M’Cheyne Bible Reading Plan
6 (A)Nígbà náà ní Olúwa sọ fún Mose pé, “Ní ìsin yìí, ìwọ yóò rí ohun tí èmi yóò ṣe sí Farao pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá mi ni yóò fi jẹ́ kí wọn lọ; pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá mi, òun yóò lé wọn jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ̀.”
2 (B)Ọlọ́run sì tún sọ fún Mose pé, “Èmi ni Olúwa. 3 Mo fi ara hàn Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu bí Ọlọ́run alágbára (Eli-Ṣaddai) ṣùgbọ́n nípa orúkọ mi Olúwa, Èmi kò fi ara Mi hàn wọ́n. 4 Èmí sì tún fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú wọn láti fún wọn ní ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ tí wọn gbé gẹ́gẹ́ bí àjèjì. 5 Èmi sì ti tún gbọ́ kíkùn àwọn ọmọ Israẹli àwọn tí àwọn ará Ejibiti mú gẹ́gẹ́ bí ẹrú, àti pé èmi sì ti rántí májẹ̀mú Mi.
6 “Sọ fún àwọn ará ilé Israẹli: ‘Èmi ni Olúwa, Èmi yóò sọ yín di òmìnira kúrò nínú àjàgà àwọn ará Ejibiti. Èmi yóò sì gbà yín sílẹ̀ kúrò ní oko ẹrú wọn. Èmi yóò dá a yín sílẹ̀ pẹ̀lú apá nínà (àwọn iṣẹ́ ìyanu) àti pẹ̀lú ìdájọ́ ńlá. 7 Èmi yóò mú un yín bí ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹni tí ó mú un yín jáde kúrò nínú àjàgà àwọn ará Ejibiti. 8 Èmi yóò mú un yín wá ilẹ̀ náà ti èmi ti búra pẹ̀lú ìgbọ́wọ́sókè láti fi fún Abrahamu. Isaaki àti Jakọbu. Èmi yóò fi fún un yín bí ohun ìní, Èmi ni Olúwa.’ ”
9 Mose sì sọ èyí fún àwọn ará Israẹli, ṣùgbọ́n wọn kò fi etí sílẹ̀ sí Mose nítorí ọkàn wọn tó rẹ̀wẹ̀sì àti nítorí ìgbèkùn búburú bí ohun tí ó ti kọ́ sọ kó wọn sí ní oko ẹrú wọn.
10 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose. 11 “Lọ, sọ fún Farao ọba Ejibiti pé kí ó jẹ́ kí àwọn ará Israẹli lọ kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ̀.”
12 Ṣùgbọ́n Mose sọ fún Olúwa pé, “Nígbà ti àwọn ará Israẹli tó jẹ́ ènìyàn mi kó fetí sí ọ̀rọ̀ mi, báwo ni Farao yóò ṣe fetí sí ọ̀rọ̀ mi, nígbà ti mo jẹ́ akólòlò?”
Àkọsílẹ̀ ìdílé Mose Àti Aaroni
13 Olúwa bá ìran Mose àti Aaroni sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará Israẹli àti Farao ọba Ejibiti, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn kó àwọn Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.
14 Wọ̀nyí ni olórí ìran wọn:
Àwọn ọmọ Reubeni àkọ́bí Israẹli ni:
Hanoku, Pallu, Hesroni àti Karmi.
Àwọn wọ̀nyí ni ìdílé Reubeni.
15 Àwọn ọmọ Simeoni ní:
Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari àti Saulu ọmọ obìnrin Kenaani.
Àwọn wọ̀nyí ni ìran Simeoni.
16 (C)Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn:
Gerṣoni, Kohati àti Merari.
Lefi lo ẹ̀tàndínlógóje (137) ọdún láyé.
17 Àwọn ọmọ Gerṣoni ni ìran wọn ni:
Libni àti Ṣimei.
18 Àwọn ọmọ Kohati ni:
Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli.
Kohati lo ẹ̀tàléláádóje (133) ọdún láyé.
19 Àwọn ọmọ Merari ni:
Mahili àti Muṣi.
Ìwọ̀nyí ni ìran Lefi gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn.
20 (D)Amramu sì fẹ́ Jokebedi arábìnrin baba rẹ̀ ní ìyàwó. Jokebedi sì bí Aaroni àti Mose fún un.
Amramu lo ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún láyé.
21 Àwọn ọmọ Isari ni:
Kora, Nefegi àti Sikri.
22 Àwọn ọmọ Usieli ni:
Miṣaeli, Elsafani àti Sitiri.
23 Aaroni fẹ́ Eliṣeba ọmọbìnrin Amminadabu tí í ṣe arábìnrin Nahiṣoni, ó sì bí Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari.
24 Àwọn ọmọ Kora ni:
Asiri, Elkana àti Abiasafu.
Ìwọ̀nyí ni ìran Kora.
25 Eleasari ọmọ Aaroni fẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Putieli ní ìyàwó, ó sì bí Finehasi fún un.
Ìwọ̀nyí ni olórí àwọn Lefi ni ìdílé ìdílé.
26 Aaroni àti Mose yìí kan náà ni Olúwa sọ fún pé, “Ẹ kó àwọn ará Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí.” 27 Àwọn ni ó bá Farao ọba Ejibiti sọ̀rọ̀ nípa kíkó àwọn ará Israẹli jáde kúrò ni Ejibiti, àní Mose àti Aaroni yìí kan náà ni.
Aaroni di agbẹnusọ fún Mose
28 Nígbà tí Olúwa bá Mose sọ̀rọ̀ ni Ejibiti, 29 Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Èmi ni Olúwa. Sọ ohun gbogbo ti mo ti sọ fún ọ fún Farao ọba Ejibiti.”
30 Ṣùgbọ́n Mose sì wí ní iwájú Olúwa pé, “Níwọ́n ìgbà ti mo jẹ́ akólòlò, ọ̀nà dà ti Farao yóò ṣe fi etí sí mi?”
Jesu rán ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá lọ wàásù
9 (A)Ó sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá jọ, ó sì fún wọn ní agbára àti àṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí èṣù gbogbo, àti láti wo ààrùn sàn. 2 Ó sì rán wọn lọ wàásù ìjọba Ọlọ́run, àti láti mú àwọn ọlọkùnrùn láradá. 3 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe mú nǹkan lọ́wọ́ fún àjò yín, ọ̀pá, tàbí àpò tàbí àkàrà, tàbí owó: bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má sì ṣe ní ẹ̀wù méjì. 4 Ní ilékílé tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin gbé, láti ibẹ̀ ni kí ẹ̀yin sì ti jáde. 5 (B)Iye àwọn tí kò bá si gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá jáde kúrò ní ìlú náà, ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín fún ẹ̀rí sí wọn.” 6 Wọ́n sì lọ, wọ́n ń la ìletò kọjá wọ́n sì ń wàásù ìhìnrere, wọ́n sì ń mú ènìyàn láradá níbi gbogbo.
7 (C)Herodu tetrarki gbọ́ nǹkan gbogbo èyí tí a ṣe láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá: ó sì dààmú, nítorí tí àwọn ẹlòmíràn ń wí pé, Johanu ni ó jíǹde kúrò nínú òkú; 8 Àwọn ẹlòmíràn sì wí pé Elijah ni ó farahàn; àwọn ẹlòmíràn sì wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde. 9 (D)Herodu sì wí pé, “Johanu ni mo ti bẹ́ lórí: ṣùgbọ́n ta ni èyí tí èmi ń gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí sí?” Ó sì ń fẹ́ láti rí i.
Jesu bọ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn
10 (E)Nígbà tí àwọn aposteli sì padà dé, wọ́n ròyìn ohun gbogbo fún un tí wọ́n ti ṣe. Ó sì mú wọn, lọ sí apá kan níbi tí a ń pè ní Betisaida. 11 (F)Nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sì mọ̀, wọ́n tẹ̀lé e: ó sì gbà wọ́n, ó sì sọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún wọn; àwọn tí ó fẹ́ ìmúláradá, ni ó sì mú láradá.
12 Nígbà tí ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ sí rọlẹ̀, àwọn méjìlá wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Tú ìjọ ènìyàn ká, kí wọn lè lọ sí ìletò àti sí ìlú yíká, kí wọn lè wò, àti kí wọn lè wá oúnjẹ: nítorí ijù ni àwa sá wà níhìn-ín.”
13 (G)Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Ẹ fi oúnjẹ fún wọn jẹ!”
Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-ún lọ, pẹ̀lú ẹja méjì: bí kò ṣe pé àwa lọ ra oúnjẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí.” 14 Nítorí àwọn ọkùnrin náà tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn.
Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Kí wọ́n mú wọn jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, ní àràádọ́ta.” 15 Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì mú gbogbo wọn jókòó. 16 (H)Nígbà náà ni ó mú ìṣù àkàrà márùn-ún, àti ẹja méjì náà, nígbà tí ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó súre sí i, ó sì bù ú, ó sì fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, kí wọn gbé e kalẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn. 17 Wọ́n sì jẹ, gbogbo wọn sì yó: wọ́n ṣa agbọ̀n méjìlá jọ nínú àjẹkù tí ó kù.
Peteru pe Jesu ní ọmọ Ọlọ́run
18 (I)(J) Ó sì ṣe, nígbà tí ó ku òun nìkan ó gbàdúrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀: ó sì bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi mí pè?”
19 (K)Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi; ṣùgbọ́n ẹlòmíràn ní Elijah ni; àti àwọn ẹlòmíràn wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde.”
20 Ó sì bi wọ́n pé, “Ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin ń fi èmi pè?”
Peteru sì dáhùn, wí pe, “Kristi ti Ọlọ́run.”
21 Ó sì kìlọ̀ fún wọn, pé, kí wọn má ṣe sọ èyí fún ẹnìkan. 22 (L)Ó sì wí pé, “Ọmọ ènìyàn yóò jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà, olórí àlùfáà àti láti ọ̀dọ̀ àwọn akọ̀wé, a ó sì pa á, ní ọjọ́ kẹta a ó sì jí i dìde.”
23 (M)Ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Bí ẹnìkan bá ń fẹ́ láti máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀ ní ọjọ́ gbogbo, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn. 24 (N)Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọkàn rẹ̀ nù nítorí mi, òun náà ni yóò sì gbà á là. 25 Nítorí pé èrè kín ni fún ènìyàn, bí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sì sọ ara rẹ̀ nù tàbí kí ó fi ṣòfò. 26 (O)Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú mi, àti ọ̀rọ̀ mi, òun ni ọmọ ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé inú ògo tirẹ̀, àti ti baba rẹ̀, àti ti àwọn angẹli mímọ́.
27 (P)“Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹlòmíràn dúró níhìn-ín yìí, tí kì yóò rí ikú, títí wọn ó fi rí ìjọba Ọlọ́run.”
Ìràpadà
28 (Q)(R) Ó sì ṣe bí ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Peteru àti Johanu àti Jakọbu, ó gun orí òkè lọ láti lọ gbàdúrà. 29 Bí ó sì ti ń gbàdúrà, àwọ̀ ojú rẹ̀ yípadà, aṣọ rẹ̀ sì funfun gbòò, 30 (S)Sì kíyèsi i, àwọn ọkùnrin méjì, Mose àti Elijah, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀: 31 Tí wọ́n fi ara hàn nínú ògo, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ikú rẹ̀, tí òun yóò ṣe parí ní Jerusalẹmu. 32 (T)Ṣùgbọ́n ojú Peteru àti ti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wúwo fún oorun. Nígbà tí wọ́n sì tají, wọ́n rí ògo rẹ̀, àti ti àwọn ọkùnrin méjèèjì tí ó bá a dúró. 33 (U)Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, Peteru wí fún Jesu pé, “Olùkọ́, ó dára fún wa kí a máa gbé ìhín yìí: jẹ́ kí àwa pa àgọ́ mẹ́ta; ọ̀kan fún ìwọ, àti ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.” (Kò mọ èyí tí òun ń wí.)
34 Bí ó ti ń sọ báyìí, ìkùùkuu kan wá, ó ṣíji bò wọ́n: ẹ̀rù sì bà wọ́n nígbà tí wọ́n ń wọ inú ìkùùkuu lọ. 35 (V)Ohùn kan sì ti inú ìkùùkuu wá wí pé, “Èyí yìí ni àyànfẹ́ ọmọ mi: ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.” 36 (W)Nígbà tí ohùn náà sì dákẹ́, Jesu nìkan ṣoṣo ni a rí. Wọ́n sì pa á mọ́, wọn kò sì sọ ohunkóhun tí wọ́n rí fún ẹnikẹ́ni ní ọjọ́ wọ̀nyí.
Ìwòsàn ọmọkùnrin kan tí o ní ẹ̀mí èṣù
37 (X)Ó sì ṣe, ní ọjọ́ kejì, nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti orí òkè, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn wá pàdé rẹ̀. 38 Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan nínú ìjọ ènìyàn kígbe sókè, pé “Olùkọ́ mo bẹ̀ ọ́, wo ọmọ mi: nítorí ọmọ mi kan ṣoṣo náà ni. 39 Sì kíyèsi i, ẹ̀mí èṣù a máa mú un, a sì máa kígbe lójijì; a sì máa nà án tàntàn títí yóò fi yọ ìfófó lẹ́nu, a máa pa á lára, kì í tilẹ̀ ń fẹ́ fi í sílẹ̀ lọ. 40 Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ láti lé e jáde: wọn kò sì lè ṣe é.”
41 Jesu sì dáhùn pé, “Ìran aláìgbàgbọ́ àti àrékérekè, èmi ó ti bá yín gbé pẹ́ tó? Èmi yóò sì ti ṣe sùúrù fún yín pẹ́ tó? Fa ọmọ rẹ wá níhìn-ín yìí.”
42 Bí ó sì ti ń bọ̀, ẹ̀mí èṣù náà gbé e ṣánlẹ̀, ó sì nà án tàntàn. Jesu sì bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí, ó sì mú ọmọ náà láradá, ó sì fà á lé baba rẹ̀ lọ́wọ́. 43 (Y)Ẹnu sì ya gbogbo wọn sí iṣẹ́ títóbi Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nígbà tí hà sì ń ṣe gbogbo wọn sí ohun gbogbo tí Jesu ṣe, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, 44 “Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wọ̀ yín létí: nítorí a ó fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́.” 45 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yé wọn, ó sì ṣú wọn lójú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì mọ̀ ọ́n: ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti béèrè ìdí ọ̀rọ̀ náà.
Ta ni yí o ga jùlọ
46 (Z)Iyàn kan sì dìde láàrín wọn, ní ti ẹni tí yóò ṣe olórí nínú wọn. 47 Nígbà tí Jesu sì mọ èrò ọkàn wọn, ó mú ọmọdé kan, ó gbé e jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀. 48 (AA)Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọdé yìí nítorí orúkọ mi, ó gbà mí: àti ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi: nítorí ẹni tí ó bá kéré jù nínú gbogbo yín, òun náà ni yóò pọ̀jù.”
49 (AB)(AC) Johanu sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́, àwa rí ẹnìkan ó ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde; àwa sì dá a lẹ́kun, nítorí tí kò bá wa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”
50 Jesu sì wí fún un, pé, “Má ṣe dá a lẹ́kun mọ́: nítorí ẹni tí kò bá lòdì sí i yín, ó wà fún yín.”
Ìtakò àwọn ará Samaria
51 (AD)Nígbà tí ọjọ́ àti gbà á sókè ń súnmọ́, ó pinnu láti lọ sí Jerusalẹmu. 52 (AE)Ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ lọ sí iwájú rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì lọ wọ́n wọ ìletò kan tí í ṣe ti ará Samaria láti pèsè sílẹ̀ dè é. 53 Wọn kò sì gbà á, nítorí pé ó ń lọ sí Jerusalẹmu. 54 (AF)Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Jakọbu àti Johanu sì rí i, wọ́n ní, “Olúwa wa, jẹ́ kí a pe iná láti ọ̀run wá, kí a sì pa wọ́n run, bí Elijah ti ṣe?” 55 Ṣùgbọ́n Jesu yípadà, ó sì bá wọn wí, ó ní, ẹ̀yin kò mọ irú ẹ̀mí tí ń bẹ nínú yín 56 Nítorí ọmọ ènìyàn kò wá láti pa ẹ̀mí ènìyàn run, bí kò ṣe láti gbà á là. Wọ́n sì lọ sí ìletò mìíràn.
Ìpinnu láti tọ Jesu lẹ́yìn
57 (AG)Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ọkùnrin kan wí fún un pé, “Olúwa, Èmi ń fẹ́ láti máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”
58 Jesu sì wí fún un pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́; ṣùgbọ́n ọmọ ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”
59 Ó sì wí fún ẹlòmíràn pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”
Ṣùgbọ́n èyí wí fún un pé, “Olúwa, jẹ́ kí èmi lọ sìnkú baba mi ná.”
60 Jesu sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí àwọn òkú máa sìnkú ara wọn: ṣùgbọ́n ìwọ lọ kí o sì máa wàásù ìjọba Ọlọ́run.”
61 (AH)Ẹlòmíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, èmi yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ṣùgbọ́n jẹ́ kí n kọ́kọ́ lọ dágbére fún àwọn ará ilé mi.”
62 Jesu sì wí fún un pé, “Kò sí ẹni, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun èlò ìtulẹ̀, tí ó sì wo ẹ̀yìn, tí ó yẹ fún ìjọba Ọlọ́run.”
Èsì Jobu
23 Ìgbà náà ni Jobu sì dáhùn wí pé:
2 “Àní lónìí ni ọ̀ràn mi korò;
ọwọ́ mí sì wúwo sí ìkérora mi.
3 Háà! èmi ìbá mọ ibi tí èmí ìbá wá
Ọlọ́run rí, kí èmí kí ó tọ̀ ọ́ lọ sí ibùgbé rẹ̀!
4 Èmi ìbá sì to ọ̀ràn náà níwájú rẹ̀,
ẹnu mi ìbá sì kún fún àròyé.
5 Èmi ìbá sì mọ ọ̀rọ̀ tí òun ìbá fi dá
mi lóhùn; òye ohun tí ìbáwí a sì yé mi.
6 Yóò ha fi agbára ńlá bá mi wíjọ́ bí?
Àgbẹdọ̀, kìkì pé òun yóò sì kíyèsi mi.
7 Níbẹ̀ ni olódodo le è bá a wíjọ́,
níwájú rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì bọ́ ni ọwọ́ onídàájọ́ mi láéláé.
8 “Sì wò ó, bí èmi bá lọ sí iwájú,
òun kò sí níbẹ̀, àti sí ẹ̀yìn, èmi kò sì rí òye rẹ̀:
9 Ni apá òsì bí ó bá ṣiṣẹ́ níbẹ̀, èmi kò rí i,
ó fi ara rẹ̀ pamọ́ ni apá ọ̀tún, tí èmi kò le è rí i.
10 Ṣùgbọ́n òun mọ ọ̀nà tí èmi ń tọ̀,
nígbà tí ó bá dán mí wò, èmi yóò jáde bí wúrà.
11 Ẹsẹ̀ mí ti tẹ̀lé ipasẹ̀ ìrìn rẹ̀;
ọ̀nà rẹ̀ ni mo ti kíyèsi, tí ń kò sì yà kúrò.
12 Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò padà sẹ́yìn kúrò nínú òfin ẹnu rẹ̀,
èmi sì pa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ mọ́ ju oúnjẹ òòjọ́ lọ.
13 “Ṣùgbọ́n onínú kan ni òun, ta ni yóò sì yí i padà?
Èyí tí ọkàn rẹ̀ sì ti fẹ́, èyí náà ní í ṣe.
14 Nítòótọ́ ohun tí a ti yàn fún mi ní í ṣe;
ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú ohun bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀.
15 Nítorí náà ni ara kò ṣe rọ̀ mí níwájú rẹ̀;
nígbà tí mo bá rò ó, ẹ̀rù a bà mi.
16 Nítorí pé Ọlọ́run ti pá mi ní àyà,
Olódùmarè sì ń dààmú mi.
17 Nítorí tí a kò tí ì ké mi kúrò níwájú òkùnkùn,
bẹ́ẹ̀ ni kò pa òkùnkùn biribiri mọ́ kúrò níwájú mi.
Ìkìlọ̀ láti inú ìtàn àwọn ọmọ Israẹli
10 (A)Nítorí èmi kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè si òtítọ́, ẹ̀yin arákùnrin ọ̀wọ́n, a kó gbọdọ̀ gbàgbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn wa nínú aginjù. Ọlọ́run ṣamọ̀nà wọn nípa rírán ìkùùkuu síwájú wọn, ó sì sìn wọ́n la omi Òkun pupa já. 2 (B)A lè pe eléyìí ní ìtẹ̀bọmi ti Mose nínú ìkùùkuu àti nínú omi Òkun. 3 (C)Nípa iṣẹ́ ìyanu, gbogbo wọn jẹ oúnjẹ ẹ̀mí kan náà. 4 (D)Wọ́n mu nínú omi tí Kristi fi fún wọn. Wọ́n mu omi ẹ̀mí láti inú àpáta tí ó ń tẹ̀lé wọn, àpáta náà ni Kristi. Ó wà pẹ̀lú wọn nínú aginjù náà, òun ni àpáta tí ń fi omi ẹ̀mí tu ọkàn lára. 5 (E)Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni inú Ọlọ́run kò dún sí; nítorí a pa wọ́n run nínú aginjù.
6 (F)Àwọn nǹkan wọ̀nyí sì jásí àpẹẹrẹ fún àwa, kí a má ṣe ní ìfẹ́ sí àwọn ohun búburú gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe ní ìfẹ́ si. 7 (G)Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jẹ́ abọ̀rìṣà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde dúró láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.” 8 (H)Bẹ́ẹ̀ ni kí àwa kí ó má ṣe ṣe àgbèrè gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti ṣe, tí ẹgbàá-mọ̀kànlá-lé-ẹgbẹ̀rún ènìyàn sì kú ní ọjọ́ kan. 9 (I)Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má ṣe dán Olúwa wò, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti dán an wò, tí a sì fi ejò run wọ́n. 10 (J)Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó má ṣe kùn, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọ́n ṣe kùn, tí a sì ti ọwọ́ olùparun run wọ́n.
11 Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí wọn bí àpẹẹrẹ fún wa, a sì kọ̀wé wọn fún ìkìlọ̀ fún wa, àwa ẹni tí ìgbẹ̀yìn ayé dé bá. 12 Nítorí náà, ẹni tí ó bá rò pé òun dúró, kí ó kíyèsára kí ó ma ba à ṣubú. 13 (K)Kò sí ìdánwò kan tí ó ti bá yín, bí kò ṣe irú èyí tí ó mọ níwọ̀n fún ènìyàn, ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlọ́run, ẹni ti kì yóò jẹ́ kí á dán an yín wò ju bí ẹ̀yin ti le gbà, ṣùgbọ́n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ̀yin ba à lè faradà á.
Oúnjẹ òrìṣà àti oúnjẹ alẹ́ Olúwa
14 (L)Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà. 15 Èmi ń sọ̀rọ̀ bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn, ṣe ìdájọ́ fúnrarẹ̀ ohun tí mo sọ. 16 (M)Ǹjẹ́ ago ìdúpẹ́ nípasẹ̀ èyí tí a ń dúpẹ́ fún, kì í ha ṣe jíjẹ́ alábápín ìdàpọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ Kristi bí? Àkàrà tí a bù, kì í ha ṣe jíjẹ́ alábápín nínú ara Kristi bi? 17 Nítorí àkàrà kan ni ó ń bẹ, àwa tí a pọ̀ níye, tí a sì jẹ ara kan ń pín nínú àkàrà kan ṣoṣo.
18 (N)Ẹ wo Israẹli nípa ti ara, àwọn tí ń jẹ ohun ẹbọ kò ha ṣe alábápín pẹpẹ bí? 19 Ǹjẹ́ kí ni mo ń wí? Ṣé pé ohun tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà jẹ́ nǹkan kan tàbí pé òrìṣà jẹ́ nǹkan kan? 20 (O)Rárá, ṣùgbọ́n ohun tí mo ń wí ni pé, ohun tí àwọn aláìkọlà fi ń rú ẹbọ wọn fi fun àwọn ẹ̀mí èṣù. Dájúdájú kì í ṣe ìrúbọ sí Ọlọ́run. Èmi kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ẹ̀mí èṣù. 21 (P)Ẹ̀yin kò lè mu nínú ago tí Olúwa àti ago ti èṣù lẹ́ẹ̀kan náà; ẹ̀yin kò le ṣe àjọpín ní tábìlì Olúwa, àti ni tábìlì ẹ̀mí èṣù lẹ́ẹ̀kan náà. 22 (Q)Kí ni ẹ̀ ń gbìyànjú láti ṣe? Àwa ha ń mú Olúwa jowú bí? Àwa ha ní agbára jù ú lọ bi?
Òmìnira àwọn onígbàgbọ́
23 (R)“Ohun gbogbo ni o yẹ fún mi,” ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ní èrè. “Ohun gbogbo ni ó yẹ fún mi,” ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ń gbe ni rò. 24 Má ṣe ronú nípa ara rẹ̀ nìkan; ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù máa wá rere ọmọnìkejì rẹ̀.
25 Jẹ ẹrankẹ́ran tí wọ́n bá ń tà lọ́jà. Má ṣe gbìyànjú láti wádìí lọ́wọ́ ẹni tí ń tà á nítorí ẹ̀rí ọkàn. 26 (S)Nítorí “Ayé àti gbogbo nǹkan rere tí ń bẹ nínú rẹ̀, tí Olúwa ni wọ́n jẹ́.”
27 Bí ẹnikẹ́ni tí kì í bá ṣe onígbàgbọ́ ba pè yín sí ibi àsè láti jẹun, bá a lọ. Gba ìpè rẹ̀ tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rùn. Jẹ ohunkóhun tí ó bá pèsè sílẹ̀ fún àsè náà, má ṣe béèrè ohunkóhun nípa rẹ̀ nítorí ẹ̀rí ọkàn. 28 (T)Bí ẹnikẹ́ni bá sì kìlọ̀ fún un yín pé, “A ti fi ẹran yìí rú ẹbọ,” ẹ má ṣe jẹ́ ẹ nítorí ẹni ti o sọ fun ọ àti nítorí ẹ̀rí ọkàn. 29 Èmi ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀rí ọkàn ẹni tí ó sọ fún ọ kì í ṣe tirẹ̀. Nítorí kín ni a ó fi dá mi lẹ́jọ́ nítorí ẹ̀rí ọkàn ẹlòmíràn. 30 Bí èmi ba fi ọpẹ́ jẹ ẹ́, èéṣe tí a fì ń sọ̀rọ̀ mi ní búburú nítorí ohun tí èmi dúpẹ́ fún.
31 Nítorí náà tí ẹ̀yin bá jẹ tàbí tí ẹ bá mu tàbí ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sè, e máa ṣe gbogbo rẹ̀ fún ògo Ọlọ́run. 32 (U)Nítorí náà, má ṣe jẹ́ òkúta ìkọ̀sẹ̀ tí ó lè gbé ẹlòmíràn ṣubú ìbá à ṣe Júù tàbí Giriki tàbí ìjọ Ọlọ́run. 33 (V)Bí mo ṣè n gbìyànjú láti tẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan lọ́rùn nínú gbogbo nǹkan tí mo bá ń ṣe láì wa ohun rere fún ara mi bí kò ṣe ti ènìyàn púpọ̀ kí ó lè ṣe é ṣe fún wọn láti le ní ìgbàlà.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.