M’Cheyne Bible Reading Plan
Ìbí Mose
2 Ó sì ṣe, ọkùnrin ará ilé Lefi kan fẹ́ ọmọbìnrin ará Lefi kan ni ìyàwó. 2 (A)Obìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Nígbà tí ó rí í pé ọmọ náà rẹwà, ó gbé ọmọ náà pamọ́ fún oṣù mẹ́ta. 3 Ṣùgbọ́n nígbà tí kò le è gbé e pamọ́ mọ́, ó fi ewé papirusi hun apẹ̀rẹ̀, ó sì fi ọ̀dà àti òjé igi sán apẹ̀rẹ̀ náà. Ó sì tẹ́ ọmọ náà sínú rẹ̀, ó sì gbe é sí inú eèsún ni etí odò Naili. 4 Arábìnrin rẹ̀ dúró ni òkèèrè láti wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà.
5 (B)Nígbà náà ni ọmọbìnrin Farao sọ̀kalẹ̀ wá sí etí odò Naili láti wẹ̀, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì ń rìn ni etí bèbè odò. Ó sì ri apẹ̀rẹ̀ náà ni àárín eèsún, ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin kan láti lọ gbé e wá, 6 ó ṣí i, ó sì rí ọmọ náà. Ọmọ náà ń sọkún, àánú ọmọ náà sì ṣe é. Ó wí pé “Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Heberu ni èyí.”
7 Nígbà náà ni arábìnrin rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ ọmọbìnrin Farao pé “Ṣé kí èmi lọ wá ọ̀kan lára àwọn obìnrin Heberu wá fún ọ láti bá ọ tọ́jú ọmọ náà?”
8 Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni; lọ.” Arábìnrin náà sì lọ, ó sì pe ìyá ọmọ náà wá, 9 Ọmọbìnrin Farao sì wí fún un pé, “Gba ọmọ yìí kí o sì tọ́jú rẹ̀ fún mi, èmi yóò san owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ fún ọ” Ọmọbìnrin náà sì gbé ọmọ náà lọ, ó sì tọ́jú rẹ̀. 10 Nígbà tí ọmọ náà sì dàgbà, ó mú un tọ ọmọbìnrin Farao wá, ó sì di ọmọ rẹ̀. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Mose, ó wí pé “Nítorí tí mo fà á jáde nínú omi.”
Mose sálọ sí Midiani
11 (C)Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Mose ti dàgbà, ó jáde lọ sí ibi ti àwọn ènìyàn rẹ̀ wà, ó ń wò wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ líle wọn, O ri ará Ejibiti tí ń lu ará Heberu, ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn rẹ̀. 12 (D)Ó wo ìhín, ó wo ọ̀hún, nígbà tí kò rí ẹnìkankan, ni ó bá pa ará Ejibiti náà, ó sì bò ó mọ́ inú iyanrìn. 13 Ní ọjọ́ kejì, ó jáde lọ, ó rí àwọn ará Heberu méjì tí wọ́n ń jà. Ó béèrè lọ́wọ́ èyí tí ó jẹ̀bi pé “Èéṣe tí ìwọ fi ń lu Heberu arákùnrin rẹ?”
14 (E)Ọkùnrin náà sì dáhùn pé “Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti onídàájọ́ lórí wa? Ṣé ìwọ fẹ́ pa mí bí o ti pa ará Ejibiti?” Nígbà náà ni ẹ̀rù ba Mose, ó sì wí pé, “lóòótọ́ ni ọ̀ràn yìí ti di mí mọ̀.”
15 (F)Nígbà ti Farao sì gbọ́ nípa èyí, ó wá ọ̀nà láti pa Mose, ṣùgbọ́n Mose sá kúrò ní àrọ́wọ́tó o Farao, ó lọ sí Midiani láti máa gbé, nígbà tí ó dé bẹ̀, ó jókòó ni ẹ̀bá a kànga kan. 16 Ó sì ṣe, àlùfáà Midiani kan ni àwọn ọmọbìnrin méje, wọn sì wá láti pọn omi kún ọpọ́n ìmumi fún ẹran ọ̀sìn baba wọn. 17 Àwọn darandaran kan wá, wọ́n sì lé wọn sẹ́yìn, ṣùgbọ́n Mose dìde láti gbà wọ́n sílẹ̀ àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fún ẹran wọn ní omi.
18 Nígbà ti àwọn ọmọbìnrin náà padà dé ọ̀dọ̀ Reueli baba wọn, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé “Èéṣe tí ẹ̀yin fi tètè dé ni òní?”
19 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ará Ejibiti kan ni ó gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn darandaran, ó tilẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti fa omi àti láti fún agbo ẹran ní omi.”
20 Ó sọ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, “Níbo ni ó wà? Èéṣe ti ẹ fi fi ọkùnrin náà sílẹ̀? Ẹ pè é wá jẹun.”
21 Mose gbà láti dúró lọ́dọ̀ ọkùnrin náà, ẹni tí o fi Sippora, ọmọbìnrin rẹ̀ fún Mose láti fi ṣe aya. 22 Ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Gerṣomu, ó wí pé “Èmi ń ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì.”
23 Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ọba Ejibiti kú. Àwọn ará Israẹli ń kérora ní oko ẹrú wọn, wọ́n ń ké fún ìrànlọ́wọ́ nítorí oko ẹrú tí wọ́n wà, igbe wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. 24 (G)Ọlọ́run gbọ́ igbe wọn, Ó sì rántí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Abrahamu, Isaaki àti pẹ̀lú Jakọbu. 25 Nítorí náà, Ọlọ́run bojú wo àwọn ará Israẹli, Ó sì wà láti gbà wọ́n sílẹ̀.
Ìpè àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àkọ́kọ́
5 (A)Ó sì ṣe, nígbà tí ìjọ ènìyàn súnmọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì dúró létí adágún Genesareti. 2 Ó rí ọkọ̀ méjì ti o wá létí adágún: èyí tí àwọn apẹja ti sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú wọn, nítorí tí wọ́n ń fọ àwọ̀n wọn. 3 (B)Ó sì wọ ọ̀kan nínú àwọn ọkọ̀ náà, tí í ṣe ti Simoni, ó sì bẹ̀ ẹ́ kí ó tì í sí ẹ̀yìn díẹ̀ kúrò ní ilẹ̀. Ó sì jókòó, ó sì ń kọ́ ìjọ ènìyàn láti inú ọkọ̀ náà.
4 Bí ó sì ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, ó wí fún Simoni pé, “Tì í sí ibú, kí o sì ju àwọ̀n yín sí ìsàlẹ̀ fún àkópọ̀.”
5 (C)Simoni sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́ni, gbogbo òru ni àwa fi ṣiṣẹ́, àwa kò sì mú nǹkan kan: ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀ rẹ èmi ó ju àwọ̀n náà sí ìsàlẹ̀.”
6 Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe èyí, wọ́n kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja: àwọ̀n wọn sì ya. 7 Wọ́n sì pe àwọn ẹgbẹ́ wọn, tí ó wà nínú ọkọ̀ kejì, kí wọn kí ó wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n sì wá, wọ́n kó ẹja ọkọ̀ méjèèjì sì kún, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rì.
8 Nígbà tí Simoni Peteru sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá eékún Jesu, ó wí pé, “Lọ kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa; nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.” 9 Ẹnu sì yà wọ́n, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀, fún àkópọ̀ ẹja tí wọ́n kó: 10 Bẹ́ẹ̀ ni Jakọbu àti Johanu àwọn ọmọ Sebede, tí ń ṣe alábákẹ́gbẹ́ Simoni.
Jesu sì wí fún Simoni pé, “Má bẹ̀rù; láti ìsinsin yìí lọ ìwọ ó máa mú ènìyàn.” 11 Nígbà tí wọ́n sì ti mú ọkọ̀ wọn dé ilẹ̀, wọ́n fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lọ.
Ọkùnrin pẹ̀lú ẹ̀tẹ̀
12 (D)Ó sì ṣe, nígbà tí Jesu wọ ọ̀kan nínú àwọn ìlú náà, kíyèsi i, ọkùnrin kan tí ẹ̀tẹ̀ bò wa síbẹ̀: nígbà tí ó rí Jesu, ó wólẹ̀, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, wí pé, “Olúwa, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè sọ mí di mímọ́.”
13 Jesu sì na ọwọ́ rẹ̀, ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́!” Lójúkan náà ẹ̀tẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ.
14 (E)Ó sì kìlọ̀ fún u pé, “Kí ó má ṣe sọ fún ẹnìkan: ṣùgbọ́n kí ó lọ, kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn fún àlùfáà, kí ó sì ta ọrẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ gẹ́gẹ́ bi ẹ̀rí fun wọn.”
15 (F)Ṣùgbọ́n òkìkí rẹ̀ ń kàn kálẹ̀: tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì jùmọ̀ pàdé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti gba ìwòsàn lọ́dọ̀ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àìlera wọn. 16 (G)Ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà ni Jesu a máa yẹra kúrò si ibi ìdákẹ́rọ́rọ́, òun á sì máa dá wà láti gbàdúrà.
Jesu wo arọ sàn
17 (H)(I) Ní ọjọ́ kan, bí ó sì ti ń kọ́ni, àwọn Farisi àti àwọn amòfin jókòó pẹ̀lú rẹ̀, àwọn tí ó ti àwọn ìletò Galili gbogbo, àti Judea, àti Jerusalẹmu wá: agbára Olúwa sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ láti mú wọn láradá. 18 Sá à sì kíyèsi i, àwọn Ọkùnrin kan gbé ẹnìkan tí ó ní ààrùn ẹ̀gbà wà lórí àkéte: wọ́n ń wá ọ̀nà àti gbé e wọlé, àti láti tẹ́ ẹ síwájú Jesu. 19 Nígbà tí wọn kò sì rí ọ̀nà tí wọn ìbá fi gbé e wọlé nítorí ìjọ ènìyàn, wọ́n gbé e gun òkè àjà ilé lọ, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ sí àárín èrò ti òun ti àkéte rẹ̀ níwájú Jesu.
20 (J)Nígbà tí ó sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí pé, “Ọkùnrin yìí, a darí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”
21 (K)Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ sí í gbèrò wí pé, “Ta ni eléyìí tí ń sọ ọ̀rọ̀-òdì? Ta ni ó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí kò ṣe Ọlọ́run nìkan ṣoṣo.”
22 Jesu sì mọ èrò inú wọn, ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ fi ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín? 23 Èwo ni ó yá jù: láti wí pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ tàbí láti wí pé, ‘Dìde kí ìwọ sì máa rìn’? 24 Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé ọmọ ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni.” Ó wí fún ẹlẹ́gbà náà pé, “Mo wí fún ọ, dìde, sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa lọ sí ilé!” 25 Ó sì dìde lọ́gán níwájú wọn, ó gbé ohun tí ó dùbúlẹ̀ lé, ó sì lọ sí ilé rẹ̀, ó yin Ọlọ́run lógo. 26 Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, ẹ̀rù sì bà wọ́n, wọ́n ń wí pé, “Àwa rí ohun ìyanu lónìí.”
Ìpè Lefi
27 (L)Lẹ́hìn èyí, Jesu jáde lọ, ó sì rí agbowó òde kan tí à ń pè ní Lefi ó jókòó sí ibi tí ó ti ń gba owó òde, Jesu sì wí fún un pé “Tẹ̀lé mi,” 28 Lefi sì fi ohun gbogbo sílẹ̀ ó sì ń tẹ̀lé e.
29 Lefi sì ṣe àsè ńlá kan fún Jesu ní ilé rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti àwọn mìíràn sì ń jẹun pẹ̀lú wọn. 30 (M)Ṣùgbọ́n àwọn Farisi, àwọn olùkọ́ òfin tí ó jẹ́ ara wọn fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pe “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń jẹun tí ẹ sì ń mú pẹ̀lú àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
31 Jesu dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹni tí ara rẹ̀ le kò nílò oníṣègùn, bí kò ṣe ẹni tí ara rẹ̀ kò dá. 32 (N)Èmí kò wá láti pe àwọn olódodo bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ìrònúpìwàdà.”
A béèrè nípa àwẹ̀ lọ́wọ́ Jesu
33 (O)(P) Wọ́n wí fún pé “Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu a máa gbààwẹ̀, wọn a sì máa gbàdúrà, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú sì ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn Farisi ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ a máa jẹ, wọn a sì máa mu pẹ̀lú.”
34 Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ó ṣe é ṣe kí àwọn àlejò ọkọ ìyàwó máa gbààwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó wà pẹ̀lú wọn bí? 35 Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn, ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ni wọn yóò gbààwẹ̀.”
36 Ó sì pa òwe yìí fún wọn wí pé: “Kò sí ẹni tó lè ya aṣọ tuntun kí ó sì rán mọ́, èyí tó ti gbó. Tí ó ba ṣe èyí, yóò ba aṣọ tuntun jẹ́, èyí tí ó tuntun náà kì yóò sì dọ́gba pẹ̀lú èyí tí ó ti gbó. 37 Àti wí pé, kò sí ẹni tí ó lè dá ọtí wáìnì tuntun sínú ògbólógbòó ìgò-awọ, tí ó bá ṣe èyí, wáìnì tuntun yóò fa awọ náà ya, wáìnì náà yóò dànù, awọ náà a sì bàjẹ́. 38 Nítorí náà, ó tọ́ kí á da wáìnì tuntun sínú awọ tuntun. 39 Kò sì ẹni tí yóò fẹ́ láti mu wáìnì tuntun lẹ́yìn tí ó bá ti mu ògbólógbòó tán, nítorí yóò wí pé, ‘Èyí tí ó jẹ́ ògbólógbòó dára jù.’ ”
Ìdáhùn Jobu fún Bilidadi
19 Ìgbà náà ni Jobu dáhùn, ó sì wí pé:
2 “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin ó fi máa fi ìyà jẹ mí,
tí ẹ̀yin ó fi máa fi ọ̀rọ̀ yìí?
3 Ìgbà mẹ́wàá ní yin yọ mi lénu ẹ̀yin ti ń gàn mí;
ojú kò tì yín tí ẹ fi jẹ mí ní yà.
4 Kí a sì wí bẹ́ẹ̀ pé, mo ṣìnà nítòótọ́,
ìṣìnà mi wà lára èmi tìkára mi.
5 Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ̀yin ó ṣògo si mi lórí nítòótọ́,
tí ẹ ó sì máa fi ẹ̀gàn mi gún mí lójú,
6 Kí ẹ mọ̀ nísinsin yìí pé, Ọlọ́run ni ó bì mí ṣubú,
ó sì nà àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká.
7 “Kíyèsi, èmi ń kígbe pe, ‘Ọwọ́ alágbára!’ Ṣùgbọ́n a kò gbọ́ ti èmi;
mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdájọ́.
8 Ó ṣọgbà dí ọ̀nà mi tí èmi kò le è kọjá,
Ó sì mú òkùnkùn ṣú sí ipa ọ̀nà mi.
9 Ó ti bọ́ ògo mi,
ó sì ṣí adé kúrò ní orí mi.
10 Ó ti bà mí jẹ́ ní ìhà gbogbo,
ẹ̀mí sì pin; ìrètí mi ni a ó sì fàtu bí igi.
11 Ó sì tiná bọ ìbínú rẹ̀ sí mi,
ó sì kà mí sí bí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀tá rẹ̀.
12 Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ sì dàpọ̀ sí mi,
wọ́n sì mọ odi yí mi ká,
wọ́n sì yí àgọ́ mi ká.
13 “Ó mú àwọn arákùnrin mi jìnà sí mi réré,
àti àwọn ojúlùmọ̀ mi di àjèjì sí mi pátápátá.
14 Àwọn alájọbí mi fàsẹ́yìn,
àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi sì di onígbàgbé mi.
15 Àwọn ará inú ilé mi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi kà mí sí àjèjì;
èmi jásí àjèjì ènìyàn ní ojú wọn.
16 Mo pe ìránṣẹ́ mi, òun kò sì dá mi lóhùn;
mo fi ẹnu mi bẹ̀ ẹ́.
17 Ẹ̀mí mi ṣú àyà mi, àti òórùn mi
ṣú àwọn ọmọ inú ìyá mi.
18 Àní àwọn ọmọdékùnrin fi mí ṣẹ̀sín:
Mo dìde, wọ́n sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi.
19 Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi kórìíra mi,
àwọn olùfẹ́ mi sì kẹ̀yìndà mí.
20 Egungun mi lẹ̀ mọ́ ara mi àti mọ́ ẹran-ara mi,
mo sì yọ́ pẹ̀lú awọ eyín mi.
21 “Ẹ ṣàánú fún mi, ẹ ṣàánú fún mi,
ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, nítorí ọwọ́ Ọlọ́run ti bà mí.
22 Nítorí kí ni ẹ̀yin ṣe lépa mi bí
Ọlọ́run, tí ẹran-ara mi kò tẹ́ yín lọ́rùn?
23 “Háà! Ìbá ṣe pé a le kọ̀wé ọ̀rọ̀ mi
nísinsin yìí, ìbá ṣe pé a le kọ ọ sínú ìwé!
24 Kí a fi kálámù irin àti ti òjé kọ
wọ́n sínú àpáta fún láéláé.
25 Nítorí èmi mọ̀ pé olùdáǹdè mi ń bẹ láààyè
àti pe òun ni yóò dìde dúró lórí ilẹ̀ ní ìkẹyìn;
26 Àti lẹ́yìn ìgbà tí a pa àwọ̀ ara
mi run, síbẹ̀ láìsí ẹran-ara mi ni èmi ó rí Ọlọ́run,
27 Ẹni tí èmi ó rí fún ara mi,
tí ojú mi ó sì wo, kì sì í ṣe ti ẹlòmíràn;
ọkàn mi sì dákú ní inú mi.
28 “Bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘àwa ó ti lépa rẹ̀ tó!
Àti pé, gbogbo ọ̀rọ̀ náà ni a sá à rí ní ọwọ́ rẹ̀,’
29 Kí ẹ̀yin kí ó bẹ̀rù;
nítorí ìbínú ní í mú ìjìyà wá nípa idà,
Kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé ìdájọ́ kan ń bẹ.”
Ìyànjú èdè-àìyedè àwọn onígbàgbọ́
6 (A)Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ni èdè-àìyedè sí ẹnìkejì rẹ̀, ó ha gbọdọ̀ lọ pè é lẹ́jọ́ níwájú àwọn aláìṣòótọ́ bí, bí kò ṣe níwájú àwọn ènìyàn mímọ́? 2 Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn ẹni mímọ́ ni yóò ṣe ìdájọ́ ayé? Ǹjẹ́ bí ó ba ṣe ìpàṣẹ yín ni a o ti ṣe ìdájọ́ ayé, kín ni ìdí tí ẹ kò fi yanjú àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèkéé wọ̀nyí láàrín ara yín. 3 Ẹ kò mọ̀ pé àwa ni a ó ṣe ìdájọ́ àwọn angẹli ní? Mélòó mélòó àwọn nǹkan tó wà nínú ayé yìí. 4 Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá ni aáwọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ǹjẹ́ ẹ ó yàn láti gba ìdájọ́ lọ́dọ̀ àwọn tí ìgbé ayé wọn ń di gígàn nínú ìjọ. 5 Mo sọ èyí kí ojú lè tì yín. Ṣé ó ṣe é ṣe kí a máa rín ẹnìkan láàrín yín tí ó gbọ́n níwọ̀n láti ṣe ìdájọ́ èdè-àìyedè láàrín àwọn onígbàgbọ́? 6 Ṣùgbọ́n dípò èyí, arákùnrin kan ń pe arákùnrin kejì lẹ́jọ́ sí ilé ẹjọ́ níwájú àwọn aláìgbàgbọ́.
7 (B)Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àbùkù ni fún un yín pátápátá pé ẹ̀yin ń bá ara yín ṣe ẹjọ́. Kín ní ṣe tí ẹ kò kúkú gba ìyà? Kín ló dé tí ẹ kò kúkú gba ìrẹ́jẹ kí ẹ sì fi i sílẹ̀ bẹ́ẹ̀? 8 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń jẹ ni ní ìyà, ẹ sì ń rẹ́ ni jẹ. Ẹ̀yin si ń ṣe èyí sí àwọn arákùnrin yín. 9 (C)Ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn aláìṣòótọ́ kì í yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a máa tàn yín jẹ; kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ṣe ìṣe obìnrin tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ba ara wọn lòpọ̀ 10 tàbí àwọn olè, tàbí àwọn wọ̀bìà, tàbí àwọn ọ̀mùtí, tàbí àwọn apẹ̀gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run. 11 (D)Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn nínú yín sì tí jẹ́ rí; ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti dá yín láre ni orúkọ Jesu Kristi Olúwa, àti nípa Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run wa.
Ìwà àgbèrè
12 (E)“Ohun gbogbo ní ó tọ́ fún mi,” ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ní èrè; “Ohun gbogbo ni ó yẹ fún mi,” ṣùgbọ́n èmi kì yóò jẹ́ kí ohunkóhun ṣe olórí fun mi. 13 “Oúnjẹ fún inú àti inú fún oúnjẹ,” ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò fi òpin sí méjèèjì, ara kì í ṣe fún ìwà àgbèrè ṣíṣe, ṣùgbọ́n fún Olúwa, àti Olúwa fún ara náà. 14 Nínú agbára rẹ̀, Ọlọ́run jí Olúwa dìde kúrò nínú òkú bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò jí àwa náà dìde. 15 (F)Ṣé ẹ kò tilẹ̀ mọ̀ pé ara yín gan an jẹ́ ẹ̀yà ara Kristi fún ara rẹ̀? Ǹjẹ́ tí ó ba jẹ́ bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ó yẹ kí ń mú ẹ̀yà ara Kristi kí ń fi ṣe ẹ̀yà ara àgbèrè bí? Kí a má rí i! 16 (G)Tàbí ẹ kò mọ̀ pé bí ẹnìkan bá so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àgbèrè ó jẹ́ ara kan pẹ̀lú rẹ̀? Nítorí a tí kọ ọ́ wí pé, “Àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.” 17 (H)Ṣùgbọ́n ẹni ti ó dàpọ̀ mọ́ Olúwa di ẹ̀mí kan náà pẹ̀lú rẹ̀.
18 Ẹ máa sá fún àgbèrè. Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ènìyàn ń dá wà lóde ara, ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbèrè ń ṣe sí ara òun tìkára rẹ̀. 19 (I)Tàbí, ẹ̀yin kò mọ̀ pé ara yín ni tẹmpili Ẹ̀mí Mímọ́, ti ń bẹ nínú yín, ti ẹ̀yin ti gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run? Ẹ̀yin kì í ṣe ti ara yín, 20 (J)nítorí a ti rà yín ni iye kan; Nítorí náà ẹ yìn Ọlọ́run lógo nínú ara yín, àti nínú ẹ̀mí yín, tì í ṣe ti Ọlọ́run.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.