Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Eksodu 10

Ìyọnu Eṣú

10 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Lọ sí ọ̀dọ̀ Farao, mo ti ṣé àyà Farao le àti àyà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kí èmi kí o ba le ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu mi láàrín wọn. Kí ẹ̀yin ki ó le sọ fún àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ ọmọ yín; Bí mo ti jẹ àwọn ará Ejibiti ní yà àti bí mo ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu láàrín wọn. Kí ìwọ ba á le mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”

Nígbà náà ni Mose àti Aaroni tọ Farao lọ, tiwọn sí wí fún un pé, “Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run àwọn Heberu sọ: ‘Yóò ti pẹ́ to ti ìwọ yóò kọ̀ láti tẹrí ara rẹ ba ní iwájú mi? Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó sìn mi. Bí ìwọ bá kọ̀ láti jẹ́ kí wọn lọ, èmi yóò mú eṣú wa sí orílẹ̀-èdè rẹ ní ọ̀la. Wọn yóò bo gbogbo ilẹ̀. Wọn yóò ba ohun gbogbo tí ó kù fún ọ lẹ́yìn òjò yìnyín jẹ́, tí ó fi dórí gbogbo igi tí ó ń dàgbà ni ilẹ̀ rẹ. Wọn yóò kún gbogbo ilé rẹ àti ilé àwọn ìjòyè rẹ àti ilé gbogbo àwọn ará Ejibiti. Ohun ti baba rẹ tàbí baba baba rẹ kò tí ì rí láti ìgbà tí wọ́n ti wà ní ilẹ̀ náà títí di àkókò yìí.’ ” Nígbà náà ni Mose pẹ̀yìndà kúrò níwájú Farao.

Àwọn ìjòyè Farao sọ fún un “Yóò ti pẹ́ to tí ọkùnrin yìí yóò máa jẹ́ ìkẹ́kùn fún wa? Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí lọ, kí wọn kí ó le sìn Olúwa Ọlọ́run wọn. Ṣe ìwọ kò ṣe àkíyèsí síbẹ̀ pé, ilẹ̀ Ejibiti ti parun tán?”

Nígbà náà ni a mú Aaroni àti Mose padà wá sí iwájú Farao ó sì wí fún wọn pé “Ẹ lọ sìn Olúwa Ọlọ́run yín. Ṣùgbọ́n àwọn ta ni nínú yín ni yóò ha lọ.”

Mose dáhùn ó wí pé, “A ó lọ pẹ̀lú àwọn ọmọdé àti àgbà wa, pẹ̀lú àwọn ọmọ wa ọkùnrin àti ọmọ wa obìnrin pẹ̀lú agbo àgùntàn wa àti agbo màlúù wa nítorí pé a gbọdọ̀ ṣe àjọ fún Olúwa.”

10 Farao sì wí pé, “Mo fi Olúwa búra pé èmi kí yóò jẹ́ kí ẹ lọ, pẹ̀lú àwọn obìnrin yín àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, dájúdájú èrò ibi ní ń bẹ nínú yín. 11 Rárá! Ọkùnrin yín nìkan ni kí ó lọ, láti lọ sin Olúwa, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé èyí ni ẹ̀yin ń béèrè fún.” Wọ́n sì lé Mose àti Aaroni kúrò ní iwájú Farao.

12 Ní ìgbà náà ni Ọlọ́run sọ fún Mose, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè lórí Ejibiti kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣú bo gbogbo ilẹ̀, kí ó sì ba gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ni inú oko wọn jẹ́, àní gbogbo ohun tí òjò yìnyín kò bàjẹ́ tan.”

13 Nígbà náà ni Mose na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ sórí ilẹ̀ Ejibiti, Olúwa sì mú kí afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn fẹ́ kọjá lórí ilẹ̀ náà ni gbogbo ọ̀sán àti ni gbogbo òru ni ọjọ́ náà. Ní òwúrọ̀ afẹ́fẹ́ náà ti gbá ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣú wá; 14 (A)Wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n wà ní ibi gbogbo ní orí ilẹ̀ ní àìmoye, ṣáájú àkókò yìí kò sí irú ìyọnu eṣú bẹ́ẹ̀ rí, kò sì ní sí irú rẹ mọ́ lẹ́yìn èyí. 15 Wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ tí ilẹ̀ fi di dúdú. Wọ́n ba gbogbo ohun tókù ní orí ilẹ̀ lẹ́yìn òjò yìnyín jẹ́; gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ní inú oko àti gbogbo èso tí ó wà lórí igi. Kò sí ewé tí ó kù lórí igi tàbí lórí ohun ọ̀gbìn ní gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.

16 Farao yára ránṣẹ́ pe Mose àti Aaroni, ó sì sọ fún wọn pé, “Èmi ti ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín àti sí i yín pẹ̀lú. 17 Nísinsin yìí ẹ dáríjì mi lẹ́ẹ̀kan sí i kí ẹ sì gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run yín kí ó lè mú ìpọ́njú yìí kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.”

18 Nígbà náà ni Mose kúrò ní iwájú Farao ó sì gbàdúrà sí Olúwa. 19 Olúwa sì yí afẹ́fẹ́ náà padà di afẹ́fẹ́ líle láti apá ìwọ̀-oòrùn wá láti gbá àwọn eṣú náà kúrò ní orí ilẹ̀ Ejibiti lọ sínú Òkun pupa. Bẹ́ẹ̀ ni ẹyọ eṣú kan kò ṣẹ́kù sí orí ilẹ̀ Ejibiti. 20 Síbẹ̀ Olúwa ṣe àyà Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ.

Òkùnkùn bo ilẹ̀

21 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run kí òkùnkùn bá à le bo gbogbo ilẹ̀ Ejibiti; àní òkùnkùn biribiri.” 22 (B)Nígbà náà ni Mose gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run, òkùnkùn biribiri sì bo gbogbo ilẹ̀ Ejibiti fún ọjọ́ mẹ́ta. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli ní ìmọ́lẹ̀ ní ibi tí wọn ń gbé. 23 Kò sí ẹni tí ó le è ríran rí ẹlòmíràn tàbí kí ó kúrò ní ibi tí ó wà fún ọjọ́ mẹ́ta. Síbẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli ni ìmọ́lẹ̀ ni gbogbo ibi tí wọ́n ń gbé.

24 Farao sì ránṣẹ́ pe Mose ó sì wí fún un pé, “Lọ sin Olúwa, kódà àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé lè lọ pẹ̀lú yín, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó fi agbo àgùntàn àti agbo màlúù yín sílẹ̀.”

25 Ṣùgbọ́n Mose sọ pé, “Ìwọ gbọdọ̀ fún wa láààyè láti rú ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ sísun ní iwájú Olúwa Ọlọ́run wa. 26 Àwọn ohun ọ̀sìn wa gbọdọ̀ lọ pẹ̀lú wa, a kì yóò fi pátákò ẹsẹ̀ ẹran sílẹ̀. A ní láti lò lára wọn fún sínsin Olúwa Ọlọ́run wa, ìgbà tí a bá sì dé ibẹ̀ ni a ó to mọ̀ ohun ti a ó lò láti fi sin Olúwa.”

27 Ṣùgbọ́n Olúwa sé ọkàn Farao le, kò sì ṣetán láti jẹ́ kí wọn lọ. 28 Farao sọ fún Mose pé, “Kúrò ní iwájú mi! Rí i dájú pé o kò wá sí iwájú mi mọ́! Ọjọ́ tí ìwọ bá rí ojú mi ni ìwọ yóò kùú.”

29 Mose sì dáhùn pé, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wí, “Èmi kí yóò wá sí iwájú rẹ mọ́.”

Luku 13

Ẹ ronúpìwàdà kí ẹ má bà á ṣègbé

13 Àwọn kan sì wá ní àkókò náà tí ó sọ ti àwọn ará Galili fún un, ẹ̀jẹ̀ ẹni tí Pilatu dàpọ̀ mọ́ ẹbọ wọn. (A)Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ṣe bí àwọn ará Galili wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo àwọn ará Galili lọ, nítorí wọ́n jẹ irú ìyà bá-wọ̀n-ọn-nì? Mo wí fún yín, bẹ́ẹ̀ kọ́: bí kò ṣe pé ẹ̀yin pẹ̀lú ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Tàbí àwọn méjì-dínlógún, tí ilé ìṣọ́ ní Siloamu wó lù, tí ó sì pa wọ́n, ẹ̀yin ṣe bí wọ́n ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ ní Jerusalẹmu lọ? Mo wí fún yín, bẹ́ẹ̀ kọ́: bí kò ṣe pé ẹ̀yin ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.”

(B)Ó sì pa òwe yìí fún wọn pé: “Ọkùnrin kan ní igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tí a gbìn sí ọgbà àjàrà rẹ̀; ó sì dé, ó ń wá èso lórí rẹ̀, kò sì rí nǹkan. (C)Ó sì wí fún olùṣọ́gbà rẹ̀ pé, ‘Sá à wò ó, láti ọdún mẹ́ta ni èmi ti ń wá í wo èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí, èmi kò sì rí nǹkan: ké e lulẹ̀; èéṣe tí ó fi ń gbilẹ̀ lásán pẹ̀lú?’

“Ó sì dáhùn ó wí fún un pé, ‘Olúwa, jọ̀wọ́ rẹ̀ ní ọdún yìí pẹ̀lú, títí èmi ó fi tu ilẹ̀ ìdí rẹ̀ yíká, títí èmi ó sì fi bu ìlẹ̀dú sí i: Bí ó bá sì so èso, o dara bẹ́ẹ̀: bí kò bá sì so, ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí nì kí ìwọ kí ó ké e lulẹ̀.’ ”

A mú obìnrin arọ láradá ní ọjọ́ ìsinmi

10 Ó sì ń kọ́ni nínú Sinagọgu kan ní ọjọ́ ìsinmi. 11 Sì kíyèsi i, obìnrin kan wà níbẹ̀ tí ó ní ẹ̀mí àìlera, láti ọdún méjì-dínlógún wá, ẹni tí ó tẹ̀ tán, tí kò le gbé ara rẹ̀ sókè bí ó ti wù kí ó ṣe. 12 Nígbà tí Jesu rí i, ó pè é sí ọ̀dọ̀, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, a tú ọ sílẹ̀ lọ́wọ́ àìlera rẹ.” 13 Ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ lé e: Lójúkan náà a sì ti sọ ọ́ di títọ́, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo.

14 (D)Olórí Sinagọgu sì kún fún ìrunú, nítorí tí Jesu mú ni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì wí fún ìjọ ènìyàn pé, ọjọ́ mẹ́fà ní ń bẹ tí a fi í ṣiṣẹ́: nínú wọn ni kí ẹ̀yin kí ó wá kí á ṣe dídá ara yín, kí ó má ṣe ní ọjọ́ ìsinmi.

15 (E)Nígbà náà ni Olúwa dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ẹ̀yin àgàbàgebè, olúkúlùkù yín kì í tú màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ kúrò ní ibùso, kì í sì í fà á lọ mu omi ní ọjọ́ ìsinmi. 16 (F)Kò sì yẹ kí a tú obìnrin yìí tí í ṣe ọmọbìnrin Abrahamu sílẹ̀ ní ìdè yìí ní ọjọ́ ìsinmi, ẹni tí Satani ti dè, sá à wò ó láti ọdún méjì-dínlógún yìí wá?”

17 Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí, ojú ti gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀: gbogbo ìjọ ènìyàn sì yọ̀ fún ohun ìyanu gbogbo tí ó ṣe.

Òwe irúgbìn tó kéré jùlọ àti ohun tí n mú ìyẹ̀fun wú

18 (G)Ó sì wí pé, “Kín ni ìjọba Ọlọ́run jọ? Kín ni èmi ó sì fiwé? 19 Ó dàbí hóró musitadi, tí ọkùnrin kan mú, tí ó sì sọ sínú ọgbà rẹ̀; tí ó sì hù, ó sì di igi ńlá; àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé orí ẹ̀ka rẹ̀.”

20 (H)Ó sì tún wí pé, “Kín ni èmi ìbá fi ìjọba Ọlọ́run wé? 21 Ó dàbí ìwúkàrà, tí obìnrin kan mú, tí ó fi sínú òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun mẹ́ta, títí gbogbo rẹ̀ ó fi di wíwú.”

Ọ̀nà tóóró

22 (I)Ó sì ń la àárín ìlú àti ìletò lọ, ó ń kọ́ni, ó sì ń rìn lọ sí Jerusalẹmu. 23 (J)Ẹnìkan sì bi í pé, Olúwa, díẹ̀ ha kọ ni àwọn tí a ó gbàlà?

Ó sì wí fún wọn pé, 24 “Ẹ làkàkà láti gba ojú ọ̀nà tóóró wọlé: nítorí mo wí fún yín, ènìyàn púpọ̀ ni yóò wá ọ̀nà láti wọ̀ ọ́, wọn kì yóò sì lè wọlé. 25 (K)Nígbà tí baálé ilé bá dìde lẹ́ẹ̀kan fùú, tí ó bá sí ti ìlẹ̀kùn, ẹ̀yin ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dúró lóde, tí ẹ ó máa kan ìlẹ̀kùn, wí pé, ‘Olúwa, Olúwa, ṣí i fún wa!’

“Òun ó sì dáhùn wí fún yín pé, ‘Èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá.’ Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mọ̀ yín.

26 (L)“Nígbà náà ni ẹ̀yin ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, ‘Àwa ti jẹ, àwa sì ti mu níwájú rẹ, ìwọ sì kọ́ni ní ìgboro ìlú wa.’

27 “Òun ó sì wí pé, ‘Èmi wí fún yín èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá; ẹ lọ kúrò lọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’

28 (M)“Níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpahínkeke yóò wà, nígbà tí ẹ̀yin ó rí Abrahamu, àti Isaaki, àti Jakọbu, àti gbogbo àwọn wòlíì, ní ìjọba Ọlọ́run, tí a ó sì ti ẹ̀yin sóde. 29 Wọn ó sì ti ilẹ̀ ìlà-oòrùn, àti ìwọ̀-oòrùn wá, àti láti àríwá, àti gúúsù wá, wọn ó sì jókòó ní ìjọba Ọlọ́run. 30 (N)Sì wò ó, àwọn ẹni ẹ̀yìn ń bẹ tí yóò di ẹni iwájú, àwọn ẹni iwájú ń bẹ tí yóò di ẹni ẹ̀yìn.”

Jesu káàánú fún Jerusalẹmu

31 Ní wákàtí kan náà, díẹ̀ nínú àwọn Farisi tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Jáde, kí ìwọ sì lọ kúrò níhìn-ín yìí: nítorí Herodu ń fẹ́ pa ọ́.”

32 (O)Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ, kí ẹ̀yin sì sọ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà pé, ‘Kíyèsi i, èmi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, èmi ń ṣe ìmúláradá lónìí àti lọ́la, àti ní ọjọ́ mẹ́ta èmi ó ṣe àṣepé.’ 33 Ṣùgbọ́n èmi kò jẹ́ má rìn lónìí, àti lọ́la, àti ní ọ̀túnla: dájúdájú wòlíì kan ki yóò ṣègbé lẹ́yìn odi Jerusalẹmu.

34 (P)“Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìwọ tí o pa àwọn wòlíì, tí o sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí ọ pa; nígbà mélòó ni èmi ń fẹ́ ràgà bo àwọn ọmọ rẹ, bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í ràgà bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ apá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́! 35 (Q)Sá wò ó, a fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro. Lóòtítọ́ ni mo sì wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi títí yóò fi di àkókò tí ẹ̀yin ó wí pé, ‘Olùbùkún ni ẹni tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa.’ ”

Jobu 28

Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n àti òye Jobu

28 Nítòótọ́, koto fàdákà ń bẹ,
    àti ibi tí wọ́n ti máa ń da wúrà.
Nínú ilẹ̀ ni à ń gbé ń wa irin,
    bàbà ni a sì ń dà láti inú òkúta wá.
Ènìyàn ni ó fi òpin si òkùnkùn,
    ó sì ṣe àwárí ìṣúra
    láti inú òjìji ikú sí ìhà gbogbo.
Wọ́n wa ihò ilẹ̀ tí ó jì sí àwọn tí ń gbé òkè,
    àwọn tí ẹsẹ̀ ènìyàn gbàgbé wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀,
    wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀ jìnnà sí àwọn ènìyàn.
Bí ó ṣe ti ilẹ̀ ni, nínú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde wá,
    àti ohun tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni ó yí padà bi iná
Òkúta ibẹ̀ ni ibi òkúta Safire,
    o sì ní erùpẹ̀ wúrà.
Ipa ọ̀nà náà ni ẹyẹ kò mọ̀,
    àti ojú gúnnugún kò rí i rí;
Àwọn ẹranko agbéraga kò rìn ibẹ̀ rí,
    bẹ́ẹ̀ ni kìnnìún tí ń ké ramúramù kò kọjá níbẹ̀ rí.
Ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé akọ òkúta,
    ó yí òkè ńlá po láti ìdí rẹ̀ wá.
10 Ó sì la ipa odò ṣíṣàn nínú àpáta,
    ojú inú rẹ̀ sì rí ohun iyebíye gbogbo.
11 Ó sì ṣe ìṣàn odò kí ó má ṣe kún àkúnya,
    ó sì mú ohun tí ó pamọ́ hàn jáde wá sí ìmọ́lẹ̀.

12 Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wá ọgbọ́n rí,
    níbo sì ni òye ń gbe?
13 Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè.
14 Ọ̀gbun wí pé, “Kò sí nínú mi”;
    omi Òkun sì wí pé, “Kò si nínú mi.”
15 A kò le è fi wúrà rà á,
    bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi òṣùwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀.
16 A kò le è fi wúrà ofiri,
    tàbí òkúta óníkìsì iyebíye, tàbí òkúta Safire díye lé e.
17 Wúrà àti òkúta kristali kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀;
    bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èlò wúrà ṣe pàṣípàrọ̀ rẹ̀.
18 A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta jasperi;
    iye ọgbọ́n sì ju iyùn lọ.
19 Òkúta topasi ti Kuṣi kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀;
    bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀.

20 Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá?
    Tàbí níbo ni òye ń gbé?
21 A rí i pé, ó fi ara sinko kúrò ní ojú àwọn alààyè gbogbo,
    ó sì fi ara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run.
22 Ibi ìparun àti ikú wí pé,
    àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀.
23 Ọlọ́run ni ó mọ òye ipa ọ̀nà rẹ̀,
    òun ni ó sì mọ ibi tí ó ń gbé.
24 Nítorí pé ó wòye dé òpin ayé,
    ó sì rí gbogbo ìsàlẹ̀ ọ̀run,
25 Láti dà òṣùwọ̀n fún afẹ́fẹ́,
    ó sì fi òṣùwọ̀n wọ́n omi.
26 Nígbà tí ó pàṣẹ fún òjò,
    tí ó sì la ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,
27 Nígbà náà ni ó rí i, ó sì sọ ọ́ jáde;
    ó pèsè rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ṣe ìwádìí rẹ̀ rí.
28 Àti fún ènìyàn ni ó wí pé,
    “Kíyèsi i, ẹ̀rù Olúwa èyí ni ọgbọ́n,
    àti láti jáde kúrò nínú ìwà búburú èyí ni òye.”

1 Kọrinti 14

Ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ àti ìfèdèfọ̀

14 Ẹ máa lépa ìfẹ́, ki ẹ sí máa fi ìtara ṣàfẹ́rí ẹ̀bùn tí í ṣe ti Ẹ̀mí, ṣùgbọ́n ki ẹ kúkú lé máa sọtẹ́lẹ̀. Nítorí ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, kò bá ènìyàn sọ̀rọ̀ bì ko ṣe Ọlọ́run: nítorí kó sí ẹni tí ó gbọ́; ṣùgbọ́n nípá ti Ẹ̀mí ó ń sọ ohun ìjìnlẹ̀; Ṣùgbọ́n ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ ń ba àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ìmúdúró, àti ìgbani-níyànjú, àti ìtùnú. Ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀ ń fi ẹsẹ̀ ara rẹ̀ mulẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni ti ń sọtẹ́lẹ̀ ń fi ẹsẹ̀ ìjọ múlẹ̀. Ṣùgbọ́n ìbá wù mí ki gbogbo yín lè máa sọ onírúurú èdè, ṣùgbọ́n kí ẹ kúkú máa sọtẹ́lẹ̀: Ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ pọ̀ jú ẹni ti ń fèdèfọ̀ lọ, bi kọ ṣe pé ó bá ń ṣe ìtumọ̀, kí ìjọ bá à lè kọ́ ẹ̀kọ́.

Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ará, bí mo bá wá sí àárín yín, tí mo sì ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, èrè kín ni èmi yóò jẹ́ fún yin, bi ko ṣe pé mo bá ń bá yín sọ̀rọ̀, yálà nípa ìṣípayá, tàbí ìmọ̀ tàbí nípá ìsọtẹ́lẹ̀, tàbí nípa ẹ̀kọ́? Bẹ́ẹ̀ ní pẹ̀lú àwọn nǹkan tí kò ní ẹ̀mí tí ń dún, ìbá à ṣe fèrè tàbí dùùrù bí kò ṣe pé ìyàtọ̀ bá wà nínú wọn, a ó tí ṣe mọ ohùn tí fèrè tàbí tí dùùrù ń wí? Nítorí pé bi ohùn ìpè kò bá dájú, ta ni yóò múra fún ogun? Bẹ́ẹ̀ sí ni ẹ̀yin, bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá ń fi ahọ́n yín sọ̀rọ̀ tí ó yé ni, a ó ti ṣe mọ ohun ti ẹ ń wí? Nítorí pé ẹ̀yin yóò kàn máa sọ̀rọ̀ si afẹ́fẹ́ lásán. 10 Ó lé jẹ́ pé onírúurú ohùn èdè ní ń bẹ ní ayé, kò sí ọ̀kan tí kò ní ìtumọ̀ 11 Ǹjẹ́ bí èmí kò mọ ìtumọ̀ ohùn èdè náà, èmí ó jásí aláìgbédè sí ẹni tí ń sọ̀rọ̀, ẹni tí ń sọ̀rọ̀ yóò sí jásí aláìgbédè sí mi. 12 Bẹ́ẹ̀ sì ní ẹ̀yin, bí ẹ̀yin ti ní ìtara fún ẹ̀bùn Ẹ̀mí, ẹ máa ṣe àfẹ́rí àti máa pọ̀ sí i fún ìdàgbàsókè ìjọ.

13 Nítorí náà jẹ́ ki ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀ gbàdúrà ki ó lè máa ṣe ìtumọ̀ ohun tí ó sọ. 14 Nítorí bí èmi bá ń gbàdúrà ní èdè àìmọ̀, ẹ̀mí mi ni ń gbàdúrà, ṣùgbọ́n ọkàn mi jẹ́ aláìléso. 15 (A)Ǹjẹ́ kín ni èmi yóò ṣe? Èmi yóò fi ẹ̀mí mi gbàdúrà, èmi yóò sí fi òye mi gbàdúrà pẹ̀lú; Èmi yóò fi ẹ̀mí mi kọrin, èmi yóò sí fi òye mi kọrin pẹ̀lú. 16 (B)Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ìwọ bá yin Ọlọ́run nípa ẹ̀mí, báwo ni ẹni tí ń bẹ ni ipò òpè yóò ṣe ṣe “Àmín” si ìdúpẹ́ rẹ, nígbà tí kò mọ ohun tí ìwọ wí? 17 Nítorí ìwọ dúpẹ́ gidigidi nítòótọ́, ṣùgbọ́n a kó fi ẹsẹ̀ ẹnìkejì rẹ múlẹ̀.

18 Mó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run tí èmi ń fọ onírúurú èdè ju gbogbo yín lọ: 19 Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí n kúkú fi ọkàn mi sọ ọ̀rọ̀ márùn-ún ni inú ìjọ, kí n lè kọ́ àwọn ẹlòmíràn ju ẹgbàárùn-ún ọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀.

20 (C)Ará, ẹ má ṣe jẹ ọmọdé ni òye, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ọmọdé ní àrankàn, ṣùgbọ́n ni òye ẹ jẹ́ àgbà. 21 (D)A tí kọ ọ́ nínú òfin pé,

“Nípa àwọn aláhọ́n mìíràn
    àti elétè àjèjì
ní èmi ó fi ba àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀;
    síbẹ̀ wọn kì yóò gbọ́ tèmi,”
ni Olúwa wí.

22 Nítorí náà àwọn ahọ́n jásí ààmì kan, kì í ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́, bí kò ṣe fún àwọn aláìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n ìsọtẹ́lẹ̀ kì í ṣe fún àwọn tí kò gbàgbọ́ bí kò ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́. 23 Ǹjẹ́ bí gbogbo ìjọ bá péjọ sí ibi kan, tí gbogbo wọn sí ń fi èdè fọ̀, bí àwọn tí ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìgbàgbọ́ bá wọlé wá, wọn kí yóò ha wí pé ẹ̀yin ń ṣe òmùgọ̀? 24 Ṣùgbọ́n bí gbogbo yín bá ń sọtẹ́lẹ̀, ti ẹnìkan tí kò gbàgbọ́ tàbí tí ko ni ẹ̀kọ́ bá wọlé wá, gbogbo yin ní yóò fi òye ẹ̀ṣẹ̀ yé e, gbogbo yin ní yóò wádìí rẹ̀. 25 Bẹ́ẹ̀ ní a ó sì fi àṣírí ọkàn rẹ̀ hàn; bẹ́ẹ̀ ni òun ó sì dojúbolẹ̀, yóò sí sin Ọlọ́run yóò sì sọ pé, “Nítòótọ́ Ọlọ́run ń bẹ láàrín yín!”

Ètò ìsìn lẹ́sẹẹsẹ

26 (E)Ǹjẹ́ èéha ti ṣe, kín ni àwa yóò sọ ẹ̀yin ará? Nígbà tí ẹ̀yin péjọpọ̀, tí olúkúlùkù yín ni Saamu kan tàbí ẹ̀kọ́ kan, èdè kan, ìfihàn kan àti ìtumọ̀ kan. Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láti gbé ìjọ ró. 27 Bí ẹnìkan bá fi èdè fọ̀, kí ó jẹ ènìyàn méjì, tàbí bí ó pọ̀ tán, kí ó jẹ́ mẹ́ta, kí ó sọ̀rọ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, kí ẹnìkan sì túmọ̀ rẹ̀, 28 Ṣùgbọ́n bí kò bá sí ògbufọ̀, kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ nínú ìjọ; sì jẹ́ kí ó máa bá ara rẹ̀ àti Ọlọ́run sọ̀rọ̀.

29 Jẹ́ kí àwọn wòlíì méjì tàbí mẹ́ta sọ̀rọ̀, ki àwọn ìyókù sì wòye ìtumọ̀ ohun tí a sọ. 30 Bí a bá sì fi ohunkóhun hàn ẹni tí ó jókòó níbẹ̀, jẹ́ kí ẹni tí ó kọ́ sọ̀rọ̀ ṣáájú dákẹ́. 31 Nítorí gbogbo yín lè sọtẹ́lẹ̀ ni ọ̀kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo yín lè kọ́ ẹ̀kọ́, kí a lè tu gbogbo yín nínú. 32 Ẹ̀mí àwọn wòlíì a sí máa tẹríba fún àwọn wòlíì. 33 Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run ohun rúdurùdu, ṣùgbọ́n ti àlàáfíà. Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ nínú gbogbo ìjọ ènìyàn mímọ́.

34 (F)Jẹ́ ki àwọn obìnrin yín dákẹ́ nínú ìjọ: nítorí a kò fi fún wọn láti sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ kí wọn wà lábẹ́ ìtẹríba, gẹ́gẹ́ bí òfin pẹ̀lú ti wí. 35 Bí wọ́n bá sì fẹ́ mọ̀ nípa ohunkóhun, kí wọn béèrè lọ́wọ́ ọkọ wọn ní ilé; nítorí ohun ìtìjú ni fún àwọn obìnrin láti máa sọ̀rọ̀ nínú ìjọ.

36 Kín ni? Ṣe lọ́dọ̀ yín ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jáde ni, tàbí ẹ̀yin nìkan ni o tọ̀ wá? 37 Bí ẹnikẹ́ni bá ró ará rẹ̀ pé òun jẹ́ wòlíì, tàbí òun jẹ́ ẹni tí ó ní ẹ̀bùn ẹ̀mí, jẹ́ kí nǹkan wọ̀nyí ti mo kọ sí yin yé e dájú pé òfin Olúwa ni wọ́n. 38 Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá fi ojú fo èyí dá, òun fúnrarẹ̀ ní a ó fi ojú fò dá.

39 Nítorí náà ará, ẹ máa fi ìtara ṣàfẹ́rí láti sọtẹ́lẹ̀, kí ẹ má sì ṣe dánilẹ́kun láti fi èdè fọ̀. 40 Ẹ máa ṣe ohun gbogbo tẹ̀yẹtẹ̀yẹ àti lẹ́sẹẹsẹ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.