Chronological
Àwọn yàrá fún àwọn àlùfáà
42 Lẹ́yìn náà ó mú mi lọ sí ìta gbangba ni ìhà àríwá ó sì mú mi wọ àwọn yàrá ni òdìkejì ìta gbangba ilé Ọlọ́run àti ni òdìkejì ògiri ìta ní apá ìhà àríwá. 2 Ilé tí ìlẹ̀kùn rẹ̀ kọjú sí àríwá jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ó sì jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú. 3 Méjèèjì ní ogún ìgbọ̀nwọ́ ìpín láti inú ilé ìdájọ́ àti ni ìpín tí ó dojúkọ iwájú ìta ìdájọ́, ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè kọjú sì ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè ní ìdọ́gba mẹ́ta. 4 Ní iwájú àwọn ọ̀nà, yàrá wà nínú tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní ìbú tí ó sì jẹ́ ọgọ́ọ̀rún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn. Àwọn ìlẹ̀kùn wọn wà ní apá ìhà àríwá. 5 Nísinsin yìí àwọn yàrá òkè ṣe tóóró, nítorí ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè dàbí ẹni pé ó ní ààyè láti ara wọn ju láti ara àwọn yàrá ti ó wà ní ìsàlẹ̀ tàbí àárín ilé. 6 Àwọn yàrá tí ó wà ní àgbékà kẹta kò ni àwọn òpó gẹ́gẹ́ bí ilé ìdájọ́ ṣe ní; nítorí náà wọ́n kéré ní ààyè ju àwọn tí ó wà ní ìsàlẹ̀ àti àwọn àgbékà ti àárín. 7 Ògiri kan wà ní ìta tí ó ṣe déédé pẹ̀lú àwọn yàrá àti ìta ilé ìdájọ́; a fà á gùn ní iwájú àwọn yàrá ní àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́. 8 Nígbà tí ọ̀wọ́ yàrá ní ẹ̀gbẹ́ tí ó kángun sí ìta ilé ìdájọ́ jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ọ̀wọ́ ti ó wà ní ẹ̀gbẹ́ tí ó súnmọ́ ibi mímọ́ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn. 9 Yàrá ìsàlẹ̀ ni ẹnu-ọ̀nà ní ìhà ìlà-oòrùn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ṣe wọ inú rẹ̀ láti ìta ilé ìdájọ́.
10 Ní ìhà gúúsù lọ sí ìbú ògiri ìta ilé ìdájọ́ tí o ṣe déédé pẹ̀lú àgbàlá ilé Ọlọ́run, ní òdìkejì ògiri ìta ni àwọn yàrá náà wà. 11 Àti ọ̀nà ni iwájú wọn rí gẹ́gẹ́ bí ti ìrí àwọn yàrá tí ó wà ní ọ̀nà àríwá bí wọ́n ti gùn mọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbòòrò mọ àti gbogbo ìjáde wọn sì dàbí ìṣe wọn àti bí ìlẹ̀kùn wọn 12 bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní yàrá tí òun ti ìlẹ̀kùn wọn ní ọ̀nà gúúsù, ìlẹ̀kùn kan wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ojú ọ̀nà tí ó ṣe déédé pẹ̀lú ògiri tí ó gùn dé ìhà ìlà-oòrùn tí ènìyàn ń gba wọ inú àwọn yàrá.
13 Ó sì wí fún mi pé, “Àwọn yàrá àríwá àti àwọn yàrá gúúsù, tí ó wà níwájú ibi tí a yà sọ́tọ̀ àwọn ni yàrá mímọ́, níbi tí àwọn àlùfáà ti ń súnmọ́ Olúwa yó máa jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ; níbẹ̀ ní wọn o máa gbé ohun mímọ́ jùlọ kà, àti ọrẹ ẹbọ jíjẹ, àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ọrẹ ẹbọ ìrékọjá; nítorí ibẹ̀ jẹ́ mímọ́ 14 Níwọ̀n ìgbà tí àwọn àlùfáà bá ti wọ aṣọ funfun ibi mímọ́, wọn kò gbọdọ̀ lọ sí ìta ilé ìdájọ́ àfi tí wọ́n bá bọ àwọn aṣọ tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ ìsin sílẹ̀ ní ibi tí wọn tí lò ó, nítorí wọ́n jẹ́ mímọ́. Wọn gbọdọ̀ wọ aṣọ mìíràn kí wọn tó súnmọ́ ibi tí àwọn ènìyàn yòókù máa ń wà.”
15 Nígbà tí o parí nǹkan tí ó wà nínú ilé Ọlọ́run tán, o mú mi jáde lọ sí ọ̀nà tí ó wà ní ìhà ìlà-oòrùn, ó sì wọn agbègbè náà yípo: 16 Ó wọn ìhà ìlà-oòrùn pẹ̀lú ọ̀pá-ìwọ̀n nǹkan; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́. 17 Ó wọn ìhà àríwá; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pá-ìwọ̀n nǹkan. 18 O wọn ìhà gúúsù; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pá wíwọ̀n nǹkan. 19 Lẹ́yìn èyí ni ó wà yí padà sí ìhà ìwọ̀-oòrùn o sì wọ̀n-ọ́n: ó sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pá wíwọ̀n. 20 Báyìí ní ó wọ̀n-ọ́n ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Ó ní ògiri kan yípo rẹ̀, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú, àti ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, láti ya ibi mímọ́ sọ́tọ̀ kúrò ní ibi àìmọ́.
Ògo padà sí inú ilé Ọlọ́run
43 Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi gba ti ẹnu-ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn, 2 (A)mo sì ri ògo Ọlọ́run Israẹli ń bọ láti ìhà ìlà-oòrùn. Ohùn rẹ̀ dàbí híhó omi, ìtànṣán ògo rẹ̀ sì bo ilẹ̀. 3 Ó sì dàbí ìran tí mo rí, gẹ́gẹ́ bí ìran tí mo rí nígbà tí mo wá láti pa ìlú náà run; ìran náà sì dà bí ìran tí mo rí lẹ́bàá odò Kebari, mo sì dojú mi bolẹ̀. 4 Ògo Olúwa gba ọ̀nà tí o dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn wọ inú ilé Ọlọ́run wá. 5 Mo ni ìrusókè ẹ̀mí, ó sì mú mi lọ inú ilé ìdájọ́, sì kíyèsi ògo Olúwa kún inú ilé Ọlọ́run.
6 Nígbà tí ọkùnrin náà dúró ní ẹ̀gbẹ́ mi, mo gbọ́ ẹnìkan tí ó bá mi sọ̀rọ̀ láti inú ilé Ọlọ́run. 7 Ó sì wí pé: “Ọmọ ènìyàn, èyí yìí ni ibi ìgúnwà mi àti ibi tí ó wà fún àtẹ́lẹsẹ̀ mi, Ibi yìí ni èmi yóò máa gbé ní àárín àwọn ọmọ Israẹli títí láéláé. Ilé Israẹli kò ní ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́ láéláé àwọn tàbí àwọn ọba wọn nípa àgbèrè àti àwọn ère aláìlẹ́mìí àwọn ọba wọn ní ibi gíga. 8 Nígbà tí wọ́n ba gbé ìloro ilé wọn kángun sí ìloro ilé mi àti ìlẹ̀kùn wọn sì ẹ̀gbẹ́ ìlẹ̀kùn mi, pẹ̀lú ògiri nìkan ní àárín èmi pẹ̀lú wọn, wọ́n ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú ìwà ìríra wọn. Nígbà náà ni mo pa wọ́n run ní ìbínú mi. 9 Nísinsin yìí jẹ́ kí wọn mú ìwà àgbèrè wọn àti àwọn ère aláìlẹ́mìí àwọn ọba wọn kúrò ni iwájú mi, èmi yóò sì gbé àárín wọn láéláé.
10 “Ọmọ ènìyàn, ṣàpèjúwe ilé Ọlọ́run náà fún àwọn ènìyàn Israẹli kí ojú ẹ̀ṣẹ̀ wọn, lè tì wọ́n sì jẹ́ kí wọn wo àwòrán ilé náà, 11 tí ojú gbogbo ohun tí wọn ti ṣe bá tì wọ́n, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ àwòrán ilé Ọlọ́run náà bí wọ́n ṣe tò ó lẹ́sẹẹsẹ, àbájáde àti àbáwọlé rẹ̀ gbogbo àwòrán àti gbogbo òfin àti ìlànà rẹ̀. Kọ ìwọ̀nyí sílẹ̀ ní iwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ́ olóòtítọ́ si àwòrán rẹ̀, kí wọ́n sì tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀.
12 “Èyí yìí ní òfin ilé Ọlọ́run náà: Gbogbo àyíká lórí òkè gíga ní yóò jẹ́ ibi mímọ́ jùlọ. Bí èyí ni òfin tẹmpili náà.
Pẹpẹ ìrúbọ náà
13 “Ìwọ̀nyí ni wíwọ̀n pẹpẹ ìrúbọ ní gígùn ìgbọ̀nwọ́, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni jíjìn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni ìbú, igun rẹ̀ yípo àti etí rẹ̀ jẹ́ ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan: Èyí yìí sì ni gíga pẹpẹ ìrúbọ náà: 14 Láti ìsàlẹ̀ rẹ̀ ni ilẹ̀ títí dé ìsàlẹ̀ igun rẹ̀, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì ni gíga o sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ní ìbú: 15 Ibi ìdáná pẹpẹ ìrúbọ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gíga, ìwo mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì yọrí jáde sókè láti ibi ìdáná. 16 Ibi ìdáná pẹpẹ náà jẹ́ igun mẹ́rin mẹ́rin lọ́gbọọgba, ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ní gígùn, o sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ní ìbú. 17 Igun ni apá òkè náà jẹ́ igun mẹ́rin lọ́gbọọgba, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá ní gígùn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá ní ìbú, pẹ̀lú etí tí ó jẹ́ ìdajì ìgbọ̀nwọ́, ìsàlẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan yípo. Àtẹ̀gùn pẹpẹ ìrúbọ náà dojúkọ ìlà-oòrùn.”
18 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ìwọ̀nyí yóò jẹ́ òfin fún ìrúbọ ẹbọ sísun àti wíwọ̀n ẹ̀jẹ̀ sórí pẹpẹ nígbà tí a bá mọ pẹpẹ tán: 19 Ẹ̀yin ní láti mú ọ̀dọ́ akọ màlúù gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrékọjá fún àwọn àlùfáà, tí ó jẹ́ Lefi, tí ìdílé Sadoku tí ó wá sí agbègbè láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún mi ní Olúwa Olódùmarè wí. 20 Ẹ ni láti mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí ẹ sì fi sórí ìwo mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà lórí pẹpẹ, àti lórí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ìjókòó náà àti sí gbogbo etí rẹ̀ yípo, ìwọ yóò sì sọ pẹpẹ di mímọ́, ìwọ yóò sì ṣe ètùtù rẹ̀. 21 Ìwọ gbọdọ̀ mú akọ màlúù fún ìrékọjá, ìwọ yóò sì sun ún ní apá ibi tí a sàmì sí ní agbègbè ilé Ọlọ́run ní ìta ibi mímọ́.
22 “Ní ọjọ́ kejì ìwọ yóò fi ewúrẹ́, òbúkọ aláìlábàwọ́n fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, a sì gbọdọ̀ sọ pẹpẹ di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí a ti ṣọ́ di mímọ́ pẹ̀lú akọ màlúù. 23 Nígbà tí ìwọ bá parí ìsọdimímọ́, ìwọ yóò fi ọ̀dọ́ akọ màlúù àti ọ̀dọ́ àgbò aláìlábàwọ́n láti inú agbo fún ìrúbọ. 24 Ìwọ yóò mú wọn lọ sí iwájú Olúwa, àwọn àlùfáà ni yóò fi iyọ̀ wọ́n wọn, wọn yóò sì fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí Olúwa.
25 “Fún ọjọ́ méje, ìwọ ní láti pèsè akọ ewúrẹ́ kan lójoojúmọ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; ìwọ yóò sì pèsè ọ̀dọ́ akọ màlúù àti àgbò láti inú agbo, méjèèjì yóò sì jẹ́ aláìlábàwọ́n. 26 Fún ọjọ́ méje wọn yóò jẹ́ ètùtù fún pẹpẹ, wọn yóò sì sọ ọ́ di mímọ́; nípa bẹ́ẹ̀ wọn yóò yà á sọ́tọ̀. 27 Ní ìparí ọjọ́ wọ̀nyí, láti ọjọ́ mẹ́jọ síwájú, àwọn àlùfáà ni yóò gbé àwọn ẹbọ sísun rẹ àti ẹbọ ìdàpọ̀ rẹ̀ kalẹ̀ lórí pẹpẹ. Lẹ́yìn náà, èmi yóò tẹ́wọ́gbà yín ní Olúwa Olódùmarè wí.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.