Chronological
Ìkòkò ìdáná náà
24 Ní ọdún kẹsànán, oṣù kẹwàá, ọjọ́ kẹwàá, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 2 “Ọmọ ènìyàn, kọ ọjọ́ náà sílẹ̀, ọjọ́ náà gan an, nítorí ọba Babeli náà ti da ojú ti Jerusalẹmu ní ọjọ́ yìí gan an. 3 Sì pa òwe yìí fún ilé ọlọ́tẹ̀ náà, sọ fún wọn pé: ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Gbé ìkòkò ìdáná náà ka iná:
Gbé e ka iná kí o sì da omi sí i nínú.
4 Kó àwọn ègé ẹran tí a gé náà sínú rẹ̀,
gbogbo àwọn ègé ẹran tí ó tóbi, itan àti apá.
Kó àwọn egungun tí ó dára jù sínú rẹ̀
5 Mú àwọn tí ó jọjú nínú agbo ẹran.
Kó àwọn egungun sí abẹ́ ẹ rẹ̀;
sì jẹ́ kí ó hó dáradára
sì jẹ́ kí àwọn egungun náà bọ̀ nínú rẹ̀.
6 “ ‘Nítorí báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà,
fún ìkòkò náà tí èérí rẹ̀ wà nínú rẹ̀,
tí èérí kò dà kúrò lójú rẹ̀!
Mú ẹran náà jáde ní ekìrí ekìrí
má ṣe ṣà wọ́n mú.
7 “ ‘Nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ wà ní àárín rẹ̀;
à á sí orí àpáta kan lásán
kò dà á sí orí ilẹ̀,
níbi ti erùpẹ̀ yóò ti bò ó
8 Láti bá à le jẹ́ kí ìbínú kí ó dé láti gbẹ̀san
mo da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí orí àpáta kan lásán,
kí o ma bà á wà ni bíbò.
9 “ ‘Nítorí náà báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà!
Èmi pàápàá yóò jẹ́ kí òkìtì iná náà tóbi.
10 Nítorí náà kó igi náà jọ sí i,
kí o sì fi iná sí i.
Ṣe ẹran náà dáradára,
fi tùràrí dùn ún;
kí o sì jẹ́ kí egungun náà jóná.
11 Lẹ́yìn náà gbé òfìfo ìkòkò náà lórí ẹyin iná
kí idẹ rẹ̀ lè gbóná, kí ó lè pọ́n
àti ki ìfófó rẹ̀ le di yíyọ́ nínú rẹ̀
kí èérí rẹ̀ le jó dànù.
12 Ó ti ba gbogbo akitiyan jẹ:
èérí rẹ̀ kò sì jáde kúrò lára rẹ̀,
èérí náà gan an yóò wà nínú iná.
13 “ ‘Nísinsin yìí èérí rẹ̀ ni ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wà. Nítorí mo gbìyànjú láti wẹ̀ ọ́ mọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò sì mọ́ kúrò nínú ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, a kì yóò sì tún wẹ̀ ọ mọ́ kúrò nínú èérí rẹ, títí èmi yóò fi jẹ́ kí ìbínú mi balẹ̀ sórí rẹ̀.
14 “ ‘Èmi Olúwa ni ó sọ ọ́, yóò sì ṣe, èmi yóò sì ṣe é. Èmi kì yóò padà sẹ́yìn; bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá sí i, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọkàn mi padà; gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ, ni wọn yóò dá ọ lẹ́jọ́, ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ”
Ìyàwó Esekiẹli kú
15 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá pé: 16 “Ọmọ ènìyàn, kíyèsi i, mo mú ìfẹ́ ojú rẹ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, nípa lílù kan. Ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ gbààwẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sọkún, bẹ́ẹ̀ ni omijé ojú rẹ kò gbọdọ̀ kán sílẹ̀. 17 Má ṣe sọkún, má ṣe gbààwẹ̀ fún òkú. Wé ọ̀já sí orí rẹ, sì bọ bàtà sí ẹsẹ̀ rẹ: má ṣe bo ètè ìsàlẹ̀ rẹ, ma ṣe jẹ oúnjẹ tí àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ń jẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà.”
18 Báyìí ni mo sọ̀rọ̀ fún àwọn ènìyàn ní òwúrọ̀, ní àṣálẹ́ ìyàwó mi sì kú. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, mo ṣe bí a ti pàṣẹ fún mi.
19 Lẹ́yìn náà àwọn ènìyàn bi mí léèrè pé, “Ṣe o kò ni sọ fún wa ohun ti nǹkan wọ̀nyí ní láti ṣe pẹ̀lú wa?”
20 Mo sọ báyìí fún wọn pé, “Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 21 Sọ fún ilé Israẹli, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, èmi yóò sọ ibi mímọ́ mi di ibi àìmọ́ tayọ agbára yín, ìfẹ́ ojú yín, ìkáàánú yín, àti ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin tí ẹ̀yin fi sílẹ̀ sẹ́yìn yóò ṣubú nípa idà. 22 Ẹyin yóò sì ṣe bí mo ti ṣe. Ẹ̀yin kì yóò bo ìsàlẹ̀ ojú yín tàbí jẹ oúnjẹ ti àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ń jẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà. 23 Ẹ̀yin yóò fi àwọn ọ̀já wé àwọn orí yín àti àwọn bàtà ni ẹsẹ̀ yín, ẹ̀yin kì yóò ṣọ̀fọ̀ tàbí sọkún, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò ṣòfò dànù nítorí àwọn àìṣedéédéé yín, ẹ̀yin yóò sì máa kérora láàrín ara yín. 24 Esekiẹli yóò jẹ ààmì fún un yín; ẹ̀yin yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe. Nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.’
25 “Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ, Ọmọ ènìyàn, kì yóò ha jẹ́ pé, ní ọjọ́ náà, nígbà ti mo bá gba agbára wọn, ayọ̀ wọn àti ògo wọn, ìfẹ́ ojú wọn, ohun tí wọn gbé ọkàn wọn lé, àti àwọn ọmọ ọkùnrin wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ obìnrin wọn kúrò lọ́dọ̀ wọn, 26 ní ọjọ́ náà ẹni tí ó bá sálà yóò tọ̀ ọ́ wá láti sọ ìròyìn náà fún ọ 27 Ní ọjọ́ náà ẹnu rẹ yóò sì ṣí; ìwọ yóò sọ̀rọ̀, ìwọ kì yóò sì yadi mọ́. Báyìí ìwọ yóò jẹ́ ààmì fún wọn; wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ní Olúwa.”
Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Ammoni
25 (A)Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 2 “Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí àwọn ará Ammoni kí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí wọn. 3 Sì wí fún àwọn ará Ammoni pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè tí ó wí pé: Nítorí tí ìwọ wí pé, “Á hà!” Sí ibi mímọ́ mi nígbà tí ó di àìlọ́wọ̀ àti sí orí ilẹ̀ Israẹli nígbà tí ó di ahoro; àti sí ilẹ̀ Juda, nígbà tí wọ́n lọ sí ìgbèkùn, 4 kíyèsi i, nítorí náà ni èmi yóò fi fi ọ lé àwọn ènìyàn ìlà-oòrùn lọ́wọ́ ni ohun ìní. Wọn yóò sì gbé ààfin wọn kalẹ̀ nínú rẹ, wọn yóò sì gbé ibùgbé wọn nínú rẹ: wọn yóò jẹ èso rẹ, wọn yóò sì mu wàrà rẹ. 5 Èmi yóò sì sọ Rabba di ibùjẹ, fún àwọn ìbákasẹ àti àwọn ọmọ Ammoni di ibùsùn fún agbo ẹran. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa. 6 Nítorí báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Nítorí pé ìwọ pàtẹ́wọ́, ìwọ sì jan ẹsẹ̀ mọ́lẹ̀, tí ìwọ ń yọ̀ pẹ̀lú gbogbo àrankàn rẹ sí ilẹ̀ Israẹli 7 nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mi lé ọ, èmi yóò sì fi ọ fún àwọn aláìkọlà fún ìkógun. Èmi yóò sì gé ọ kúrò láàrín àwọn ènìyàn, èmi yóò sì jẹ́ kí o parun kúrò ni ilẹ̀ gbogbo. Èmi yóò sì pa ọ́ run, ìwọ yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ”
Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Moabu
8 (B)“Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: ‘Nítorí pé Moabu àti Seiri sọ wí pé, “Wò ó, ilé Juda ti dàbí gbogbo àwọn kèfèrí,” 9 nítorí náà Èmi yóò ṣí Moabu sílẹ̀ láti àwọn ìlú gbogbo tí ó wà ní ààlà rẹ̀, ògo ilẹ̀ náà, Beti-Jeṣimoti, Baali-Meoni àti Kiriataimu. 10 Èmi yóò fi Moabu pẹ̀lú àwọn ará Ammoni lé àwọn ènìyàn ìlà-oòrùn ní ìní, kí a má bà á lè rántí àwọn ará Ammoni láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo; 11 Èmi yóò sì mú ìdájọ́ sẹ sí Moabu lára, wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ”
Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Edomu
12 (C)“Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí pé: ‘Nítorí pé Edomu gbẹ̀san lára ilé Juda, ó sì jẹ̀bi gidigidi nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, 13 nítorí náà báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí pé: Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Edomu èmi yóò sì pa àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko rẹ̀. Èmi yóò fi ṣófo láti Temani dé Dedani yóò ti ipa idà ṣubú. 14 Èmi yóò gbẹ̀san lára Edomu láti ọwọ́ àwọn ènìyàn mi Israẹli, wọn sì ṣe sí Edomu gẹ́gẹ́ bí ìbínú àti ìrunú mi: wọn yóò mọ̀ ìgbẹ̀san mi ní Olúwa Olódùmarè wí.’ ”
Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Filistia
15 (D)“Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí pé: ‘Nítorí tí àwọn ará Filistini hùwà ẹ̀san tí wọ́n sì gbẹ̀san pẹ̀lú odì ní ọkàn wọn, àti pẹ̀lú ìkórìíra gbangba àtijọ́ ní wíwá ọ̀nà láti pa Juda run, 16 nítorí náà báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí pé: Èmi ti ṣetán láti na ọwọ́ mi jáde sí àwọn ará Filistini, èmi yóò sì ké àwọn ará Kereti kúrò, èmi yóò sì pa àwọn tí ó kù ní etí kún run. 17 Èmi yóò sì gbẹ̀san ńlá lára wọn nípa ìbáwí gbígbóná; wọn yóò sì mọ̀ wí pé, Èmi ni Olúwa. Nígbà tí èmi yóò gba ẹ̀san lára wọn.’ ”
Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Tire
26 (E)Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kọ́kànlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 2 “Ọmọ ènìyàn, nítorí pé Tire sọ nípa Jerusalẹmu pé, ‘Háà! A fọ́ èyí tí í ṣe bodè àwọn orílẹ̀-èdè, a yí i padà sí mi, èmi yóò di kíkún, òun yóò sì di ahoro,’ 3 nítorí náà, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, èmí dojúkọ ọ́ ìwọ Tire, Èmi yóò sì jẹ́ kí orílẹ̀-èdè púpọ̀ dìde sí ọ, gẹ́gẹ́ bí Òkun tí ru sókè. 4 Wọn yóò wó odi Tire lulẹ̀, wọn yóò sì wo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀; Èmi yóò sì ha erùpẹ̀ rẹ̀ kúrò, Èmi yóò sì sọ ọ́ di orí àpáta. 5 Yóò sì jẹ́ ibi nína àwọ̀n tí wọn fi ń pẹja sí láàrín Òkun, ní Olúwa Olódùmarè wí. Yóò di ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè. 6 Ìlú tí ó tẹ̀dó sí, ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ rẹ̀ ni a ó fi idà sọ ọ́ di ahoro. Nígbà náà ní wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.
7 “Nítorí báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, láti ìhà àríwá ni èmi yóò ti mú Nebukadnessari ọba Babeli, ọba àwọn ọba, dìde sí Tire pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ológun. 8 Yóò sì fi idà sá àwọn ọmọbìnrin rẹ ní oko, yóò sì kọ́ odi tì ọ́, yóò sì mọ òkìtì tì ọ́, yóò sì gbé apata sókè sí ọ. 9 Yóò sì gbé ẹ̀rọ ogun tí odi rẹ, yóò sì fi ohun èlò ogun wó ilé ìṣọ́ rẹ palẹ̀. 10 Àwọn ẹṣin rẹ̀ yóò pọ̀ dé bí pé wọn yóò fi eruku bò ọ́ mọ́lẹ̀. Àwọn ògiri rẹ yóò mì tìtì fún igbe àwọn ẹṣin ogun kẹ̀kẹ́ ẹrù àti kẹ̀kẹ́ ogun nígbà tí ó bá wọ ẹnu-ọ̀nà odi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń wọ ìlú láti inú àwọn ògiri rẹ̀ ti ó di fífọ́ pátápátá. 11 Pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin rẹ̀ ni yóò fi tẹ gbogbo òpópónà rẹ mọ́lẹ̀; yóò fi idà pa àwọn ènìyàn rẹ, àwọn ọ̀wọ́n rẹ ti o lágbára yóò wó palẹ̀. 12 Wọn yóò kó ọrọ̀ rẹ, wọn yóò sì fi òwò rẹ ṣe ìjẹ ogun; wọn yóò sì wó odi rẹ lulẹ̀, wọn yóò sì ba àwọn ilé rẹ dídára jẹ́, wọn yóò sì kó àwọn òkúta rẹ̀, àti igi ìtì ìkọ́lé rẹ̀, àti erùpẹ̀ rẹ̀, dà sí inú Òkun. 13 (F)Èmi yóò sì mú ariwo orin rẹ̀ dákẹ́ àti ìró dùùrù orin rẹ̀ ni a kì yóò gbọ́ mọ́. 14 Èmi yóò sọ ọ di àpáta lásán, ìwọ yóò sì di ibi tí a ń sá àwọ̀n ẹja sí. A kì yóò sì tún ọ mọ nítorí èmi Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ ní Olúwa Olódùmarè wí.
15 “Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí Tire: Ǹjẹ́ àwọn erékùṣù kì yóò ha wárìrì nípa ìṣubú rẹ, nígbà tí ìkórìíra ìpalára àti rírẹ́ni lọ́run bá ń ṣẹlẹ̀ ní inú rẹ? 16 (G)Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ-aládé etí Òkun yóò sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ wọn, wọn yóò sì pa àwọn aṣọ ìgúnwà wọn da, tì wọn yóò sì bọ́ àwọn aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ kúrò. Ẹ̀rù yóò bò wọ́n, wọn yóò sì jókòó lórí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀, wọn yóò sì máa wárìrì ní gbogbo ìgbà, ẹnu yóò sì yà wọ́n sí ọ́. 17 Nígbà náà wọn yóò gbóhùn ẹkún sókè nítorí rẹ, wọn yóò sì wí fún ọ pé:
“ ‘Báwo ni a ṣe pa ọ́ run, ìwọ ìlú olókìkí
ìwọ tí àwọn èrò okun ti gbé inú rẹ̀!
Ìwọ jẹ alágbára lórí okun gbogbo
òun àti àwọn olùgbé inú rẹ̀;
ìwọ gbé ẹ̀rù rẹ
lórí gbogbo olùgbé ibẹ̀.
18 Nísinsin yìí erékùṣù wárìrì
ní ọjọ́ ìṣubú rẹ;
erékùṣù tí ó wà nínú Òkun
ni ẹ̀rù bà torí ìṣubú rẹ.’
19 “Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ìlú ahoro, gẹ́gẹ́ bi àwọn ìlú tí a kò gbé inú wọn mọ́, àti nígbà tí èmi yóò mú ibú agbami Òkun wá sí orí rẹ, omi ńlá yóò sì bò ọ́, 20 nígbà tí èmi yóò mú ọ wálẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ihò, pẹ̀lú àwọn ènìyàn àtijọ́. Èmi yóò sì gbé ọ lọ si bi ìsàlẹ̀, ní ibi ahoro àtijọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ihò, ìwọ kì yóò sì padà gbé inú rẹ̀ mọ́, èmi yóò sì gbé ògo kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn alààyè. 21 Èmi yóò ṣe ọ ní ẹ̀rù, ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́. Bí a tilẹ̀ wá ọ, síbẹ̀ a kì yóò tún rí ọ mọ́, ní Olúwa Olódùmarè wí.”
Ìpohùnréré ẹkún fún Tire
27 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 2 “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún fún Tire. 3 Sọ fún Tire, tí a tẹ̀dó sí ẹnu-bodè Òkun, oníṣòwò àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù. ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Ìwọ Tire wí pé
“Ẹwà mi pé.”
4 Ààlà rẹ wà ní àárín Òkun;
àwọn ọ̀mọ̀lé rẹ ti mú ẹwà rẹ pé.
5 Wọn ṣe gbogbo pákó rẹ
ní igi junifa láti Seniri;
wọ́n ti mú igi kedari láti Lebanoni wá
láti fi ṣe òpó ọkọ̀ fún ọ.
6 Nínú igi óákù ti Baṣani
ní wọn ti fi gbẹ́ ìtukọ̀ ọ̀pá rẹ̀;
ìjókòó rẹ ni wọn fi eyín erin ṣe pẹ̀lú
igi bokisi láti erékùṣù Kittimu wá
7 Ọ̀gbọ̀ dáradára aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ láti Ejibiti wá
ni èyí tí ìwọ ta láti fi ṣe àsíá ọkọ̀ rẹ;
aṣọ aláró àti elése àlùkò
láti erékùṣù ti Eliṣa
ni èyí tí a fi bò ó
8 Àwọn ará ìlú Sidoni àti Arfadi ni àwọn atukọ̀ rẹ̀
àwọn ọlọ́gbọ́n ẹ̀rọ rẹ, ìwọ Tire,
ni àwọn atukọ̀ rẹ.
9 Àwọn àgbàgbà Gebali,
àti àwọn ọlọ́gbọ́n ibẹ̀,
wà nínú ọkọ̀ bí òṣìṣẹ́ atukọ̀ rẹ,
gbogbo ọkọ̀ ojú Òkun
àti àwọn atukọ̀ Òkun
wá pẹ̀lú rẹ láti dòwò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.
10 “ ‘Àwọn ènìyàn Persia, Ludi àti Puti
wà nínú jagunjagun rẹ
àwọn ẹgbẹ́ ọmọ-ogun rẹ.
Wọ́n gbé asà àti àṣíborí wọn ró
sára ògiri rẹ,
wọn fi ẹwà rẹ hàn.
11 Àwọn ènìyàn Arfadi àti Heleki
wà lórí odi rẹ yíká;
àti àwọn akọni Gamadi,
wà nínú ilé ìṣọ́ rẹ.
Wọ́n fi àwọn asà wọn kọ ara odi rẹ;
wọn ti mú ẹwà rẹ pé.
12 “ ‘Tarṣiṣi ṣòwò pẹ̀lú rẹ torí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ tí ó ní; wọn ṣe ìpààrọ̀ fàdákà, irin idẹ àti òjé fún ọjà títà rẹ̀.
13 “ ‘Àwọn ará Giriki, Tubali, Jafani àti Meṣeki, ṣòwò pẹ̀lú rẹ: wọ́n fi ẹrù àti ohun èlò idẹ ṣe pàṣípàrọ̀ fún ọrọ̀ rẹ.
14 “ ‘Àwọn ti ilé Beti-Togarma ṣe ìpààrọ̀ ẹṣin-ìṣiṣẹ́, ẹṣin ogun àti ìbáaka ṣòwò ní ọjà rẹ.
15 “ ‘Àwọn ènìyàn Dedani ni àwọn oníṣòwò rẹ, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù ni wọ́n jẹ́ oníbàárà rẹ̀; wọ́n mú eyín erin àti igi eboni san owó rẹ.
16 “ ‘Aramu ṣòwò pẹ̀lú nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ òwò rẹ̀; wọn ṣe ìpààrọ̀ (turikuoṣe) òkúta iyebíye, òwú elése àlùkò, aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́, aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ìlẹ̀kẹ̀ iyùn pupa fún ọjà títà rẹ.
17 “ ‘Juda àti Israẹli, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọn ṣe ìpààrọ̀ ọkà, Minniti, àkàrà àdídùn; pannagi, oyin, epo àti ìkunra olóòórùn dídùn ni wọ́n fi ná ọjà rẹ.
18 “ ‘Damasku, ni oníṣòwò rẹ, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọjà tí ó ṣe àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀; ní ti ọtí wáìnì tí Helboni, àti irun àgùntàn funfun láti Sahari, 19 àti ìdẹ̀ ọtí wáìnì láti Isali, ohun wíwọ̀: irin dídán, kasia àti kálàmù ni àwọn ohun pàṣípàrọ̀ fún ọjà rẹ.
20 “ ‘Dedani ni oníṣòwò rẹ ní aṣọ ìjókòó-lẹ́sin fún ẹṣin-gígùn.
21 “ ‘Àwọn ará Arabia àti gbogbo àwọn ọmọ-aládé Kedari àwọn ni àwọn oníbàárà rẹ: ní ti ọ̀dọ́-àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́, nínú ìwọ̀nyí ni wọ́n ti jẹ́ oníbàárà rẹ.
22 “ ‘Àwọn oníṣòwò ti Ṣeba àti Raama, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọ́n ta onírúurú tùràrí olóòórùn dídùn dáradára ní ọjà rẹ, àti àwọn òkúta iyebíye àti wúrà.
23 “ ‘Harani àti Kanneh àti Edeni, àwọn oníṣòwò Ṣeba, Asiria àti Kilmadi, ni àwọn oníṣòwò rẹ. 24 Wọ̀nyí ní oníbàárà rẹ ní onírúurú nǹkan: aṣọ aláró, àti oníṣẹ́-ọnà àti àpótí aṣọ olówó iyebíye, tí a fi okùn dì, tí a sì fi igi Kedari ṣe, nínú àwọn ilé-ìtajà rẹ.
25 “ ‘Àwọn ọkọ̀ Tarṣiṣi ní èrò
ní ọjà rẹ
a ti mú ọ gbilẹ̀
a sì ti ṣe ọ́ lógo
ní àárín gbùngbùn Òkun
26 Àwọn atukọ̀ rẹ ti mú ọ
wá sínú omi ńlá.
Ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn yóò fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́
ní àárín gbùngbùn Òkun.
27 Ọrọ̀ rẹ, ọjà rẹ àti àwọn ohun títà rẹ,
àwọn ìṣúra rẹ, òṣìṣẹ́ ìtukọ̀ rẹ.
Àwọn oníbàárà rẹ àti gbogbo àwọn
jagunjagun rẹ, tí ó wà nínú rẹ
àti nínú gbogbo ẹgbẹ́ rẹ
tí ó wà ní àárín rẹ
yóò rì sínú àárín gbùngbùn Òkun
ní ọjọ́ ìparun rẹ.
28 Ilẹ̀ etí Òkun yóò mì
nítorí ìró igbe àwọn atukọ̀ rẹ.
29 Gbogbo àwọn alájẹ̀,
àwọn atukọ̀ Òkun
àti àwọn atọ́kọ̀ ojú Òkun;
yóò sọ̀ kálẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ wọn,
wọn yóò dúró lórí ilẹ̀.
30 Wọn yóò jẹ́ kí a gbọ́ ohùn wọn lòdì sí ọ
wọn yóò sì sọkún kíkorò lé ọ lórí
wọn yóò ku eruku lé orí ara wọn
wọn yóò sì yí ara wọn nínú eérú.
31 Wọn yóò fá irun orí wọn nítorí rẹ
wọn yóò wọ aṣọ yíya
wọn yóò pohùnréré ẹkún pẹ̀lú
ìkorò ọkàn nítorí rẹ
pẹ̀lú ohùn réré ẹkún kíkorò.
32 Àti nínú arò wọn ni wọn yóò sì pohùnréré ẹkún fún ọ
wọn yóò sì pohùnréré ẹkún sórí rẹ, wí pé:
“Ta ni ó dàbí Tire
èyí tí ó parun ní àárín Òkun?”
33 Nígbà tí ọjà títà rẹ ti Òkun jáde wá
ìwọ tẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè lọ́rùn
ìwọ fi ọrọ̀ tí ó pọ̀ àti àwọn ọjà títà rẹ
sọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀.
34 Ní ìsinsin yìí tí Òkun fọ ọ túútúú
nínú ibú omi;
nítorí náà òwò rẹ àti gbogbo ẹgbẹ́ rẹ
ní àárín rẹ,
ni yóò ṣubú.
35 Ẹnu yóò ya gbogbo àwọn ti ń gbé
ní erékùṣù náà sí ọ
jìnnìjìnnì yóò bo àwọn ọba wọn,
ìyọnu yóò sì han ní ojú wọn.
36 Àwọn oníṣòwò láàrín àwọn orílẹ̀-èdè dún bí ejò sí ọ
ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù
ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́ láéláé.’ ”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.