Chronological
Àwọn ọ̀tá kò dáwọ́ àtakò dúró
6 Nígbà tí Sanballati, Tobiah Geṣemu ará Arabia àti àwọn ọ̀tá wa tókù gbọ́ pé, mo ti tún odi náà mọ, kò sì sí àlàfo kankan tí ó ṣẹ́kù nínú rẹ̀—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò ì tí ì ri àwọn ìlẹ̀kùn ibodè ní àkókò náà. 2 Sanballati àti Geṣemu rán iṣẹ́ yìí sí mi pé: “Wá jẹ́ kí a jọ pàdé pọ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn ìletò ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ono.”
Ṣùgbọ́n wọ́n ń gbèrò láti ṣe mí ní ibi; 3 Bẹ́ẹ̀ ni mo rán oníṣẹ́ padà pẹ̀lú èsì yìí pé; “Èmi ń ṣe iṣẹ́ ńlá kan, èmi kò le è sọ̀kalẹ̀ wá. Èéṣe tí iṣẹ́ náà yóò fi dúró, nígbà tí mo bá fi í sílẹ̀ tí mo sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá?” 4 Wọ́n rán iṣẹ́ náà sí mi nígbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, mo sì fún wọn ní èsì bákan náà fún ìgbà kọ̀ọ̀kan.
5 Ní ìgbà karùn-ún, Sanballati rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí mi pẹ̀lú irú iṣẹ́ kan náà, lẹ́tà kan tí a kò fi sínú àpò ìwé wà ní ọwọ́ rẹ̀ 6 tí a kọ sínú un rẹ̀ pé:
“A ròyìn rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè—Geṣemu sì sọ pé, òtítọ́ ni, pé—ìwọ àti àwọn Júù ń gbèrò láti ṣọ̀tẹ̀, nítorí náà ni ẹ ṣe ń mọ odi. Síwájú sí i, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn yìí, ìwọ sì ń gbèrò láti di ọba wọn 7 àti pé ó ti yan àwọn wòlíì kí wọn lè kéde nípa rẹ̀ ní Jerusalẹmu: ‘ọba kan wà ní Juda!’ Nísinsin yìí, ìròyìn yìí yóò padà sí ọ̀dọ̀ ọba; nítorí náà wá, jẹ́ kí a bá ara wa sọ̀rọ̀.”
8 Mo dá èsì yìí padà sí i pé: “Kò sí ohun kan nínú irú ohun tí ìwọ sọ tí ó ṣẹlẹ̀; ìwọ kàn rò wọ́n ní orí ara rẹ ni.”
9 Gbogbo wọn múra láti dẹ́rùbà wá, wọ́n ń rò ó wí pé, “Ọwọ́ wọn kò ní ran iṣẹ́ náà, àti wí pé wọn kò ní parí rẹ̀.”
Ṣùgbọ́n mo gbàdúrà pé, “Nísinsin yìí Ọlọ́run fi agbára fún ọwọ́ mi.”
10 Ní ọjọ́ kan mo lọ sí ilé Ṣemaiah ọmọ Delaiah, ọmọ Mehetabeeli, ẹni tí a há mọ́ sínú ilé rẹ̀. Ó wí pé, “Jẹ́ kí a pàdé ní ilé Ọlọ́run nínú tẹmpili, kí o sì jẹ́ kí a pa àwọn ìlẹ̀kùn tẹmpili dé, nítorí àwọn ènìyàn ń bọ̀ láti pa ọ́, ní òru ni wọn yóò wá láti pa ọ́.”
11 Ṣùgbọ́n mo wí pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí irú ènìyàn bí èmi sálọ? Tàbí kí ènìyàn bí èmi sálọ sínú tẹmpili láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là? Èmi kò ní lọ!” 12 Èmi wòye pé Ọlọ́run kò rán an, ṣùgbọ́n ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí mi nítorí Tobiah àti Sanballati ti bẹ̀ ẹ́ ní ọ̀wẹ̀. 13 Wọ́n bẹ̀ ẹ́ ní ọ̀wẹ̀ láti dẹ́rùbà mí nítorí kí èmi lè dẹ́ṣẹ̀ nípa ṣíṣe èyí, kí wọn lè bà mí lórúkọ jẹ́, kí n sì di ẹni ẹ̀gàn.
14 A! Ọlọ́run mi, rántí Tobiah àti Sanballati, nítorí ohun tí wọ́n ti ṣe; kí o sì tún rántí Noadiah wòlíì obìnrin àti àwọn wòlíì tókù tí wọ́n ń gbèrò láti dẹ́rùbà mí. 15 Bẹ́ẹ̀ ni a parí odi náà ní ọjọ́ kẹẹdọ́gbọ̀n oṣù Eluli (oṣù kẹsànán), láàrín ọjọ́ méjìléláàdọ́ta.
Píparí odi
16 Nígbà tí àwọn ọ̀tá wa gbọ́ èyí, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká bẹ̀rù jìnnìjìnnì sì mú wọn, nítorí wọ́n wòye pé iṣẹ́ yìí di ṣíṣe pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa.
17 Bákan náà, ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ọlọ́lá Juda ń kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́tà ránṣẹ́ sí Tobiah, èsì láti ọ̀dọ̀ Tobiah sì ń wá sí ọ̀dọ̀ wọn. 18 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Juda ti mulẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, nítorí tí ó jẹ́ àna Ṣekaniah ọmọ Arah (Sanballati fẹ́ ọmọ Ṣekaniah), ọmọ rẹ̀ Jehohanani sì tún fẹ́ ọmọbìnrin Meṣullamu ọmọ Berekiah 19 Síwájú sí í, wọ́n túbọ̀ ń ròyìn iṣẹ́ rere rẹ̀ fún mi, wọ́n sì ń sọ ohun tí mo sọ fún un. Tobiah sì ń kọ àwọn lẹ́tà ránṣẹ́ sí mi láti dẹ́rùbà mí.
7 Lẹ́yìn ìgbà tí a tún odi mọ tán tí mo sì ri àwọn ìlẹ̀kùn sí ààyè wọn, a sì yan àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin àti àwọn Lefi. 2 Mo fún Hanani arákùnrin mi pẹ̀lú Hananiah olórí ilé ìṣọ́ ní àṣẹ lórí Jerusalẹmu, nítorí tí ó jẹ́ ènìyàn olóòtítọ́, ó sì bẹ̀rù Ọlọ́run jù bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti ṣe lọ. 3 Mo sọ fún wọn pé, “A kò gbọdọ̀ ṣí ìlẹ̀kùn Jerusalẹmu títí oòrùn yóò fi mú. Nígbà tí àwọn aṣọ́bodè bá sì wà lẹ́nu iṣẹ́, jẹ́ kí wọn ti ìlẹ̀kùn kí wọn sì há wọn. Bákan náà, yàn nínú àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́. Àwọn mìíràn níbi tí a pín wọn sí àti àwọn mìíràn ní tòsí ilé e wọn.”
Àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ìgbèkùn tí wọ́n padà
4 Ìlú náà tóbi ó sì ní ààyè, ṣùgbọ́n ènìyàn inú rẹ̀ kéré, a kò sì tí ì tún àwọn ilé inú rẹ̀ kọ́. 5 Nígbà náà ni Ọlọ́run mi fi sí mi ní ọkàn láti kó àwọn ọlọ́lá, àwọn ìjòyè, àti àwọn ènìyàn jọ fún ìforúkọsílẹ̀ ní ìdílé ìdílé. Mo rí ìwé àkọsílẹ̀ ìtàn ìran àwọn tí ó kọ́ gòkè padà wá láti ìgbèkùn. Èyí ni ohun tí mo rí tí a kọ sínú ìwé náà:
6 (A)Èyí ni àwọn ènìyàn agbègbè náà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti ìgbèkùn, àwọn tí Nebukadnessari ọba Babeli ti kó ní ìgbèkùn (wọ́n padà sí Jerusalẹmu àti Juda, olúkúlùkù sí ìlú u rẹ̀. 7 Wọ́n jọ rìn wá pẹ̀lú u Serubbabeli, Jeṣua, Nehemiah, Asariah, Raamiah, Nahamani, Mordekai, Bilṣani, Misperi, Bigfai, Nehumu, àti Baanah):
Àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọkùnrin Israẹli:
8 Àwọn ọmọ
Paroṣi jẹ́ ẹgbàá ó-lé-méjìléláàádọ́sàn-án (2,172)
9 Ṣefatia jẹ́ òjì-dín-nírínwó ó-lé-méjìlá (372)
10 Arah jẹ́ ẹgbẹ̀tàléláàádọ́ta ó-lé-méjì (652)
11 Pahati-Moabu (láti ipasẹ̀ ọmọ Jeṣua àti Joabu) jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìnlá ó-lé-méjì-dínlógún (2,818)
12 Elamu jẹ́ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀fà ó-lé-mẹ́rin (1,254)
13 Sattu jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀rin ó-lé-márùn-ún (845)
14 Sakkai jẹ́ òjì-dínlẹ́gbẹ̀rin (760)
15 Binnui jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó-lé-mẹ́jọ (648)
16 Bebai jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó-lé-méjì-dínlọ́gbọ̀n (628)
17 Asgadi jẹ́ ẹgbẹ̀ta-ó-dín méjì-dínlọ́gọ́rin (2,322)
18 Adonikami jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó-lé-méje (667)
19 Bigfai jẹ́ ẹgbàá ó-lé-mẹ́tà-dínláàádọ́rin (2,067)
20 Adini jẹ́ àádọ́tà-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó-lé-márùn-ún (655)
21 Ateri, (láti ipasẹ̀ Hesekiah) jẹ́ méjì-dínlọ́gọ́rùn-ún (98)
22 Haṣumu jẹ́ ọ̀rìn-dínnírínwó ó-lé-mẹ́jọ (328)
23 Besai jẹ́ ọ̀rìn-dínnírínwó ó-lé-mẹ́rin (324)
24 Harifu jẹ́ méjìléláàdọ́fà (112)
25 Gibeoni jẹ́ márùn-dínlọ́gọ́rùn (95)
26 Àwọn ọmọ
Bẹtilẹhẹmu àti Netofa jẹ́ igba ó-dínméjìlélógún (188)
27 Anatoti jẹ́ méjì-dínláàdóje (128)
28 Beti-Asmafeti jẹ́ méjìlélógójì (42)
29 Kiriati-Jearimu, Kefira, àti Beeroti jẹ́ ọ̀tà-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-lé-mẹ́ta (743)
30 Rama àti Geba jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó-lé-mọ́kànlélógún (621)
31 Mikmasi jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà (122)
32 Beteli àti Ai jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà (123)
33 Nebo mìíràn jẹ́ méjìléláàdọ́ta (52)
34 Elamu mìíràn jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó-lé-mẹ́rìnléláàdọ́ta (1,254)
35 Harimu jẹ́ ọ̀rìn-dínnírínwó (320)
36 Jeriko jẹ́ ọ̀tà-dínnírínwó ó-lé-márùn-ún (345)
37 Lodi, Hadidi, àti Ono jẹ́ ọ̀rìn-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-lé-ọ̀kan (721)
38 Senaa jẹ́ ẹgbàajì ó-dínàádọ́rin (3,930)
39 Àwọn àlùfáà:
àwọn ọmọ
Jedaiah (láti ipasẹ̀ ìdílé Jeṣua) jẹ́ ogún-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-dínméje (973)
40 Immeri jẹ́ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀rún ó-lé-méjì (1,052)
41 Paṣuri jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó-lé-mẹ́tà-dínláàdọ́ta (1,247)
42 Harimu jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó-lé-mẹ́tà-dínlógún (1,017)
43 Àwọn ọmọ Lefi:
àwọn ọmọ
Jeṣua (láti ipasẹ̀ Kadmieli, láti ipasẹ̀ Hodafiah) jẹ́ mẹ́rìnléláàdọ́rin (74)
44 Àwọn akọrin:
àwọn ọmọ
Asafu jẹ́ méjì-dínláàdọ́jọ (148)
45 Àwọn aṣọ́nà:
àwọn ọmọ
Ṣallumu, Ateri, Talmoni,
Akkubu, Hatita, àti Ṣobai jẹ́ méjì-dínlógóje (138)
46 Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili:
Àwọn ọmọ
Ṣiha, Hasufa, Tabboati,
47 Kerosi, Sia, Padoni,
48 Lebana, Hagaba, Ṣalmai,
49 Hanani, Giddeli, Gahari,
50 Reaiah, Resini, Nekoda,
51 Gassamu, Ussa, Pasea,
52 Besai, Mehuni, Nefisimu,
53 Bakbu, Hakufa, Harhuri,
54 Basluti, Mehida, Harṣa,
55 Barkosi, Sisera, Tema,
56 Nesia, àti Hatifa.
57 Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni:
àwọn ọmọ
Sotai, Sofereti; Perida,
58 Jaala, Darkoni, Giddeli,
59 Ṣefatia, Hattili,
Pokereti-Haṣṣebaimu, àti Amoni.
60 Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irínwó-ó-dínmẹ́jọ (392)
61 Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Teli-Mela, Teli-Harṣa, Kerubu, Addoni àti Immeri, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Israẹli:
62 Àwọn ọmọ
Delaiah, Tobiah àti Nekoda jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó-lé-méjì (642)
63 Lára àwọn àlùfáà ni:
àwọn ọmọ
Hobaiah, Hakosi àti Barsillai (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Barsillai ará Gileadi, ẹni tí a ń fi orúkọ yìí pè).
64 Àwọn wọ̀nyí wá àkọsílẹ̀ orúkọ ìran wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí í níbẹ̀, fún ìdí èyí, a yọ wọ́n kúrò nínú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ́; 65 Baálẹ̀ sọ fún wọn nítorí náà pé wọn kò gbọdọ̀ kópa nínú jíjẹ oúnjẹ mímọ́ títí tí àlùfáà tí yóò wá tí ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Urimu àti Tumimu yóò fi dé.
66 Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélógún ó-lé-òjìdínnírínwó (42,360), 67 yàtọ̀ sí àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀tà-dínlẹ́gbaàrin-ó-dín-ẹ̀tàlélọ́gọ́ta (7,337); wọ́n sì tún ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ òjìlúgba ó-lé-márùn-ún (245). 68 Ẹṣin wọn jẹ́ ọ̀tà-dínlẹ́gbẹ̀rin ó-dínmẹ́rin (736), ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlúgba ó-dínmárùn-ún (245); 69 Ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlénírínwó ó-dínmárùn-ún (435); kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlélọ́gbọ̀n ó-dínọgọ́rin (6,720).
70 Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé náà kópa nínú ṣíṣe iṣẹ́ náà. Baálẹ̀ fún ilé ìṣúra ní ẹgbẹ̀rún dariki wúrà, àádọ́ta àwo koto àti ọ̀rìn-dínlẹ́gbẹ̀ta-lé-mẹ́wàá ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà. 71 Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé fún ilé ìṣúra ní ẹgbàáwàá (20,000) dariki wúrà àti ẹgbọ̀kànlá minas fàdákà (2,200). 72 Àròpọ̀ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn tókù fi sílẹ̀ jẹ́ ẹgbàáwàá dariki wúrà, ẹgbẹ̀rún méjì minas fàdákà àti ẹ̀tà-dínláàdọ́rin ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà.
73 Àwọn àlùfáà, àwọn Lefi, àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin, àwọn ènìyàn díẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ ilé Ọlọ́run, àti gbogbo ènìyàn Israẹli wà ní ìlú wọn.
Esra ka òfin
Nígbà tí ó di oṣù keje, tí àwọn ọmọ Israẹli sì ti wà nínú ìlú u wọn,
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.