

43 (E)“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ, kí ìwọ sì kórìíra ọ̀tá rẹ̀.’ 44 Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín. 45 Kí ẹ̀yin lè jẹ́ ọmọ Baba yín ti ń bẹ ní ọ̀run. Ó mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sára ènìyàn búburú àti ènìyàn rere, ó rọ̀jò fún àwọn olódodo àti fún àwọn aláìṣòdodo. 46 Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn yín nìkan, èrè kí ni ẹ̀yin ní? Àwọn agbowó òde kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́? 47 Àti bí ó bá sì jẹ́ pé kìkì àwọn arákùnrin yín nìkan ni ẹ̀yin ń kí, kín ni ẹ̀yin ń ṣe ju àwọn mìíràn lọ? Àwọn kèfèrí kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí? 48 Nítorí náà, ẹ jẹ́ pípé, gẹ́gẹ́ bí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ṣe jẹ́ pípé.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.