Add parallel Print Page Options

Àwọn ìlànà ọjọ́ ìsinmi

35 Mose pe gbogbo ìjọ Israẹli ó sì wí fún wọn pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ohun ti Olúwa ti pàṣẹ fún un yín láti ṣe: (A)Fún ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje yóò jẹ́ ọjọ́ mímọ́ fún yín, ọjọ́ ìsinmi ni sí Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ni ọjọ́ náà ní a ó pa. Ẹ má ṣe dáná kankan ní ibùgbé yín ní ọjọ́ ìsinmi.”

Ohun èlò fun Àgọ́

(B)Mose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún Olúwa ní ti:

“wúrà, fàdákà àti idẹ;

aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára;

àti irun ewúrẹ́;

awọ àgbò tí a kùn ní pupa àti awọ màlúù;

odò igi kasia;

òróró olifi fún títan iná;

olóòórùn fún òróró ìtasórí, àti fún tùràrí dídùn;

òkúta óníkìsì àti òkúta tí a tò sí ẹ̀wù efodu àti ìgbàyà.

10 “Gbogbo ẹni tí ó ní ọgbọ́n láàrín yín, kí ó wa, kí ó sì wá ṣe gbogbo ohun tí Olúwa ti pàṣẹ:

11 “àgọ́ náà pẹ̀lú àgọ́ rẹ àti ìbòrí rẹ̀, kọ́kọ́rọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, ọ̀wọ́n rẹ̀ àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀;

12 Àpótí náà pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀, ìbò àánú àti aṣọ títa náà tí ó ṣíji bò ó;

13 Tábìlì náà pẹ̀lú òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti àkàrà ìfihàn náà;

14 Ọ̀pá fìtílà tí ó wà fún títanná pẹ̀lú ohun èlò rẹ̀, fìtílà àti òróró fún títanná;

15 Pẹpẹ tùràrí náà pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀, òróró ìtasórí àti tùràrí dídùn;

aṣọ títa fún ọ̀nà ìlẹ̀kùn ní ẹnu-ọ̀nà sí àgọ́ náà;

16 Pẹpẹ ẹbọ sísun pẹ̀lú ojú ààrò idẹ rẹ̀, òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀;

agbada idẹ pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀;

17 aṣọ títa ti àgbàlá pẹ̀lú, ọ̀wọ́n àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀ àti aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà;

18 Èèkàn àgọ́ náà fún àgọ́ náà àti fún àgbàlá àti okùn wọn;

19 aṣọ híhun láti ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́ aṣọ mímọ́ fún Aaroni àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n sìn bí àlùfáà.”

20 Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli sì kúrò níwájú Mose, 21 Olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ àti ẹni tí ọkàn rẹ̀ gbé sókè wá, wọ́n sì mú ọrẹ fún Olúwa, fún iṣẹ́ àgọ́ àjọ, fún gbogbo ìsìn rẹ̀ àti fún aṣọ mímọ́ náà. 22 Gbogbo àwọn tí ó fẹ́, ọkùnrin àti obìnrin, wọ́n wá wọ́n sì mú onírúurú ìlẹ̀kẹ̀ wúrà: òrùka etí, òrùka àti ọ̀ṣọ́. Gbogbo wọn mú wúrà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ wá fún Olúwa. 23 Olúkúlùkù ẹni tí ó ni aṣọ aláró elése àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára, tàbí irun ewúrẹ́, awọ àgbò tí a rì ní pupa tàbí awọ màlúù odò, kí ó mú wọn wá. 24 Àwọn tí ó mú ọrẹ fàdákà tàbí idẹ wá, mú ọrẹ wá fún Olúwa, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ní igi ṣittimu fún ipa kankan nínú iṣẹ́ mú un wá. 25 Gbogbo àwọn obìnrin tí ó ní ọgbọ́n ríran owú pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀, kí ó mú èyí ti ó ti ran wá ti aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó tàbí ti ọ̀gbọ̀ dáradára. 26 Gbogbo àwọn obìnrin tí ó fẹ́, tí ó sì ní ọgbọ́n ń ran òwú irun ewúrẹ́ 27 Àwọn olórí mú òkúta óníkìsì wá láti tò ó lórí ẹ̀wù efodu àti ìgbàyà. 28 Wọ́n sì tún mú olóòórùn àti òróró olifi wá fún títanná àti fún òróró ìtasórí àti fún tùràrí dídùn. 29 Gbogbo àwọn ènìyàn Israẹli ọkùnrin àti obìnrin ẹni tí ó fẹ́ mú ọrẹ àtinúwá fún Olúwa fún gbogbo iṣẹ́ tí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn láti ṣe nípasẹ̀ Mose.

Besaleli àti Oholiabu

30 (C)Nígbà náà ni Mose wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Wò ó, Olúwa ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, 31 Ó sì ti fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún un, pẹ̀lú ọgbọ́n, òye, ìmọ̀ àti gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà 32 Láti máa ṣe aláràbarà iṣẹ́ ní ti wúrà, fàdákà àti idẹ, 33 láti gbẹ́ òkúta àti láti tò ó, láti fún igi àti láti ṣiṣẹ́ ni gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. 34 Ó sì fún òun àti Oholiabu ọmọ Ahisamaki ti ẹ̀yà Dani, ni agbára láti kọ́ àwọn tókù. 35 Ó sì fi ọgbọ́n kún wọn láti ṣe gbogbo onírúurú iṣẹ́, ti oníṣọ̀nà, ti ayàwòrán, ti aránsọ, ti aláṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ní ọ̀gbọ̀ dáradára àti ti ahunṣọ, gbogbo èyí tí ọ̀gá oníṣẹ́-ọnà àti ayàwòrán ń ṣe. 36 Besaleli, Oholiabu àti olúkúlùkù ọlọ́gbọ́n ẹni tí Olúwa tí fún ní ọgbọ́n àti òye láti mọ bí a ti í ṣe gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ ni kí wọn ṣe iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ.”

Mose sì pe Besaleli àti Oholiabu àti gbogbo ọlọ́gbọ́n ènìyàn ẹni tí Olúwa ti fún ni agbára àti gbogbo ẹni tí ó fẹ́ láti wá sé iṣẹ́ náà. Wọ́n gba gbogbo ọrẹ tí àwọn ọmọ Israẹli ti mú wá lọ́wọ́ Mose fún kíkọ́ ibi mímọ́ náà. Àwọn ènìyàn sì ń mú ọrẹ àtinúwá wá ní àràárọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣẹ́-ọnà tí wọn ń ṣe gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀. Mose sì wí pé, “Àwọn ènìyàn mú púpọ̀ wá fún ṣíṣe iṣẹ́ náà ju bi Olúwa ti pa á láṣẹ láti ṣe lọ.”

Mose sì pàṣẹ, wọ́n sì rán iṣẹ́ yìí sí gbogbo ibùdó: “Kí ọkùnrin tàbí obìnrin má ṣe ṣe ohun kankan bí ọrẹ fún ibi mímọ́ náà mọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni a dá àwọn ènìyàn lẹ́kun láti mú un wá sí i, nítorí ohun tí wọ́n ti ní ti ju ohun tí wọn fẹ́ fi ṣe gbogbo iṣẹ́ náà lọ.

Àgọ́ náà

(D)Gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin láàrín àwọn òṣìṣẹ́ ni wọ́n ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú aṣọ títa mẹ́wàá ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, tí aṣọ aláró, ti elése àlùkò àti ti òdòdó, pẹ̀lú àwọn kérúbù ṣe iṣẹ́ sí wọn nípa ọgbọ́n iṣẹ́ ọnà. Gbogbo aṣọ títa náà ni kí ó jẹ́ ìwọ̀n kan náà: ìgbọ̀nwọ́ méjì-dínlọ́gbọ̀n ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ni fífẹ̀. 10 Aṣọ títa márùn-ún ni kí a so papọ̀ mọ́ ara wọn, àti aṣọ títa márùn-ún ni kí a so papọ̀ mọ́ ara wọn. 11 Ìwọ yóò ṣì ṣe ajábó aṣọ aláró sí aṣọ títa kan láti ìṣẹ́tí rẹ̀ wá níbi ìsopọ̀, àti bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìwọ yóò ṣe ni etí ìkangun aṣọ títa kejì, ni ibi ìsopọ̀ kejì. 12 Àádọ́ta ajábó ní ó pa lára aṣọ títa kan, àti àádọ́ta ajábó ni ó sì lò pa ní etí aṣọ títa tí ó wà ní ìsolù kejì, ajábó náà sì wà ní ọ̀kánkán ara wọn. 13 Ó sì ṣe àádọ́ta ìkọ́ wúrà, ó sì lò ìkọ́ wọ̀n-ọn-nì láti fi aṣọ títa kan kọ́ èkejì, bẹ́ẹ̀ ó sì di odidi àgọ́ kan.

14 Ìwọ ó sì ṣe aṣọ títa irun ewúrẹ́ láti fi ṣe ìbò sórí àgọ́ náà—aṣọ títa mọ́kànlá ni ìwọ ó ṣe é. 15 Gbogbo aṣọ títa mọ́kọ̀ọ̀kànlá náà jẹ́ ìwọ̀n kan náà, ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní fífẹ̀. 16 Ó so aṣọ títa márùn-ún pọ̀ mọ́ ara wọn se ọ̀kan, ó sì tún so mẹ́fà tókù mọ́ ara wọn se ọ̀kan. 17 Ó sì pa àádọ́ta ajábó sí ìṣẹ́tí ìkangun aṣọ títa ní apá kan, wọ́n sì tún pa ajábó mìíràn sí ìṣẹ́tí ìkangun aṣọ títa ní apá kejì. 18 Wọ́n ṣe àádọ́ta (50) ìkọ́ idẹ láti so àgọ́ náà pọ̀ kí o lè jẹ́ ọ̀kan. 19 Ó sì ṣe ìbòrí awọ àgbò tí a rì ní pupa fún àgọ́ náà, àti ìbòrí awọ seali sórí rẹ̀.

20 (E)Ó sì ṣe pákó igi kasia tí ó dúró òró fún àgọ́ náà. 21 Ọ̀kọ̀ọ̀kan pákó náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní fífẹ̀, 22 pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ méjì tí ó kọjú sí ara wọn. Wọ́n ṣe gbogbo pákó àgọ́ náà bí èyí. 23 Ó sì ṣe ogún pákó sí ìhà gúúsù àgọ́ náà. 24 Ó sì ṣe ogójì (40) fàdákà ihò ìtẹ̀bọ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ wọn ìtẹ̀bọ̀ méjì fún pákó kọ̀ọ̀kan, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìsàlẹ̀ ìtẹ̀bọ̀. 25 Fún ìhà kejì, ìhà àríwá àgọ́ náà, wọ́n ṣe ogún pákó 26 àti ogójì ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà méjì ní abẹ́ pákó kọ̀ọ̀kan. 27 Ó ṣe pákó mẹ́fà sì ìkangun, ní ìkangun ìhà ìwọ̀-oòrùn àgọ́ náà, 28 pákó méjì ni ìwọ ó ṣe fún igun àgọ́ náà ní ìhà ẹ̀yìn. 29 Ní igun méjèèjì yìí, pákó méjì ni ó wà níbẹ̀ láti ìdí dé orí rẹ̀ wọ́n sì kó wọ́n sí òrùka kan; méjèèjì rí bákan náà. 30 Wọ́n ó sì jẹ́ pákó mẹ́jọ, àti ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà mẹ́rìnlélógún, méjì wà ní ìsàlẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan.

31 Ó sì ṣe ọ̀pá igi kasia márùn-ún fún pákó ìhà kan àgọ́ náà, 32 márùn-ún fún àwọn tí ó wà ní ìhà kejì, márùn-ún fún pákó tí ó wà ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ní ìkangun àgọ́ náà. 33 Wọ́n sì ṣe ọ̀pá àárín tí yóò fi jáde láti ìkangun dé ìkangun ní àárín àwọn pákó náà. 34 Ó sì bo àwọn pákó pẹ̀lú wúrà, wọ́n sì ṣe àwọn òrùka wúrà láti gbá ọ̀pá náà mú. Wọ́n sì tún bo ọ̀pá náà pẹ̀lú wúrà.

35 (F)Ó ṣe aṣọ títa aláró, àti elése àlùkò, àti òdòdó, àti ọ̀gbọ̀ olókùn wẹ́wẹ́ tí í ṣe ọlọ́nà, tí òun ti àwọn kérúbù ni kí á ṣe é. 36 Wọ́n sì ṣe òpó igi ṣittimu mẹ́rin fún un wọ́n sì bò wọ́n pẹ̀lú wúrà. Wọ́n sì ṣe àwọn ìkọ́ wúrà fún wọn, wọ́n sì dá ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà mẹ́rin mẹ́rin fún wọn. 37 Fún ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà wọ́n ṣe aṣọ títa ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdódó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe; 38 Ó sì ṣe òpó márùn-ún pẹ̀lú ìkọ́ wọn. Ó bo orí àwọn òpó náà àti ìgbànú wọn pẹ̀lú wúrà, ó sì fi idẹ ṣe ihò ìtẹ̀bọ̀ wọn márààrùn-ún.

Àpótí náà

37 (G)Besaleli sì fi igi ṣittimu ṣe àpótí náà, ìgbọ̀nwọ́ méjì ààbọ̀ ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni gíga rẹ̀. Ó sì fi ojúlówó wúrà bò ó ní inú àti ní òde, ó sì fi wúrà gbá etí rẹ̀ yíká. Ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún, láti fi wọ́n sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ẹsẹ̀ rẹ̀, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹgbẹ́ kejì. Ó sì fi igi kasia ṣe ọ̀pá, ó sì fi wúrà bò wọ́n. Ó sì fi ọ̀pá náà bọ òrùka ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan àpótí ẹ̀rí náà láti fi gbé e.

Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú; ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní fífẹ̀. Ó sì ṣe kérúbù méjì láti inú wúrà tí a fi òòlù sí igun ìtẹ́ àánú náà. Ó ṣe kérúbù kan ní igun kìn-ín-ní, àti kérúbù kejì sí igun kejì; kí kérúbù náà jẹ́ irú kan náà ní igun méjèèjì pẹ̀lú ìbòrí wọn. Àwọn kérúbù sì na ìyẹ́ apá wọn sókè, tí wọn yóò sì fi ìyẹ́ apá wọn ṣe ibòòji sí orí ìtẹ́ àánú. Àwọn kérúbù náà yóò kọ ojú sí ara wọn, wọn yóò máa wo ọ̀kánkán ìtẹ́.

Tábìlì náà

10 (H)Ó ṣe tábìlì igi ṣittimu ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn, ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní gíga. 11 Ó sì fi ojúlówó wúrà bò ó, ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí i ká. 12 Ó sì ṣe etí kan ní ìbú àtẹ́lẹwọ́ sí i yíká, ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí etí rẹ̀ ká. 13 Ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún tábìlì náà, ìwọ ó sì fi òrùka kọ̀ọ̀kan sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. 14 Ní abẹ́ ìgbátí náà ni àwọn òrùka náà yóò wà, ààyè láti máa fi gbé tábìlì náà. 15 Ó sì fi igi kasia ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì fi wúrà bò wọ́n, láti máa fi wọ́n gbé tábìlì náà. 16 Ó sì ṣe àwọn ohun èlò tí ó wà lórí tábìlì náà ní ojúlówó wúrà, abọ́ rẹ̀, àwo rẹ, àwokòtò rẹ̀ àti ìgò rẹ̀ fún dída ọrẹ mímu jáde.

Ọ̀pá fìtílà náà

17 (I)Ó sì ṣe ọ̀pá fìtílà náà ní ojúlówó wúrà, ó sì lù ú jáde, ọ̀pá rẹ̀, ìtànná ìfẹ́ rẹ̀, ìrudí rẹ àti agogo rẹ̀, wọ́n jẹ́ ọ̀kan náà. 18 Ẹ̀ka mẹ́fà ni yóò yọ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pá fìtílà: mẹ́ta ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní mẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ kejì. 19 Àwo mẹ́ta ni a ṣe bí ìtànná almondi pẹ̀lú ìrudí àti ìtànná wà ni ẹ̀ka kan, mẹ́ta sì tún wà ní ẹ̀ka mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni ní ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà jáde lára ọ̀pá fìtílà. 20 Ní ara ọ̀pá fìtílà ni àwo mẹ́rin ti a ṣe gẹ́gẹ́ bí òdòdó almondi ti ó ni ìṣọ àti ìtànná yóò wà. 21 Irúdì kan yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì àkọ́kọ́ tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà, irúdì kejì ó sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kejì, irúdì kẹta yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kẹta: ẹ̀ka mẹ́fà ní àpapọ̀. 22 Irúdì wọn àti ẹ̀ka wọn kí ó rí bákan náà, kí gbogbo rẹ̀ kí ó jẹ́ lílù ojúlówó wúrà.

23 Ó ṣe fìtílà rẹ̀, méje, àti alumagaji rẹ̀, àti àwo rẹ̀, kìkì wúrà ni. 24 Ó sì ṣe ọ̀pá fìtílà náà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ láti ara tálẹ́ǹtì kan tí ó jẹ́ kìkì wúrà.

Pẹpẹ tùràrí

25 (J)Igi kasia ní ó fi ṣe pẹpẹ tùràrí náà. Igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ jẹ́ déédé, gígùn rẹ̀ jẹ ìgbọ̀nwọ́ kan, fífẹ̀ rẹ̀ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì, ìwo rẹ̀ sì jẹ́ bákan náà. 26 Kìkì wúrà ni ó fi bo orí rẹ̀, gbogbo ìhà rẹ̀ àti ìwo rẹ̀, ó sì fi ìgbátí wúrà yìí ká. 27 Ó ṣe òrùka wúrà méjì sí ìsàlẹ̀ ìgbátí náà méjì ní òdìkejì ara wọn láti gbá òpó náà mú láti máa fi gbé e. 28 Ó ṣe òpó igi ṣittimu, ó sì bò wọ́n pẹ̀lú u wúrà.

29 Ó sì túnṣe òróró mímọ́ ìtasórí àti kìkì òórùn dídùn tùràrí—iṣẹ́ àwọn tí ń ṣe nǹkan olóòórùn.

Pẹpẹ ẹbọ sísun

38 (K)Ó sì fi igi kasia kọ́ pẹpẹ ẹbọ sísun, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ni gíga rẹ̀: ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, igun rẹ̀ ṣe déédé. Ó ṣe ìwo sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, nítorí kí ìwo àti pẹpẹ náà lè jẹ́ ọ̀kan, ó sì bo pẹpẹ náà pẹ̀lú idẹ. Idẹ ni ó ṣe gbogbo ohun èlò pẹpẹ, ìkòkò rẹ̀, ọkọ, àwokòtò rẹ̀, fọ́ọ̀kì tí a fi n mú ẹran àti àwo iná rẹ̀. Ó ṣe ààrò fún pẹpẹ náà, àwọ̀n onídẹ, kí ó wà níṣàlẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀, dé ìdajì òkè pẹpẹ náà. Ó dá òrùka idẹ láti mú kí ó di òpó igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin idẹ ààrò náà mú. Ó sì fi igi kasia ṣe àwọn òpó náà, ó sì bò wọ́n pẹ̀lú idẹ. Ó sì fi òpó náà bọ inú òrùka, nítorí kí ó lè wà ní ìhà pẹpẹ náà láti máa fi gbé e. Ó sì fi pákó ṣé pẹpẹ náà ní oníhò nínú.

Agbada fún fífọ̀

(L)Ó ṣe agbada idẹ, o sì fi idẹ ṣe ẹsẹ̀ rẹ̀ ti àwòjìji àwọn obìnrin tí ó ń sìn ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ.

Àgbàlá inú

(M)Ó sì ṣe àgbàlá inú náà. Ní ìhà gúúsù ni aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára wà, ó jẹ́ mítà mẹ́rìn-dínláàádọ́ta ní gígùn, 10 pẹ̀lú ogún òpó àti ogún (20) ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, àti pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà. 11 Ní ìhà àríwá náà tún jẹ mítà mẹ́rìn-dínláàádọ́ta ní gígùn, ó sì ní ogún òpó àti ogun ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà.

12 Ìhà ìwọ̀-oòrùn jẹ́ mítà mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà pọ̀. 13 Fún ìhà ìlà-oòrùn, sí ibi tí oòrùn ti ń yọ náà jẹ́ mítà mẹ́tàlélógún ni fífẹ̀ 14 Aṣọ títa ìhà ẹnu-ọ̀nà kan jẹ́ mítà mẹ́fà ààbọ̀, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta, 15 àti aṣọ títa ní ìhà kejì tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà jẹ́ mítà mẹ́fà ààbọ̀ pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́fà. 16 Gbogbo aṣọ tí ó yí àgbàlá náà jẹ́ ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára. 17 Ihò ìtẹ̀bọ̀ fún òpó náà idẹ ni. Ìkọ́ òpó náà àti ìgbànú tí ó wà lára òpó náà jẹ́ fàdákà, a sì bo orí wọn pẹ̀lú fàdákà; gbogbo àwọn òpó àgbàlá náà ní ìgbànú fàdákà.

18 Aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà jẹ́ ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wẹ́wẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe; ogún ìgbọ̀nwọ́ sì ni gígùn rẹ̀, àti gíga rẹ̀ ní ìbò rẹ̀ jẹ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, ó bá aṣọ títa àgbàlá wọ̀n-ọn-nì ṣe déédé, 19 pẹ̀lú òpó mẹ́rin àti ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ mẹ́rin. Ìkọ́ àti ìgbànú wọn jẹ́ fàdákà, a sì bo orí wọn pẹ̀lú fàdákà. 20 Gbogbo èèkàn àgọ́ tabanaku náà àti ti àyíká àgbàlá náà jẹ́ idẹ.

Àwọn ohun èlò tí a lò

21 Wọ̀nyí ni iye ohun èlò tí a lò fún tabanaku náà, tabanaku ẹ̀rí, èyí ti a kọ bí òfin Mose nípa àwọn ọmọ Lefi ní abẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni àlùfáà. 22 (Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, ṣe ohun gbogbo ti Olúwa pàṣẹ fún Mose; 23 Pẹ̀lú rẹ̀ ni Oholiabu ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani: alágbẹ̀dẹ, àti oníṣẹ́-ọnà àti oníṣọ̀nà tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe ní aṣọ aláró àti elése àlùkò àti òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára.) 24 Àròpọ̀ iye wúrà lára wúrà ọrẹ tí a lò fún gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà jẹ́ tálẹ́ǹtì mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n àti ẹgbẹ̀rin ṣékélì gẹ́gẹ́ bí i ṣékélì ibi mímọ́.

25 (N)Fàdákà tí a rí nínú ìjọ, ẹni tí a kà nínú ìkànìyàn jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ǹtì àti òjìlélẹ́gbẹ̀sán ó-lé-mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ṣékélì gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́, 26 ààbọ̀ ṣékélì kan ní orí ẹnìkọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́, lórí olúkúlùkù ẹni tí ó ti kọjá tí a ti kà, láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, àròpọ̀ wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n-ọ̀kẹ́-lé-ẹgbẹ̀ta-dínlógún ó-lé-àádọ́jọ ọkùnrin (603,550). 27 Ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà ní a lò láti fi dá ihò ìtẹ̀bọ̀ fún ibi mímọ́ àti fún aṣọ títa ọgọ́rùn-ún ihò ìtẹ̀bọ̀ nínú ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì náà tálẹ́ǹtì kan fún ihò ìtẹ̀bọ̀ kọ̀ọ̀kan. 28 Ó lo òjì-dínlẹ́gbẹ̀san ó-lé-mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ṣékélì (1,775 shekels) ni ó fi ṣe ìkọ́ fún òpó náà, láti fi bo orí òpó náà àti láti fi ṣe ọ̀já wọn.

29 Idẹ ara ọrẹ náà jẹ́ àádọ́rin tálẹ́ǹtì àti egbèjìlá ṣékélì. 30 Ó lò ó láti fi ṣe ihò ìtẹ̀bọ̀ fún ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, pẹpẹ idẹ náà pẹ̀lú ààrò idẹ rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, 31 ihò ìtẹ̀bọ̀ àgbàlá náà àyíká àti ihò ìtẹ̀bọ̀ ẹnu-ọ̀nà àgbàlá àti gbogbo èèkàn àgọ́ náà, àti gbogbo èèkàn àgbàlá náà yíká.

Aṣọ àlùfáà

39 Nínú aṣọ aláró, ti elése àlùkò àti ti òdòdó ni wọ́n fi ṣe aṣọ híhun fún àwọn òṣìṣẹ́ ní ibi mímọ́. Ó sì tún dá aṣọ mímọ́ fún Aaroni gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Ẹ̀wù efodu

(O)Ó ṣe ẹ̀wù efodu wúrà, ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára. Ó sì lu wúrà náà di ewé fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì tún gé e láti fi ṣe iṣẹ́ sí aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó, àti sínú ọ̀gbọ̀ dáradára, iṣẹ́ ọlọ́nà. Ó ṣe aṣọ èjìká fún ẹ̀wù efodu náà, èyí tí ó so mọ igun rẹ̀ méjèèjì, nítorí kí ó lè so ó pọ̀. Ọnà ìgbànú híhun rẹ̀ rí bí i ti rẹ̀ ó rí bákan náà pẹ̀lú ẹ̀wù efodu ó sì sé e pẹ̀lú wúrà, àti pẹ̀lú aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Ó ṣiṣẹ́ òkúta óníkìsì tí a tò sí ojú ìdè wúrà, tí a sì fín wọn gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ àwọn ọmọ Israẹli. Ó sì so wọ́n mọ́ aṣọ èjìká ẹ̀wù efodu náà bí òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Ìgbàyà

(P)Ó ṣe iṣẹ́ ọnà sí ìgbàyà náà iṣẹ́ ọgbọ́n ọlọ́nà. Ó ṣe é bí ẹ̀wù efodu: ti wúrà ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára. Igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ṣe déédé ìwọ̀n ìka kan ní ìnà rẹ̀, ìwọ̀n ìka kan ní ìbú rẹ̀, ó sì jẹ́ ìṣẹ́po méjì. 10 Ó sì to ipele òkúta oníyebíye mẹ́rin sí i. Ní ipele kìn-ín-ní ní rúbì wà, topasi àti bereli; 11 ní ipele kejì, turikuoṣe, safire, emeradi àti diamọndi; 12 ní ipele kẹta, jasiniti, agate àti ametisiti; 13 ní ipele kẹrin, karisoliti, óníkìsì, àti jasperi. Ó sì tò wọ́n ní ojú ìdè wúrà ní títò wọn. 14 Wọ́n jẹ́ òkúta méjìlá, ọ̀kan fún orúkọ àwọn ọmọ Israẹli kọ̀ọ̀kan, a fín ọ̀kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ ẹnìkọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjèèjìlá.

15 Fún ìgbàyà náà, wọ́n ṣe ẹ̀wọ̀n iṣẹ́ kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bi okùn. 16 Wọ́n sì ṣe ojú ìdè wúrà méjì àti òrùka wúrà méjì, wọ́n sì so àwọn òkúta náà mọ́ igun méjèèjì ìgbàyà náà. 17 Wọ́n sì so ẹ̀wọ̀n wúrà méjèèjì náà mọ́ àwọn òrùka náà ni igun ìgbàyà náà, 18 àti ní àwọn òpin ẹ̀wọ̀n tókù ni wọ́n fi mọ ojú ìdè méjèèjì, wọ́n so wọ́n mọ́ aṣọ èjìká ẹ̀wù efodu náà ní iwájú. 19 Wọ́n ṣe òrùka wúrà méjì, wọ́n sì so wọ́n mọ́ igun méjèèjì ìgbàyà náà ní etí tí ó wà ní inú lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀wù efodu náà. 20 Wọ́n sì túnṣe òrùka wúrà méjì sí i, wọ́n sì so wọ́n mọ́ ìdí aṣọ èjìká ní iwájú ẹ̀wù efodu náà tí ó súnmọ́ ibi tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ ní òkè ìgbànú ẹ̀wù efodu náà. 21 Wọn so àwọn òrùka ìgbàyà mọ́ àwọn òrùka ẹ̀wù efodu ọ̀já aṣọ aláró, kí a pa á pọ̀ mọ́ ìgbànú, nítorí kí ìgbàyà náà má ṣe tú kúrò lára ẹ̀wù efodu náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Àwọn aṣọ àlùfáà mìíràn

22 (Q)Ó sì ṣe ọ̀já àmùrè ẹ̀wù efodu gbogbo rẹ̀ jẹ́ aṣọ aláró iṣẹ́ aláṣọ híhun 23 Pẹ̀lú ihò ní àárín ọ̀já àmùrè náà gẹ́gẹ́ bí i ojú kọ́là, àti ìgbànú yí ihò yìí ká, nítorí kí ó má ba à ya. 24 Ó sì ṣe pomegiranate ti aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára yí ìṣẹ́tí ọ̀já àmùrè náà ká. 25 Ó sì ṣe agogo kìkì wúrà, ó sì so wọ́n mọ́ àyíká ìṣẹ́tí àárín pomegiranate náà. 26 Ago àti pomegiranate kọjú sí àyíká ìṣẹ́tí ọ̀já àmùrè láti máa wọ̀ ọ́ fún iṣẹ́ àlùfáà, bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

27 (R)Fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ, wọ́n ṣe àwọ̀tẹ́lẹ̀ ti ọ̀gbọ̀ dáradára tí iṣẹ́ aláṣọ híhun. 28 Àti fìlà ọ̀gbọ̀ dáradára, ìgbàrí ọ̀gbọ̀ àti aṣọ abẹ́ ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára. 29 Ọ̀já náà jẹ́ ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, aṣọ aláró, elése àlùkò àti òdòdó tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún Mose.

30 (S)Ó ṣe àwo, adé mímọ́, láti ara kìkì wúrà, wọ́n sì kọ̀wé sí i, gẹ́gẹ́ bí i ìkọ̀wé lórí èdìdì:

mímọ́ sí Olúwa.

31 Wọ́n sì so ọ̀já aláró mọ́ ọn láti ṣo ó mọ́ fìlà náà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Mose bẹ àgọ́ náà wò

32 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo iṣẹ́ àgọ́ náà, ti àgọ́ àjọ parí. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. 33 Wọ́n sì mú tabanaku náà tọ Mose wá:

àgọ́ náà àti gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ìkọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, òpó rẹ̀ àti àwọn ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀;

34 ìbòrí awọ àgbò tí a kùn ní pupa, ìbòrí awọ àti ìji aṣọ títa;

35 àpótí ẹ̀rí pẹ̀lú àwọn òpó rẹ̀ àti ìbòrí àánú;

36 (T)tábìlì pẹ̀lú gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti àkàrà ìfihàn;

37 ọ̀pá fìtílà kìkì wúrà pẹ̀lú ipele fìtílà rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, àti òróró fún títanná rẹ̀;

38 pẹpẹ wúrà àti òróró ìtasórí, tùràrí dídùn, àti aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà.

39 Pẹpẹ idẹ pẹ̀lú idẹ ọlọ, àwọn òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀;

agbada pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀;

40 aṣọ títa ti àgbàlá pẹ̀lú àwọn òpó rẹ̀ àti àgbàlá, àti aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá;

ọ̀já àmùrè àti èèkàn àgọ́ fún àgbàlá náà;

gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ fún àgọ́, àgọ́ àjọ náà;

41 aṣọ híhun tí wọ́n ń wọ̀ fún iṣẹ́ ibi mímọ́, aṣọ mímọ́ fún Aaroni àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ àlùfáà.

42 Àwọn ọmọ Israẹli ti ṣe gbogbo iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. 43 Mose bẹ iṣẹ́ náà wò, ó sì rí i wí pé wọ́n ti ṣe é gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ. Nítorí náà Mose sì bùkún fún wọn.

Gbígbé àgọ́ ró

40 Olúwa sì wí fún Mose pé: Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní ni kí ó gbé àgọ́ náà, àgọ́ àjọ náà ró. Gbé àpótí ẹ̀rí sí inú rẹ̀, kí ó sì bo àpótí náà pẹ̀lú aṣọ títa. Gbé tábìlì náà wọ ilé, kí o sì to àwọn ohun tí ó jẹ́ tirẹ̀ lé e lórí. Nígbà náà gbé ọ̀pá fìtílà wọlé, kí o sì to àwọn fìtílà rẹ̀. Gbé pẹpẹ wúrà ti tùràrí sí iwájú àpótí ẹ̀rí, kí o sì fi aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà sí ara àgọ́ náà.

“Gbé pẹpẹ ẹbọ sísun sí iwájú ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà, àgọ́ àjọ; gbé agbada sí àárín àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, kí o sì fi omi sí inú rẹ̀. Gbé àgbàlá ró yìí ka, kí ó sì fi aṣọ títa sí ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà.

“Mú òróró ìtasórí, kí ó sì ta á sára àgọ́ náà àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀: yà pẹpẹ sí mímọ́ àti gbogbo ọ̀ṣọ́ rẹ̀, yóò sì jẹ́ mímọ́. 10 Ta òróró sára pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ya pẹpẹ náà sí mímọ́, yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ. 11 Ta òróró sára agbada náà àti ẹsẹ̀ rẹ, kí o sì yà wọ́n sí mímọ́.

12 “Mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì wẹ̀ wọ́n pẹ̀lú omi. 13 Nígbà náà wọ Aaroni ní aṣọ mímọ́, ta òróró sí i ní orí, kí o sì yà á sí mímọ́, nítorí kí ó lè máa sìn mi bí àlùfáà. 14 Mú àwọn ọmọ rẹ̀ kí o sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n. 15 Ta òróró sí wọn ní orí gẹ́gẹ́ bí o ti ta òróró sí baba wọn ní orí, nítorí kì wọn lè máa sìn mi bí àlùfáà. Ìtasórí wọn yóò jẹ́ iṣẹ́ àlùfáà ti yóò máa lò fún gbogbo ìrandíran tó ń bọ̀.” 16 Mose ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un.

17 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé àgọ́ náà ró ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní ní ọdún kejì. 18 Nígbà tí Mose gbé àgọ́ náà ró ó fi ihò ìtẹ̀bọ̀ sí ààyè rẹ̀, ó to pákó rẹ̀, ó fi ọ̀pá rẹ̀ bọ̀ ọ́, ó sì gbé àwọn òpó rẹ̀ ró. 19 Ó na aṣọ àgọ́ náà sórí àgọ́, ó sì fi ìbòrí bo orí àgọ́ náà, bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún Mose.

20 Ó mu ẹ̀rí, ó sì fi sínú àpótí, ó so àwọn òpó mọ́ àpótí náà, ó sì fi àánú bo orí rẹ. 21 Ó sì gbé àpótí náà wá sínú àgọ́; ó sì sọ aṣọ títa, ó sì ta á bo àpótí ẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

22 Mose gbé tábìlì sínú àgọ́ àjọ sí ìhà àríwá àgọ́ náà lẹ́yìn aṣọ títa, 23 (U)ó sì to àkàrà sórí rẹ̀ níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

24 Ó gbé ọ̀pá fìtílà sínú àgọ́ àjọ ní òdìkejì tábìlì ní ìhà gúúsù àgọ́ náà. 25 Ó sì tan àwọn fìtílà náà níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

26 Mose gbé pẹpẹ wúrà sínú àgọ́ àjọ níwájú aṣọ títa 27 ó sì jó tùràrí dídùn lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

28 Ó sì ta aṣọ títa sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà. 29 Ó gbé pẹpẹ ẹbọ sísun sí ẹ̀gbẹ́ ẹnu-ọ̀nà àgọ́, àgọ́ àjọ, ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ (ọkà), gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

30 (V)Ó gbé agbada sí àárín àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, ó sì pọn omi sínú rẹ̀ fún wíwẹ̀, 31 Mose, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ lò ó láti fi wẹ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn. 32 Wọ́n máa ń wẹ̀ nígbàkúgbà tí wọ́n bá wọ àgọ́ àjọ tàbí tí wọ́n bá súnmọ́ pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

33 Mose sì gbé àgbàlá tí ó yí àgọ́ náà kà ró àti pẹpẹ, ó sì ta aṣọ títa ti ẹnu-ọ̀nà sí àgbàlá náà. Bẹ́ẹ̀ ni Mose ṣe parí iṣẹ́ náà.

Ògo Olúwa

34 (W)Nígbà náà ni àwọsánmọ̀ bo àgọ́ àjọ, ògo Olúwa bo àgọ́ náà. 35 Mose kò sì lè wọ inú àgọ́ àjọ, nítorí àwọsánmọ̀ wà ní orí àgọ́, ògo Olúwa sì ti kún inú àgọ́ náà.

36 Ní gbogbo ìrìnàjò àwọn ọmọ Israẹli nígbàkúgbà tí a bá ti fa ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà sókè kúrò lórí àgọ́, wọ́n máa ń jáde lọ; 37 ṣùgbọ́n tí àwọsánmọ̀ kò bá gòkè wọn kò ní jáde títí di ọjọ́ tí ó bá gòkè. 38 Nítorí náà àwọsánmọ̀ Olúwa wà lórí àgọ́ ní ọ̀sán, iná sì wà nínú àwọsánmọ̀ ní alẹ́, ní ojú gbogbo ilé Israẹli ní gbogbo ìrìnàjò wọn.