Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Gẹnẹsisi 35-36

Jakọbu padà sí Beteli

35 (A)Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Jakọbu pé, “Gòkè lọ sí Beteli kí o sì tẹ̀dó síbẹ̀, kí ó mọ pẹpẹ níbẹ̀ fún Ọlọ́run tó farahàn ọ́ nígbà tí o ń sálọ kúrò níwájú Esau arákùnrin rẹ.”

Nítorí náà, Jakọbu wí fún gbogbo ará ilé rẹ̀ pé, “Ẹ mú gbogbo àjèjì òrìṣà tí ó wà lọ́dọ̀ yín kúrò, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì pààrọ̀ aṣọ yín. Nígbà náà ni kí ẹ wá, kí ẹ jẹ́ kí a lọ sí Beteli, níbi tí n ó ti mọ pẹpẹ fún Ọlọ́run, tí ó dá mi lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú mi tí ó sì ti ń pẹ̀lú mi níbi gbogbo tí mo ń lọ.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fún Jakọbu ní gbogbo àjèjì òrìṣà tí ó wà lọ́wọ́ wọn, àti yẹtí etí wọn, Jakọbu sì bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ sábẹ́ igi óákù ní Ṣekemu. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run sì ń bẹ lára gbogbo ìlú tí ó yí wọn ká, wọ́n kò sì lépa àwọn ọmọ Jakọbu.

Jakọbu àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì dé sí Lusi (Beteli) tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani. Níbẹ̀ ni ó sì mọ pẹpẹ kan tí ó pè ní El-Beteli (Ọlọ́run Beteli), nítorí níbẹ̀ ni Ọlọ́run ti gbé fi ara hàn án nígbà tí ó ń sálọ fún arákùnrin rẹ̀.

Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí ni Debora, olùtọ́jú Rebeka kú, a sì sin ín sábẹ́ igi óákù ní ìsàlẹ̀ Beteli: Nítorí náà a sọ ọ́ ní Aloni-Bakuti (Óákù Ẹkún).

(B)(C) Lẹ́yìn tí Jakọbu padà dé láti Padani-Aramu, Ọlọ́run tún fi ara hàn án, ó sì súre fún un. 10 Ọlọ́run sì wí fun un pé, “Jakọbu ni orúkọ rẹ̀, a kì yóò pè ọ́ ní Jakọbu (alọ́nilọ́wọ́gbà) mọ́ bí kò ṣe Israẹli (ẹni tí ó bá Ọlọ́run jìjàkadì, tí ó sì ṣẹ́gun).” Nítorí náà, ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Israẹli.

11 Ọlọ́run sì wí fún un pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára (Eli-Ṣaddai); máa bí sí i, kí o sì máa pọ̀ sí i. Orílẹ̀-èdè àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, àwọn ọba yóò sì jáde wá láti ara rẹ̀. 12 Gbogbo ilẹ̀ tí mo fi fún Abrahamu àti Isaaki ni èmi yóò fún ọ pẹ̀lú, àti fún àwọn ìran rẹ tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn.” 13 Nígbà náà ni Ọlọ́run gòkè lọ kúrò ní ibi tí ó ti ń bá a sọ̀rọ̀.

14 (D)Jakọbu sì fi òkúta ṣe ọ̀wọ̀n kan sí ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀ ó sì ta ọrẹ ohun mímu (wáìnì) ní orí rẹ̀, ó sì da òróró olifi sí orí rẹ̀ pẹ̀lú. 15 Jakọbu sì pe orúkọ ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀ ní Beteli.

Ikú Rakeli àti Isaaki

16 Nígbà náà ni wọ́n ń tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò wọn láti Beteli. Nígbà tí ó sì ku díẹ̀ kí wọn dé Efrata, Rakeli bẹ̀rẹ̀ sí ní rọbí, ó sì ní ìdààmú púpọ̀. 17 Bí ó sì ti ń rọbí pẹ̀lú ìrora yìí, agbẹ̀bí wí fún un pé “Má bẹ̀rù nítorí ọmọkùnrin mìíràn ni ó ń bọ̀ yìí.” 18 Bí o sì ti fẹ́ gbé ẹ̀mí mi (torí pé ó ń kú lọ), ó pe ọmọ rẹ̀ náà ní Bene-Oni (ọmọ ìpọ́njú mi). Ṣùgbọ́n Jakọbu sọ ọmọ náà ní Benjamini (ọmọ oókan àyà mi).

19 Báyìí ni Rakeli kú, a sì sin ín sí ọ̀nà Efrata (Bẹtilẹhẹmu). 20 Jakọbu sì mọ ọ̀wọ̀n (ọ̀wọ́n) kan sí ibojì rẹ̀, ọ̀wọ̀n náà sì tọ́ka sí ojú ibojì Rakeli títí di òní.

21 Israẹli sì ń bá ìrìnàjò rẹ̀ lọ, ó sì pa àgọ́ rẹ̀ sí Migida-Ederi (ilé ìṣọ́ Ederi). 22 (E)Nígbà tí Israẹli sì ń gbé ní ibẹ̀, Reubeni wọlé tọ Biliha, àlè (ìyàwó tí a kò fi owó fẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀) baba rẹ̀ lọ, ó sì bá a lòpọ̀, Israẹli sì gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.

Jakọbu sì bí ọmọkùnrin méjìlá:

23 Àwọn ọmọ Lea:

Reubeni tí í ṣe àkọ́bí Jakọbu,

Simeoni, Lefi, Juda, Isakari àti Sebuluni.

24 Àwọn ọmọ Rakeli:

Josẹfu àti Benjamini.

25 Àwọn ọmọ Biliha ìránṣẹ́bìnrin Rakeli:

Dani àti Naftali.

26 Àwọn ọmọ Silipa ìránṣẹ́bìnrin Lea:

Gadi àti Aṣeri.

Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Jakọbu bí ní Padani-Aramu.

27 (F)Jakọbu sì padà dé ilé lọ́dọ̀ Isaaki baba rẹ̀ ni Mamre ní tòsí i Kiriati-Arba (Hebroni). Níbi tí Abrahamu àti Isaaki gbé. 28 Ẹni ọgọ́sàn-án (180) ọdún ni Isaaki. 29 Isaaki sì kú láìpẹ́ lẹ́yìn ìpadàbọ̀ Jakọbu, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Esau àti Jakọbu ọmọ rẹ̀ sì sin ín.

Àwọn ìránṣẹ́ Esau

36 Wọ̀nyí ni ìran Esau, ẹni tí a ń pè ní Edomu.

(G)Nínú àwọn ọmọbìnrin Kenaani ni Esau ti fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀: Adah ọmọbìnrin Eloni ará Hiti àti Oholibama, ọmọbìnrin Ana, ọmọ ọmọ Sibeoni ará Hifi. (H)Ó sì tún fẹ́ Basemati ọmọ Iṣmaeli arábìnrin Nebaioti.

Adah bí Elifasi fún Esau, Basemati sì bí Reueli, Oholibama pẹ̀lú sì bí Jeuṣi, Jalamu, àti Kora. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Esau bí ní Kenaani.

Esau sì mú àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ àti àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn àti gbogbo ohun ìní mìíràn tí ó ní, ni Kenaani, ó sì kó lọ sí ilẹ̀ mìíràn, jìnà sí ibi tí Jakọbu arákùnrin rẹ̀ wà. Ohun ìní wọn pọ̀ ju èyí tí àwọn méjèèjì lè máa gbé ní ojú kan lọ. Ilẹ̀ tí wọ́n wà kò le gba àwọn méjèèjì nítorí àwọn ohun ọ̀sìn wọn. Báyìí ni Esau tí a tún mọ̀ sí Edomu tẹ̀dó sí àwọn orílẹ̀-èdè olókè tí Seiri.

Èyí ni ìran Esau baba àwọn ará Edomu ní àwọn orílẹ̀-èdè olókè Seiri.

10 Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Esau:

Elifasi ọmọ Adah aya Esau àti Reueli, ọmọ Basemati tí í ṣe aya Esau pẹ̀lú.

11 Àwọn ọmọ Elifasi ni ìwọ̀nyí:

Temani, Omari, Sefi, Gatamu, àti Kenasi. 12 Elifasi ọmọ Esau sì tún ní àlè tí a ń pè ní Timna pẹ̀lú, òun ló bí Amaleki fún un. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ọmọ Adah aya Esau.

13 Àwọn ọmọ Reueli:

Nahati, Sera, Ṣamma àti Missa. Àwọn ni ọmọ ọmọ Basemati aya Esau.

14 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Oholibama ọmọbìnrin Ana ọmọ ọmọ Sibeoni: tí ó bí fún Esau:

Jeuṣi, Jalamu àti Kora.

15 Àwọn wọ̀nyí ni olórí nínú àwọn ọmọ Esau:

Àwọn ọmọ Elifasi, àkọ́bí Esau:

Temani, Omari, Sefi, Kenasi, 16 Kora, Gatamu àti Amaleki. Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Elifasi ní Edomu wá, wọ́n jẹ́ ọmọ ọmọ Adah.

17 Wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Esau, ọmọ Rueli:

Nahati olórí, Sera olórí, Ṣamma olórí, Missa olórí; Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Reueli jáde ní Edomu. Ọmọ ọmọ Basemati aya Esau ni wọ́n jẹ́.

18 Àwọn ọmọ Oholibama aya Esau:

Jeuṣi, Jalamu, àti Kora, àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Oholibama ọmọ Ana, ìyàwó Esau wá.

19 Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Esau (Edomu). Àwọn wọ̀nyí ni olórí wọn.

20 (I)Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Seiri ará Hori tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà:

Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Ana, 21 Diṣoni, Eseri, àti Diṣani, àwọn wọ̀nyí olórí ènìyàn Hori, àwọn ọmọ Seiri ni ilẹ̀ Edomu.

22 Àwọn ọmọ Lotani:

Hori àti Homamu: Timna sì ni arábìnrin Lotani.

23 Àwọn ọmọ Ṣobali:

Alifani, Manahati, Ebali, Ṣefo àti Onamu.

24 Àwọn ọmọ Sibeoni:

Aiah àti Ana. Èyí ni Ana tí ó rí ìsun omi gbígbóná ní inú aginjù bí ó ti ń da àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Ṣebeoni baba rẹ̀.

25 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ana:

Diṣoni àti Oholibama (Àwọn ọmọbìnrin ni wọn).

26 Àwọn ọmọ Diṣoni ni:

Hemdani, Eṣbani, Itrani àti Kerani.

27 Àwọn ọmọ Eseri:

Bilhani, Saafani àti Akani.

28 Àwọn ọmọ Diṣani ni:

Usi àti Arani.

29 Àwọn wọ̀nyí ni olórí ìdílé Hori:

Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Ana, 30 Diṣoni Eseri, àti Diṣani.

Àwọn ni olórí ìdílé àwọn ará Hori gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní ilẹ̀ Seiri.

Àwọn aláṣẹ Edomu

31 (J)Àwọn wọ̀nyí ni ọba tí ó jẹ ní Edomu kí ó tó di pé ọba kankan jẹ lórí Israẹli:

32 Bela ọmọ Beori jẹ ní Edomu. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba.

33 Nígbà tí Bela kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

34 Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu láti ilẹ̀ Temani sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

35 Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi ọmọ Bedadi tí ó kọlu Midiani ní ìgbẹ́ Moabu, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti.

36 Nígbà tí Hadadi sì kú, Samla láti Masreka, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

37 Samla sì kú, Saulu ti Rehoboti, létí odò sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

38 Nígbà tí Saulu kú, Baali-Hanani ọmọ Akbori jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

39 Nígbà tí Baali-Hanani ọmọ Akbori kú, Hadadi ni ó jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Pau, orúkọ ìyàwó sì ni Mehetabeeli ọmọbìnrin Matiredi, ọmọbìnrin Mesahabu.

40 Àwọn wọ̀nyí ni orúkọ àwọn baálẹ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Esau jáde wá, ní orúkọ ìdílé wọn, bí ìpínlẹ̀ wọn ti rí:

baálẹ̀ Timna, baálẹ̀ Alfa, baálẹ̀ Jeteti.

41 baálẹ̀ Oholibama, baálẹ̀ Ela, baálẹ̀ Pinoni,

42 baálẹ̀ Kenasi, baálẹ̀ Temani, baálẹ̀ Mibsari,

43 Magdieli, àti Iramu.

Àwọn wọ̀nyí ni baálẹ̀ Edomu, gẹ́gẹ́ bí wọn ti tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí wọ́n gbà.

Èyí ni Esau baba àwọn ará Edomu.

Marku 6

Wòlíì tí kò ní ọlá

(A)Jesu fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí ìlú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ (B)Nígbà tí ó di ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sí Sinagọgu láti kọ́ àwọn ènìyàn: ẹnu sì ya àwọn ènìyàn púpọ̀ tí ó gbọ́.

Wọ́n wí pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí gbé ti rí nǹkan wọ̀nyí? Irú ọgbọ́n kí ni èyí tí a fi fún un, tí irú iṣẹ́ ìyanu báyìí ń ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe? (C)Gbẹ́nàgbẹ́nà náà kọ́ yìí? Ọmọ Maria àti arákùnrin Jakọbu àti Josẹfu, Judasi àti Simoni? Àwọn arábìnrin rẹ̀ gbogbo ha kọ́ ni ó ń bá wa gbé níhìn-ín yìí?” Wọ́n sì kọsẹ̀ lára rẹ̀.

Nígbà náà, Jesu wí fún wọn pé, “A máa ń bu ọlá fún wòlíì níbi gbogbo àfi ní ìlú ara rẹ̀ àti láàrín àwọn ìdílé àti àwọn ẹbí òun pàápàá.” (D)Nítorí àìgbàgbọ́ wọn, òun kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá láàrín wọn, àfi àwọn aláìsàn díẹ̀ tí ó gbé ọwọ́ lé lórí, tí wọ́n sì rí ìwòsàn.

Jesu rán ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá jáde

(E)Ẹnu si yà á nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, Jesu lọ sí àárín àwọn ìletò kéékèèkéé, ó sì ń kọ́ wọn. (F)(G)Ó sì pe àwọn méjìlá náà sọ́dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí rán wọn lọ ní méjì méjì, Ó sì fi àṣẹ fún wọn lórí ẹ̀mí àìmọ́.

O sọ fún wọn pé, wọn kò gbọdọ̀ mú ohunkóhun lọ́wọ́, àfi ọ̀pá ìtìlẹ̀ wọn. Wọn kò gbọdọ̀ mú oúnjẹ, àpò ìgbànú, tàbí owó lọ́wọ́. Wọn kò tilẹ̀ gbọdọ̀ mú ìpààrọ̀ bàtà tàbí aṣọ lọ́wọ́. 10 Jesu wí pé, “Ẹ dúró sí ilé kan ní ìletò kan. Ẹ má ṣe sípò padà láti ilé dé ilé, nígbà tí ẹ bá wà ní ìlú náà. 11 (H)Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà yín, tí kò sì gbọ́rọ̀ yín, nígbà tí ẹ̀yin bá jáde kúrò níbẹ̀, ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín síbẹ̀ fún ẹ̀rí fún wọn.”

12 (I)Wọ́n jáde lọ láti wàásù ìrònúpìwàdà fún àwọn ènìyàn. 13 (J)Wọ́n lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde. Wọ́n sì ń fi òróró kun orí àwọn tí ara wọn kò dá, wọ́n sì mú wọn láradá.

A bẹ́ Johanu onítẹ̀bọmi lórí

14 (K)Láìpẹ́, ọba Herodu gbọ́ nípa Jesu, nítorí níbi gbogbo ni a ti ń sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. Ọba náà rò pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi jíǹde kúrò nínú òkú, nítorí náà ni iṣẹ́ ìyanu ṣe ń ṣe láti ọwọ́ rẹ.”

15 Àwọn mìíràn wí pé, “Elijah ní.”

Àwọn mìíràn wí pé, “Wòlíì bí ọ̀kan lára àwọn àtijọ́ tó ti kú ló tún padà sáyé.”

16 Ṣùgbọ́n nígbà tí Herodu gbọ́ èyí, ó wí pé “Johanu tí mo tí bẹ́ lórí ni ó ti jíǹde kúrò nínú òkú.”

17 (L)Herodu fúnrarẹ̀ sá ti ránṣẹ́ mú Johanu, tìkára rẹ̀ sínú túbú nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀ nítorí tí ó fi ṣe aya. 18 Johanu sì ti wí fún Herodu pé, “Kò tọ́ sí ọ láti fi ìyàwó arákùnrin rẹ ṣe aya.” 19 (M)Nítorí náà ni Herodia ṣe ní sínú, òun sì fẹ́ pa á, ṣùgbọ́n kò le ṣe é. 20 (N)Nítorí Herodu bẹ̀rù Johanu, ó sì mọ̀ ọ́n ni olóòtítọ́ ènìyàn àti ẹni mímọ́, ó sì ń tọ́jú rẹ̀. Nígbà tí Herodu ba gbọ́rọ̀ Johanu, ó máa ń dààmú síbẹ̀, ó sì fi ayọ̀ gbọ́rọ̀ rẹ̀.

21 Níkẹyìn Herodia rí ààyè. Àkókò yìí ni ọjọ́ ìbí Herodu, òun sì pèsè àsè ní ààfin ọba fún àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀: àwọn balógun àti àwọn ènìyàn pàtàkì ní Galili. 22 Nígbà náà, ni ọmọbìnrin Herodia wọlé láti jó. Inú Herodu àti àwọn àlejò rẹ̀ dùn tó bẹ́ẹ̀.

Ọba sọ fún ọmọbìnrin náà pé, “Béèrè ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fi fún ọ.” 23 (O)Ó sì búra fún un wí pé, “Ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́, ìbá à ṣe ìdajì ìjọba mi ni, èmi yóò fi fún ọ.”

24 Ó jáde lọ sọ fún ìyá rẹ̀ pé “Kí ní kí ń béèrè?”

Ó dáhùn pé, “Orí Johanu Onítẹ̀bọmi.”

25 Ọmọbìnrin yìí sáré padà wá sọ́dọ̀ Herodu ọba. Ó sì wí fún un pé, “Mo ń fẹ́ orí Johanu Onítẹ̀bọmi nísinsin yìí nínú àwopọ̀kọ́.”

26 Inú ọba sì bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí àwọn ìbúra rẹ, àti nítorí àwọn tí ó bá a jókòó pọ̀, kò sì fẹ́ kọ̀ fún un. 27 Nítorí èyí, ọba rán ẹ̀ṣọ́ kan, ó fi àṣẹ fún un pé, kí ó gbé orí Johanu wá. Ọkùnrin náà sì lọ, ó bẹ́ Johanu lórí nínú túbú. 28 Ó sì gbé orí Johanu wa nínú àwopọ̀kọ́. Ó sì gbé e fún ọmọbìnrin náà. Òun sì gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ. 29 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu gbọ́, wọ́n wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n sì lọ tẹ́ ẹ sínú ibojì.

Jesu bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ènìyàn

30 (P)Àwọn aposteli kó ara wọn jọ sí ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n sí ròyìn ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe àti ohun gbogbo tí wọ́n ti kọ́ni. 31 Nígbà tí Jesu rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ tí wọ́n sì ń bọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ààyè fún wọn láti jẹun, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí a kúrò láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí fún ìgbà díẹ̀, kí a sì sinmi.”

32 (Q)Nítorí náà, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibi tí ó parọ́rọ́. 33 Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ènìyàn ni o rí wọn nígbà tí wọ́n ń lọ. Àwọn wọ̀nyí sì tún wá láti ìlú ńlá gbogbo wọn sáré gba etí Òkun, wọ́n ṣáájú wọn gúnlẹ̀ ní èbúté. 34 (R)Bí Jesu ti ń sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀ náà, ó bá ọ̀pọ̀ ènìyàn bí i tí àtẹ̀yìnwá, tí wọ́n ti ń dúró dè e. Ó káàánú fún wọn, nítorí wọ́n dàbí àgùntàn tí kò ní olùtọ́jú. Ó sì kọ́ wọn ni ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó yẹ kí wọ́n mọ̀.

35 Nígbà tí ọjọ́ sì ti bù lọ tán, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí fún un pé, ibi aṣálẹ̀ ni ìbí yìí, ọjọ́ sì bù lọ tán. 36 “Rán àwọn ènìyàn wọ̀nyí láti lọ sí àwọn abúlé àti ìlú láti ra oúnjẹ fún ara wọn.”

37 (S)Ṣùgbọ́n Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.”

Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wí fún pé, “Èyí yóò ná wa tó owó iṣẹ́ ọya oṣù mẹ́jọ, Ṣe kí a lọ fi èyí ra àkàrà fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn yìí láti jẹ.”

38 Jesu tún béèrè pé, “Ìṣù àkàrà mélòó ni ẹ̀yin ni lọ́wọ́? Ẹ lọ wò ó.”

Wọ́n padà wá jíṣẹ́ pé, “Ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì.”

39 Nígbà náà ni Jesu sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn náà kí a mú wọn jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ lórí koríko. 40 Lẹ́sẹ̀kan náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jókòó, ní àádọ́ta tàbí ọgọọgọ́rùn-ún. 41 (T)Nígbà tí ó sì mú ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run. Ó dúpẹ́ fún oúnjẹ náà, ó bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé e kalẹ̀ síwájú àwọn ènìyàn náà àti àwọn ẹja méjì náà ni ó pín fún gbogbo wọn. 42 Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó. 43 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì kó agbọ̀n méjìlá tí ó kún fún àjẹkù àkàrà àti ti ẹja pẹ̀lú. 44 Àwọn tí ó sì jẹ́ àkàrà náà tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin.

Jesu rìn lórí omi

45 (U)Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jesu pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti padà sínú ọkọ̀ kí wọn sì ṣáájú rékọjá sí Betisaida. Níbẹ̀ ni òun yóò ti wà pẹ̀lú wọn láìpẹ́. Nítorí òun fúnra a rẹ̀ yóò dúró sẹ́yìn láti rí i pé àwọn ènìyàn túká lọ ilé wọn. 46 Lẹ́yìn náà, ó lọ sórí òkè láti lọ gbàdúrà.

47 Nígbà tí ó di alẹ́, ọkọ̀ wà láàrín Òkun, òun nìkan sì wà lórí ilẹ̀. 48 (V)Ó rí i wí pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wà nínú wàhálà púpọ̀ ní wíwa ọkọ̀ náà nítorí ti ìjì líle ṣe ọwọ́ òdì sí wọn, nígbà tí ó sì dì ìwọ̀n ìṣọ́ kẹrin òru, ó tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi Òkun, òun sì fẹ́ ré wọn kọjá, 49 ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí i tí ó ń rìn, wọ́n rò pé iwin ni. Wọ́n sì kígbe sókè lóhùn rara, 50 (W)nítorí gbogbo wọn ni ó rí i, tí ẹ̀rù sì bà wọ́n.

Ṣùgbọ́n òun sọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé, “Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù.” 51 Nígbà náà ni ó gòkè sínú ọkọ̀ pẹ̀lú wọn, ìjì líle náà sì dáwọ́ dúró. Ẹ̀rù sì bà wọ́n rékọjá gidigidi, ẹnu sì yà wọ́n. 52 (X)Wọn kò sá tó ni òye iṣẹ́ ìyanu ti ìṣù àkàrà, nítorí ti ọkàn wọn yigbì.

53 (Y)Lẹ́yìn tí wọ́n la Òkun náà kọjá, wọ́n gúnlẹ̀ sí Genesareti. Wọ́n sì so ọkọ̀ sí èbúté. 54 Wọ́n jáde kúrò nínú ọkọ̀. Àwọn ènìyàn tó wà níbẹ̀ rí Jesu, wọ́n sì dá a mọ̀ ọ́n. 55 Wéré, wọ́n ròyìn dídé rẹ̀, gbogbo àwọn ènìyàn sáré gbé gbogbo àwọn aláìsàn lórí àkéte wọn wá pàdé rẹ̀. 56 (Z)Ní ibi gbogbo tí ó sì dé, yálà ní abúlé, ìlú ńlá tàbí àrọ́ko, ń ṣe ni wọ́n ń kó àwọn aláìsàn pàdé rẹ̀ ní àárín ọjà. Wọ́n sì ń bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹ́ kí wọn fi ọwọ́ kan etí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí wọ́n sì fi ọwọ́ kàn án ni a mú láradá.

Jobu 2

Ìdánwò Jobu lẹ́ẹ̀kejì

Ó sì tún di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá síwájú Olúwa, Satani sì wá pẹ̀lú wọn láti pe níwájú Olúwa. Olúwa sì bi Satani pé, Níbo ni ìwọ ti wá?

Satani sì dá Olúwa lóhùn pé, “Láti lọ síwá sẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.”

Olúwa sì wí fún Satani pé, “Ìwọ ha kíyèsi Jobu ìránṣẹ́ mi, pé, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí ń ṣe olóòtítọ́ tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì kórìíra ìwà búburú, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di ìwà òtítọ́ rẹ̀ mu ṣinṣin, bí ìwọ tilẹ̀ ti dẹ mí sí i láti run ún láìnídìí.”

Satani sì dá Olúwa lóhùn wí pé, “Awọ fún awọ; àní ohun gbogbo tí ènìyàn ní, òun ni yóò fi ra ẹ̀mí rẹ̀. Ṣùgbọ́n nawọ́ rẹ nísinsin yìí, kí ó tọ́ egungun rẹ̀ àti ara rẹ̀, bí kì yóò sì bọ́hùn ní ojú rẹ.”

Olúwa sì wí fún Satani pé, “Wò ó, ó ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ sí.”

Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú Olúwa, ó sì sọ Jobu ní oówo kíkankíkan láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀ Ó sì mú àpáàdì, ó fi ń họ ara rẹ̀, ó sì jókòó nínú eérú.

Nígbà náà ni aya rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ di ìwà òtítọ́ mú síbẹ̀! Bú Ọlọ́run, kí ó sì kú!”

10 Ṣùgbọ́n ó dá a lóhùn pé, “Ìwọ sọ̀rọ̀ bí ọ̀kan lára àwọn aṣiwèrè obìnrin ti í sọ̀rọ̀; há bà! Àwa yóò ha gba ìre lọ́wọ́ Ọlọ́run, kí a má sì gba ibi?”

Nínú gbogbo èyí, Jobu kò fi ètè rẹ̀ ṣẹ̀.

Ọ̀rẹ́ Jobu mẹ́ta

11 Nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹ́ta gbúròó gbogbo ibi tí ó bá a, wọ́n wá, olúkúlùkù láti ibùjókòó rẹ̀; Elifasi, ara Temani àti Bilidadi, ará Ṣuhi, àti Sofari, ará Naama: nítorí pé wọ́n ti dájọ́ ìpàdé pọ̀ láti bá a ṣọ̀fọ̀, àti láti ṣìpẹ̀ fún un. 12 Nígbà tí wọ́n gbójú wọn wò ní òkèrè réré, tí wọ́n kò sì mọ̀ ọ́n, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sọkún: olúkúlùkù sì fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, wọ́n sì ku erùpẹ̀ sí ojú ọ̀run, wọ́n sì tẹ́ orí gbà á. 13 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jókòó tì í ní inú erùpẹ̀ ní ọjọ́ méje ti ọ̀sán ti òru, ẹnikẹ́ni kò sì bá a sọ ọ̀rọ̀ kan, nítorí tí wọ́n ti rí i pé ìbànújẹ́ rẹ̀ pọ̀ jọjọ.

Romu 6

Ikú sí ẹsẹ̀, iyè nínú Kristi

(A)Ǹjẹ́ àwa ó ha ti wí? Ṣé kí àwa ó jókòó nínú ẹ̀ṣẹ̀, kí oore-ọ̀fẹ́ ba à lè máa pọ̀ sí i? (B)Kí a má ri! Àwa ẹni tí ó ti kú sí ẹ̀ṣẹ̀, àwa ó ha ṣe wà láààyè nínú rẹ̀ mọ́? (C)Tàbí ẹyin kò mọ pé gbogbo wa ti a ti bamitiisi wa sínú Jesu Kristi ni a ti bamitiisi sínú ikú rẹ. (D)Nítorí náà, a sin wa pẹ̀lú Kristi nípa ìtẹ̀bọmi si ikú, kí ó bá le jẹ́ pe bí a ti jí Kristi dìde pẹ̀lú ògo Baba, àwa pẹ̀lú gbé ìgbé ayé tuntun.

(E)Nítorí pé ẹ̀yin ti di ọ̀kan ṣoṣo pẹ̀lú rẹ̀, àti pé ẹ kú pẹ̀lú rẹ̀, nígbà tí òun kú. Nísinsin yìí, ẹ ń pín ìyè tuntun rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì jí dìde gẹ́gẹ́ bí òun náà ti jí dìde. (F)Gbogbo èrò búburú ọkàn yín ni a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ̀mí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sì ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ nínú yín ni a ti sọ di aláìlera. Nítorí náà, ara yín tí ó ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ kò sí lábẹ́ àkóso ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, kò sì ní láti jẹ́ ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. (G)Nítorí pé nígbà tí ẹ ti di òkú fún ẹ̀ṣẹ̀, a ti gbà yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ kò ní agbára lórí yín mọ́.

(H)Nísinsin yìí, bí àwa bá kú pẹ̀lú Kristi àwa gbàgbọ́ pé àwa yóò wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀. (I)Nítorí àwa mọ̀ pé Kristi ti jí dìde kúrò nínú òkú. Òun kò sì ní kú mọ́. Ikú kò sì lè ní agbára lórí rẹ̀ mọ́. 10 Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, láti ṣẹ́gun agbára ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó wà láààyè títí ayé àìnípẹ̀kun ní ìdàpọ̀ mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.

11 (J)Nítorí náà, ẹ ka ara yín bí òkú sí ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n bí alààyè sí Ọlọ́run nínú Kristi Jesu. 12 Nítorí náà kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ ọba lórí ara kíkú yín kí ó lè ba à máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀. 13 (K)Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀yà ara yín kan di ohun èlò ohun búburú, nípa ẹ̀ṣẹ̀ dídá. Ṣùgbọ́n ẹ fi wọn fún Ọlọ́run pátápátá. Wọ́n ti di ààyè, ẹ jẹ́ kí wọn di ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run, kí ó lè lò wọ́n fún àwọn ìlànà rẹ̀ tí ó dára. 14 (L)Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ kì yóò tún ní ipá lórí yín mọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí lábẹ́ ìdè òfin, bí kò ṣe lábẹ́ oore-ọ̀fẹ́.

Ẹrú sí ìṣòdodo

15 (M)Ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí pé, nísinsin yìí, a lè tẹ̀síwájú láti máa dẹ́ṣẹ̀ láìbìkítà, nítorí ìgbàlà wa kò dúró nípa òfin mọ́, bí kò ṣe nípa gbígba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run! 16 (N)Àbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé, ẹnikẹ́ni lè yan ọ̀gá tí ó bá fẹ́? Ẹ lè yan ẹ̀ṣẹ̀ ti o yọrí si ikú tàbí ìgbọ́ràn ti o yọrí sí ìdáláre. Ẹnikẹ́ni tí ẹ bá fi ara yín fún, òun náà ni yóò jẹ́ ọ̀gá yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ẹrú rẹ̀. 17 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run pé, bí ẹ̀yin ti jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ rí, ẹ̀yin jẹ́ olùgbọ́ran láti ọkàn wá sí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ èyí tí Ọlọ́run fi lé yín lọ́wọ́. 18 (O)Nísinsin yìí, ẹ ti dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ọ̀gá yín àtijọ́, èyí tí í ṣe ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ẹrú ọ̀gá tuntun èyí ni òdodo.

19 (P)Èmi ń sọ̀rọ̀ bí ènìyàn nítorí àìlera yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yín ti jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín lọ́wọ́ bí ẹrú fún ìwà èérí àti ẹ̀ṣẹ̀ dé inú ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí ẹ̀yin kí ó jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín lọ́wọ́ nísinsin yìí bí ẹrú fún òdodo sí ìwà mímọ́. 20 (Q)Nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin wà ní òmìnira sí òdodo. 21 (R)Àti pé, kín ni ìyọrísí rẹ̀? Dájúdájú àbájáde rẹ̀ kò dára. Níwọ́n ìgbà tí ojú ń tì ọ́ nísinsin yìí láti ronú nípa àwọn wọ̀n-ọn-nì tí o ti máa ń ṣe nítorí gbogbo wọn yọrí sí ìparun ayérayé. 22 Ṣùgbọ́n báyìí, ẹ ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ẹrú Ọlọ́run àwọn ìbùkún rẹ̀ sí yin ni ìwà mímọ́ àti ìyè tí kò nípẹ̀kun. 23 (S)Nítorí ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn Ọlọ́run ni ìyè àìnípẹ̀kun nínú Kristi Jesu Olúwa wa.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.