M’Cheyne Bible Reading Plan
Ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Jakọbu sí àwọn ọmọ rẹ̀
49 Nígbà náà ni Jakọbu ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí n le è sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú fún un yín.
2 “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí ẹ sì tẹ́tí, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu;
Ẹ fetí sí Israẹli baba yín.
3 “Reubeni, ìwọ ni àkọ́bí mi,
agbára mi, ìpilẹ̀ṣẹ̀ ipá mi,
títayọ ní ọlá àti títayọ ní agbára.
4 Ẹni ríru bí omi Òkun, ìwọ kì yóò tayọ mọ́,
nítorí pé ìwọ gun ibùsùn baba rẹ,
lórí àkéte mi, ìwọ sì bà á jẹ́
(ìwọ bá ọ̀kan nínú àwọn aya baba rẹ lòpọ̀).
5 “Simeoni àti Lefi jẹ́ arákùnrin—
idà wọn jẹ́ ohun èlò ogun alágbára.
6 Kí ọkàn mi má ṣe ni àṣepọ̀ pẹ̀lú wọn,
kí n má sì ṣe dúró níbí ìpéjọpọ̀ wọn,
nítorí wọ́n ti pa àwọn ènìyàn ní ìbínú wọn,
wọ́n sì da àwọn màlúù lóró bí ó ti wù wọ́n.
7 Ìfibú ni ìbínú wọn nítorí tí ó
gbóná púpọ̀, àti fún ìrunú wọn nítorí tí ó kún fún ìkà.
Èmi yóò tú wọn ká ní Jakọbu,
èmi ó sì fọ́n wọn ká ní Israẹli.
8 “Juda, àwọn arákùnrin rẹ yóò yìn ọ,
ọwọ́ rẹ yóò wà ní ọrùn àwọn ọ̀tá rẹ,
àwọn ọmọkùnrin baba rẹ yóò foríbalẹ̀ fún ọ.
9 (A)Ọmọ kìnnìún ni ọ́, ìwọ Juda,
o darí láti igbó ọdẹ, ọmọ mi.
Bí i kìnnìún, o ba mọ́lẹ̀, o sì sùn sílẹ̀ bí i abo kìnnìún,
Ta ni ó tó bẹ́ẹ̀, kí o lé e dìde?
10 Ọ̀pá oyè kì yóò kúrò ní Juda
bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá-ìṣàkóso kì yóò kúrò láàrín ẹsẹ̀ rẹ̀,
títí tí Ṣilo tí ó ni í yóò fi dé,
tí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa wárí fún un.
11 Yóò má so ọmọ ẹṣin rẹ̀ mọ́ igi àjàrà,
àti ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ mọ́ ẹ̀ka tí ó dára jù.
Yóò fọ aṣọ rẹ̀ nínú wáìnì
àti ẹ̀wù rẹ̀ nù nínú omi-pupa ti èso àjàrà (gireepu).
12 Ojú rẹ̀ yóò rẹ̀ dòdò ju wáìnì lọ,
eyín rẹ yóò sì funfun ju omi-ọyàn lọ.
13 “Sebuluni yóò máa gbé ní etí Òkun,
yóò sì jẹ́ èbúté fún ọkọ̀ ojú omi,
agbègbè rẹ yóò tàn ká títí dé Sidoni.
14 “Isakari jẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ alágbára
tí ó dùbúlẹ̀ láàrín agbo àgùntàn.
15 Nígbà tí ó bá rí bí ibi ìsinmi òun ti dára tó,
àti bí ilẹ̀ rẹ̀ ti ní ìdẹ̀ra tó,
yóò tẹ èjìká rẹ̀ ba láti ru àjàgà,
yóò sì fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ipá.
16 “Dani yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀
gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà Israẹli.
17 Dani yóò jẹ́ ejò ni pópónà
àti paramọ́lẹ̀ ní ẹ̀bá ọ̀nà,
tí ó bu ẹṣin jẹ ní ẹsẹ̀,
kí ẹni tí ń gùn ún bá à le è ṣubú sẹ́yìn.
18 “Mo ń dúró de ìtúsílẹ̀ rẹ, Olúwa.
19 “Ẹgbẹ́ ogun àwọn ẹlẹ́ṣin yóò kọlu Gadi,
ṣùgbọ́n yóò kọlu wọ́n ní gìgísẹ̀ wọn.
20 “Oúnjẹ Aṣeri yóò dára;
yóò ṣe àsè tí ó yẹ fún ọba.
21 “Naftali yóò jẹ́ abo àgbọ̀nrín
tí a tú sílẹ̀ tí ó ń bí ọmọ dáradára.
22 “Josẹfu jẹ́ àjàrà eléso,
àjàrà eléso ní etí odò,
tí ẹ̀ka rẹ̀ gun orí odi.
23 Pẹ̀lú ìkorò, àwọn tafàtafà dojú ìjà kọ ọ́,
wọ́n tafà sí í pẹ̀lú ìkanra,
24 Ṣùgbọ́n ọrun rẹ̀ dúró ni agbára,
ọwọ́ agbára rẹ̀ ni a sì mu lára le,
nítorí ọwọ́ alágbára Jakọbu,
nítorí olùtọ́jú àti aláàbò àpáta Israẹli,
25 nítorí Ọlọ́run baba rẹ tí ó ràn ọ́ lọ́wọ́,
nítorí Olódùmarè tí ó bùkún ọ
pẹ̀lú láti ọ̀run wá,
ìbùkún ọ̀gbìn tí ó wà ní ìsàlẹ̀,
ìbùkún ti ọmú àti ti inú.
26 Ìbùkún baba rẹ pọ̀ púpọ̀
ju ìbùkún àwọn òkè ńlá ìgbàanì,
ju ẹ̀bùn ńlá àwọn òkè láéláé.
Jẹ́ kí gbogbo èyí sọ̀kalẹ̀ sí orí Josẹfu,
lé ìpéǹpéjú ọmọ-aládé láàrín arákùnrin rẹ̀.
27 “Benjamini jẹ́ ìkookò tí ó burú;
ní òwúrọ̀ ni ó jẹ ẹran ọdẹ rẹ,
ní àṣálẹ́, ó pín ìkógun.”
28 Gbogbo ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá, èyí sì ni ohun tí baba wọn sọ fún wọn nígbà tí ó súre fún wọn, tí ó sì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ìbùkún tí ó tọ́ sí i.
Ikú Jakọbu
29 Nígbà náà ni ó fún wọn ní àwọn ìlànà yìí, “Ọjọ́ ikú mi kù fẹ́ẹ́rẹ́. Kí ẹ sin mí sí ibojì pẹ̀lú àwọn baba mi ní inú àpáta ní ilẹ̀ Hiti ará Efroni. 30 (B)Ihò àpáta tí ó wà ní ilẹ̀ Makpela, nítòsí Mamre ní Kenaani, èyí tí Abrahamu rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìsìnkú lọ́wọ́ Efroni ará Hiti pẹ̀lú ilẹ̀ rẹ̀. 31 (C)Níbẹ̀ ni a sin Abrahamu àti aya rẹ̀ Sara sí, níbẹ̀ ni a sin Isaaki àti Rebeka aya rẹ̀ sí, níbẹ̀ sì ni mo sìnkú Lea sí. 32 Ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni a rà lọ́wọ́ ará Hiti.”
33 (D)Nígbà tí Jakọbu ti pàṣẹ yìí fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó gbé ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè sórí ibùsùn, ó sì kú, a sì ko jọ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.
Ìbí Jesu
2 (A)Ó sì ṣe ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àṣẹ ti ọ̀dọ̀ Kesari Augustu jáde wá pé, kí a kọ orúkọ gbogbo ayé sínú ìwé. 2 (Èyí ni ìkọ sínú ìwé èkínní tí a ṣe nígbà tí Kirene fi jẹ baálẹ̀ Siria.) 3 Gbogbo àwọn ènìyàn sì lọ láti kọ orúkọ wọn sínú ìwé, olúkúlùkù sí ìlú ara rẹ̀.
4 (B)Josẹfu pẹ̀lú sì gòkè láti Nasareti ni Galili, sí ìlú Dafidi ní Judea, tí à ń pè ní Bẹtilẹhẹmu; nítorí ti ìran àti ìdílé Dafidi ní í ṣe, 5 láti kọ orúkọ rẹ̀, pẹ̀lú Maria aya rẹ̀ àfẹ́sọ́nà, tí oyún rẹ̀ ti tó bí. 6 Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, ọjọ́ rẹ̀ pé tí òun yóò bí. 7 Ó sì bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkùnrin, ó sì fi ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran; nítorí tí ààyè kò sí fún wọn nínú ilé èrò.
Àwọn olùṣọ́-àgùntàn àti àwọn angẹli
8 Àwọn olùṣọ́-àgùntàn ń bẹ tí wọ́n ń gbé ní ìlú náà, wọ́n ń ṣọ́ agbo àgùntàn wọn ní òru ní pápá tí wọ́n ń gbé. 9 (C)Angẹli Olúwa sì yọ sí wọn, ògo Olúwa sì ràn yí wọn ká: ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. 10 Angẹli náà sì wí fún wọn pé, Má bẹ̀rù: sá wò ó, mo mú ìhìnrere ayọ̀ ńlá fún yín wá, tí yóò ṣe ti ènìyàn gbogbo. 11 (D)Nítorí a ti bí Olùgbàlà fún yín lónìí ní ìlú Dafidi, tí í ṣe Kristi Olúwa. 12 (E)Èyí ni yóò sì ṣe ààmì fún yín; ẹ̀yin yóò rí ọmọ ọwọ́ tí a fi ọ̀já wé, ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran.
13 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ọ̀run sì darapọ̀ mọ́ angẹli náà ní òjijì, wọ́n ń yin Ọlọ́run, wí pé,
14 (F)“Ògo ni fún Ọlọ́run lókè ọ̀run,
Àti ní ayé Àlàáfíà, ìfẹ́ inú rere sí ènìyàn.”
15 Ó sì ṣe, nígbà tí àwọn angẹli náà padà kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn olùṣọ́-àgùntàn náà bá ara wọn sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ tààrà sí Bẹtilẹhẹmu, kí á lè rí ohun tí ó ṣẹ̀, tí Olúwa fihàn fún wa.”
16 Wọ́n sì wá lọ́gán, wọ́n sì rí Maria àti Josẹfu, àti ọmọ ọwọ́ náà, ó dùbúlẹ̀ nínú ibùjẹ ẹran. 17 Nígbà tí wọ́n sì ti rí i, wọ́n sọ ohun tí a ti wí fún wọn nípa ti ọmọ yìí. 18 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ sí nǹkan wọ̀nyí tí a ti wí fún wọn láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́-àgùntàn wá. 19 (G)Ṣùgbọ́n Maria pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́, ó ń rò wọ́n nínú ọkàn rẹ̀. 20 Àwọn olùṣọ́-àgùntàn sì padà lọ, wọ́n ń fi ògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì yìn ín, nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti gbọ́ àti tí wọ́n ti rí, bí a ti wí i fún wọn.
A gbé Jesu kalẹ̀ nínú Tẹmpili
21 (H)Nígbà tí ọjọ́ mẹ́jọ sì pé láti kọ ọmọ náà nílà, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu, bí a ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ angẹli náà wá kí á tó lóyún rẹ̀.
22 (I)Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nù Maria sì pé gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, Josẹfu àti Maria gbé Jesu wá sí Jerusalẹmu láti fi í fún Olúwa 23 (J)(bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Olúwa pé, “Gbogbo ọmọ ọkùnrin tí ó ṣe àkọ́bí, òun ni a ó pè ní mímọ́ fún Olúwa”), 24 àti láti rú ẹbọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí nínú òfin Olúwa: “Àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì.”
25 (K)Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan wà ní Jerusalẹmu, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Simeoni; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́ àti olùfọkànsìn, ó ń retí ìtùnú Israẹli: Ẹ̀mí mímọ́ sì bà lé e. 26 A sì ti fihàn án láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ náà wá pé, òun kì yóò rí ikú, kí ó tó rí Kristi Olúwa. 27 Ó sì ti ipa Ẹ̀mí wá sínú tẹmpili: nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ sì gbé Jesu wá, láti ṣe fún un bí ìṣe òfin, 28 Nígbà náà ni Simeoni gbé e ní apá rẹ̀, ó fi ìbùkún fún Ọlọ́run, ó ní:
29 “Olúwa Olódùmarè, nígbà yìí ni ó tó jọ̀wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ lọ́wọ́ lọ,
ní Àlàáfíà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ:
30 (L)Nítorí tí ojú mi ti rí ìgbàlà rẹ ná,
31 Tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀ níwájú ènìyàn gbogbo;
32 (M)ìmọ́lẹ̀ láti mọ́ sí àwọn aláìkọlà,
àti ògo Israẹli ènìyàn rẹ̀.”
33 Ẹnu sì ya Josẹfu àti ìyá rẹ̀ sí nǹkan tí a ń sọ sí i wọ̀nyí. 34 Simeoni sì súre fún wọn, ó sì wí fún Maria ìyá rẹ̀ pé: “Kíyèsi i, a gbé ọmọ yìí kalẹ̀ fún ìṣubú àti ìdìde ọ̀pọ̀ ènìyàn ní Israẹli; àti fún ààmì tí a ń sọ̀rọ̀-òdì sí; 35 (Idà yóò sì gún ìwọ náà ní ọkàn pẹ̀lú) kí á lè fi ìrònú ọ̀pọ̀ ọkàn hàn.”
36 (N)Ẹnìkan sì ń bẹ, Anna wòlíì, ọmọbìnrin Penueli, nínú ẹ̀yà Aṣeri: ọjọ́ ogbó rẹ̀ pọ̀, ó ti bá ọkọ gbé ní ọdún méje láti ìgbà wúńdíá rẹ̀ wá; 37 Ó sì ṣe opó títí ó fi di ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, ẹni tí kò kúrò ní tẹmpili, ṣùgbọ́n ó ń fi àwẹ̀ àti àdúrà sin Ọlọ́run lọ́sàn án àti lóru. 38 Ó sì wólẹ̀ ní àkókò náà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pẹ̀lú, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún gbogbo àwọn tí ó ń retí ìdáǹdè Jerusalẹmu.
39 Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe nǹkan gbogbo tán gẹ́gẹ́ bí òfin Olúwa, wọ́n padà lọ sí Galili, sí Nasareti ìlú wọn. 40 (O)Ọmọ náà sì ń dàgbà, ó sì ń lágbára, ó sì kún fún ọgbọ́n: oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sì ń bẹ lára rẹ̀.
Ọ̀dọ́mọkùnrin Jesu ni tẹmpili
41 (P)Àwọn òbí rẹ̀ a sì máa lọ sí Jerusalẹmu ní ọdọọdún sí àjọ ìrékọjá. 42 Nígbà tí ó sì di ọmọ ọdún méjìlá, wọ́n gòkè lọ sí Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ìṣe àjọ náà. 43 Nígbà tí ọjọ́ wọn sì pé bí wọ́n ti ń padà bọ̀, ọmọ náà, Jesu dúró lẹ́yìn ní Jerusalẹmu; Josẹfu àti ìyá rẹ̀ kò mọ̀. 44 Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe bí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ èrò, wọ́n rin ìrìn ọjọ́ kan; wọ́n wá a kiri nínú àwọn ará àti àwọn ojúlùmọ̀ wọn. 45 Nígbà tí wọn kò sì rí i, wọ́n padà sí Jerusalẹmu, wọ́n ń wá a kiri. 46 Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta wọ́n rí i nínú tẹmpili ó jókòó ní àárín àwọn olùkọ́ni, ó ń gbọ́ tiwọn, ó sì ń bi wọ́n léèrè. 47 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún òye àti ìdáhùn rẹ̀. 48 (Q)Nígbà tí wọ́n sì rí i, háà ṣe wọ́n: ìyá rẹ̀ sì bi í pé, “Ọmọ, èéṣe tí ìwọ fi ṣe wá bẹ́ẹ̀? Sá wò ó, baba rẹ̀ àti èmi ti ń fi ìbànújẹ́ wá ọ kiri.”
49 Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá mi kiri, ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi kò lè ṣàìmá wà níbi iṣẹ́ Baba mi?” 50 Ọ̀rọ̀ tí o sọ kò sì yé wọn.
51 (R)Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí Nasareti, sì fi ara balẹ̀ fún wọn: ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn rẹ̀. 52 (S)Jesu sì ń pọ̀ ní ọgbọ́n, sì ń dàgbà, ó sì wà ní ojúrere ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.
Elifasi tako ọrọ̀ Jobu
15 Ìgbà náà ní Elifasi, ará Temani, dáhùn wí pé:
2 “Ọlọ́gbọ́n a máa sọ̀rọ̀ ìmọ̀ asán, kí
ó sì máa fi afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn kún ara rẹ̀ nínú?
3 Òun lè máa fi àròyé sọ̀rọ̀ tí kò ní
èrè, tàbí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ nínú èyí tí kò lè fi ṣe rere?
4 Ṣùgbọ́n ìwọ ṣá ìbẹ̀rù tì,
ìwọ sì dí iṣẹ́ ìsìn lọ́nà níwájú Ọlọ́run.
5 Nítorí pé ẹnu ara rẹ̀ ni ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀
rẹ̀, ìwọ sì yàn ahọ́n alárékérekè ni ààyò.
6 Ẹnu ara rẹ̀ ni ó dá lẹ́bi, kì í ṣe èmi;
àní ètè ara rẹ̀ ni ó jẹ́rìí gbè ọ́.
7 “Ìwọ ha í ṣe ọkùnrin tí a kọ́ bí?
Tàbí a ha dá ọ ṣáájú àwọn òkè?
8 Ìwọ gbúròó àṣírí Ọlọ́run rí, tàbí
ìwọ ha dá ọgbọ́n dúró sọ́dọ̀ ara rẹ?
9 Kí ni ìwọ mọ̀ tí àwa kò mọ̀?
Òye kí ní ó yé ọ tí kò sí nínú wa?
10 Àwọn arúgbó àti ògbólógbòó ènìyàn wà pẹ̀lú wa,
tí wọ́n dàgbà ju baba rẹ lọ.
11 Ìtùnú Ọlọ́run ha kéré lọ́dọ̀ rẹ?
Ọ̀rọ̀ kan sì ṣe jẹ́jẹ́ jù lọ́dọ̀ rẹ?
12 Èéṣe ti ọkàn rẹ fi ń ti ọ kiri,
kí ni ìwọ tẹjúmọ́ tóbẹ́ẹ̀.
13 Tí ìwọ fi yí ẹ̀mí rẹ padà lòdì sí Ọlọ́run,
tí ó fi ń jẹ́ ki ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ kí ó máa bọ́ ní ẹnu rẹ̀ bẹ́ẹ̀?
14 “Kí ni ènìyàn tí ó fi jẹ mímọ́,
àti ẹni tí a tinú obìnrin bí tí yóò fi ṣe olódodo?
15 Kíyèsi i, bi Ọlọ́run ko ba gbẹ́kẹ̀lé àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀,
àní àwọn ọ̀run kò mọ́ ní ojú rẹ̀,
16 mélòó mélòó ni ènìyàn, ẹni ìríra àti eléèérí,
tí ń mu ẹ̀ṣẹ̀ bi ẹní mu omi.
17 “Èmi ó fihàn ọ́, gbọ́ ti èmi;
Èyí tí èmi sì rí, òun ni èmi ó sì sọ,
18 ohun tí àwọn ọlọ́gbọ́n ti pa ní ìtàn láti
ọ̀dọ̀ àwọn baba wọn wá, ti wọ́n kò sì fi pamọ́,
19 Àwọn tí a fi ilẹ̀ ayé fún nìkan,
ti àlejò kan kò sì là wọ́n kọjá.
20 Ènìyàn búburú ń ṣe làálàá,
pẹ̀lú ìrora, ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo,
àti iye ọdún ní a dá sílẹ̀ fún aninilára.
21 Ìró ìbẹ̀rù ń bẹ ní etí rẹ̀;
nínú ìrora ni apanirun yóò dìde sí i.
22 Kò gbàgbọ́ pé òun ó jáde kúrò nínú òkùnkùn;
a sì ṣà á sápá kan fún idà.
23 Ó ń wò káàkiri fún oúnjẹ wí pé, níbo ní ó wà?
Ó mọ̀ pé ọjọ́ òkùnkùn súnmọ́ tòsí.
24 Ìpọ́njú pẹ̀lú ìrora ọkàn yóò mú un
bẹ̀rù, wọ́n ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ bi ọba ti ìmúra ogun.
25 Nítorí pé ó ti nawọ́ rẹ̀ jáde lòdì
sí Ọlọ́run, ó sì múra rẹ̀ le lòdì sí Olódùmarè,
26 Ó súre, ó sì fi ẹ̀yìn gíga,
àní fi ike-kókó àpáta rẹ̀ tí ó nípọn kọlù ú.
27 “Nítorí tí òun fi ọ̀rá rẹ̀ bo ara rẹ̀
lójú, o sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.
28 Òun sì gbé inú ahoro ìlú,
àti nínú ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé
mọ́, tí ó múra tán láti di àlàpà.
29 Òun kò lé di ọlọ́rọ̀, bẹ́ẹ̀ ohun ìní rẹ̀ kò
lè dúró pẹ́; Bẹ́ẹ̀ kò lè mú pípé rẹ̀ dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.
30 Òun kì yóò jáde kúrò nínú òkùnkùn;
ọ̀wọ́-iná ni yóò jó ẹ̀ka rẹ̀,
àti nípasẹ̀ ẹ̀mí ẹnu Ọlọ́run ní a ó gba kúrò.
31 Kí òun kí ó má ṣe gbẹ́kẹ̀lé asán, kí ó má sì ṣe tan ara rẹ̀ jẹ.
Nítorí pé asán ní yóò jásí èrè rẹ̀.
32 A ó mú un ṣẹ ṣáájú pípé ọjọ́ rẹ̀,
ẹ̀ka rẹ̀ kì yóò sì tutù.
33 Yóò dàbí àjàrà tí a gbọn èso àìpọ́n rẹ̀ dànù,
yóò sì rẹ̀ ìtànná rẹ̀ dànù bí i ti igi Olifi.
34 Nítorí pé ayọ̀ àwọn àgàbàgebè
yóò túká, iná ní yóò sì jó àgọ́ àwọn tí ó fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
35 Wọ́n lóyún ìwà ìkà, wọ́n sì bí ẹ̀ṣẹ̀,
ikùn wọn sì pèsè ẹ̀tàn.”
Lórí ìyapa nínú ìjọ
3 (A)Ará, èmí kò sí le bá yín sọ̀rọ̀ bí àwọn tí í ṣe ti Ẹ̀mí, bí kò ṣe bí àwọn ti í ṣe ti ara, àní bí àwọn ọmọ ọwọ́ nínú Kristi. 2 (B)Wàrà ni mo ti fi bọ́ yín, kì í ṣe oúnjẹ; nítorí ẹ kò í tí le gbà á nísinsin yìí náà, ẹ kò í tí le gbà a. 3 Nítorí ẹ̀yin jẹ́ ti ara síbẹ̀. Nítorí, níwọ̀n bí owú jíjẹ àti ìjà ṣe wà láàrín ara yín, ẹ̀yin kò ha ṣe ti ayé bí? Ẹ̀yin kò ha ṣe bí ènìyàn lásán bí? 4 (C)Ǹjẹ́ ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn lásán bí? Níwọ́n ìgbà tí ẹ ba ń sọ pé, “Èmi ń tẹ̀lé Paulu,” àti ti ẹlòmíràn tún wí pé, “Èmi ń tẹ̀lé Apollo.”
5 (D)Jú gbogbo rẹ̀ lọ, kí ni Apollo ha jẹ́, kín ni Paulu sì jẹ́, àwọn ìránṣẹ́ lásán, nípasẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti fi fún olúkúlùkù. 6 (E)Èmi gbìn, Apollo ń bomirin; ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni ń mú ìbísí wá. 7 Ǹjẹ́ kì í ṣe ẹni tí ó ń gbìn nǹkan kan, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ẹni tí ń bomirin; bí kò ṣe Ọlọ́run tí ó ń mú ìbísí wá. 8 Ẹni tí ó ń gbìn àti ẹni tí ó ń bu omi rín ní ìrònú kan àti èrèdí kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yóò gba èrè tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe é kárakára tó. 9 (F)A ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ pọ̀ ni, ẹ̀yin pàápàá sì jẹ́ ọgbà ohun ọ̀gbìn fún Ọlọ́run, kì í ṣe fún wa, ilé Ọlọ́run ni yín, kì í ṣe ilé tiwa.
10 (G)Nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọ́run tí fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọ̀mọ̀lé, mo ti fi ìpìlẹ̀ ilé lélẹ̀, ẹlòmíràn sì ń mọ lé e, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù kíyèsára bí yóò ṣe mọ ọ́n lé e. 11 (H)Nítorí kò sí ẹlòmíràn tó le fi ìpìlẹ̀ tòótọ́ mìíràn lélẹ̀ ju èyí tí a fi lélẹ̀ àní Jesu Kristi ni ìpìlẹ̀ náà. 12 Ǹjẹ́ bí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà, fàdákà, òkúta olówó-iyebiye, igi, koríko, àgékù koríko mọ lé orí ìpìlẹ̀ yìí. 13 (I)Iṣẹ́ olúkúlùkù ènìyàn yóò hàn, nítorí ọjọ́ náà yóò fi í hàn, nítorí pé nínú iná ni a ó ti fihàn, iná náà yóò sì dán irú iṣẹ́ èyí tí olúkúlùkù ṣe wò. 14 Bí iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni bá ṣe lórí rẹ̀ bá dúró, òun yóò sì gba èrè rẹ̀. 15 (J)Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá jóná, òun yóò pàdánù: Ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ ni a ó gbàlà, ṣùgbọ́n bí ìgbà tí ènìyàn bá la àárín iná kọjá.
16 (K)Ṣé ẹ̀yin kò tilẹ̀ mọ̀ pé tẹmpili Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́? Àti pẹ̀lú pe Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín? 17 Bí ẹnikẹ́ni bá ba tẹmpili Ọlọ́run jẹ́, òun ni Ọlọ́run yóò parun; nítorí pé mímọ́ ni tẹmpili Ọlọ́run, èyí tí ẹ̀yin jẹ́.
18 (L)Kí ẹnikẹ́ni, má ṣe tan ara rẹ̀ jẹ mọ́. Bí ẹnikẹ́ni yín nínú ayé yìí ba rò pé òun gbọ́n, ẹ jẹ́ kí ó di òmùgọ̀ kí ó bá a le è gbọ́n. 19 (M)Nítorí ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú Ìwé Mímọ́ pé, “Ẹni ti tí ó mu àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àrékérekè wọn”; 20 (N)lẹ́ẹ̀kan sí i, “Olúwa mọ̀ èrò inú àwọn ọlọ́gbọ́n pé asán ní wọn.” 21 (O)Nítorí kí ẹnikẹ́ni má ṣe ṣògo nínú ènìyàn. Nítorí tí yín ni ohun gbogbo. 22 (P)Ìbá ṣe Paulu, tàbí Apollo, tàbí Kefa, tàbí ayé tàbí ìyè, tàbí ikú, tàbí ohun ìsinsin yìí, tàbí ohun ìgbà tí ń bọ̀; tiyín ni gbogbo wọn. 23 Ẹ̀yin sì ni ti Kristi; Kristi sì ni ti Ọlọ́run.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.