Add parallel Print Page Options

Ìbéèrè nípa àwẹ̀ lọ́wọ́ Jesu

14 (A)Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu tọ̀ ọ́ wá láti béèrè wí pé, “Èéṣe tí àwa àti àwọn Farisi fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò gbààwẹ̀?”

15 Jesu sì dáhùn pé, “Àwọn ọmọ ilé ìyàwó ha le máa ṣọ̀fọ̀, nígbà tí ọkọ ìyàwó ń bẹ lọ́dọ̀ wọn? Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó lọ́wọ́ wọn; nígbà náà ni wọn yóò gbààwẹ̀.

16 “Kò sí ẹni tí ń fi ìrépé aṣọ tuntun lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù; nítorí èyí tí a fi lẹ̀ ẹ́ yóò ya ní ojú lílẹ̀, aṣọ náà yóò sì ya púpọ̀ sì i ju ti ìṣáájú lọ. 17 Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí fi ọtí tuntun sínú ògbólógbòó ìgò-awọ; bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgò-awọ yóò bẹ́, ọtí á sì tú jáde, ìgò-awọ á sì ṣègbé. Ṣùgbọ́n ọtí tuntun ni wọn í fi sínú ìgò-awọ tuntun àwọn méjèèjì a sì ṣe déédé.”

Read full chapter

Ìbéèrè nípa àwẹ̀ lọ́wọ́ Jesu

18 (A)Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu àti àwọn Farisi a máa gbààwẹ̀: Àwọn ènìyàn kan sì wá, wọ́n sì bi í pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Farisi fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò gbààwẹ̀?”

19 Jesu dáhùn wí pé, “Báwo ni àwọn àlejò ọkọ ìyàwó yóò ṣe máa gbààwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó ṣì wà lọ́dọ̀ wọn? 20 (B)Ṣùgbọ́n láìpẹ́ ọjọ́, a ó gba ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn. Nígbà náà wọn yóò gbààwẹ̀ ni ọjọ́ wọ̀nyí.”

21 “Kò sí ẹni tí ń fi ìrépé aṣọ tuntun lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù, bí ó ba ṣe bẹ́ẹ̀, èyí tuntun tí a fi lẹ̀ ẹ́ yóò fàya kúrò lára ògbólógbòó, yíya rẹ̀ yóò sí burú púpọ̀ jù. 22 Kò sì sí ẹni tí ń fi ọtí wáìnì tuntun sínú ìgò wáìnì ògbólógbòó. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọtí wáìnì náà yóò fa ìgò náà ya, ọtí wáìnì a sì dàànù, bákan náà ni ìgò náà, ṣùgbọ́n ọtí wáìnì tuntun ni a n fi sínú ìgò wáìnì tuntun.”

Read full chapter