Add parallel Print Page Options

Ohun èlò fun Àgọ́

(A)Mose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún Olúwa ní ti:

“wúrà, fàdákà àti idẹ;

aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára;

àti irun ewúrẹ́;

awọ àgbò tí a kùn ní pupa àti awọ màlúù;

odò igi kasia;

òróró olifi fún títan iná;

olóòórùn fún òróró ìtasórí, àti fún tùràrí dídùn;

òkúta óníkìsì àti òkúta tí a tò sí ẹ̀wù efodu àti ìgbàyà.

Read full chapter