M’Cheyne Bible Reading Plan
Kọ́ọ̀bù idẹ nínú àpò
44 Nígbà náà ni Josẹfu pàṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Di oúnjẹ kún inú àpò àwọn ọkùnrin náà tó ìwọ̀n èyí tí wọ́n le rù, kí o sì mú owó olúkúlùkù àwọn ọkùnrin náà padà sí ẹnu àpò rẹ̀. 2 Nígbà náà ni kí o mú kọ́ọ̀bù idẹ mi sí ẹnu àpò èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn nínú wọn pẹ̀lú owó tí ó fi ra ọkà,” ó sì ṣe bí Josẹfu ti sọ.
3 Bí ilẹ̀ ti ń mọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn padà lọ pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. 4 Wọn kò tí ì rìn jìnnà sí ìlú náà tí Josẹfu fi wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Lépa àwọn ọkùnrin náà, nígbà tí o bá sì bá wọn, kí o wí pé, ‘Èéṣe ti ẹ fi búburú san rere? 5 Èyí ha kọ́ ni kọ́ọ̀bù tí olúwa mi ń lò fún ohun mímu tí ó sì tún ń fi í ṣe àyẹ̀wò? Ohun tí ẹ ṣe yìí burú púpọ̀.’ ”
6 Nígbà tí ó sì bá wọn, o sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún wọn 7 Ṣùgbọ́n wọ́n dá a lóhùn pé, “Kí ló dé tí olúwa mi sọ irú nǹkan wọ̀nyí? Ká má rí i! Àwọn ìránṣẹ́ rẹ kò le ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀! 8 A tilẹ̀ mú owó tí a rí lẹ́nu àpò wa padà tọ̀ ọ́ wá láti ilẹ̀ Kenaani. Nítorí náà èéṣe tí àwa yóò fi jí wúrà tàbí idẹ ní ilé olúwa à rẹ? 9 Bí a bá rí i lọ́wọ́ èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ, kíkú ni yóò kú, àwọn tí ó kù yóò sì di ẹrú fún olúwa à rẹ.”
10 Ó wí pé, “Ó dára, kí ó rí bí ẹ ti ṣe sọ; Ẹnikẹ́ni tí mo bá rí i lọ́wọ́ rẹ̀ yóò di ẹrú mi. Ẹ̀yin tí ó kù yóò sì wà láìlẹ́bi.”
11 Olúkúlùkù wọn yára sọ àpò rẹ̀ kalẹ̀, wọ́n sì tú u. 12 Nígbà náà ni ìránṣẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí ní í wá a, bẹ̀rẹ̀ láti orí ẹ̀gbọ́n títí lọ sórí àbúrò pátápátá. Ó sì rí kọ́ọ̀bù náà nínú àpò ti Benjamini. 13 Nígbà tí wọ́n rí èyí, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọ́n sì banújẹ́ gidigidi, wọn tún ẹrù wọn dì sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọ́n sì padà sí inú ìlú.
14 Josẹfu sì wà nínú ilé nígbà tí Juda àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wọlé wá. Gbogbo wọn sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀. 15 Josẹfu wí fún wọn pé, “Èwo ni èyí tí ẹ ṣe yìí? Ṣe ẹ kò mọ pé, ènìyàn bí èmi le è rí ìdí nǹkan nípa ṣíṣe àyẹ̀wò?”
16 Juda dáhùn pé, “Kí ni à bá sọ fún olúwa mi? Báwo ni a ṣe lè wẹ ara wa mọ́? Ọlọ́run ti tú àṣírí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, a ti di ẹrú olúwa à mi báyìí àwa fúnra wa àti ẹni náà tí a rí kọ́ọ̀bù lọ́wọ́ rẹ̀.”
17 Ṣùgbọ́n Josẹfu dáhùn pé, “Ká má rí i pé mo ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀! Ẹni tí a bá kọ́ọ̀bù mi lọ́wọ́ rẹ̀ nìkan ni yóò di ẹrú mi, ẹ̀yin tí ó kù, ẹ máa lọ sọ́dọ̀ baba yín ní àlàáfíà.”
18 Nígbà náà ni Juda súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Jọ̀wọ́ olúwa mi, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ kí ó sọ ọ̀rọ̀ kan fún olúwa mi, má ṣe bínú sí ìránṣẹ́ rẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ pẹ̀lú láṣẹ bí i ti Farao. 19 Olúwa mi béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ ó ní baba tàbí arákùnrin?’ 20 Àwa sì wí fún olúwa mi pé, ‘A ni baba tí ó ti darúgbó, ọmọkùnrin kan sì wà pẹ̀lú tí a bí fún un ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan sì ni ó kù nínú àwọn ọmọ ìyá rẹ̀, baba rẹ̀ sì fẹ́ràn án rẹ̀.’
21 “Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ mu un tọ̀ mí wá kí n le fojú ara mi rí i.’ 22 A sì sọ fún olúwa à mi pé, ‘Ọmọkùnrin náà kò le è fi baba rẹ̀ sílẹ̀, bí ó bá dán an wò baba rẹ̀ yóò kú.’ 23 Ṣùgbọ́n ìwọ wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ má ṣe padà tọ̀ mí wá àyàfi bí àbíkẹ́yìn yín bá bá yín wá.’ 24 Nígbà tí a padà lọ sọ́dọ̀ baba wa, tí í ṣe ìránṣẹ́ rẹ, a sọ ohun tí olúwa à mi wí fún un.
25 “Nígbà náà ni baba wa wí pé, ‘Ẹ padà lọ láti lọ ra oúnjẹ díẹ̀ wá.’ 26 Ṣùgbọ́n a wí pe, ‘Àwa kò le è padà lọ, àyàfi bí àbúrò wa pátápátá yóò bá bá wa lọ. A kò le è rí ojú ọkùnrin náà àyàfi tí àbúrò wa bá lọ pẹ̀lú wa.’
27 “Baba mi, ìránṣẹ́ rẹ wí fún wa pé, ‘Ẹ mọ̀ pé ìyàwó mi bí ọmọkùnrin méjì fún mi. 28 Ọ̀kan nínú wọn lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, mo sì wí pé, “Dájúdájú a ti fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.” N kò sì tí ì ri láti ọjọ́ náà. 29 Tí ẹ bá tún mú èyí lọ, kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ohunkóhun bá ṣe é, ìbànújẹ́ ni ẹ ó fi mú ewú orí mi lọ sí ipò òkú.’
30 “Nítorí náà, bí a bá padà tọ baba wa lọ láìsí ọmọ náà pẹ̀lú wa nígbà tí a mọ̀ pé, ọmọ náà ni ẹ̀mí baba wa. 31 Tí ó bá ri pé ọmọkùnrin náà kò wá pẹ̀lú wa, yóò kùú. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ yóò wá mú baba wa tòun ti ewú orí lọ sí ipò òkú ní ìbànújẹ́. 32 Ìránṣẹ́ rẹ ló ṣe onídùúró fún ààbò ọmọ náà lọ́dọ̀ baba mi. Mo wí pé, ‘Bí n kò bá mú un padà tọ̀ ọ́ wá, baba mi, èmi ó ru ẹ̀bi rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé mi!’
33 “Nítorí náà, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ kí ó dúró ní ìhín lọ́dọ̀ olúwa à mi bí ẹrú dípò ọmọ náà. Kí ọmọ náà bá àwọn arákùnrin rẹ̀ padà. 34 Báwo ni mo ṣe lè padà tọ baba mi lọ láì bá ṣe pé ọmọ náà wà pẹ̀lú mi? Rárá, èmi kò fẹ́ kí n rí ìbànújẹ́ tí yóò dé bá baba mi.”
A da tùràrí sí ara Jesu
14 (A)Lẹ́yìn ọjọ́ méjì ni àjọ ìrékọjá àti tí àìwúkàrà, àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin sì ń wá ọ̀nà láti mú Jesu ní ìkọ̀kọ̀, kí wọn sì pa á. 2 Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, “A kò ní mú un ní ọjọ́ àjọ, kí àwọn ènìyàn má bá á fa ìjàngbọ̀n.”
3 (B)Nígbà tí ó sì wà ní Betani ni ilé Simoni adẹ́tẹ̀ bí ó ti jókòó ti oúnjẹ, obìnrin kan wọlé, ti òun ti alabasita òróró ìkunra olówó iyebíye, ó ṣí ìgò náà, ó sì da òróró náà lé Jesu lórí.
4 Àwọn kan nínú àwọn tí ó jókòó ti tábìlì kún fún ìbànújẹ́. Wọ́n sì ń bi ara wọn pé, “Nítorí kí ni a ṣe fi òróró yìí ṣòfò? 5 Òun ìbá ta òróró ìkunra yìí ju owó iṣẹ́ ọdún kan lọ, kí ó sì fi owó rẹ̀ ta àwọn tálákà lọ́rẹ.” Báyìí ni wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ gún obìnrin náà lára.
6 Ṣùgbọ́n Jesu wí fún pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, kí ni ẹ ń yọ ọ́ lẹ́nu fún ṣé nítorí tí ó ṣe ohun rere sí mi? 7 (C)Nígbà gbogbo ni àwọn tálákà wà ní àárín yín, wọ́n sì ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ yín. Ẹ sì lè ṣe oore fún wọn nígbàkúgbà tí ẹ bá fẹ́. 8 (D)Ó ti ṣe èyí tí ó lè ṣe, o ti fi òróró kùn mí ni ara ní ìmúrasílẹ̀ de ìgbà tí wọn yóò sin òkú mi. 9 Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, níbikíbi tí wọ́n bá ti wàásù mi, ní gbogbo ayé, wọn kò ní ṣe aláìsọ ohun tí obìnrin yìí ṣe pẹ̀lú ní ìrántí rẹ̀.”
10 (E)Nígbà náà ni Judasi Iskariotu, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, láti ṣètò bí yóò ti fi Jesu lé wọn lọ́wọ́. 11 Inú wọn dùn láti gbọ́ èyí, wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì ṣe ìlérí láti fún un ní owó. Nítorí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ àkókò tí ó rọrùn tí òun yóò fi Jesu lé wọn lọ́wọ́.
Oúnjẹ alẹ́ Olúwa
12 (F)Ní ọjọ́ kìn-ín-ní àjọ̀dún ìrékọjá tí í ṣe ọjọ́ tí wọ́n máa ń pa ẹran àgùntàn fún ìrúbọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu bi í léèrè pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a lọ pèsè sílẹ̀ tí ìwọ yóò ti jẹ àsè ìrékọjá?”
13 Ó rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sínú ìlú, ọkùnrin kan tó ru ìkòkò omi yóò pàdé yín, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. 14 Ilé tí ọkùnrin náà bá wọ̀, kí ẹ wí fún baálé náà pé, ‘Olùkọ́ rán wa pé: Níbo ni gbàngàn àpèjẹ náà gbé wa, níbi tí èmi yóò gbé jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’ 15 Òun yóò sì mú un yín lọ sí gbàngàn ńlá kan lókè ilé náà, tí a ti ṣe lọ́sọ́. Níbẹ̀ ni kí ẹ pèsè sílẹ̀ dè wá.”
16 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì jáde lọ àárín ìlú. Wọ́n bá gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Jesu tí sọ fún wọn. Wọ́n sì pèsè àsè ìrékọjá.
17 (G)Nígbà tí ó di alẹ́, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé síbẹ̀. 18 Bí wọ́n sì ti jókòó yí tábìlì ká, tí wọ́n ń jẹun, Jesu wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, ọ̀kan nínú ẹ̀yin tí ẹ ń bá mi jẹun yìí ni yóò fi mí hàn.”
19 Ọkàn wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í dàrú. Olúkúlùkù sì ń bi í ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wí pé, “Dájúdájú, kì í ṣe èmi?”
20 Ó sì dáhùn wí pé, “Ọ̀kan nínú ẹ̀yin méjìlá tí ó ń bá mi tọwọ́ bọ àwo jẹun nísinsin yìí ni. 21 Nítòótọ́ Ọmọ Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀: Ṣùgbọ́n ègbé ní fún ọkùnrin náà, láti ọwọ́ ẹni tí a ti fi Ọmọ Ènìyàn hàn. Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i rárá.”
22 (H)(I) Bí wọ́n ti ń jẹun lọ́wọ́, Jesu mú ìṣù àkàrà kan, ó gbàdúrà sí i. Lẹ́yìn náà ó bù ú sí wẹ́wẹ́, ó sì fi fún wọn. Ó wí pé, “Ẹ gbà jẹ, èyí yìí ni ara mi.”
23 (J)Bákan náà, ó sì mú ago wáìnì, ó dúpẹ́ fún un, ó sì gbé e fún wọn. Gbogbo wọn sì mu nínú rẹ̀.
24 (K)Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí májẹ̀mú tuntun, tí a ta sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn. 25 Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, èmi kò tún ní mu ọtí wáìnì mọ́ títí yóò fi di ọjọ́ náà tí Èmi yóò mu ún ní tuntun nínú ìjọba Ọlọ́run.”
26 (L)Lẹ́yìn náà wọ́n kọ orin, wọ́n sì gun orí òkè olifi lọ.
Jesu sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Peteru yóò sẹ́ òun
27 (M)Jesu sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ ó sa kúrò lọ́dọ̀ mi, a ti kọ̀wé rẹ pé:
“ ‘Èmi yóò lu olùṣọ́-àgùntàn
àwọn agbo àgùntàn yóò sì fọ́nká.’
28 (N)Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà ti mo ba jíǹde tan, Èmi yóò síwájú yin lọ sí Galili.”
29 Ṣùgbọ́n Peteru dá a lóhùn, ó wí pé, “Bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ sá kúrò lẹ́yìn rẹ, èmi kò ní sá.”
30 (O)Jesu si wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń sọ òótọ́ fún ọ. Kí àkùkọ tó ó kọ lẹ́ẹ̀kejì ní òwúrọ̀ ọ̀la, ìwọ, pàápàá yóò ti sọ lẹ́ẹ̀mẹ́ta wí pe ìwọ kò mọ̀ mí rí.”
31 Ṣùgbọ́n Peteru fa ara ya, ó wí pé, “Bí mo tilẹ̀ ní láti kú pẹ̀lú rẹ̀, èmi kò jẹ́ sọ pé n kò mọ̀ ọ́n rí.” Ìlérí yìí kan náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe.
Ọgbà Getsemane
32 (P)Nígbà tí wọ́n dé ibi kan tí wọ́n ń pè ní ọgbà Getsemane. Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jókòó dè mí níhìn-ín títí n ó fi lọ gbàdúrà.” 33 Ó sì mú Peteru àti Jakọbu àti Johanu lọ pẹ̀lú rẹ̀. Òun sì kún fún ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìbànújẹ́ gidigidi. 34 (Q)Ó sì wí fún wọn pé, “ọkàn mi ń káàánú gidigidi títí dé ojú ikú. Ẹ dúró níhìn-ín kí ẹ sì máa bá mi ṣọ́nà.”
35 Ó sì lọ síwájú díẹ̀, ó dojúbo ilẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i gbàdúrà pé, bí ó bá ṣe e ṣe kí wákàtí tí ó bọ̀ náà ré òun kọjá. 36 (R)Ó sì wí pé, “Ábbà, Baba, ìwọ lè ṣe ohun gbogbo, mú ago yìí kúrò lórí mi, ṣùgbọ́n kì í ṣe èyí tí èmi fẹ́, bí kò ṣe èyí tí ìwọ fẹ́.”
37 Nígbà tí ó sì padà dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́ta, ó bá wọn lójú oorun. Ó sì wí fún Peteru pé, “Simoni, o ń sùn ni? Ìwọ kò lè bá mi ṣọ́nà fún wákàtí kan? 38 (S)Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà, ki ẹ má ba à bọ́ sínú ìdánwò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ‘Ẹ̀mí ń fẹ́ ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara.’ ”
39 Ó sì tún lọ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó sì gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti gbà á ti ìṣáájú. 40 Nígbà tí ó sì tún padà dé, ó bá wọn wọ́n ń sùn, nítorí pé ojú wọn kún fún oorun. Wọn kò sì mọ irú èsì tí wọn ìbá fún un.
41 Ó sì wá nígbà kẹta, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa sùn kí ẹ sì máa sinmi ó tó bẹ́ẹ̀, wákàtí náà ti dé, wò ó, a fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. 42 Ẹ dìde, Ẹ jẹ́ kí a máa lọ. Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mí hàn wà ní tòsí!”
A mú Jesu
43 (T)Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, lójú ẹsẹ̀ náà ni Judasi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá dé pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti idà àti kùmọ̀ lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà, àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn àgbàgbà Júù ni ó rán wọn wá.
44 Judasi tí fi ààmì fún wọn wí pe, “Ẹni tí mo bá fi ẹnu kò lẹ́nu nínú wọn, òun ní Jesu, Ẹ mú un.” 45 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, Judasi lọ sì ọ̀dọ̀ rẹ̀ tààrà, ó wí pé, “Rabbi!” ó sì fi ẹnu kò Jesu lẹ́nu. 46 Wọ́n sì mú Jesu. 47 Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn tí ó dúró fa idà rẹ̀ yọ, ó fi ṣá ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé etí rẹ̀ bọ́ sílẹ̀.
48 Nígbà náà Jesu dáhùn, ó bi wọ́n léèrè pé, “Ṣé Èmi ni ẹ̀yin jáde tọ̀ wá bi olè, ti ẹ̀yin ti idà àti kùmọ̀ láti mú? 49 (U)Ojoojúmọ́ ni èmi wà pẹ̀lú yín ní tẹmpili, tí mo ń kọ́ni; ẹ kò mú mi. Ṣùgbọ́n eléyìí ṣẹlẹ̀, kí ohun tí ìwé Mímọ́ wí lè ṣẹ.” 50 Ní àkókò yìí, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti fi í sílẹ̀, wọ́n sálọ.
51 Ọ̀dọ́mọkùnrin kan sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn tí ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ bo ìhòhò rẹ̀ àwọn ọmọ-ogun gbìyànjú láti mú òun náà. 52 Ó sì fi aṣọ funfun náà sílẹ̀ fún wọn, ó sì sálọ ní ìhòhò.
Jesu níwájú ìgbìmọ̀ Sahẹndiri
53 (V)Wọ́n mú Jesu lọ sí ilé olórí àlùfáà, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù àti àwọn olùkọ́ òfin péjọ síbẹ̀. 54 Peteru tẹ̀lé Jesu lókèèrè, ó sì yọ́ wọ inú àgbàlá olórí àlùfáà, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, ó ń yáná.
55 Bí ó ti ń ṣe èyí lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ ilé ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ń wá ẹni tí yóò jẹ́rìí èké sí Jesu, èyí tí ó jọjú dáradára láti lè dájọ́ ikú fún un. Ṣùgbọ́n wọn kò rí. 56 Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí wọ́n ní kò bá ara wọn mu.
57 Níkẹyìn àwọn kan dìde, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́rìí èké sí i, wọ́n ní 58 (W)“A gbọ́ tí ó wí pé ‘Èmi yóò wó tẹmpili tí ẹ fi ọwọ́ kọ́ yìí, nígbà tí yóò bá sì fi di ọjọ́ kẹta, èmi yóò kọ́ òmíràn ti a kò fi ọwọ́ ènìyàn kọ́.’ ” 59 Síbẹ̀, ẹ̀rí i wọn kò dọ́gba.
60 Nígbà náà ni àlùfáà àgbà dìde, ó bọ́ síwájú. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bi Jesu léèrè, ó ní, “Ṣé o kò ní fèsì sí ẹ̀sùn tí wọ́n fi sùn ọ? Kí ni ìwọ gan an ní sọ fúnrarẹ̀?” 61 Ṣùgbọ́n Jesu dákẹ́.
Olórí àlùfáà tún bi í, lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ní, “Ṣé ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Olùbùkún un nì?”
62 (X)Jesu wá dáhùn, ó ni, “Èmi ni: Ẹ̀yin yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára. Ẹ̀yin yóò sì tún rí Ọmọ Ènìyàn tí ó ń bọ̀ láti inú àwọsánmọ̀ ojú ọ̀run.”
63 (Y)Nígbà náà ni Olórí àlùfáà fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ní, “Kí ló kù tì a ń wá? Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rìí fún? 64 (Z)Ẹ̀yin fúnrayín ti gbọ́ ọ̀rọ̀-òdì tí ó sọ. Kí ni ẹ rò pé ó tọ́ kí a ṣe?”
Gbogbo wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ó jẹ̀bi ikú.” 65 Àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í tu itọ́ sí i lára. Wọ́n dì í lójú. Wọ́n ń kàn án lẹ́ṣẹ̀ẹ́ lójú. Wọ́n fi ṣe ẹlẹ́yà pé, “Sọtẹ́lẹ̀!” Àwọn olùṣọ́ sì ń fi àtẹ́lẹwọ́ wọn gbá a lójú.
Peteru sẹ́ Jesu
66 (AA)Ní àkókò yìí Peteru wà ní ìsàlẹ̀ inú àgbàlá ilé ìgbẹ́jọ́. Nínú àgbàlá yìí, ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àlùfáà àgbà kíyèsi í tí Peteru ń yáná. 67 Nígbà tí ó rí Peteru tí ó ti yáná, Ó tẹjúmọ́ ọn.
Ó sì sọ gbangba pé, “Ìwọ pàápàá wà pẹ̀lú Jesu ara Nasareti.”
68 Ṣùgbọ́n Peteru sẹ́, ó ni, “N kò mọ Jesu náà rí; ohun tí ó ń sọ yìí kò tilẹ̀ yé mi.” Peteru sì jáde lọ sí ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ilé ìgbẹ́jọ́. Àkùkọ sì kọ.
69 Ọmọbìnrin náà sì tún rí Peteru. Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀. Ó ní, “Ọkùnrin yìí gan an jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu.” 70 Ṣùgbọ́n Peteru tún sẹ́.
Nígbà tí ó sí túnṣe díẹ̀ sí i, àwọn tí wọ́n dúró lẹ́gbẹ́ Peteru wá wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni, ọ̀kan ní ara wọn ni ìwọ í ṣe. Nítorí ará Galili ni ìwọ, èdè rẹ sì jọ bẹ́ẹ̀.”
71 Nígbà náà ni Peteru bẹ̀rẹ̀ sí í sẹ́ ó sì ń búra, ó ni, “N kò mọ ẹni ti ẹ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yí rí!”
72 Lójúkan náà tí àkùkọ yìí kọ lẹ́ẹ̀kejì Peteru rántí ọ̀rọ̀ Jesu fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀méjì, ìwọ yóò sẹ́ mí nígbà mẹ́ta.” Ó sì rẹ̀ ẹ́ láti inú ọkàn wá, ó sì sọkún.
Àròyé Jobu tẹ̀síwájú
10 “Agara ìwà ayé mi dá mi tán,
èmi yóò tú àròyé mi sókè lọ́dọ̀ mi,
èmi yóò máa sọ̀rọ̀ nínú kíkorò ìbìnújẹ́ ọkàn mi.
2 Èmi yóò wí fún Ọlọ́run pé: má ṣe dá mi lẹ́bi;
fihàn mí nítorí ìdí ohun tí ìwọ fi ń bá mi jà.
3 Ó ha tọ́ tí ìwọ ìbá fi máa ni mí lára,
tí ìwọ ìbá fi máa gan iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,
tí ìwọ yóò fi máa tàn ìmọ́lẹ̀ sí ìmọ̀ ènìyàn búburú.
4 Ojú rẹ kì ha ṣe ojú ènìyàn bí?
Tàbí ìwọ a máa ríran bí ènìyàn ti í ríran?
5 Ọjọ́ rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn,
ọdún rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn?
6 Tí ìwọ fi ń béèrè àìṣedéédéé mi,
tí ìwọ sì fi wá ẹ̀ṣẹ̀ mi rí?
7 Ìwọ mọ̀ pé èmi kì í ṣe oníwà búburú,
kò sì sí ẹni tí ó le gbà mí kúrò ní ọwọ́ rẹ?
8 “Ọwọ́ rẹ ni ó mọ mi, tí ó sì da mi.
Síbẹ̀ ìwọ tún yípadà láti jẹ mí run.
9 Èmi bẹ̀ ọ́ rántí pé ìwọ ti mọ mí bí amọ̀;
ìwọ yóò ha sì tún mú mi padà lọ sínú erùpẹ̀?
10 Ìwọ kò ha ti tú mí dà jáde bí i wàrà,
ìwọ kò sì mú mí dìpọ̀ bí i wàràǹkàṣì?
11 Ìwọ sá ti fi àwọ̀ ẹran-ara wọ̀ mí,
ìwọ sì fi egungun àti iṣan ṣọgbà yí mi ká.
12 Ìwọ ti fún mi ní ẹ̀mí àti ojúrere,
ìbẹ̀wò rẹ sì pa ọkàn mi mọ́.
13 “Nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ sì ti fi pamọ́ nínú rẹ;
èmi mọ̀ pé, èyí ń bẹ ní ọkàn rẹ.
14 Bí mo bá ṣẹ̀, nígbà náà ni ìwọ yóò máa ṣọ́ mi
ìwọ kì yóò sì dárí àìṣedéédéé mi jì.
15 Bí mo bá ṣe ẹni búburú, ègbé ni fún mi!
Bí mo bá sì ṣe ẹni rere,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì le gbe orí mi sókè.
Èmi dààmú, mo si wo ìpọ́njú mi.
16 Bí mo bá gbé orí mi ga. Ìwọ ń dẹ mí kiri bi i kìnnìún;
àti pẹ̀lú, ìwọ a sì fi ara rẹ hàn fún mi ní ìyànjú.
17 Ìwọ sì tún mun àwọn ẹlẹ́rìí rẹ dìde sí mi
di ọ̀tún, Ìwọ sì sọ ìrunú rẹ di púpọ̀ sí mi;
Àwọn ogun rẹ si dìde sinmi bi igbe omi Òkun.
18 “Nítorí kí ni ìwọ ṣe mú mi jáde láti inú wá?
Háà! Èmi ìbá kúkú ti kú, ojúkójú kì bá tí rí mi.
19 Tí kò bá le jẹ́ pé èmi wà láààyè,
À bá ti gbé mi láti inú lọ isà òkú.
20 Ọjọ́ mi kò ha kúrú bí? Rárá!
Dáwọ́ dúró, kí ó sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ mi.
Nítorí kí èmi lè ni ayọ̀ ní ìṣẹ́jú kan.
21 Kí èmi kí ó tó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà sẹ́yìn mọ́,
Àní si ilẹ̀ òkùnkùn àti òjìji ikú.
22 Ilẹ̀ òkùnkùn bí òkùnkùn tìkára rẹ̀,
Àti ti òjìji ikú àti rúdurùdu,
Níbi tí ìmọ́lẹ̀ dàbí òkùnkùn.”
Aláìlera àti alágbára
14 Ẹ gba ẹni tí ó bá ṣe àìlera ní ìgbàgbọ́ mọ́ra, kí ẹ má ṣe tọpinpin ìṣeyèméjì rẹ̀. 2 Ẹnìkan gbàgbọ́ pé òun lè máa jẹ ohun gbogbo: ṣùgbọ́n ẹlòmíràn tí ó sì jẹ́ aláìlera ní ìgbàgbọ́ ń jẹ ewébẹ̀ nìkan. 3 (A)Kí ẹni tí ń jẹ ohun gbogbo má ṣe kẹ́gàn ẹni tí kò jẹ; kí ẹni tí kò sì jẹ ohun gbogbo kí ó má ṣe dá ẹni tí ń jẹ lẹ́bi: nítorí Ọlọ́run ti gbà á. 4 Ta ni ìwọ láti dá ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn lẹ́jọ́? Lójú olúwa tirẹ̀ ni òun dúró, tàbí ṣubú. Òun yóò sì dúró nítorí Ọlọ́run ní agbára láti mú kí òun dúró.
5 (B)Ẹnìkan bu ọlá fún ọjọ́ kan ju òmíràn; ẹlòmíràn bu ọlá fún ọjọ́ gbogbo bákan náà. Kí olúkúlùkù kí ó dá ara rẹ̀ lójú ní inú ara rẹ̀. 6 Ẹni tí ó bá ya ọjọ́ kan sí ọ̀tọ̀, ó ń yà á sọ́tọ̀ fún Olúwa. Ẹni tí ó ń jẹ ẹran, ó ń jẹ ẹran fún Olúwa, nítorí pé òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run; ẹni tí kò bá sì jẹ ẹran, kò jẹ ẹran fún Olúwa, òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. 7 (C)Nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè fún ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó kú fún ara rẹ̀. 8 (D)Bí a bá wà láààyè, a wà láààyè fún Olúwa; bí a bá sì kú, a kú fún Olúwa. Nítorí náà, bí a wà láààyè, tàbí bí a kú, ti Olúwa ni àwa i ṣe. 9 Nítorí ìdí èyí náà ni Kristi ṣe kú, tí ó sì tún yè, kí ó bá le jẹ́ Olúwa òkú àti alààyè.
10 (E)Èéṣe nígbà náà tí ìwọ fi ń dá arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ lẹ́jọ́? Tàbí èéṣe tí ìwọ fi ń gàn wọn? Nítorí gbogbo wa ni yóò dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run. 11 (F)A ti kọ ìwé rẹ̀ pé:
“ ‘Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè,’ ni Olúwa wí,
‘gbogbo eékún ni yóò wólẹ̀ fún mi;
gbogbo ahọ́n ni yóò jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run.’ ”
12 Ǹjẹ́ nítorí náà, olúkúlùkù wa ni yóò jíyìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.
13 (G)Nítorí náà, ẹ má ṣe tún jẹ́ kí a máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ẹ pinu nínú ọkàn yín láti má ṣe fi ohun ìkọ̀sẹ̀ tàbí òkúta ìdìgbòlù kankan sí ọ̀nà arákùnrin tàbí arábìnrin yín. 14 Mo mọ̀ dájú gbangba bí ẹni tí ó wà nínú Jesu Olúwa pé, kò sí ohun tó ṣe àìmọ́ fún ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ka ohunkóhun sí àìmọ́, òun ni ó ṣe àìmọ́ fún. 15 (H)Bí inú arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ ba bàjẹ́ nítorí oúnjẹ rẹ, ìwọ kò rìn nínú ìfẹ́ mọ́. Má ṣe fi oúnjẹ rẹ sọ ẹni tí Kristi kú fún di ẹni ègbé. 16 (I)Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sọ̀rọ̀ ohun tí ẹ mọ̀ sí rere ní búburú. 17 Nítorí ìjọba ọ̀run kì í ṣe jíjẹ àti mímu, bí kò ṣe nípa ti òdodo, àlàáfíà àti ayọ̀ nínú Ẹ̀mí Mímọ́, 18 nítorí ẹni tí ó bá sin Kristi nínú nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì ní ìyìn lọ́dọ̀ ènìyàn.
19 (J)Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a ṣa gbogbo ipá wa láti máa lépa àlàáfíà, àti ohun tí àwa yóò fi gbé ara wa ró. 20 (K)Má ṣe bi iṣẹ́ Ọlọ́run ṣubú nítorí oúnjẹ. Gbogbo oúnjẹ ni ó mọ́, ṣùgbọ́n ohun búburú ni fún ẹni náà tí ó jẹ ohunkóhun tí ó le mú ẹlòmíràn kọsẹ̀. 21 (L)Ó dára kí a má tilẹ̀ jẹ ẹran tàbí mu wáìnì tàbí ṣe ohunkóhun tí yóò mú arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ ṣubú.
22 (M)Nítorí náà, ohun tí ìwọ bá gbàgbọ́ nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí, pa á mọ́ ní àárín ìwọ àti Ọlọ́run. Alábùkún fún ni ẹni náà tí kò dá ara rẹ̀ lẹ́bi nínú ohun tí ó yàn. 23 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ṣe iyèméjì, ó jẹ̀bi bí ó ba jẹ ẹ́, nítorí jíjẹ ẹ́ rẹ̀ kò ti inú ìgbàgbọ́ wá; bẹ́ẹ̀ sì ni, ohun gbogbo tí kò bá ti inú ìgbàgbọ́ wá, ẹ̀ṣẹ̀ ni.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.