M’Cheyne Bible Reading Plan
Àwọn arákùnrin Josẹfu lọ sí Ejibiti
42 Nígbà tí Jakọbu mọ̀ pé ọkà wà ní Ejibiti, ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pé, “Èéṣe tí ẹ ń wo ara yín lásán?” 2 (A)“Mo tí gbọ́ pé ọkà wà ní ilẹ̀ Ejibiti. Ẹ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibẹ̀ kí ẹ sì rà wá fún wa, kí a má ba à kú.”
3 Nígbà náà ni mẹ́wàá nínú àwọn arákùnrin Josẹfu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti láti ra ọkà. 4 Ṣùgbọ́n Jakọbu kò rán Benjamini àbúrò Josẹfu lọ pẹ̀lú wọn nítorí ẹ̀rù ń bà á kí aburú má ba à ṣẹlẹ̀ sí i. 5 (B)Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli wà lára àwọn tó lọ Ejibiti lọ ra oúnjẹ nítorí ìyàn náà mú ni ilẹ̀ Kenaani pẹ̀lú.
6 Nísinsin yìí, Josẹfu ni alábojútó fún gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, òun sì ni ó ń bojútó ọkà títà fún gbogbo ènìyàn ìlú náà. Nítorí náà nígbà tí àwọn arákùnrin Josẹfu dé, wọ́n tẹríba, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Josẹfu. 7 Lọ́gán tí Josẹfu ti rí àwọn arákùnrin rẹ̀ ni ó ti dá wọn mọ̀, ṣùgbọ́n ó ṣe bí i wí pé kò mọ̀ wọ́n, ó sì sọ̀rọ̀ líle sí wọn. Ó béèrè pé, “Níbo ni ẹ ti wá?”
Wọ́n sì dáhùn pé, “Láti ilẹ̀ Kenaani ni a ti wá ra oúnjẹ.”
8 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, Josẹfu mọ àwọn arákùnrin rẹ̀, síbẹ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ kò mọ̀ ọ́n. 9 (C)Nígbà náà ni ó rántí àlá rẹ̀ tí ó lá sí wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Ayọ́lẹ̀wò (Amí) ni yín, ẹ wá láti wo àṣírí ilẹ̀ wa ni.”
10 Wọ́n dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ olúwa wa, àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá láti ra oúnjẹ ni, 11 Ọmọ baba ni wá, olóòtítọ́ ènìyàn sì ni wá pẹ̀lú, àwa kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò.”
12 Ó wí fún wọn pé, “Rárá! Ẹ wá láti wo àṣírí ilẹ̀ wa ni.”
13 Ṣùgbọ́n wọ́n tún dáhùn pé, “Arákùnrin méjìlá ni àwa ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ baba kan náà, tí ó ń gbé ní ilẹ̀ Kenaani. Èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wa ń bẹ lọ́dọ̀ baba wa, ọ̀kan sì ti kú.”
14 Josẹfu wí fún wọn pé, “Bí mo ti wí fún un yín náà ni: Ayọ́lẹ̀wò ni yín! 15 Èyí sì ni a ó fi dán an yín wò, èmi búra pé, níwọ̀n ìgbà tí Farao bá wà láààyè, ẹ kì yóò kúrò níbí, àyàfi bí arákùnrin yín kan tókù bá wá sí ibí. 16 Ẹ rán ọ̀kan nínú yín lọ láti mú arákùnrin yín wá, àwa yóò fi ẹ̀yin tókù pamọ́ sínú túbú, kí àwa ba à lè mọ bóyá òtítọ́ ni ẹ̀yin ń wí. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé irọ́ ni ẹ̀yin ń pa, ní òtítọ́ bí Farao ti ń bẹ láààyè ayọ́lẹ̀wò ni yín!” 17 Ó sì fi gbogbo wọn sínú túbú fún ọjọ́ mẹ́ta.
18 Ní ọjọ́ kẹta, Josẹfu wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe kí ẹ̀yin ba à le yè nítorí mo bẹ̀rù Ọlọ́run: 19 Tí ó bá jẹ́ pé olóòtítọ́ ènìyàn ni yín, ẹ jẹ́ kí ọ̀kan nínú yín dúró ni túbú ní ìhín, nígbà tí àwọn yòókù yín yóò gbé ọkà lọ fún àwọn ará ilé e yín tí ebi ń pa. 20 Ṣùgbọ́n ẹ gbọdọ̀ mú arákùnrin tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn yín wá, kí n ba à le mọ òtítọ́ ohun ti ẹ ń wí, kí ẹ má ba à kú.” Wọn sì gbà láti ṣe èyí.
21 Wọ́n ń sọ ọ́ láàrín ara wọn wí pé, “Àwa jẹ̀bi nítòótọ́ nípa ti arákùnrin wa. A rí ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀ nígbà tí ó ń bẹ̀ wá nítorí ẹ̀mí rẹ̀, ṣùgbọ́n a kò gbẹ́bẹ̀, nítorí náà ni ìdààmú yìí fi dé bá wa.”
22 (D)Reubeni dá wọn ní ohùn pé, “Èmi kò wí fún yín pé kí ẹ má se ṣẹ̀ sí ọmọdékùnrin náà? Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́! ṣùgbọ́n nísinsin yìí a ń béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ wa.” 23 Wọn kò sì mọ̀ pé, Josẹfu ń gbọ́ wọn ní àgbọ́yé nítorí ògbufọ̀ ni ó ń lò tẹ́lẹ̀.
24 Ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún. Ó sì tún yí padà sí wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀. Ó mú Simeoni kúrò láàrín wọn, ó sì dè é ní ojú wọn.
25 Josẹfu pàṣẹ pé kí wọn bu ọkà kún inú àpò wọn, kí wọn sì mú owó ẹnìkọ̀ọ̀kan padà sínú àpò rẹ̀, kí wọn sì fún wọn ní ohun tí wọn yóò lò nírín-àjò wọn padà sílé. Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe èyí fún wọn, 26 Wọn gbé ẹrù wọn lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọn sì padà lọ sí ilé.
27 Níbi tí wọ́n ti dúró láti sùn lóru ọjọ́ náà, ọ̀kan nínú wọn tú àpò rẹ̀ láti mú oúnjẹ fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì rí owó rẹ̀ ní ẹnu àpò rẹ̀. 28 Ó sì wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “a ti dá owó mi padà, òun nìyí ní ẹnu àpò mi.”
Ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì ń gbọ̀n, wọ́n sì wí pé, “Èwo nìyí tí Ọlọ́run ṣe sí wa yìí.”
29 Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un wí pé, 30 “Ọkùnrin náà tí í ṣe alábojútó ilẹ̀ náà, sọ̀rọ̀ líle sí wa, ó sì fi ẹ̀sùn kàn wá pé a wá yọ́ ilẹ̀ náà wò ni. 31 Ṣùgbọ́n, a wí fún un pé, ‘Rárá o, olóòtítọ́ ènìyàn ni wá, a kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò. 32 Arákùnrin méjìlá ni wá, ọmọ baba kan náà, ọ̀kan ti kú, èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wà lọ́dọ̀ baba wa ni ilẹ̀ Kenaani.’
33 “Nígbà náà ni ọkùnrin tí ó jẹ́ alábojútó ilẹ̀ náà wí fún wa pé, ‘Báyìí ni n ó ṣe mọ̀ bóyá olóòtítọ́ ènìyàn ni yín; Ẹ fi ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin yín sílẹ̀ níbí, pẹ̀lú mi, ẹ sì mú oúnjẹ lọ fún àwọn ará ilé yín tí ebi ń pa kú lọ, lọ́wọ́ ìyàn. 34 Ṣùgbọ́n ẹ mú arákùnrin yín tí ó kéré jùlọ wá fún mi kí n le mọ̀ pé dájúdájú ẹ kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò bí kò ṣe ènìyàn tòótọ́. Nígbà náà ni n ó mú arákùnrin yín padà fún un yín, lẹ́yìn náà ẹ le máa wá ṣe òwò bí ó ti wù yín ní ilẹ̀ yìí.’ ”
35 Bí wọ́n sì ti ń tú àpò ẹrù wọn, ẹnìkọ̀ọ̀kan bá owó tí ó san fún ọjà náà lẹ́nu àpò rẹ̀! Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi, àwọn àti baba wọn. 36 Jakọbu baba wọn wí fún wọn pé, “Ẹ ti mú mi pàdánù àwọn ọmọ mi. N kò rí Josẹfu mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì rí Simeoni náà mọ. Ẹ sì tún fẹ́ mú Benjamini lọ! Èmi ni gbogbo ohun búburú yìí wá ń ṣẹlẹ̀ sí.”
37 Nígbà náà ni Reubeni wí fún baba rẹ̀ pé, “Pa àwọn ọmọ mi méjèèjì bí n kò bá mú Benjamini padà wá fún ọ, èmi ni kí o fà á lé lọ́wọ́, n ó sì mu un padà wá.”
38 Ṣùgbọ́n Jakọbu wí pé, “Ọmọ mi kì yóò bá a yín lọ, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan sì ni ó kù nínú àwọn ọmọ ìyá rẹ̀. Bí ohunkóhun bá ṣẹlẹ̀ sí i, ìbànújẹ́ ni yóò sì pa mi kú ni ọjọ́ ogbó mi yìí.”
Òwe àwọn ayálégbé
12 (A)Lẹ́yìn ìgbà tí Jesu pa àwọn olórí ẹ̀sìn lẹ́nu mọ́: ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan. Ó ṣe ọgbà yìí ká, ó sì wá ibi ìfúntí wáìnì, ó sì kọ́ ilé ìṣọ́ sí i ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùṣọ́gbà, ó sì lọ sí ìrìnàjò tí ó jìnnà. 2 Lákokò ìkórè, ọkùnrin náà rán ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí àwọn olùṣọ́gbà náà, kí ó gbà nínú èso ọgbà àjàrà náà lọ́wọ́ àwọn olùṣọ́gbà. 3 Ṣùgbọ́n àwọn àgbẹ̀ wọ̀n-ọn-nì lu ìránṣẹ́ ọkùnrin náà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo. 4 Ó sì tún rán ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn sí wọn. Bí àwọn àgbẹ̀ ti tún rí ọmọ ọ̀dọ̀ tí ó rán sí wọn; wọ́n lù ú. Àní, wọ́n tilẹ̀ dá ọgbẹ́ sí i lórí, wọn rán an lọ ni ìtìjú. 5 Ó sì tún rán òmíràn, èyí n nì wọ́n sì pa, àti ọ̀pọ̀ mìíràn, wọ́n lu òmíràn wọ́n sì pa òmíràn.
6 “Ìránṣẹ́ kan ṣoṣo ló kù tí Baba olóko kò ì tí ì rán níṣẹ́, èyí ni ọmọ òun tìkára rẹ̀. Níkẹyìn ó ran an sí àwọn olùṣọ́gbà náà, pẹ̀lú èrò pé, ‘Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ òun.’
7 “Ṣùgbọ́n àwọn olùṣọ́gbà wọ̀n-ọn-nì wí fún ara wọn pé, ‘Èyí yìí ni àrólé. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, ogún rẹ̀ yóò sì jẹ́ tiwa.’ 8 Báyìí ni wọ́n mú ọmọ náà tí wọ́n pa á. Wọ́n sì wọ́ òkú rẹ̀ jáde kúrò nínú ọgbà àjàrà náà.
9 “Kí ni olúwa ọgbà àjàrà yóò ṣe nígbà tí ó bá gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Dájúdájú yóò pa àwọn ẹni ibi wọ̀nyí. Yóò sì gba àwọn olùtọ́jú mìíràn sínú oko rẹ̀. 10 (B)Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ka ẹsẹ yìí nínú ìwé mímọ́:
“ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀
òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé.
11 Èyí ni iṣẹ́ Olúwa
ó sì jẹ́ ìyàlẹ́nu lójú tiwa’?”
12 (C)Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin pẹ̀lú àwọn àgbàgbà fẹ́ mú Jesu lákokò náà. Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ló ń pòwe mọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn ni alágbàtọ́jú búburú nínú ìtàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà wọ́n láti fọwọ́ kàn án nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìhùwàsí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí náà wọ́n fi í sílẹ̀ lọ.
Sísan owó orí fún Kesari
13 (D)(E) Ṣùgbọ́n wọ́n rán àwọn Farisi pẹ̀lú àwọn kan tí í ṣe ọmọ-ẹ̀yìn Herodu wá sọ́dọ̀ Jesu, láti fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, títí yóò fi sọ ohun kan kí wọn lè rí fi mú. 14 Bí wọn ti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé: “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé ìwọ máa ń sọ òtítọ́ láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Ṣùgbọ́n òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ máa ń kọ́ni. Nísinsin yìí, sọ fún wa, ó tọ́ tàbí kò tọ́ láti máa san owó orí fún Kesari?” 15 Kí àwa kí ó fi fún un, tàbí kí a máa fi fún un?
Ṣùgbọ́n Jesu mọ ìwà àgàbàgebè wọn. Ó sì wí pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi n fi èyí dán mi wo? Ẹ mú owó idẹ kan wá kí n wò ó.” 16 Nígbà tí wọ́n mú owó idẹ náà fún un, ó bi wọ́n léèrè pé, “Ẹ wò ó! Àwòrán àti orúkọ ta ni ó wà níbẹ̀?”
Wọ́n dáhùn pé, “Àwòrán àti orúkọ Kesari ni.”
17 (F)Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Kesari fún Kesari. Ṣùgbọ́n ẹ fi ohun gbogbo tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”
Ẹnu sì yà wọ́n gidigidi sí èsì rẹ̀.
Ìgbéyàwó ní àjíǹde
18 (G)Àwọn Sadusi tún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn wọ̀nyí kò gbàgbọ́ pé àjíǹde ń bẹ. Ìbéèrè wọn ni pé, 19 (H)“Olùkọ́, Mose fún wa ní òfin pé: Nígbà tí ọkùnrin kan bá kú láìbí ọmọ, arákùnrin rẹ̀ gbọdọ̀ ṣú ìyàwó náà lópó kí wọn sì bímọ ní orúkọ ọkọ tí ó kú náà. 20 Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan wà, èyí tí ó dàgbà jùlọ gbéyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ. 21 Arákùnrin rẹ̀ kejì ṣú obìnrin tí ó fi sílẹ̀ lópó, láìpẹ́, òun pẹ̀lú tún kú láìbímọ. Arákùnrin kẹta tó ṣú obìnrin yìí lópó tún kú bákan náà láìbímọ. 22 Àwọn méjèèje sì ṣú u lópó, wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀. Ní ìkẹyìn gbogbo wọn, obìnrin náà kú pẹ̀lú. 23 Ǹjẹ́ ní àjíǹde, nígbà tí wọ́n bá jíǹde, aya ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Àwọn méjèèje ni ó sá ni ní aya?”
24 Jesu dáhùn ó wí fún wọn pé, “Kì í há ṣe nítorí èyí ni ẹ ṣe ṣìnà, pé ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́, tàbí agbára Ọlọ́run. 25 Nítorí pé, nígbà tí àwọn arákùnrin méje yìí àti obìnrin náà bá jí dìde nínú òkú, a kò ní ṣe ìgbéyàwó fún wọn. Wọn yóò dàbí àwọn angẹli tí ń bẹ ní ọ̀run. 26 (I)Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa bóyá àjíǹde yóò wà. Àbí ẹ̀yin kò ì tí ka ìwé Eksodu, nípa Mose àti pápá tí ń jó? Ọlọ́run sọ fún Mose pé, ‘Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu.’ 27 Òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú bí kò ṣe Ọlọ́run àwọn alààyè: nítorí ẹ̀yin ṣe àṣìṣe gidigidi.”
Òfin tí ó ga jùlọ
28 (J)Ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ òfin ti ó dúró níbẹ̀ tí ó sì fetísílẹ̀ dáradára sí àròyé yìí ṣàkíyèsí pé, Jesu ti dáhùn dáradára. Òun pẹ̀lú sì béèrè lọ́wọ́ Jesu pé, “Nínú gbogbo òfin, èwo ló ṣe pàtàkì jùlọ?”
29 (K)Jesu dá ọkùnrin yìí lóhùn pé, “Èyí tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú àwọn òfin ni èyí tí ó kà báyìí pé: ‘Gbọ́ Israẹli; Olúwa Ọlọ́run wa Olúwa kan ni. 30 Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo ẹ̀mí rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, èyí ní òfin kìn-ín-ní.’ 31 (L)Èkejì ni pé: ‘Fẹ́ ọmọnìkejì rẹ.’ Kò sí òfin mìíràn tó ga ju méjèèjì yìí lọ.”
32 Olùkọ́ òfin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, ìwọ sọ òtítọ́ nípa pé Ọlọ́run kan ni ó ń bẹ, àti pé kò sí òmíràn àfi òun nìkan. 33 (M)Àti kí a fi gbogbo àyà, àti gbogbo òye, àti gbogbo ọkàn àti gbogbo agbára fẹ́ ẹ, àti fẹ́ ọmọnìkejì ẹni bí ara ẹni, ó ju gbogbo ẹbọ sísun, àti ẹbọ lọ.”
34 Jesu rí i dájú pé òye ọkùnrin yìí ga, nítorí náà, Jesu sọ fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ kò jìnà sí à ti dé ìjọba Ọ̀run.” Láti ìgbà náà lọ, ẹnikẹ́ni kò tún béèrè ohun kan lọ́wọ́ Jesu.
Ọmọ ta ni Kristi ń ṣe?
35 (N)Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jesu ń kọ́ àwọn ènìyàn nínú tẹmpili, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí àwọn olùkọ́ òfin fi gbà wí pé Kristi náà ní láti jẹ́ ọmọ Dafidi? 36 (O)Nítorí tí Dafidi tìkára rẹ̀, ti ń ti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ sọ̀rọ̀ wí pé:
“ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé:
“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,
títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’
37 Níwọ́n ìgbà tí Dafidi tìkára rẹ̀ pè é ní ‘Olúwa,’ Báwo ni ó túnṣe lè jẹ́ ọmọ rẹ̀?”
Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.
38 (P)Ó sì wí fún wọn nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣọ́ra fun àwọn olùkọ́ òfin tí wọ́n fẹ́ láti máa wọ aṣọ gígùn káàkiri, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, 39 àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu àti ipò ọlá níbi àsè. 40 Àwọn tí wọ́n jẹ ilé àwọn opó rún, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn, nítorí èyí, ìjìyà wọn yóò pọ̀ púpọ̀.”
Ọ̀rẹ́ opó
41 (Q)Jesu jókòó ní òdìkejì kọjú sí àpótí ìṣúra: ó ń wo ìjọ ènìyàn ti ń sọ owó sínú àpótí ìṣúra, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì sọ púpọ̀ sí i. 42 Ṣùgbọ́n obìnrin opó kan wà, ó sì fi ààbọ̀ owó idẹ méjì síbẹ̀, tí ì ṣe ìdá méjì owó-babà kan sínú rẹ̀.
43 Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, tálákà opó yìí sọ sínú àpótí ìṣúra ju gbogbo àwọn ìyókù to sọ sínú rẹ lọ. 44 Nítorí pé, àwọn ìyókù mú nínú ọ̀pọ̀ ìní wọ́n, ṣùgbọ́n ní tirẹ̀, nínú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tí ó ní náà sílẹ̀ àní gbogbo ìní rẹ̀.”
Bilidadi
8 Ìgbà náà ni Bilidadi, ará Ṣuhi, sì dáhùn wí pé:
2 “Ìwọ yóò ti máa sọ nǹkan wọ̀nyí pẹ́ tó?
Tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ yóò sì máa bí ẹ̀fúùfù ńlá?
3 Ọlọ́run a ha máa yí ìdájọ́ po bí?
Tàbí Olódùmarè a máa gbé ẹ̀bi fún aláre?
4 Nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣẹ̀ sí i,
ó sì gbá wọn kúrò nítorí ìrékọjá wọn.
5 Bí ìwọ bá sì ké pe Ọlọ́run ní àkókò,
tí ìwọ sì gbàdúrà ẹ̀bẹ̀ sí Olódùmarè.
6 Ìwọ ìbá jẹ́ mímọ, kí ó sì dúró ṣinṣin:
ǹjẹ́ nítòótọ́ nísinsin yìí òun yóò tají fún ọ,
òun a sì sọ ibùjókòó òdodo rẹ di púpọ̀.
7 Ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ ìbá tilẹ̀ kéré si í,
bẹ́ẹ̀ ìgbẹ̀yìn rẹ ìbá pọ̀ sí i gidigidi.
8 “Èmi bẹ̀ ọ́ ǹjẹ́, béèrè lọ́wọ́ àwọn ará ìgbà nì
kí o sì kíyèsi ìwádìí àwọn baba wọn.
9 Nítorí pé ọmọ-àná ni àwa, a kò sì mọ nǹkan,
nítorí pé òjìji ni ọjọ́ wa ni ayé.
10 Àwọn kì yóò wa kọ ọ́, wọn kì yóò sì sọ fún ọ?
Wọn kì yóò sì sọ̀rọ̀ láti inú òye wọn jáde wá?
11 Papirusi ha lè dàgbà láìní ẹrẹ̀
tàbí eèsún ha lè dàgbà láìlómi?
12 Nígbà tí ó wà ní tútù, tí a kò ké e lulẹ̀,
ó rọ dànù, ewéko gbogbo mìíràn hù dípò rẹ̀
13 Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọ́run,
bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn àgàbàgebè yóò di òfo.
14 Àbá ẹni tí a ó kèé kúrò,
àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí ó dàbí ilé aláǹtakùn.
15 Yóò fi ara ti ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró,
yóò fi di ara rẹ̀ mú ṣinṣin ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró pẹ́.
16 Ó tutù bí irúgbìn tí a bomirin níwájú oòrùn,
ẹ̀ka rẹ̀ sì yọ jáde nínú ọgbà rẹ̀.
17 Gbòǹgbò rẹ̀ ta yí ebè ká,
ó sì wó ibi òkúta wọ̀n-ọn-nì.
18 Bí ó bá sì pa á run kúrò ní ipò rẹ̀,
nígbà náà ni ipò náà yóò sọ, ‘Èmi kò ri ọ rí!’
19 Kíyèsi i, ayé rẹ̀ gbẹ dànù
àti láti inú ilẹ̀ ní irúgbìn òmíràn yóò hù jáde wá.
20 “Kíyèsi i, Ọlọ́run kì yóò ta ẹni òtítọ́ nù,
bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ran oníwà búburú lọ́wọ́
21 títí yóò fi fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹnu,
àti ètè rẹ pẹ̀lú ìhó ayọ̀,
22 ìtìjú ní a o fi bo àwọn tí ó kórìíra rẹ̀,
àti ibùjókòó ènìyàn búburú kì yóò sí mọ́.”
Ẹbọ ààyè mímọ́
12 (A)Nítorí náà mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run bẹ̀ yín ará, kí ẹ̀yin kí ó fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè mímọ́, ìtẹ́wọ́gbà, èyí ni iṣẹ́ ìsìn yín tí ó tọ̀nà. 2 (B)Kí ẹ má sì da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí; ṣùgbọ́n kí ẹ paradà láti di tuntun ní èrò inú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè rí ìdí ìfẹ́ Ọlọ́run, tí ó dára, tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ti ó sì pé.
Ìsìn ìrẹ̀lẹ̀ nínú Kristi
3 Ǹjẹ́ mo wí fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wà nínú yín, nípa oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n kí ó le rò níwọ́ntún-wọ́nsì, bí Ọlọ́run ti fi ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún olúkúlùkù. 4 (C)Nítorí gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ẹ̀yà púpọ̀ nínú ara kan, tí gbogbo ẹ̀yà kò sì ní iṣẹ́ kan náà: 5 (D)Bẹ́ẹ̀ ni àwa, tí a jẹ́ púpọ̀, a jẹ́ ara kan nínú Kristi, àti olúkúlùkù ẹ̀yà ara ọmọnìkejì rẹ̀. 6 (E)Ǹjẹ́ bí àwa sì ti ń rí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹ̀bùn gbà gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún wa, bí ó ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, kí a máa sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ìgbàgbọ́; 7 Tàbí iṣẹ́ ìránṣẹ́, kí a kọjú sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa tàbí ẹni tí ń kọ́ni, kí ó kọjú sí kíkọ́. 8 Tàbí ẹni tí ó ń gbani níyànjú, sí ìgbìyànjú; ẹni tí ń fi fún ni kí ó máa fi inú kan ṣe é; ẹni tí ń ṣe olórí, kí ó máa ṣe é ní ojú méjèèjì; ẹni tí ń ṣàánú, kí ó máa fi inú dídùn ṣe é.
Ẹ̀kọ́ nípa ìfẹ́
9 Kí ìfẹ́ kí ó wà ní àìṣẹ̀tàn. Ẹ máa takété sí ohun tí í ṣe búburú; ẹ fi ara mọ́ ohun tí í ṣe rere. 10 Ní ti ìfẹ́ ará, ẹ máa fi ìyọ́nú fẹ́ràn ara yín; ní ti ọlá, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣáájú. 11 Ní ti iṣẹ́ ṣíṣe, ẹ má ṣe ọ̀lẹ; ẹ máa ní ìgbóná ọkàn; ẹ máa sìn Olúwa. 12 (F)Ẹ máa yọ̀ ni ìrètí; ẹ máa mú sùúrù nínú ìpọ́njú; ẹ máa dúró gbọingbọin nínú àdúrà. 13 Ẹ máa pèsè fún àìní àwọn ènìyàn mímọ́; ẹ fi ara yín fún àlejò ṣíṣe.
14 (G)Ẹ máa súre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; ẹ máa súre, ẹ má sì ṣépè. 15 Àwọn tí ń yọ̀, ẹ máa bá wọn yọ̀, àwọn tí ń sọkún, ẹ máa bá wọn sọkún. 16 (H)Ẹ máa wà ní inú kan náà sí ara yín. Ẹ má ṣe gbéraga, ṣùgbọ́n ẹ má tẹ̀lé àwọn onírẹ̀lẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara yín.
17 (I)Ẹ má ṣe fi búburú san búburú fún ẹnikẹ́ni. Ẹ má pèsè ohun tí ó tọ́ níwájú gbogbo ènìyàn. 18 (J)Bí ó bá sé é ṣe, bí ó ti wà ní ipa tiyín, ẹ má wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. 19 (K)Olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ṣùgbọ́n ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún ìbínú Ọlọ́run; nítorí a ti kọ ọ́ pé, Olúwa wí pé, “Tèmi ni ẹ̀san, èmi ó gbẹ̀san.” 20 (L)Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀,
“Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ;
bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu.
Ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó kó ẹ̀yín iná lé e ní orí.”
21 Má ṣe jẹ́ kí búburú ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n fi rere ṣẹ́gun búburú.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.