Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Esekiẹli 18-19

Ọkàn tí o bá sẹ̀ ni yóò kú

18 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: (A)“Kín ni ẹ̀yin rò tí ẹ̀yin fi ń pa òwe nípa Israẹli wí pé:

“ ‘Àwọn baba ti jẹ èso àjàrà kíkan,
    eyín àwọn ọmọ sì kan.’

“Bí mo ti wà láààyè ni Olúwa Olódùmarè wí, ẹ̀yin kí yóò pa òwe yìí mọ́ ni Israẹli. (B)Nítorí pé èmi ló ní gbogbo ọkàn, ọkàn baba tèmi bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ọmọ pàápàá jẹ tèmi, ọkàn tó bá ṣẹ̀ ní yóò kú.

“Bí ọkùnrin olódodo kan bá wà,
    tó ń ṣe ohun tó tọ́, tó sì yẹ
tí kò bá wọn jẹun lórí òkè gíga,
    tí kò gbójú rẹ̀ sókè sí àwọn òrìṣà ilẹ̀ Israẹli,
ti kò sì ba obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́
    tàbí kí ó sùn ti obìnrin ni àsìkò èérí rẹ̀.
Kò sì ni ẹnikẹ́ni lára,
    ó sì sanwó fún onígbèsè rẹ̀
gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣe ìlérí fún un,
    kò fi ipá jalè
ṣùgbọ́n ó fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ,
    tí ó sì fi ẹ̀wù wọ àwọn tí ó wà ní ìhòhò.
Ẹni tí kò fi fún ni láti gba ẹ̀dá,
    tàbí kò gba èlé tó pọ̀jù.
Ó yọ ọwọ́ rẹ̀ kúrò nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀,
    ó sì ń ṣe ìdájọ́ òtítọ́ láàrín ọkùnrin kan àti èkejì rẹ̀.
Tí ó ń tẹ̀lé àṣẹ mi,
    tí ó sì ń pa òfin mi mọ́ lóòtítọ́ àti lódodo.
Ó jẹ́ olódodo,
    yóò yè nítòótọ́,
    Olúwa Olódùmarè wí.

10 “Bí ó bá bi ọmọkùnrin, oníwà ipá, tó ń jalè, tó tún ń pànìyàn, tó sì ń ṣe gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí sí arákùnrin rẹ̀ 11 (tí kò sì ṣe ọ̀kan nínú gbogbo iṣẹ́ wọ̀n-ọn-nì):

“Ó ń jẹun lójúbọ lórí òkè gíga,
tí ó sì ba obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́.
12 Ó ni àwọn tálákà àti aláìní lára,
ó ń fipá jalè, kì í dá padà gẹ́gẹ́ bí ìlérí,
o gbójú sókè sí òrìṣà,
ó sì ń ṣe ohun ìríra.
13 Ó ń fi owó ya ni pẹ̀lú èlé, ó sì tún ń gba èlé tó pọ̀jù.

Ǹjẹ́ irú ọkùnrin yìí wa le è yè bí? Òun kì yóò wá láààyè! Nítorí pé òun ti ṣe àwọn ohun ìríra yìí, kíkú ni yóò kú, ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wá lórí rẹ̀.

14 “Bí ọkùnrin yìí bá bímọ ọkùnrin, tó sì rí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ti baba rẹ ń ṣẹ̀ yìí, tó sì bẹ̀rù, ti kò ṣe irú rẹ̀:

15 “Tí kò jẹun lójúbọ lórí òkè gíga
    tàbí kò gbójú sókè sí àwọn òrìṣà ilé Israẹli,
tí kò sì ba obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́
16 tí kò sì ni ẹnikẹ́ni lára,
    tí kò dá ohun ògo dúró
tí kò gba èlé tàbí kò fipá jalè
    ṣùgbọ́n tí ó ń fún ẹni tébi ń pa lóúnjẹ,
    tó sì fi aṣọ bo àwọn oníhòhò.
17 Ó ń yọ ọwọ́ rẹ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀,
    kò sì gba èlé tàbí èlé tó pọ̀jù,
tí ó ń pa òfin mi mọ́,
    tí ó sì ń tẹ̀lé àwọn àṣẹ mi.

Kò ní kú fún ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, nítòótọ́ ní yóò yè! 18 Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀, nítorí pé ó jẹ́ arẹ́nijẹ, ó jalè arákùnrin rẹ, ó ṣe ohun tí kò dára láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

19 “Síbẹ̀, ẹ tún ń béèrè pé, ‘Kí ló dé ti ọmọ kò fi ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀?’ Níwọ́n ìgbà tí ọmọ ti ṣe ohun tó tọ́, tó sì yẹ, tó sì ti kíyèsi ara láti pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, nítòótọ́ ni pé yóò yè. 20 Ọkàn tí ó bá ṣẹ̀ ní yóò kú. Ọmọ kò ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni baba náà kò ní ru ẹ̀bi ọmọ rẹ̀. Ìwà rere ènìyàn rere yóò wà lórí rẹ̀, ìwà búburú ti ènìyàn búburú náà la ó kà sí i lọ́rùn.

21 “Ṣùgbọ́n bí ènìyàn búburú bá yípadà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tó ti dá, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa àṣẹ mi mọ́, tó sì ń ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó yẹ, nítòótọ́ ni yóò yè, kò sì ní kú. 22 A kò sì ní rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tó ti dá tẹ́lẹ̀ láti kà á sí lọ́rùn nítorí tí ìwà òdodo rẹ tó fihàn, yóò yè 23 Ǹjẹ́ èmi ha ni inú dídùn si ikú ènìyàn búburú bí í? Ní Olúwa Olódùmarè wí pé, dípò èyí inú mi kò ha ni i dùn nígbà tó ba yípadà kúrò ni àwọn ọ̀nà búburú rẹ̀ kí ó sì yè?

24 “Ṣùgbọ́n bí ènìyàn rere bá yípadà kúrò ni ọ̀nà òdodo rẹ̀ tó sì ń dẹ́ṣẹ̀, tí ó sì tún ń ṣe àwọn ohun ìríra tí ènìyàn búburú ń ṣe, yóò wa yè bí? A kì yóò rántí ọ̀kankan nínú ìwà rere rẹ̀ mọ́, nítorí ó ti jẹ̀bi ìwà àrékérekè àti ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, yóò sì kú.

25 “Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀yin tún wí pe, ‘ọ̀nà Olúwa kò gún.’ Gbọ́ nísinsin yìí ìwọ ilé Israẹli: ọ̀nà mi ni kò ha gún? Kì í wa ṣé pé ọ̀nà tiyín gan an ni kò gún? 26 Bí olódodo ba yípadà kúrò nínú olódodo rẹ̀, tó sì dẹ́ṣẹ̀, yóò ku fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá. 27 Ṣùgbọ́n bi ènìyàn búburú bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú tó ti ṣe, tó sì ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó yẹ, yóò gba ẹ̀mí rẹ̀ là. 28 Nítorí pé ó ronú lórí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá, ó sì yípadà kúrò nínú wọn, nítòótọ́ ni yóò yè; kì yóò sí kú 29 Síbẹ̀, ilé Israẹli wí pé, ‘Ọ̀nà Olúwa kò gún.’ Ọ̀nà mi kò ha tọ́ bí ilé Israẹli? Kì í wa ṣe pè ọ̀nà tiyín gan an ni ko gún?

30 “Nítorí náà, ilé Israẹli, èmi yóò da yín lẹ́jọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ẹnìkọ̀ọ̀kan yín bá ṣe rí ni Olúwa Olódùmarè wí. Ẹ yípadà! Kí ẹ si yí kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni ìrékọjá kì yóò jẹ́ ọ̀nà ìṣubú yín. 31 (C)Ẹ kọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ti ẹ ti dá sílẹ̀, kí ẹ sì gba ọkàn àti ẹ̀mí tuntun. Nítorí kí ló fi máa kú, ilé Israẹli? 32 (D)Nítorí pé inú mi kò dùn sí ikú ẹnikẹ́ni ni Olúwa Olódùmarè wí. Nítorí náà, ẹ yípadà kí ẹ sì yè!

Orin ọfọ̀ nítorí àwọn ọmọ-aládé Israẹli

19 “Kọ orin ọ̀fọ̀ nítorí àwọn ọmọ-aládé Israẹli wí pé:

“ ‘Èwo nínú abo kìnnìún ni ìyá rẹ̀ ní àárín àwọn kìnnìún yòókù?
    Ó sùn ní àárín àwọn ọ̀dọ́ kìnnìún ó sì ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.
Ó sì tọ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà, ó sì di kìnnìún tó ní agbára,
    ó kọ́ ọ láti ṣọdẹ, ó sì ń pa àwọn ènìyàn jẹ.
Àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́ nípa rẹ̀,
    wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n mú un nínú iho wọn.
    Wọn fi ẹ̀wọ̀n mu nu lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.

“ ‘Nígbà tí abo kìnnìún yìí rí pé ìrètí rẹ̀ sì jásí asán,
    ó mú ọmọ rẹ̀ mìíràn ó sì tún tọ́ ọ dàgbà di kìnnìún tó ní agbára.
Ó sì ń rìn káàkiri láàrín àwọn kìnnìún nítorí pé ó ti lágbára,
    o kọ ọdẹ ṣíṣe, ó sì pa àwọn ènìyàn.
Ó sì wó odi wọn palẹ̀ ó sì sọ àwọn ìlú wọn di ahoro.
    Ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé ibẹ̀ sì wà ní ìpayà nítorí bíbú ramúramù rẹ̀.
Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè dìde sí i,
    àwọn tó yìí ká láti ìgbèríko wá.
Wọn dẹ àwọ̀n wọn fún un,
    wọn sì mú nínú ihò wọn.
Wọn fi ìwọ̀ gbé e sínú àgò, wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli,
    wọn fi sínú ìhámọ́, a kò sì gbọ́ bíbú rẹ̀ mọ́ lórí òkè Israẹli.

10 “ ‘Ìyá rẹ dàbí àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ̀;
    tí á gbìn sí etí odò ó, kún fún èso,
    ó sì kún fún ẹ̀ka nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi,
11 Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lágbára tó láti fi ṣe ọ̀pá àṣẹ ìjòyè,
    ó ga sókè láàrín ewé rẹ̀,
    gíga rẹ̀ hàn jáde láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ka rẹ̀.
12 Ṣùgbọ́n ó fà á tu ní ìrunú,
    á sì wọ́ ọ lulẹ̀,
afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn sì gbé èso rẹ̀,
ọ̀pá líle rẹ̀ ti ṣẹ́, ó sì rọ
    iná sì jó wọn run.
13 Báyìí, a tún ún gbìn sínú aṣálẹ̀
    ni ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tó ń pòǹgbẹ omi.
14 Iná sì jáde láti ọ̀kan lára ẹ̀ka rẹ̀
    ó sì pa ẹ̀ka àti èso rẹ̀ run,
dé bi pé kò sí ẹ̀ka tó lágbára lórí rẹ̀ mọ́;
    èyí to ṣe fi ṣe ọ̀pá fún olórí mọ́.’

Èyí ni orin ọ̀fọ̀ a o sì máa lo bí orin ọ̀fọ̀.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.