Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Gẹnẹsisi 50

50 Josẹfu sì ṣubú lé baba rẹ̀, ó sọkún, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu. Nígbà náà ni Josẹfu pàṣẹ fún àwọn oníṣègùn tí ó wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pé kí wọn kí ó ṣe òkú Israẹli baba rẹ̀ lọ́jọ̀, àwọn oníṣègùn náà sì ṣe bẹ́ẹ̀, Fún ogójì ọjọ́ ni wọ́n fi ṣe èyí, nítorí èyí ni àsìkò tí a máa ń fi ṣe ẹ̀ǹbáàmù òkú. Àwọn ará Ejibiti sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ fún àádọ́rin ọjọ́.

Nígbà tí ọjọ́ ìṣọ̀fọ̀ náà kọjá. Josẹfu wí fún àwọn ará ilé Farao pé, “Bí mo bá bá ojúrere yín pàdé, ẹ bá mi sọ fún Farao. (A)‘Baba mi mú mi búra ó sì wí fún mi pé, “Mo ti fẹ́rẹ kú: sinmi sínú ibojì tí mo gbẹ́ fún ara mi ní ilẹ̀ Kenaani.” Nísinsin yìí, jẹ́ kí n lọ kí n sì sìnkú baba mi, lẹ́yìn náà èmi yóò padà wa.’ ”

Farao wí pé, “Gòkè lọ, kí o sì sin baba rẹ, bí ó tí mú ọ búra.”

Báyìí ni Josẹfu gòkè lọ láti sìnkú baba rẹ̀. Gbogbo àwọn ìjòyè Farao ni ó sìn ín lọ—àwọn àgbàgbà ilé rẹ̀, àti gbogbo àwọn àgbàgbà ilẹ̀ Ejibiti. Yàtọ̀ fún gbogbo àwọn ará ilé Josẹfu àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn tí ó jẹ́ ilé baba rẹ̀, àwọn ọmọ wọn nìkan àti agbo ẹran pẹ̀lú agbo màlúù ni ó sẹ́ kù ní Goṣeni. Kẹ̀kẹ́-ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin pẹ̀lú gòkè lọ. Àìmoye ènìyàn ni ó lọ.

10 Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ ìpakà Atadi, ní ẹ̀bá Jordani, wọn pohùnréré ẹkún; Níbẹ̀ ni Josẹfu sì tún dúró ṣọ̀fọ̀ baba rẹ̀ fún ọjọ́ méje. 11 Nígbà tí àwọn ará Kenaani tí ń gbé níbẹ̀ rí i bí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀ náà ni ilẹ̀ ìpakà Atadi, wọ́n wí pé, “Ọ̀fọ̀ ńlá ni àwọn ará Ejibiti ń ṣe yìí.” Ìdí èyí ni a fi ń pe ibẹ̀ ní Abeli-Misraimu (Ìṣọ̀fọ̀ àwọn ará Ejibiti). Kò sì jìnnà sí Jordani.

12 Báyìí ni àwọn ọmọ Jakọbu ṣe ohun tí baba wọn pàṣẹ fún wọn. 13 (B)Wọ́n gbé e lọ sí ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì sin ín sínú ihò àpáta tí ó wà ní oko Makpela, ní tòsí i Mamre tí Abrahamu rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìsìnkú lọ́wọ́ Efroni ará Hiti, pẹ̀lú ilẹ̀ náà. 14 Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti sìnkú baba rẹ̀ tan, Josẹfu padà sí Ejibiti pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn mìíràn tí ó tẹ̀lé e lọ láti sin baba rẹ̀.

Josẹfu fi ọkàn àwọn arákùnrin rẹ̀ balẹ̀

15 Nígbà tí àwọn arákùnrin Josẹfu rí i pé baba wọn kú, wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ǹjẹ́ bí ó bá ṣe pé Josẹfu ṣì fi wá sínú ńkọ́, tí ó sì fẹ́ gbẹ̀san gbogbo aburú tí a ti ṣe sí i?” 16 Nítorí náà wọ́n ránṣẹ́ sí Josẹfu wí pé, “Baba rẹ fi àṣẹ yìí sílẹ̀ kí ó tó lọ wí pé: 17 ‘Èyí ni kí ẹ̀yin kí ó sọ fún Josẹfu: Mo bẹ̀ ọ́ kí o dáríjì àwọn arákùnrin rẹ, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti aburú tí wọ́n ṣe sí ọ, èyí tí ó mú ibi bá ọ’. Nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run baba rẹ jì wọ́n.” Nígbà tí iṣẹ́ ti wọ́n rán dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Josẹfu sọkún.

18 Àwọn arákùnrin rẹ̀ wá, wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n wí pé, “Ẹrú rẹ ni a jẹ́.” 19 Ṣùgbọ́n Josẹfu wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù, èmi ha wà ní ipò Ọlọ́run bí? 20 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ gbèrò láti ṣe mi ní ibi, ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbèrò láti fi ṣe rere tí ń ṣe lọ́wọ́ yìí; ni gbígba ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn là. 21 Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù. Èmi yóò pèsè fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín.” Ó tún fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó sì sọ ọ̀rọ̀ rere fun wọn.

Ikú Josẹfu

22 Josẹfu sì ń gbé ní Ejibiti pẹ̀lú gbogbo ìdílé baba rẹ̀. Ó sì wà láààyè fún àádọ́fà (110) ọdún. 23 Ó sì rí ìran kẹta ọmọ Efraimu-Àwọn ọmọ Makiri, ọmọkùnrin Manase ni a sì gbé le eékún Josẹfu nígbà tí ó bí wọn.

24 Nígbà náà ni Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Mo ti fẹ́rẹ kú, ṣùgbọ́n dájúdájú Ọlọ́run yóò wá sí ìrànlọ́wọ́ yín, yóò sì mú un yín jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí lọ sí ilẹ̀ tí ó ti ṣèlérí ní ìbúra fún Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu.” 25 Josẹfu sì mú kí àwọn ọmọ Israẹli búra májẹ̀mú kan wí pé, “Dájúdájú Ọlọ́run yóò wá sí ìrànlọ́wọ́ yín, nígbà náà ni ẹ gbọdọ̀ kó egungun mi lọ́wọ́ kúrò ní ìhín.”

26 Báyìí ni Josẹfu kú nígbà tí ó pé àádọ́fà (110) ọdún. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ṣe òkú rẹ̀ lọ́jọ̀ tan, a gbé e sí inú pósí ní Ejibiti.

Luku 3

Johanu onítẹ̀bọmi tún ọnà náà ṣe

(A)Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún ìjọba Tiberiu Kesari, nígbà tí Pọntiu Pilatu jẹ́ baálẹ̀ Judea, tí Herodu sì jẹ́ tetrarki Galili, Filipi arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ tetrarki Iturea àti ti Trakoniti, Lisania sì jẹ́ tetrarki Abilene, (B)tí Annasi òun Kaiafa ń ṣe olórí àwọn àlùfáà, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Johanu ọmọ Sekariah wá ní ijù. (C)Ó sì wá sí gbogbo ilẹ̀ aginjù Jordani, ó ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀; (D)Bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah pé,

“Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù,
‘ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,
    ẹ mú ipa ọ̀nà rẹ̀ tọ́.
Gbogbo ọ̀gbun ni a yóò kún,
    gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni a ó tẹ́ pẹẹrẹ;
Wíwọ́ ni a ó ṣe ní títọ́,
    àti ọ̀nà gbọ́ngungbọ̀ngun ni a o sọ di dídán.
(E)Gbogbo ènìyàn ni yóò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run.’ ”

(F)Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀? (G)Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe sí í wí nínú ara yín pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu nínú òkúta wọ̀nyí. (H)Àti nísinsin yìí pẹ̀lú, a fi àáké lé gbòǹgbò igi náà: gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a óò ge lulẹ̀, a sì wọ jù sínú iná.”

10 Àwọn ènìyàn sì ń bi í pé, “Kí ni kí àwa kí ó ṣe?”

11 Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹni tí ó bá ní ẹ̀wù méjì, kí ó fi ọ̀kan fún ẹni tí kò ní; ẹni tí ó bá sì ní oúnjẹ, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”

12 Àwọn agbowó òde sì tọ̀ ọ́ wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bi í pé, “Olùkọ́, kí ni àwa ó ha ṣe?”

13 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe fi agbára gbà jù bí a ti rán yín lọ mọ́.”

14 Àwọn ọmọ-ogun sì béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Àti àwa, kí ni àwa ó ṣe?”

Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe hùwà ipá sí ẹnikẹ́ni, kí ẹ má sì ṣe ka ẹ̀sùn èké sí ẹnikẹ́ni; kí òwò ọ̀yà yín tó yín.”

15 (I)Bí àwọn ènìyàn sì ti ń retí, tí gbogbo wọn sì ń rò nínú ara wọn nítorí Johanu, bí òun ni Kristi tàbí òun kọ́; 16 (J)Johanu dáhùn ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Lóòótọ́ ni èmi ń fi omi bamitiisi yín; ṣùgbọ́n ẹni tí ó lágbára jù mí lọ ń bọ̀, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó tú: òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitiisi yín: 17 Ẹni tí àtẹ rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, láti gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tó tó, kí ó sì kó alikama rẹ̀ sínú àká; ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.” 18 Johanu lo oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ púpọ̀ láti gba àwọn ènìyàn níyànjú àti láti wàásù ìhìnrere fún wọn.

19 (K)Ṣùgbọ́n nígbà ti Johanu bú Herodu tetrarki, tí ó bá wí nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀, àti nítorí ohun búburú gbogbo tí Herodu tí ṣe, 20 Ó fi èyí parí gbogbo rẹ̀ nígba tí ó fi Johanu sínú túbú.

Ìtẹ̀bọmi àti ìtàn ìdílé Jesu

21 (L)(M) Nígbà tí a ṣe ìtẹ̀bọmi àwọn ènìyàn gbogbo tán, ó sì ṣe, a bamitiisi Jesu pẹ̀lú, bí ó ti ń gbàdúrà, ọ̀run ṣí sílẹ̀, 22 (N)Ẹ̀mí Mímọ́ sì sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ ní àwọ̀ àdàbà, ohùn kan sì ti ọ̀run wá, tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi; ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”

23 (O)(P) Jesu tìkára rẹ̀ ń tó bí ẹni ọgbọ̀n ọdún, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ (bí a ti fi pè) ọmọ Josẹfu,

tí í ṣe ọmọ Eli, 24 tí í ṣe ọmọ Mattati,

tí í ṣe ọmọ Lefi, tí í ṣe ọmọ Meliki,

tí í ṣe ọmọ Janai, tí í ṣe ọmọ Josẹfu,

25 tí í ṣe ọmọ Mattatia, tí í ṣe ọmọ Amosi,

tí í ṣe ọmọ Naumu, tí í ṣe ọmọ Esili,

tí í ṣe ọmọ Nagai, 26 tí í ṣe ọmọ Maati,

tí í ṣe ọmọ Mattatia, tí í ṣe ọmọ Ṣimei,

tí í ṣe ọmọ Josẹfu, tí í ṣe ọmọ Joda,

27 Tí í ṣe ọmọ Joana, tí í ṣe ọmọ Resa,

tí í ṣe ọmọ Serubbabeli, tí í ṣe ọmọ Ṣealitieli,

tí í ṣe ọmọ Neri, 28 tí í ṣe ọmọ Meliki,

tí í ṣe ọmọ Adi, tí í ṣe ọmọ Kosamu,

tí í ṣe ọmọ Elmadamu, tí í ṣe ọmọ Eri,

29 Tí í ṣe ọmọ Joṣua, tí í ṣe ọmọ Elieseri,

tí í ṣe ọmọ Jorimu, tí í ṣe Mattati,

tí í ṣe ọmọ Lefi, 30 tí í ṣe ọmọ Simeoni,

tí í ṣe ọmọ Juda, tí í ṣe ọmọ Josẹfu,

tí í ṣe ọmọ Jonamu, tí í ṣe ọmọ Eliakimu,

31 Tí í ṣe ọmọ Melea, tí í ṣe ọmọ Menna,

tí í ṣe ọmọ Mattata, tí í ṣe ọmọ Natani,

tí í ṣe ọmọ Dafidi, 32 tí í ṣe ọmọ Jese,

tí í ṣe ọmọ Obedi, tí í ṣe ọmọ Boasi,

tí í ṣe ọmọ Salmoni, tí í ṣe ọmọ Nahiṣoni,

33 Tí í ṣe ọmọ Amminadabu, tí í ṣe ọmọ Ramu,

tí í ṣe ọmọ Hesroni, tí í ṣe ọmọ Peresi,

tí í ṣe ọmọ Juda. 34 Tí í ṣe ọmọ Jakọbu,

tí í ṣe ọmọ Isaaki, tí í ṣe ọmọ Abrahamu,

tí í ṣe ọmọ Tẹra, tí í ṣe ọmọ Nahori,

35 Tí í ṣe ọmọ Serugu, tí í ṣe ọmọ Reu,

tí í ṣe ọmọ Pelegi, tí í ṣe ọmọ Eberi,

tí í ṣe ọmọ Ṣela. 36 Tí í ṣe ọmọ Kainani,

tí í ṣe ọmọ Arfaksadi, tí í ṣe ọmọ Ṣemu,

tí í ṣe ọmọ Noa, tí í ṣe ọmọ Lameki,

37 Tí í ṣe ọmọ Metusela, tí í ṣe ọmọ Enoku,

tí í ṣe ọmọ Jaredi, tí í ṣe ọmọ Mahalaleli,

tí í ṣe ọmọ Kainani. 38 Tí í ṣe ọmọ Enosi,

tí í ṣe ọmọ Seti, tí í ṣe ọmọ Adamu,

tí í ṣe ọmọ Ọlọ́run.

Jobu 16-17

Ìdáhùn Jobu fún Elifasi

16 Ìgbà náà ní Jobu dáhùn, ó sì wí pé:

“Èmi ti gbọ́ irú ohun púpọ̀ bẹ́ẹ̀ rí
    ayọnilẹ́nu onítùnú ènìyàn ní gbogbo yín.
Ọ̀rọ̀ asán lè ni òpin?
    Tàbí kí ni ó gbó ọ láyà tí ìwọ fi dáhùn?
Èmi pẹ̀lú le sọ bí ẹ̀yin;
    bí ọkàn yín bá wà ní ipò ọkàn mi,
èmi le sọ ọ̀rọ̀ dáradára púpọ̀ sí yín ní ọrùn,
    èmi a sì mi orí mi sí i yín.
Èmi ìbá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi gbà yín ni
    ìyànjú, àti ṣíṣí ètè mi ìbá sì tu ìbìnújẹ́ yín.

“Bí èmi tilẹ̀ sọ̀rọ̀, ìbìnújẹ́ mi kò lọ;
    bí mo sì tilẹ̀ dákẹ́, níbo ni ìtùnú mí ko kúrò?
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó dá mi lágara;
    Ìwọ Ọlọ́run mú gbogbo ẹgbẹ́ mi takété.
Ìwọ fi ìhunjọ kùn mí lára, èyí tí o jẹ́rìí tì mí;
    àti rírù tí ó hàn lára mi, ó jẹ́rìí tì mí ní ojú.
Ọlọ́run fi i ìbínú rẹ̀ fà mí ya, ó sì gbóguntì mí;
    ó pa eyín rẹ̀ keke sí mi,
    ọ̀tá mi sì gbójú rẹ̀ sí mi.
10 Wọ́n ti fi ẹnu wọn yẹ̀yẹ́ mi;
    Wọ́n gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ìgbá ẹ̀gàn;
    Wọ́n kó ara wọn pọ̀ sí mi.
11 Ọlọ́run ti fi mí lé ọwọ́ ẹni
    búburú, ó sì mú mi ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn ìkà.
12 Mo ti jókòó jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n ó fà mí já;
    ó sì dì mí ni ọrùn mú, ó sì gbọ̀n mí túútúú,
ó sì gbé mi kalẹ̀ láti ṣe ààmì ìtafàsí rẹ̀;
13     àwọn tafàtafà rẹ̀ dúró yí mi káàkiri.
Ó là mí láyà pẹ̀rẹ̀, kò si dá sí,
    ó sì tú òróòro ara mi dà sílẹ̀.
14 Ìbàjẹ́ lórí ìbàjẹ́ ní ó fi bà mí jẹ́;
    ó súré kọlù mi bí jagunjagun.

15 “Mo rán aṣọ ọ̀fọ̀ bò ara mi,
    mo sì rẹ̀ ìwo mi sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.
16 Ojú mi ti pọ́n fún ẹkún,
    òjìji ikú sì ṣẹ́ sí ìpéǹpéjú mi.
17 Kì í ṣe nítorí àìṣòótọ́ kan ní ọwọ́
    mi; àdúrà mi sì mọ́ pẹ̀lú.

18 “Háà! Ilẹ̀ ayé, ìwọ má ṣe bò ẹ̀jẹ̀ mi,
    kí ẹkún mi má ṣe wà ní ipò kan.
19 Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi i, ẹlẹ́rìí mi ń bẹ ní ọ̀run,
    ẹ̀rí mi sì ń bẹ lókè ọ̀run.
20 Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣẹ̀sín,
    ṣùgbọ́n ojú mi ń da omijé sọ́dọ̀ Ọlọ́run;
21 Ìbá ṣe pé ẹnìkan le è máa ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọ́run,
    bí ènìyàn kan ti í ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀.

22 “Nítorí nígbà tí iye ọdún díẹ̀ rékọjá tán,
    nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà bọ̀.

Ìdáhùn Jobu

17 “Ẹ̀mí mi bàjẹ́,
    ọjọ́ mi ni a ti gé kúrú,
    isà òkú dúró dè mí.
Nítòótọ́ àwọn ẹlẹ́yà wà lọ́dọ̀ mi,
    ojú mi sì tẹ̀mọ́ ìmúnibínú wọn.

“Fi fún mi Olúwa, ìlérí tí ìwọ fẹ́;
    ta ni yóò le ṣe ààbò fún mi?
Nítorí pé ìwọ ti sé wọ́n láyà kúrò nínú òye;
    nítorí náà ìwọ kì yóò gbé wọn lékè.
Ẹni tí ó sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn dídún fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fún èrè,
    òun ni ojú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò mú òfo.

“Ọlọ́run ti sọ mi di ẹni òwe fún àwọn ènìyàn;
    níwájú wọn ni mo dàbí ẹni ìtutọ́ sí ní ojú.
Ojú mí ṣú bàìbàì nítorí ìbìnújẹ́,
    gbogbo ẹ̀yà ara mi sì dàbí òjìji.
Àwọn olódodo yóò yanu sí èyí,
    ẹni aláìṣẹ̀ sì bínú sí àwọn àgàbàgebè.
Olódodo pẹ̀lú yóò di ọ̀nà rẹ̀ mú,
    àti ọlọ́wọ́ mímọ́ yóò máa lera síwájú.

10 “Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti gbogbo yín,
    ẹ yípadà, kí ẹ si tún padà nísinsin yìí;
    èmi kò le rí ọlọ́gbọ́n kan nínú yín.
11 Ọjọ́ tí èmi ti kọjá, ìrò mi ti fà yá,
    àní ìrò ọkàn mi.
12 Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń ṣọ́ òru di ọ̀sán;
    wọ́n ní, ìmọ́lẹ̀ súnmọ́ ibi tí òkùnkùn dé.
13 Bí mo tilẹ̀ ní ìrètí, ipò òku ní ilé mi;
    mo ti tẹ́ ibùsùn mi sínú òkùnkùn.
14 Èmi ti wí fún ìdíbàjẹ́ pé, ìwọ ni baba mi,
    àti fún kòkòrò pé, ìwọ ni ìyá mi àti arábìnrin mi,
15 ìrètí mi ha dà nísinsin yìí?
    Bí ó ṣe ti ìrètí mi ni, ta ni yóò rí i?
16 Yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ipò òkú,
    nígbà tí a jùmọ̀ sinmi pọ̀ nínú erùpẹ̀ ilẹ̀?”

1 Kọrinti 4

Àwọn aposteli Kristi

(A)Nítorí náà, ṣe ló yẹ kí ènìyàn máa wò wá gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ àti ìríjú tí a fún ni oore-ọ̀fẹ́ láti mọ Kristi tí a fún ní oore-ọ̀fẹ́ láti mọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run. Òun kan náà tí ó tọ́ fún ìríjú, ni kí ó jẹ́ olóòtítọ́. Ṣùgbọ́n ohun kíkíní ni fún mi pé, kí ẹ máa ṣe ìdájọ́ mi, tàbí kí a máa ṣe ìdájọ́ nípa ìdájọ́ ènìyàn; nítòótọ́, èmi kò tilẹ̀ dá ara mi lẹ́jọ́. (B)Nítorí tí ẹ̀rí ọkàn mi kò dá mi ní ẹ̀bi; ṣùgbọ́n a kò ti ipa èyí dá mi láre, ṣùgbọ́n Olúwa ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ mi. (C)Nítorí náà, kí ẹ má ṣe ṣe ìdájọ́ ohunkóhun, kí Olúwa tó padà dé, ẹni tí yóò mú ohunkóhun tí ó fi ara sin wá sí ìmọ́lẹ̀, tí yóò sì fi ìmọ̀ ọkàn ènìyàn hàn, nígbà náà ni olúkúlùkù yóò sì ní ìyìn tirẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

(D)Ẹ kíyèsi i pé, mo ti fi ara mi àti Apollo ṣe àpẹẹrẹ nǹkan tí mo wí, pé kí ẹ̀yin lè ti ipa wa kọ́ láti máa ṣe ohun tí a ti kọ̀wé kọjá. “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe tìtorí ẹnìkan gbéraga sí ẹnìkejì.” Nítorí ta ni ó mú ọ yàtọ̀ sí àwọn ẹlòmíràn? Kí ni ìwọ ni tí ìwọ kò rí gbà? Tí ìwọ ba sì gbà á, èétiṣe tí ìwọ fi ń halẹ̀ bí ẹni pé ìwọ kò gba á?

Ni báyìí ẹ ní ohun gbogbo tí ẹ ń fẹ́! Báyìí ẹ sì ti di ọlọ́rọ̀! Ẹ ti di ọba. Lójú yín, àwa ti di ẹni ẹ̀yìn. Ìbá dùn mọ́ mi tí ó bá jẹ́ pé lóòtítọ́ ni ẹ ti di ọba lórí ìtẹ́ yín: tí a ó sì máa jẹ ọba pẹ̀lú yín! (E)Nítorí mo rò pé Ọlọ́run ń fi àwa aposteli hàn ní ìkẹyìn bí ẹni tí a dá lẹ́bi ikú bí àwọn, nítorí tí a fi wá ṣe ìran wò fún àwọn ènìyàn àti àwọn angẹli àti gbogbo ayé. 10 (F)Àwa jẹ́ aṣiwèrè nítorí Kristi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ọlọ́gbọ́n nínú Kristi! Àwa jẹ́ aláìlera, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ alágbára! Ẹ̀yin jẹ́ ẹni àyẹ́sí, àwa jẹ ẹni ẹ̀gàn! 11 (G)Títí di wákàtí yìí ni a ń rìn kiri nínú ebi àti òǹgbẹ, a n wọ aṣọ àkísà, tí a sì ń lù wa, tí a kò sì ní ibùgbé kan. 12 (H)Tí a ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́, wọn ń gàn wa, àwa ń súre, wọn ń ṣe inúnibíni sí wa, àwa ń forítì i. 13 Wọn ń kẹ́gàn wa, àwa ń bẹ̀bẹ̀. Títí di ìsinsin yìí ni a ti wà bí ohun ẹ̀gbin ayé, bí orí àkìtàn gbogbo ayé.

14 Èmi kò kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí láti fi dójútì yín, ṣùgbọ́n láti kìlọ̀ fún un yín bí àwọn ọmọ mi tí mo yàn fẹ́. 15 (I)Nítorí bí ẹ̀yin tilẹ̀ ní ẹgbàárùn-ún olùkọ́ni nínú Kristi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ni baba púpọ̀; nítorí nínú Kristi Jesu ni mo jẹ́ baba fún un yín nípasẹ̀ ìhìnrere. 16 Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ máa ṣe àfarawé mi. 17 (J)Nítorí náà ni mo ṣe rán Timotiu sí i yín, ẹni tí í ṣe ọmọ mi olùfẹ́ àti olódodo nínú Olúwa, ẹni tí yóò máa mú yín rántí ọ̀nà mi tí ó wà nínú Kristi Jesu, gẹ́gẹ́ bí mo ti ń kọ́ni nínú gbogbo ìjọ níbi gbogbo.

18 Mo mọ̀ pé àwọn mìíràn nínú yín tó ya onígbèéraga ènìyàn, tí wọn ń rò pé ẹ̀rù ń bà mi láti wá sọ́dọ̀ yín. 19 Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ̀ yín wá ní àìpẹ́ yìí bí Olúwa bá fẹ́; èmi yóò ṣe ìwádìí bí àwọn agbéraga yìí ṣe ń sọ̀rọ̀ àti agbára tí wọ́n ní. 20 Nítorí ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe nínú ọ̀rọ̀, bí kò ṣe nínú agbára. 21 (K)Èwo ni ẹ yàn? Kí ń wá sọ́dọ̀ yín pẹ̀lú pàṣán, tàbí ni ìfẹ́, àti ẹ̀mí tútù?

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.