Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Eksodu 1-3

A ni àwọn ọmọ Israẹli lára

(A)Ìwọ̀nyí ni àwọn orúkọ ọmọ Israẹli tí wọ́n bá Jakọbu lọ sí Ejibiti, ẹnìkọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ìdílé rẹ̀:

Reubeni, Simeoni, Lefi àti Juda;

Isakari, Sebuluni àti Benjamini;

Dani àti Naftali;

Gadi àti Aṣeri.

(B)Àwọn ìran Jakọbu sì jẹ́ àádọ́rin ní àpapọ̀; Josẹfu sì ti wà ní Ejibiti.

Wàyí o, Josẹfu àti gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìran náà kú, (C)Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli ń bí sí i, wọ́n ń pọ̀ sí i gidigidi, wọ́n kò sì ní òǹkà tí ó fi jẹ́ pé wọ́n kún ilẹ̀ náà.

(D)Nígbà náà ni ọba tuntun mìíràn tí kò mọ Josẹfu jẹ ní ilẹ̀ Ejibiti. Ó sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ “Ẹ wò ó, àwọn ará Israẹli ti pọ̀ ní iye àti agbára jù fún wa. 10 (E)Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí láti dá wọn lẹ́kun, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ wọn yóò túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Bí ogun bá sì bẹ́ sílẹ̀, wọn yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá wa, wọn yóò sì da ojú ìjà kọ wá, wọn yóò sì sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ yìí.”

11 Nítorí náà, wọ́n yan àwọn ọ̀gá akóniṣiṣẹ́ lé wọn lórí láti máa ni wọ́n lára pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n sì kọ́ Pitomi àti Ramesesi gẹ́gẹ́ bí ìlú ìṣúra pamọ́ sí fún Farao. 12 Ṣùgbọ́n bí a ti ń ni wọ́n lára tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pọ̀ sí i, tiwọn sì ń tànkálẹ̀; Nítorí náà, àwọn ará Ejibiti bẹ̀rù nítorí àwọn ará Israẹli. 13 Àwọn ará Ejibiti sì mú àwọn ọmọ Israẹli sìn ní àsìnpa. 14 Wọ́n mú wọn gbé ìgbé ayé kíkorò nípa iṣẹ́ bíríkì àti àwọn onírúurú iṣẹ́ oko; àwọn ará Ejibiti ń lò wọ́n ní ìlòkulò.

15 Ọba Ejibiti sọ fún àwọn agbẹ̀bí Heberu ti orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣifura àti Pua pé: 16 “Nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbẹ̀bí àwọn obìnrin Heberu, tí ẹ sì kíyèsi wọn lórí ìkúnlẹ̀ ìrọbí wọn, bí ó bá jẹ́ ọkùnrin ni ọmọ náà, ẹ pa á; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ obìnrin, ẹ jẹ́ kí ó wà láààyè.” 17 Ṣùgbọ́n àwọn agbẹ̀bí bẹ̀rù Ọlọ́run, wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọba Ejibiti ti wí fún wọn; wọ́n jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin wà láààyè. 18 Ọba Ejibiti pe àwọn agbẹ̀bí ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ṣe èyí? Èéṣe tí ẹ̀yin fi dá àwọn ọmọkùnrin si?”

19 Àwọn agbẹ̀bí náà sì dá Farao lóhùn pé, “Àwọn obìnrin Heberu kò rí bí àwọn obìnrin Ejibiti, wọ́n ní agbára, wọ́n sì ti máa ń bí ọmọ kí àwọn agbẹ̀bí tó dé ọ̀dọ̀ wọn.”

20 Nítorí náà Ọlọ́run ṣàánú fún àwọn agbẹ̀bí náà, àwọn ọmọ Israẹli sì ń le sí i, wọ́n sì ń pọ̀ sí i jọjọ. 21 Nítorí pé àwọn agbẹ̀bí bẹ̀rù Ọlọ́run, Ọlọ́run sì fún wọn ni ìdílé tiwọn.

22 (F)Nígbà náà ni Farao pàṣẹ yìí fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ pé; “Gbogbo ọmọkùnrin tí a bí ni kí ẹ gbé jù sínú odò Naili, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọbìnrin ni kí ẹ jẹ́ kí wọn ó wà láààyè.”

Ìbí Mose

Ó sì ṣe, ọkùnrin ará ilé Lefi kan fẹ́ ọmọbìnrin ará Lefi kan ni ìyàwó. (G)Obìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Nígbà tí ó rí í pé ọmọ náà rẹwà, ó gbé ọmọ náà pamọ́ fún oṣù mẹ́ta. Ṣùgbọ́n nígbà tí kò le è gbé e pamọ́ mọ́, ó fi ewé papirusi hun apẹ̀rẹ̀, ó sì fi ọ̀dà àti òjé igi sán apẹ̀rẹ̀ náà. Ó sì tẹ́ ọmọ náà sínú rẹ̀, ó sì gbe é sí inú eèsún ni etí odò Naili. Arábìnrin rẹ̀ dúró ni òkèèrè láti wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà.

(H)Nígbà náà ni ọmọbìnrin Farao sọ̀kalẹ̀ wá sí etí odò Naili láti wẹ̀, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì ń rìn ni etí bèbè odò. Ó sì ri apẹ̀rẹ̀ náà ni àárín eèsún, ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin kan láti lọ gbé e wá, ó ṣí i, ó sì rí ọmọ náà. Ọmọ náà ń sọkún, àánú ọmọ náà sì ṣe é. Ó wí pé “Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Heberu ni èyí.”

Nígbà náà ni arábìnrin rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ ọmọbìnrin Farao pé “Ṣé kí èmi lọ wá ọ̀kan lára àwọn obìnrin Heberu wá fún ọ láti bá ọ tọ́jú ọmọ náà?”

Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni; lọ.” Arábìnrin náà sì lọ, ó sì pe ìyá ọmọ náà wá, Ọmọbìnrin Farao sì wí fún un pé, “Gba ọmọ yìí kí o sì tọ́jú rẹ̀ fún mi, èmi yóò san owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ fún ọ” Ọmọbìnrin náà sì gbé ọmọ náà lọ, ó sì tọ́jú rẹ̀. 10 Nígbà tí ọmọ náà sì dàgbà, ó mú un tọ ọmọbìnrin Farao wá, ó sì di ọmọ rẹ̀. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Mose, ó wí pé “Nítorí tí mo fà á jáde nínú omi.”

Mose sálọ sí Midiani

11 (I)Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Mose ti dàgbà, ó jáde lọ sí ibi ti àwọn ènìyàn rẹ̀ wà, ó ń wò wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ líle wọn, O ri ará Ejibiti tí ń lu ará Heberu, ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn rẹ̀. 12 (J)Ó wo ìhín, ó wo ọ̀hún, nígbà tí kò rí ẹnìkankan, ni ó bá pa ará Ejibiti náà, ó sì bò ó mọ́ inú iyanrìn. 13 Ní ọjọ́ kejì, ó jáde lọ, ó rí àwọn ará Heberu méjì tí wọ́n ń jà. Ó béèrè lọ́wọ́ èyí tí ó jẹ̀bi pé “Èéṣe tí ìwọ fi ń lu Heberu arákùnrin rẹ?”

14 (K)Ọkùnrin náà sì dáhùn pé “Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti onídàájọ́ lórí wa? Ṣé ìwọ fẹ́ pa mí bí o ti pa ará Ejibiti?” Nígbà náà ni ẹ̀rù ba Mose, ó sì wí pé, “lóòótọ́ ni ọ̀ràn yìí ti di mí mọ̀.”

15 (L)Nígbà ti Farao sì gbọ́ nípa èyí, ó wá ọ̀nà láti pa Mose, ṣùgbọ́n Mose sá kúrò ní àrọ́wọ́tó o Farao, ó lọ sí Midiani láti máa gbé, nígbà tí ó dé bẹ̀, ó jókòó ni ẹ̀bá a kànga kan. 16 Ó sì ṣe, àlùfáà Midiani kan ni àwọn ọmọbìnrin méje, wọn sì wá láti pọn omi kún ọpọ́n ìmumi fún ẹran ọ̀sìn baba wọn. 17 Àwọn darandaran kan wá, wọ́n sì lé wọn sẹ́yìn, ṣùgbọ́n Mose dìde láti gbà wọ́n sílẹ̀ àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fún ẹran wọn ní omi.

18 Nígbà ti àwọn ọmọbìnrin náà padà dé ọ̀dọ̀ Reueli baba wọn, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé “Èéṣe tí ẹ̀yin fi tètè dé ni òní?”

19 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ará Ejibiti kan ni ó gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn darandaran, ó tilẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti fa omi àti láti fún agbo ẹran ní omi.”

20 Ó sọ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, “Níbo ni ó wà? Èéṣe ti ẹ fi fi ọkùnrin náà sílẹ̀? Ẹ pè é wá jẹun.”

21 Mose gbà láti dúró lọ́dọ̀ ọkùnrin náà, ẹni tí o fi Sippora, ọmọbìnrin rẹ̀ fún Mose láti fi ṣe aya. 22 Ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Gerṣomu, ó wí pé “Èmi ń ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì.”

23 Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ọba Ejibiti kú. Àwọn ará Israẹli ń kérora ní oko ẹrú wọn, wọ́n ń ké fún ìrànlọ́wọ́ nítorí oko ẹrú tí wọ́n wà, igbe wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. 24 (M)Ọlọ́run gbọ́ igbe wọn, Ó sì rántí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Abrahamu, Isaaki àti pẹ̀lú Jakọbu. 25 Nítorí náà, Ọlọ́run bojú wo àwọn ará Israẹli, Ó sì wà láti gbà wọ́n sílẹ̀.

Mose àti igbó tí ń jó

(N)Ní ọjọ́ kan nígbà tí Mose ń ṣọ́ agbo ẹran Jetro baba ìyàwó rẹ̀, àlùfáà Midiani. Ó da agbo ẹran náà lọ sí ọ̀nà jíjìn nínú aginjù. Ó dé Horebu, òkè Ọlọ́run. (O)Níbẹ̀ ni angẹli Olúwa ti yọ sí i nínú ọ̀wọ́-iná tí ń jó láàrín igbó. Mose rí i pé iná ń jó nínú igbó ṣùgbọ́n igbó kò run Nígbà náà ni Mose sọ pé, “Èmi yóò lọ wo ohun ìyanu yìí, ìdí tí iná kò fi jó igbó run.”

Nígbà tí Olúwa rí i pe Mose ti lọ láti lọ wò ó, Ọlọ́run ké pè é láti àárín igbó náà, “Mose! Mose!”

Mose sì dáhùn ó wí pé, “Èmi nìyìí.”

(P)Olúwa sì wí fún Mose pé, “Má ṣe súnmọ́ ìhín yìí, bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni.” (Q)Nígbà náà ní ó wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run baba rẹ, Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu.” Nítorí ìdí èyí, Mose sì pa ojú rẹ̀ mọ́, nítorí ó bẹ̀rù láti bojú wo Ọlọ́run.

Ọlọ́run si wí pé, “Èmí ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi ní ilẹ̀ Ejibiti, mo sì ti gbọ́ ohùn igbe wọn nítorí àwọn akóniṣiṣẹ́ wọn. Ìyà tí ń jẹ wọ́n sì kan mi lára. Èmi sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti, àti láti mú wọn gòkè kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ tí ó dára tí ó sì ní ààyè, àní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; ibùgbé àwọn ará Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, wò ó, igbe àwọn ará Israẹli ti dé ọ̀dọ̀ mi, Èmi sì ti rí bí àwọn ará Ejibiti ti ṣe ń gbà ń jẹ wọ́n ní ìyà. 10 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, lọ, Èmi yóò rán ọ sí Farao láti kó àwọn ènìyàn Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.”

11 Ṣùgbọ́n Mose wí fún Ọlọ́run pé, “Ta ni èmi, tí èmi yóò tọ Farao lọ, ti èmi yóò sì kó àwọn ará Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti?”

12 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Mose pé, “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ. Èyí ni yóò jẹ́ ààmì fún ọ, tí yóò fihàn pé Èmi ni ó rán ọ lọ; Nígbà tí ìwọ bá kó àwọn ènìyàn náà jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ẹ̀yin yóò sin Ọlọ́run ni orí òkè yìí.”

13 Mose sì wí fún Ọlọ́run pé, “Bí mo bá tọ àwọn ará Israẹli lọ tí mo sì sọ fún wọn pé, ‘Ọlọ́run àwọn baba yín ni ó rán mi sí i yín,’ tí wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ mi pé, ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni èmi yóò sọ fún wọn ní ìgbà náà?”

14 Ọlọ́run sì sọ fún Mose pé, “èmi ni ti ń jẹ́ èmi ni. Èyí ni ìwọ yóò sọ fún àwọn ará Israẹli: ‘èmi ni ni ó rán mi sí i yín.’ ”

15 Ọlọ́run sì wí fún Mose pẹ̀lú pé, “Báyìí ni kí ìwọ sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín; Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu; ni ó rán mi sí i yín.’

“Èyí ni orúkọ Mi títí ayérayé,
    orúkọ ti ẹ ó fi máa rántí Mi
    láti ìran dé ìran.

16 “Lọ, kó àwọn àgbàgbà Israẹli jọ, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín, Ọlọ́run Abrahamu, ti Isaaki, àti ti Jakọbu; ni ó farahàn mi, ó sì wí pé: Lóòótọ́ èmi ti ń bojú wò yín, èmi sì ti rí ohun tí wọ́n ṣe sí i yín ni ilẹ̀ Ejibiti. 17 Èmi sì ti ṣe ìlérí láti mú un yín jáde kúrò nínú ìpọ́njú yín ni ilẹ̀ Ejibiti wá sí ilẹ̀ Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi; ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin.’

18 “Àwọn àgbàgbà Israẹli yóò fetísílẹ̀ sí ohùn rẹ. Nígbà náà ni ìwọ, àti àwọn àgbàgbà yóò jọ tọ ọba Ejibiti lọ, ẹ ó sì wí fún un pé, ‘Olúwa, Ọlọ́run àwọn ará Heberu ti pàdé wa. Jẹ́ kí a lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú aginjù láti lọ rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run.’ 19 Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé ọba Ejibiti kò ní jẹ́ kí ẹ lọ bí kò ṣe pé ọwọ́ ńlá Ọlọ́run wà ni ara rẹ̀. 20 Nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mí láti lu àwọn ará Ejibiti pẹ̀lú gbogbo ohun ìyanu tí èmi yóò ṣe ni àárín wọn. Lẹ́yìn náà, òun yóò jẹ́ kí ẹ máa lọ.

21 “Èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ bá ojúrere àwọn ará Ejibiti pàdé. Tí yóò fi jẹ́ pé ti ẹ̀yin bá ń lọ, ẹ kò ní lọ ní ọwọ́ òfo. 22 Gbogbo àwọn obìnrin ni ó ní láti béèrè lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò wọn àti gbogbo àwọn obìnrin ti ń gbé nínú ilé rẹ fún ohun fàdákà àti wúrà àti fún aṣọ, èyí ti ẹ̀yin yóò wọ̀ sí ọrùn àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin. Báyìí ni ẹ̀yin yóò sì kó ẹrù àwọn ará Ejibiti.”

Matiu 14:1-21

A bẹ́ Johanu Onítẹ̀bọmi lórí

14 (A)Ní àkókò náà ni Herodu ọba tetrarki gbọ́ nípa òkìkí Jesu, ó wí fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Dájúdájú Johanu onítẹ̀bọmi ni èyí, ó jíǹde kúrò nínú òkú. Ìdí nìyí tí ó fi ní agbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí.”

(B)Nísinsin yìí Herodu ti mú Johanu, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì fi sínú túbú, nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀, nítorí Johanu onítẹ̀bọmi ti sọ fún Herodu pé, “Kò yẹ fún ọ láti fẹ́ obìnrin náà.” (C)Herodu fẹ́ pa Johanu, ṣùgbọ́n ó bẹ̀rù àwọn ènìyàn nítorí gbogbo ènìyàn gbàgbọ́ pé wòlíì ni.

Ní ọjọ́ àsè ìrántí ọjọ́ ìbí Herodu, ọmọ Herodia obìnrin jó dáradára, ó sì tẹ́ Herodu lọ́run gidigidi. Nítorí náà ni ó ṣe fi ìbúra ṣe ìlérí láti fún un ní ohunkóhun ti ó bá béèrè fún. Pẹ̀lú ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ó béèrè pé, “Fún mi ni orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú àwopọ̀kọ́”. Inú ọba bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí ìbúra rẹ̀ àti kí ojú má ba à tì í níwájú àwọn àlejò tó wà ba jẹ àsè, ó pàṣẹ pé kí wọ́n fún un gẹ́gẹ́ bí o ti fẹ́. 10 Nítorí náà, a bẹ́ orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú ilé túbú. 11 A sì gbé orí rẹ̀ jáde láti fi fún ọmọbìnrin náà nínú àwopọ̀kọ́, òun sì gbà á, ó gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ. 12 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu wá gba òkú rẹ̀, wọ́n sì sin ín. Wọ́n sì wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jesu.

Jesu bọ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn

13 (D)Nígbà tí Jesu gbọ́ ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó kúrò níbẹ̀, ó bá ọkọ̀ ojú omi lọ sí ibi kọ́lọ́fín kan ní èbúté láti dá wà níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fi ẹsẹ̀ rìn tẹ̀lé e láti ọ̀pọ̀ ìlú wọn. 14 Nígbà ti Jesu gúnlẹ̀, tí ó sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, inú rẹ̀ yọ́ sí wọn, ó sì mú àwọn aláìsàn láradá.

15 Nígbà ti ilẹ̀ ń ṣú lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí pé, “Ibi yìí jìnnà sí ìlú ilẹ̀ sì ń ṣú lọ. Rán àwọn ènìyàn lọ sí àwọn ìletò kí wọ́n lè ra oúnjẹ jẹ.”

16 Ṣùgbọ́n Jesu fèsì pé, “Kò nílò kí wọ́n lọ kúrò. Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.”

17 Wọ́n sì dalóhùn pé, “Àwa kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì lọ níhìn-ín.”

18 Ó wí pé, “Ẹ mú wọn wá fún mi níhìn-ín yìí.” 19 (E)Lẹ́yìn náà, ó wí fún àwọn ènìyàn kí wọ́n jókòó lórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì. Ó gbé ojú rẹ̀ sí ọ̀run. Ó béèrè ìbùkún Ọlọ́run lórí oúnjẹ náà, Ó sì bù ú, ó sì fi àkàrà náà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti pín in fún àwọn ènìyàn. 20 Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó. Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kó àjẹkù jọ, ó kún agbọ̀n méjìlá. 21 Iye àwọn ènìyàn ni ọjọ́ náà jẹ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (5,000) ọkùnrin, Láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.