Chronological
Ìpè láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run
1 Ní oṣù kẹjọ ọdún kejì ọba Dariusi, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Sekariah ọmọ Berekiah, ọmọ Iddo pé:
2 “Olúwa ti bínú sí àwọn baba ńlá yín. 3 Nítorí náà sọ fún àwọn ènìyàn: Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Ẹ padà sí Ọ̀dọ̀ mi,’ Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘èmi náà yóò sì padà sí ọ̀dọ̀ yín,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 4 Ẹ má dàbí àwọn baba yín, àwọn tí àwọn wòlíì ìṣáájú ti ké sí wí pé: Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Ẹ yípadà nísinsin yìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín,’ àti kúrò nínú ìwà búburú yín; ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sí ti èmi, ni Olúwa wí. 5 Àwọn baba yín, níbo ni wọ́n wà? Àti àwọn wòlíì, wọ́n ha wà títí ayé? 6 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi àti ìlànà mi, ti mo pa ní àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì, kò ha tún bá àwọn baba yín?
“Wọ́n sì padà wọ́n wí pé, ‘Gẹ́gẹ́ bí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti rò láti ṣe sí wa, gẹ́gẹ́ bi ọ̀nà wa, àti gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa, bẹ́ẹ̀ ní o ti ṣe sí wa.’ ”
Ènìyàn láàrín àwọn igi miritili
7 Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kọkànlá, tí ó jẹ́, oṣù Sebati, ní ọdún kejì Dariusi, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Sekariah, ọmọ Bẹrẹkiah ọmọ Iddo wá, pé.
8 Mo rí ìran kan ni òru, si wò ó, ọkùnrin kan ń gun ẹṣin pupa kan, òun sì dúró láàrín àwọn igi maritili tí ó wà ní ibi òòji; lẹ́yìn rẹ̀ sì ni ẹṣin pupa, adíkálà, àti funfun gbé wà.
9 Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni wọ̀nyí olúwa mi?”
Angẹli tí ń ba mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Èmi ó fi ohun tí àwọn wọ̀nyí jẹ́ hàn ọ́.”
10 Ọkùnrin tí ó dúró láàrín àwọn igi maritili sì dáhùn ó sì wí pé, “Wọ̀nyí ní àwọn tí Olúwa ti rán láti máa rìn sókè sódò ni ayé.”
11 Wọ́n si dá angẹli Olúwa tí ó dúró láàrín àwọn igi maritili náà lóhùn pé, “Àwa ti rìn sókè sódò já ayé, àwa sí ti rí i pé gbogbo ayé wà ní ìsinmi àti àlàáfíà.”
12 Nígbà náà ni angẹli Olúwa náà dáhùn ó sì wí pé, “Olúwa àwọn ọmọ-ogun, yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ kì yóò fi ṣàánú fún Jerusalẹmu, àti fún àwọn ìlú ńlá Juda, ti ìwọ ti bínú sí ni àádọ́rin ọdún wọ̀nyí?” 13 Olúwa sì fi ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ ìtùnú dá angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn.
14 Angẹli ti ń bá mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Ìwọ kígbe wí pé: Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Èmi ń fi ìjowú ńlá jowú fún Jerusalẹmu àti fún Sioni. 15 Èmi sì bínú púpọ̀púpọ̀ si àwọn orílẹ̀-èdè tí ó rò wí pé òun ní ààbò. Nítorí nígbà tí mo bínú díẹ̀, wọ́n ran ìparun lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájú.’
16 “Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí: ‘Mo padà tọ Jerusalẹmu wá pẹ̀lú àánú; ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, a ó kọ́ ilé mi sínú rẹ̀, a o sí ta okùn ìwọ̀n kan jáde sórí Jerusalẹmu.’
17 “Máa ké síbẹ̀ pé: Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘A o máa fi ìre kún ìlú ńlá mi síbẹ̀; Olúwa yóò sì máa tu Sioni nínú síbẹ̀, yóò sì yan Jerusalẹmu síbẹ̀.’ ”
Ìwo mẹ́rin àti alágbẹ̀dẹ mẹ́rin
18 Mo si gbé ojú sókè, mo sì rí, sì kíyèsi i, ìwo mẹ́rin. 19 Mo sì sọ fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kí ni nǹkan wọ̀nyí?”
Ó si dà mí lóhùn pé, “Àwọn ìwo wọ̀nyí ni ó tí tú Juda, Israẹli, àti Jerusalẹmu ká.”
20 Olúwa sì fi alágbẹ̀dẹ mẹ́rin kan hàn mí. 21 Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni àwọn wọ̀nyí wá ṣe?”
O sì sọ wí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni ìwo tí ó ti tú Juda ká, tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò fi gbé orí rẹ̀ sókè? Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí wá láti dẹ́rùbà wọ́n, láti lé ìwo àwọn orílẹ̀-èdè jáde, ti wọ́n gbé ìwo wọn sórí ilẹ̀ Juda láti tú ènìyàn rẹ̀ ká.”
Okùn ìwọ̀n ti Jerusalẹmu
2 Mó si tún gbé ojú mi, sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, ọkùnrin kan ti o mú okùn ìwọ̀n lọ́wọ́ rẹ̀. 2 Mo sí wí pé, “Níbo ni ìwọ ń lọ?”
O sí wí fún mí pé, “Láti wọn Jerusalẹmu, láti rí iye ìbú rẹ̀, àti iye gígùn rẹ̀.”
3 Sì kíyèsi i, angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ jáde lọ, angẹli mìíràn si jáde lọ pàdé rẹ̀. 4 Ó si wí fún un pé, “Sáré, sọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin yìí wí pé, ‘A ó gbé inú Jerusalẹmu bi ìlú ti kò ní odi, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn àti ohun ọ̀sìn inú rẹ̀. 5 Olúwa wí pé, Èmí ó sì jẹ́ odi iná fún un yíká, èmi ó sì jẹ́ ògo láàrín rẹ̀.’
6 “Wá! Wá! Sá kúrò ni ilẹ̀ àríwá, ni Olúwa wí; nítorí pé bí afẹ́fẹ́ mẹ́rin ọ̀run ni mo tú yín káàkiri,” ni Olúwa wí.
7 “Gbà ara rẹ̀ sílẹ̀, ìwọ Sioni, ìwọ tí ó ń bà ọmọbìnrin Babeli gbé.” 8 Nítorí báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Lẹ́yìn ògo rẹ̀ ni a ti rán mi sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ń kó yin: nítorí ẹni tí ó tọ́ yin, ó tọ́ ọmọ ojú rẹ̀. 9 Nítorí kíyèsi i, èmi ó gbọn ọwọ́ mi sí orí wọn, wọn yóò sì jẹ́ ìkógun fún ìránṣẹ́ wọn: ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi.
10 “Kọrin kí o sì yọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Sioni: Nítorí èmi ń bọ̀ àti pé èmi yóò sì gbé àárín rẹ,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 11 “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò dàpọ̀ mọ́ Olúwa ní ọjọ́ náà, wọn yóò sì di ènìyàn mi: èmi yóò sì gbé àárín rẹ, ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí ọ. 12 Olúwa yóò sì jogún Juda ìní rẹ̀, ni ilẹ̀ mímọ́, yóò sì tún yan Jerusalẹmu. 13 (A)Ẹ̀ dákẹ́, gbogbo ẹran-ara níwájú Olúwa: nítorí a jí i láti ibùgbé mímọ́ rẹ̀ wá.”
Aṣọ mímọ́ fún olórí àlùfáà
3 Ó sì fi Joṣua olórí àlùfáà hàn mí, ó dúró níwájú angẹli Olúwa, Satani sí dúró lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ láti kọjú ìjà sí i. 2 (B)Olúwa si wí fún Satani pé, “Olúwa bá ọ wí ìwọ Satani; àní Olúwa tí ó ti yan Jerusalẹmu, bá ọ wí, igi iná kọ́ ni èyí tí a mú kúrò nínú iná?”
3 A sì wọ Joṣua ni aṣọ èérí, ó sì dúró níwájú angẹli náà. 4 Ó sì dáhùn ó wí fún àwọn tí ó dúró níwájú rẹ̀ pé, “Bọ́ aṣọ èérí nì kúrò ní ara rẹ̀.”
Ó sì wí fún Joṣua pé, “Wò ó, mo mú kí àìṣedéédéé rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, èmi yóò sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ ẹ̀yẹ.”
5 Mó sì wí pé, “Jẹ kí wọn fi gèlè mímọ́ wé e lórí.” Wọn sì fi gèlè mímọ́ wé e lórí, wọn sì fi aṣọ wọ̀ ọ́. Angẹli Olúwa sì dúró tì í.
6 Angẹli Olúwa sì tẹnumọ́ ọn fún Joṣua pé: 7 “Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Bí ìwọ ọ́ bá rìn ní ọ̀nà mi, bí ìwọ yóò bá sì pa àṣẹ mi mọ́, ìwọ yóò sì ṣe ìdájọ́ ilé mi pẹ̀lú, ìwọ yóò sì ṣe àkóso ààfin mi, èmi yóò fún ọ ní ààyè láti rìn láàrín àwọn tí ó dúró yìí.
8 “ (C)‘Gbọ́, ìwọ Joṣua olórí àlùfáà, ìwọ, àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ tí ó jókòó níwájú rẹ: nítorí ẹni ìyanu ni wọ́n: nítorí kíyèsi i, èmi yóò mú ìránṣẹ́ mi, Ẹ̀ka náà wá. 9 Nítorí kíyèsi i, òkúta tí mo tí gbé kalẹ̀ níwájú Joṣua; lórí òkúta kan ni ojú méje wà: kíyèsi i, èmi yóò fín àkọlé rẹ̀,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Èmi yóò sì mú ẹ̀bi ilẹ̀ náà kúrò ní ọjọ́ kan.
10 (D)“ ‘Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ní ọjọ́ náà ni olúkúlùkù yóò pe ẹnìkejì láti jókòó rẹ̀ sábẹ́ igi àjàrà àti sábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́.’ ”
Ọ̀pá fìtílà wúrà àti àwọn igi olifi méjì
4 Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ sì tún dé, ó sì jí mi, bí ọkùnrin tí a jí lójú oorun rẹ̀, 2 Ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?”
Mo sì wí pé, “Mo wò, sì kíyèsi i, ọ̀pá fìtílà tí gbogbo rẹ̀ jẹ́ wúrà, pẹ̀lú àwokòtò rẹ̀ lórí rẹ̀ pẹ̀lú fìtílà méje rẹ̀ lórí rẹ̀, àti ẹnu méje fún fìtílà méjèèje, tí ó wà lórí rẹ̀: 3 (E)Igi olifi méjì sì wà létí rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àwokòtò náà, àti èkejì ní apá òsì rẹ̀.”
4 Mo sì dáhùn mo sì wí fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀, pé, “Kín ni wọ̀nyí, olúwa mi?”
5 Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?”
Mo sì wí pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n, olúwa mi.”
6 Ó sì dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Serubbabeli tó wí pé: ‘Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bí kò ṣe nípa Ẹ̀mí mi,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
7 “Ta ni ìwọ, ìwọ òkè ńlá? Ìwọ yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀ níwájú Serubbabeli: òun yóò sì fi ariwo mú òkúta téńté orí rẹ̀ wá, yóò máa kígbe wí pé, ‘Ọlọ́run bùkún fun! Ọlọ́run bùkún fun!’ ”
8 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé: 9 “Ọwọ́ Serubbabeli ni a ti ṣe ìpìlẹ̀ ilé yìí, ọwọ́ rẹ̀ ni yóò sì parí rẹ̀; ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí i yín.
10 (F)“Ṣùgbọ́n ta ni ha kẹ́gàn ọjọ́ ohun kékeré? Nítorí wọn ó yọ̀ nígbà ti wọ́n bá rí okùn ìwọ̀n nì lọ́wọ́ Serubbabeli.
“(Àwọn méje wọ̀nyí ni àwọn ojú Olúwa, tí ó ń sáré síhìn-ín sọ́hùn-ún ní gbogbo ayé.)”
11 Mo sì béèrè, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn igi olifi méjì wọ̀nyí jásí, tí ó wà ní apá ọ̀tún fìtílà àti ní apá òsì rẹ̀?”
12 Mo sì tún dáhùn, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn ẹ̀ka méjì igi olifi wọ̀nyí jásí, tí ń tú òróró wúrà jáde nínú ara wọn láti ẹnu ọ̀pá oníhò wúrà méjì.”
13 Ó sì dáhùn, ó wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?”
Mo sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, olúwa à mi.”
14 Ó sì wí pé, “Àwọn méjì wọ̀nyí ni àwọn tí a fi òróró yàn, tí ó dúró ti Olúwa gbogbo ayé.”
Ìwé kíkà ti n fò
5 Nígbà náà ni mo yípadà, mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, ìwé kíká ti ń fò.
2 Ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?”
Èmi sì dáhùn pé, “Mo rí ìwé kíká tí ń fò; gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá.”
3 Ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ègún tí ó jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé: nítorí gbogbo àwọn tí ó bá jalè ni a ó ké kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀; gbogbo àwọn tí ó bá sì búra èké ni a ó ké kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀. 4 ‘Èmi yóò mú un jáde,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘yóò si wọ inú ilé olè lọ, àti inú ilé ẹni ti o bá fi orúkọ mi búra èké: yóò si wà ni àárín ilé rẹ̀, yóò si rún pẹ̀lú igi àti òkúta inú rẹ̀.’ ”
Obìnrin nínú agbọ̀n
5 Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ sì jáde lọ, ó sì wí fún mi pé, “Gbé ojú rẹ sókè nísinsin yìí, kí o sì wo nǹkan tí yóò jáde lọ.”
6 Mo sì wí pé, “Kí ni nǹkan náà?”
Ó sì wí pé, “Èyí ni òṣùwọ̀n tí ó jáde lọ.” Ó sì wí pé, “Èyí ni àwòrán ní gbogbo ilẹ̀ ayé.”
7 Sì kíyèsi i, a gbé tálẹ́ǹtì òjé sókè: obìnrin kan sì nìyìí tí ó jókòó sí àárín àpẹẹrẹ òṣùwọ̀n. 8 Ó sì wí pé, “Èyí ni ìwà búburú.” Ó sì ti sí àárín òṣùwọ̀n: ó sì ju ìdérí òjé sí ẹnu rẹ̀.
9 Mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, obìnrin méjì jáde wá, ẹ̀fúùfù sì wá nínú ìyẹ́ wọn; nítorí wọ́n ní ìyẹ́ bí ìyẹ́ àkọ̀: Wọ́n sì gbé àpẹẹrẹ òṣùwọ̀n náà dé àárín méjì ayé àti ọ̀run.
10 Mo sì sọ fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Níbo ni àwọn wọ̀nyí ń gbé òṣùwọ̀n náà lọ.”
11 Ó si wí fún mi pé, “Sí orílẹ̀-èdè Babeli láti kọ ilé fún un. Tí ó bá ṣetán, a ó sì fi ìdí rẹ̀ mulẹ̀, a o sì fi ka orí ìpìlẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀.”
Kẹ̀kẹ́ ogun mẹ́rin tí ìdájọ́ Ọlọ́run
6 (G)Mo sì yípadà, mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, kẹ̀kẹ́ mẹ́rin jáde wá láti àárín òkè ńlá méjì, àwọn òkè-ńlá náà sì jẹ́ òkè-ńlá idẹ. 2 Àwọn ẹṣin pupa wà ní kẹ̀kẹ́ èkínní; àti àwọn ẹṣin dúdú ní kẹ̀kẹ́ èkejì. 3 Àti àwọn ẹṣin funfun ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹta; àti àwọn adíkálà àti alágbára ẹṣin ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹrin. 4 Mo sì dáhùn, mo sì béèrè lọ́wọ́ angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kí ni ìwọ̀nyí, olúwa mi.”
5 (H)Angẹli náà si dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀mí mẹ́rin ti ọ̀run, tí wọn ń lọ kúrò lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ara wọn hàn níwájú Olúwa gbogbo ayé. 6 Àwọn ẹṣin dúdú tí ó wà nínú rẹ̀ jáde lọ sí ilẹ̀ àríwá; àwọn funfun sì jáde lọ si ìwọ̀-oòrùn; àwọn adíkálà sì jáde lọ sí ìhà ilẹ̀ gúúsù.”
7 Àwọn alágbára ẹṣin sì jáde lọ, wọ́n sì ń wá ọ̀nà àti lọ kí wọn bá a lè rìn síhìn-ín sọ́hùn-ún ni ayé; ó sì wí pé, “Ẹ lọ, ẹ lọ rìn síhìn-ín sọ́hùn-ún ní ayé!” Wọ́n sì rín síhìn-ín sọ́hùn-ún ní ayé.
8 Nígbà náà ni ohùn kan sì ké sí mi, ó sì bá mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wò ó, àwọn wọ̀nyí tí ó lọ síhà ilẹ̀ àríwá ti mú ẹ̀mí mi parọ́rọ́ ni ilẹ̀ àríwá.”
Adé fún Joṣua
9 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé: 10 “Mú nínú ìgbèkùn, nínú àwọn Heldai, tí Tobiah, àti ti Jedaiah, tí ó ti Babeli dé, kí ìwọ sì wá ní ọjọ́ kan náà, kí o sì wọ ilé Josiah ọmọ Sefaniah lọ. 11 Kí o sì mú fàdákà àti wúrà, kí o sì fi ṣe adé púpọ̀, sì gbé wọn ka orí Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà. 12 (I)Sì sọ fún un pé: ‘Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ wí pé, wo ọkùnrin náà ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ̀ka; yóò sì yọ ẹ̀ka láti abẹ́ rẹ̀ wá, yóò si kọ́ tẹmpili Olúwa wa. 13 Òun ni yóò sì kọ́ tẹmpili Olúwa òun ni yóò sì wọ̀ ní ògo, yóò sì jókòó, yóò sì jẹ ọba lórí ìtẹ́ rẹ̀; òun ó sì jẹ́ àlùfáà lórí ìtẹ́ rẹ̀; ìmọ̀ àlàáfíà yóò sì wá láàrín àwọn méjèèjì.’ 14 Adé wọ̀nyí yóò sì wà fún Helemu àti fún Tobiah, àti fún Jedaiah, àti fún Heni ọmọ Sefaniah fún ìrántí ni tẹmpili Olúwa. 15 Àwọn tí ó jìnnà réré yóò wá láti kọ́ tẹmpili Olúwa, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti rán mi sí yín. Yóò sì rí bẹ́ẹ̀ bí ẹ̀yin yóò bá gbà ohùn Olúwa, Ọlọ́run yín gbọ́ nítòótọ́.”
Òdodo àti àánú, kì í ṣe àwẹ̀
7 Ó sì ṣe ní ọdún kẹrin Dariusi ọba, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ́ Sekariah wá ni ọjọ́ kẹrin oṣù Kisleu tí ń ṣe oṣù kẹsànán. 2 Nígbà tí wọ́n ènìyàn Beteli rán Ṣareseri àti Regemmeleki, àti àwọn ènìyàn wọn sí ilé Ọlọ́run láti wá ojúrere Olúwa. 3 Àti láti bá àwọn àlùfáà tí ó wà ní ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti àwọn wòlíì sọ̀rọ̀ wí pé, “Ṣé kí èmi ó sọkún ní oṣù karùn-ún kí èmi ya ara mi sọ́tọ̀, bí mo ti ń ṣe láti ọdún mélòó wọ̀nyí wá bí?”
4 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tọ̀ mí wá pé, 5 “Sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti fún àwọn àlùfáà pé, ‘Nígbà tí ẹ̀yin gbààwẹ̀, tí ẹ sì ṣọ̀fọ̀ ní oṣù karùn-ún àti keje, àní fun àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, ǹjẹ́ èmi ni ẹ̀yin ha ń gbààwẹ̀ yín fún? 6 Nígbà tí ẹ sì jẹ, àti nígbà tí ẹ mu, fún ara yín kọ́ ni ẹ̀yin jẹ, àti fún ara yín kọ́ ni ẹ̀yin mú bí? 7 Wọ̀nyí kọ́ ni ọ̀rọ̀ ti Olúwa ti kígbe láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì ìṣáájú wá, nígbà tí a ń gbé Jerusalẹmu, tí ó sì wà ní àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀ tí ó yí i káàkiri, nígbà tí a ń gbé gúúsù àti pẹ̀tẹ́lẹ̀.’ ”
8 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Sekariah wá, wí pé: 9 “Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: ‘Ṣe ìdájọ́ òtítọ́, kí ẹ sì ṣe àánú àti ìyọ́nú olúkúlùkù sí arákùnrin rẹ̀. 10 Má sì ṣe ni opó lára tàbí aláìní baba, àlejò, tàbí tálákà; kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe gbèrò ibi ní ọkàn sí arákùnrin rẹ̀.’
11 “Ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti gbọ́, wọ́n sì gún èjìká, wọ́n sì pa ẹ̀yìn dà, wọ́n di etí wọn, kí wọn má ba à gbọ́. 12 Wọ́n sé ọkàn wọn bí òkúta líle, kí wọn má ba à gbọ́ òfin, àti ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rán nípa ọwọ́ àwọn wòlíì ìṣáájú wá. Ìbínú ńlá sì dé láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
13 “ ‘Ó sì ṣe, gẹ́gẹ́ bí ó ti kígbe, tí wọn kò sì fẹ́ gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kígbe, tí èmi kò sì fẹ́ gbọ́,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 14 ‘Mo sì fi ìjì tú wọn ká sí gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọn kò mọ̀. Ilẹ̀ náà sì dahoro lẹ́yìn wọn, tí ẹnikẹ́ni kò là á kọjá tàbí kí ó padà bọ̀: wọ́n sì sọ ilẹ̀ ààyò náà dahoro.’ ”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.